Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara
[ Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara ]

·Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
·Arungun Loko Mi, Gbogbo Irinse Mi Lo Ti Baje, Mi O Fe e Mo — Abigail
·Oko Mi Fi Pata Mi Soogun Owo — Philomina
·Emi Atoko Mi Ko Ja, Nitori Omo Lawon Ebi Re Se Fee Le Mi Jade - Rafia
·Latodun Merin Seyin Loko Mi Ko Ti Ba Mi Lasepo, Mi o Se Mo - Folasade
·Odo Ni Wolii Moses Ti Ni Ki David Loo We Iwe Isegun, Lo Ba Fogbon Ji Moto Re Gbe
·Oro Buruku Toun Terin: Awon Omo Poli Ojere Mefa Daku Lakooko Ti Won Fee Sedanwo
·O Sele L'Egba! Seun Bimo Kan Fokunrin Meji L'Abeokuta
·Babalawo Fewon Jura Lori Esun Aini Salanga L'Ondo

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Gbigba Kadara Gbo - Al-Imaan Bi-l-Qadar (Ayanma Tabi Akosile)
 
 
Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun Abala Ti Akojopo

Gbigba Kadara Gbo - Al-Imaan Bi-l-Qadar (Ayanma Tabi Akosile)

Eko ni soki
Kosi isinmi beeni kosi ifayabale fun eru ayafi ki o ni igbagbo si ebubu Olohun ati kadara re, eleyi ni ki o gbagbo wipe ohun ti Olohun ba fe ki o se, ni yio se,ohun ti ko baa fe ki o se,ki yio se,atiwipe, dajudaju, ti gbogbo aye yii ba parapo lori atifi inira kan-an, won ko lee se bee, ayafi ohun ti Olohun ba ti ko sile le lori, ni idakeji, ti won baa korajo lati se e ni anfaani, won ko le se bee, ayafi ohun ti Olohun ba ti ko sile fun-un.

Oripa (Koko Alaiye):

Alayẹ lori paapaa igbagbọ ninu kadara atipe orígun kan lo jẹ ninu awọn orígun igbọlọhun gbọ.
Alayẹ nipa pe kadara kose fise ikẹwọ lọri ẹsẹ dida.
Ojuse ẹniti ohunti ko tẹẹ lọrun ba sẹlẹ sii ninu kadara.
Awọn oore to mbẹ nibi inigbagbọ ninu kadara.
Isọra kuro nibi ìròrí awọn ẹni anù nibi kadara.


Apa Kini

الحمد لله رب العالمين , خلق كل شيئ فقّدره تقديرا, وقال في محكم تنزيله: " إنا خلقنا الإنسان من نطفة أمشاج نبتليه فجعلنه سميعا بصيرا (1) إنا هديناه السبيل إما شاكرا وإما كفورا" وأشهد أن لا إله ألا الله وحده لا شريك له, سبحانه وتعالى عما يقول الظالمون علوا كبيرا , وأشهد أن محمدا عبده ورسوله بعثه شاهدا وبشيرا ونذيرا, وداعيا إلى الله بإذنه وسراجا منيرا, صلّ الله عليه وعلى آله وأصحابه وسلم تسليما كثيرا – أما بعد

Ọpẹ ni fun Ọlọhun, ọba to sẹda gbogbo agbaye. O da gbogbo nkan, O si pebubu rẹ daada , O sọ ninu tira Rẹ rẹ pe: Dajudaju Awa ni A da eniyan lati ara omi gbọlọgbọlọ ti a ropọ mọ ara wọn, ki a le baa dan an wo, nitorinaa ni A se ni olugbọrọ Oluriran. Dajudaju A ti fi mọ ọna ti o tọ taara: O le jẹ oluse ọpẹ, o si le jẹ alaimore” Suratul Insani: 2 – 3.


Mọ jẹri pe: ko si ẹnikankan ti ijọsin ododo yẹ ayafi Ọlọhun nikan soso, ko ni orogún bẹni o si mọ tayọ ohunti awọn ọsẹbo nsọ nipa Rẹ. Mo si tun gba lododo pe Annọbi wa Muhammad ẹrusin Ọlọhun ni, ojisẹ Rẹ si ni, Ọlọhun ran ni olujẹri, olufinni ni iro idunnu olukininilọ ati olùpèpè si oju ọna Ọlọhun pẹlu iyọnda Re. Ikẹ Ọlọhun ati igẹ Rẹ ki o maa ba Anọbi ati awọn ara ile rẹ ati awọn ẹmẹwa rẹ ni ikẹ ti o pọ.

Akori khutuba toni yii tobi pupọ, toripe o da lori ọkan ninu awọn orígun igbagbọ mẹfẹẹfa, leyi to sepe ẹniti o ba kuna nipa rẹ Ọlọhun ko ni tẹwọ gba isẹ rẹ, akori naa ni inigbagbọ ninu kadara. Nipasẹ rẹ leeyan lefi ni ifọkanbalẹ, bẹni o jẹ idahun fun ọpọlọpọ ibere. Wo suratul Kọmari: 49 ati suratul Ala: 1-3 ati Suratul Furkoni: 1-2.

Ninu adisi to lalafia ojisẹ Ọlọhun sẹ alaye fun mọlaika Jibril to wa laworan eniyan to si bii lere nipa igbagbọ: igbagbọ ni ki a gba Ọlọhun gbọ ati awọn molaika Rẹ, ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ ati ọjọ alukiyamọ ati kadara ore rẹ ati aburu rẹ. “O sọ pe: òdodo lo sọ”.

Inigbagbọ ninu kadara ni inigbagbọ si imọ Ọlọhun to ti siwaju gbogbo nkan ki nkan naa to sẹlẹ, ati akosilẹ Rẹ fun gbogbo nkan ti yoo sẹlẹ ki o to sẹlẹ, ati siwaju ki o to da sanmo mejeeje ati ilẹ mejeeje, ni bii ẹgbẹrun odun lọna aadọta (50,000), atipe gbogbo ohunti Ọlọhun ba fẹ ko sẹlẹ ni yoo sẹlẹ bẹẹni o si da gbogbo nkan.

Mumini gbudọ nigbagbọ pe gbogbo ohunti o nsẹlẹ ko sajoji ninu imo Ọlọhun bẹni kosi baa lẹja fu u, bẹni ko salaimọ nipa rẹ ko to sẹlẹ, atipe Ọlọhun gbero dida awọn nkan, O si nimọ nipa rẹ siwaju, o si sẹlẹ nibamu si bọlọhun sẹ mọọ.

Bẹni muminu gbudọ nigbagbọ pe Ọlọhun ti kọ akọsilẹ gbogbo nkan sinu (laohil maafus) siwaju dida sanmọ mejeeje ati ilẹ, nibi ẹgbẹrun lọna aadọta ọdun (50,000) gẹgẹ bi ojisẹ Ọlọhun sẹ salaye rẹ ninu awọn adiisi to lalafia ati bi Ọlọhun se salaye rẹ ninu suratul Hadid : 22.

{مَا أَصَابَ مِنْ مُصِيبَةٍ فِي الْأَرْضِ وَلا فِي أَنْفُسِكُمْ إِلَّا فِي كِتَابٍ مِنْ قَبْلِ أَنْ نَبْرَأَهَا إِنَّ ذَلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرٌ}.

“Adanwo kan ko nii sẹlẹ ni ori ilẹ tabi ninu ara yin ayafi ki o maa bẹ ninu Tira kan siwaju ki a to muu jade dajudaju eyi jẹ irọrun fun ọlọhun”.

Tobari bẹẹ a jẹ pe: igbagbọ ninu kadara ni inigbagbọ pe ohun ti Ọlọhun ba fẹ ko sẹlẹ ni yoo sẹlẹ, ohun ti ko ba si fẹ ko sẹlẹ, ko lẹ sẹlẹ atipe bi awọn ẹniyan ba pejọ lati se nkan sugbọn ti Ọlọhun ko lọwọ sii, nkan naa ko ni seése. Wo suratul Insan: 30 – 31.

Ki o si ni igbagbọ pe Ọlọhun kii jẹniyan nipa sisẹ, buruku tabi rere, bi ko se pe Olusẹsa daada tabi aida lọmọniyan nibi kadara. O le sẹsa rere, o si lẹ sẹ sa ibi. Wo Suratul Baladi: l0 ati Suratul Samsi: 9 - 10.

"وَلِسَاناً وَشَفَتَيْنِ (9) وَهَدَيْنَاهُ النَّجْدَيْن".

“Ati ahọn kan ati ete meji atipe A wa ti fi ọna meji ti o yanju mọ ọ”

Imọ Ọlọhun to siwaju gbogbo nkan ko tu mọ si ijẹni-nipa sugbọn ki o le jẹ ibalẹjọ fun ọmọniyan atipe nkankan koni sẹlẹ a fi ki Ọlọhun ti nimọ nipa rẹ. Wo suratul Asabi: 40.

"وَكَانَ اللَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيما".

Isọkusọ iwikuwi ati asise nla ni ifi kadara se ikẹwọ lọri dida ẹsẹ ja si tori awọn idi to mbọ yii.

1. Bi a ba gbagbọ pe kadara see se ikẹwọ lọri dida ẹsẹ, koyẹ ki a bu alàbòsí ẹda, ole, onisina, apaniyan, obilẹjẹ lọri asemase wọn toripẹ kadara lọ faa.

2. Bi kadara ba see fise ikẹwọni, Asetani, firiaona ijọ Nuhu ati Adi ti Ọlọhun ti parun, ki ba ro arojare niwaju Ọlọhun, bẹni iru ọrọ yii si jẹ iwa aigbọlọhun gbọ.

3. To ba se e se ikẹwọ, ko ba ti si iyatọ laarin ẹnirere ati ẹniburuku, laarin ọmọ alujana ati ọmọ ina, ati laarin ọrẹ Ọlọhun ati ọta Rẹ sugbọn ẹyi tako ọrọ Ọlọhun. Wo suratal Fatir; 19 - 22 ati suratu Sọdi: 28 ati suratu jasiya: 21 idi niyi ti yoruba fi sọ pẹ “Àgbò kii sẹgbẹ ọda”.

"وَمَا يَسْتَوِي الْأَعْمَى وَالْبَصِيرُ(19) وَلا الظُّلُمَاتُ وَلا النُّورُ(20) وَلا الظِّلُّ وَلا الْحَرُور".

4. Atipe wọn bi ojisẹ Ọlọhun nipa rẹ, o si dawọn lohun pe: ko si ẹniti wọn ko tii kọ àyè rẹ ninu alujana ati àyè rẹ ninu ina, lawọn sahabẹ ba sọ pẹ ewo la wulẹ nsisẹ si? Ti a ko wulẹ gbe ara le akọsilẹ naa? Ojisẹ Ọlọhun dahun pe: Rara o ẹ maa sisẹ toripẹ kaluku ni Ọlọhun yoo Rọ fun ohunti o ba tori rẹ daa. Buhari ati Musilimu.

Ninu adiisi miran wọn sọ pẹ : Irẹ Ojisẹ Ọlọhun se alaye fun wa nipa isẹ ati wahala ti eniyan nse, se lọri ohun ti Ọlọhun ti kọ silẹ to ti pari ni, tabi awọn isẹ ti a sẹsẹ nse? Ojisẹ Ọlọhun dahun pe: biko sepe lori ohun ti Ọlọhun ti kọ silẹ ni, awọn sahabẹ ba sọ pe kinni a wulẹ nda arawa lamu sisẹ fun? Ojisẹ Ọlọhun (SAW) si sọ pe: ẹ maa sisẹ kaluku ni Ọlọhun yoo rọ fun ohunti o tori rẹ daa.

5. Tabi ki a dahun pẹ: latari pe Ọlọhun ti nimọ nipa gbogbo nkan, o si kọọ silẹ nibamu si bi yoo se jẹ, idi ni yi to fi kọọ silẹ pe lagbaja yoo gbọlọhun gbọ, yoo si sisẹ rere, yoo si wọ alujana, bẹni lamorin yoo yapa asẹ Ọlọhun, yoo huwa poki, yoo si wọna, bẹẹna ni dòólà yoo fẹyawo yoo baa lasepo yoo si di ọmọ, ẹniti o ba sọ pe bọlọhun ba ni n o wọ alujana, n o wọọ, kódà bi n o sisẹ kankan, ọrọ rirun ni onitohun nsọ jadẹ lẹnu, kódà o tako kadara toripe ọrọ rẹ nigbana bii ti ẹniti o nreti ọmọ, sugbọn ti ko fẹ iyawo ni.

O jẹ ọranyan fun ẹniti kadara ti ko dara sẹlẹ si ki o yara se atẹmọra, ati ifarada, ki o si yọnu si isẹlẹ naa, ki o si sẹri ọkan ati ara si ọdọ Ọlọhun.

Diẹ ninu awọn anfani ti a o ri bi a ba gba kadara gbọ

1. Gbigbe ara lọlọhun tòdodo tòdodo ọmọniyan yoo nigbagbọ pe: Ohun ti o ba sẹlẹ si oun, kosi ninu kadara pe yoo fo oun ru ni.

2. Ifọkanbalẹ ninu ẹmi pẹlu ibalẹ ọkan.

3. Onitọhun koni jọ ara rẹ loju, toripe gbogbo ohun ti ẹda nse nisẹ Ọlọhun lọ njẹ ki o rii se.

Ẹri awọn anfani wọnyi:-

Ọlọhun sọ pe:

"مَا أَصَابَ مِنْ مُصِيبَةٍ إِلَّا بِإِذْنِ اللَّهِ وَمَنْ يُؤْمِنْ بِاللَّهِ يَهْدِ قَلْبَهُ وَاللَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيم".

Adanwo ko le sẹlẹ ayafi pẹlu iyọnda ti Ọlọhun, atipe ẹnikẹni ti o ba gba Ọlọhun gbọ yoo fi ọkan rẹ mọnà, Ọlọhun ni Onimimọ gbogbo nkan. Wo suratu Tagọbuni 11 ati Hadid: 22.

Ọlọhun tun sọ pe: {الَّذِينَ آمَنُوا وَتَطْمَئِنُّ قُلُوبُهُمْ بِذِكْرِ اللَّهِ}

"Awọn ni ẹniti nwọn gbagbọ ti ọkan wọn si balẹ si iranti Ọlọhun, jẹ ki nsọ fun ọ pẹlu iranti Ọlọhun ni awọn ọkan fi nbalẹ" suratu Radu: 28.

Ojisẹ Ọlọhun (SAW) sọ pe: “Jẹki o di mimọ fun ọ, pẹ bi gbogbo aye ba fi orí ikoko sọọdúnrún (fẹnuko) lati fi inira kan ọ, wọn o lee fi ara kan ni ọ, ayafi ohunti o ba wa ninu akọsilẹ Ọlọhun, bakannaa bi wọn ba pejọ lati se ọ ni ore kan, wọn o ni ikapani lati se ọ ni ore, ayafi ohun ti Ọlọhun ba ti kọ tẹlẹ pe yoo sẹlẹ si ọ” Ojisẹ Ọlọhun (SAW) tun sọ pe : Mumini to lagbara loore, Ọlọhun si nifẹ sii ju mumini to jẹ ọlẹ lọ, bọtilẹjẹpe ore mbẹ lara awọn mejeeji, maa sapá lori ohunti yoo se o ni anfani ki o si maa wa iranlọwọ Ọlọhun, ma se kágara, bi aidara ba sẹlẹ si ọ, masẹ sọ pe: ti mo ba se bayi ni ko bari bayi, sugbọn sọ pe kadara ti ko, ohunti Ọlọhun ba si fẹ ni yoo sẹ, toripẹ sisọ bẹẹ nsi ilẹkun fun esu ni “Musilimu.

Ojisẹ Ọlọhun (SAW) tun sọ pe: Ẹ sèémò nipa ọrọ mumini, gbogbo alamori ọrọ rẹ ore ni, bẹni ko si eleyi fun ẹnikan kan ayafi musulumi, bi iduunu ba sẹlẹ sii, yoo dupẹ fọlọhun, yoo si jẹ ore fun-un, bi inira ba si de baa yoo se ifarada yoo si jẹ ore fun-un. Musilimu Ahmad ati ibinu Mojaha lọ gba wa.

Apa Keji

Ẹyin musulumi, njẹ ẹ mo pẹ awọn ikọ meji kan ti dẹni anu latipasẹ kadara ikọ kinni-in: kọdiriyya, awọn ni ikọ ti o sọ pe kosi kadara, ti wọn sọ pe ọtun ni gbagbọ nkan.

Ikọ kẹji ni “Aljabriyyatu awọn ni sọ pe ọmọniyan dabi iyẹ adirẹ ti atẹgun ndari kaa kiri.

Ikọ mejeeji ti sina kódà wọn ti sọnu pẹlu, lotitọ ni pe Ọlọhun ti mọ gbogbo nkan ti o si se akọsilẹ rẹ, ti nkan kan ko si nii sẹlẹ ayafi ohunti Ọlọhun ba fẹ, pẹlu bẹẹ naa, ọmọniyan kii se ẹniti ko lero ati ifẹ, Ọlọhun sọ pe: "وَهَدَيْنَاهُ النَّجْدَيْنِ".

Atipe Awa ti fi ọna mẹji ti o yanju mọọ” Suratul Balad; 10 tun wo saratul Insani: 3.

Nitorinaa, irẹ musulumi jinna si awọn adisọkan radarada to yapa tira Ọlọhun ati ilana ojisẹ Rẹ, ki o si mọ pe Ọlọhun koni tẹwọ gbasẹ ẹniti o ba tako kadara.

Yahya ọmọ Yaamuru sọ pe: "Akọkọ ẹniti o kọkọ bu ẹnu atẹ lu kadara ni ilu Basira ni Maabadul-juani, ni mo ba gbera atemi ati Humaedu ọmọ Abdur Rahmon Alamri lati lọ se isẹ Haji tabi umrah, a wa njẹran ki a ba ẹnikan pade ninu awọn sahabe ojisẹ Ọlọhun, ki a lee bii leere nipa awọn to nbu ẹnu atẹ lu kadara, nigbati Ọlọhun yoo se e, laba pade Abdulọhi bun Umar ti o nwọ inu mọsalasi lọ, lemi ati ẹnikẹji mi ba lọ baa, ẹnikan duro lọtun, ẹnikẹji duro losi rẹ, ni mo ba bii leere pe. Irẹ baba Abdur Rahmon okiki awọn eniyan kan ma ti gbalẹ laarin wa, ti wọn nke Alkur’an ti wọn si …… wọn ni lẹmi pe ko si kadara, atipe Ọlọhun kò nimọ nipa gbogbo nkan ki o to sẹlẹ, ni Abdullọhi bunu Umar ba sọ pe: mo ti yọwọ ninu ọrọ rẹ, oun naa si ti yọwọ ninu ọrọ mi, o si fi Ọlọhun bura pe bi a ba ri ẹnikan ninu wọn, ti o na owó goolu ti o pọ, to si ga bi oke hudu soju ọna Ọlọhun, Ọlọhun koni gba lọwọ rẹ, ko si ni san an lẹsan rere titi yoo fi gba kadara gbọ. Lẹyin naa lo wa kaa adiisi Jibrilu to gbajumo yẹn, ti ojisẹ Ọlọhun fi salaye nipa orígun igbagbọ.

Ẹyin musulumi ẹ jẹki a gbẹkẹ lọlọhun, ẹniba gbẹkẹle E, Yoo to o, Yoo pese fun un nibi to lero ati ibi ti ko fọkan si, ẹ si tẹlẹ awọn ilana ti Ọlọhun la kalẹ lori gbogbo ohun ti ẹ ba nfẹ, ki ẹ gba pe dajudaju Ọlọhun nimọ nipa gbogbo nkan bẹni O si lagbara lorii rẹ.

A n bẹ Ọlọhun, ọba iyi, ọba to gbọngbọn ki o se wa lọkan ninu awọn onigbagbọ si idajọ ati ayanmọ Rẹ, bakanna ni ki o sewa lẹniti yoo le maa tẹle asẹ Rẹ ti yoo si jinna si ẹsẹ.

نسأل الله عز وجل أن يجعلنا من المؤمنين بقضائه وقدرهء والعاملين بطاعته التاركين لمعاصيه . اللهم أعزّ الإسلام والمسلمين , وأذلّ الشرك والمشركين , ودمّر أعداء الدين اللهم اجعل هذا البلد آمنا مطمئنا وسائر بلاد المسلمين عامة يا رب العالمين.
 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Saturday, October 12 @ 14:57:14 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun:
Onka Yoruba - Numbers In Yoruba: Figures And Counting, Kika Ni Yoruba Computes


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

"Gbigba Kadara Gbo - Al-Imaan Bi-l-Qadar (Ayanma Tabi Akosile)" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: