Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
[ Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu ]

·Deji Binu Si Titi Afesona Re, Lo Ba Dana Sun Eeyan Mesan Mole L'Ondo
·Victoria Fi Obe Gun Oko Re Pa; Ladajo Ba Ni Ki Won Loo Yegi Fun Un
·Awon Olopaa Fee Mu Baba Atiya Ti Won Lu Omo Won Pa L'Akure
·O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
·Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
·Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
·Nibi Ti Sunkanmi Ti N Gbeja Iya Re Lo Ti Gun Ojo Nigo Pa l'Ondo
·Tope To Pa Lanloodu e L'Ondo Ti Wa Lewon
·N'Igbokoda, Tegbon-taburo Ri Ore Meji Mole Laaye Nitori Ti Won Ji Iya Won L

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Igbesiaiye Ati Iku Oloselu: Bi Lamidi Onaolapo Adesina Lo Nile Yii, Omo Ayisatu
 
 
Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
Lati Owo Olawale Ajao ati Funke Adebiyi

Igbesiaiye Ati Iku Oloselu: Bi Lamidi Onaolapo Adesina Lo Nile Yii, Omo Ayisatu Asabi Se Lo Aiye Ati Bi O Se Deni Ile

Ti won ba n daruko asaaju oloselu ati eeyan gidi to ti sejoba nile yii ri, yala ninu awon to ti ku ni abawon to si wa laye, won ko le rin jinna ki won too daruko Lamidi Onaolapo Aremu omo Adesina. Okunrin jeje abija kunkun to se Gomina nipinle Oyo lojosi, to waa se bee to wo kaa ile lo loju wa.

Lam lawon eeyan mo on si, agekuru Lamidi to je oruko sunna re, nitori nile Musulumi ododo lo ti jade wa. Agba musulumi, lemoomu agba ni baba re ti i je Gbadamosi Olowoporoku Adesina nigba aye re, iyen ni mosalasi Odeku, Idi Arere, n’Ibadan. Iya to bi Lam naa ki i se keferi, Ayisatu Asabi Adesina niya naa n je, musulumi ododo ni. Obinrin naa lo bi Lamidi Onaolapo fun Gbadamosi logunjo ninu osu kin-in-ni, odun 1939.


Abule kekere kan ti won n pe ni Ikija, nijoba ibile Oluyole, ni won ti bi Lam, omo’badan ni. Lamidi labigbeyin iya re, oun nikan naa si lokunrin tiya naa ni, nitori omokunrin to bi tele e salaisi ni kekere, Lam sunmo iya re pupo, owo re lo si ti ko ka laya bii kinnihun, ka koriira ireje, Iya Lamidi ni awi-konko-koloro-o-gbo, ko gberegbe, ko gbawosi, bee ni ki i fejo segbe. Iwonyi naa ni Lam si mu to fi lo igbesi aye e lona to lapeere.

Afi ti kokoro ti ko je ki Lam gbadun obi to gbo, iku ti i ya ore meji lo fa ipinya oun ati iya re nigba ti Lamidi wa lomo odun mokanla pere.

Ko too di pe iya Lam ku lomo re ti bere ileewe kan to n je IkijaSeleru United Anglican Primary School, nijoba ibile Oluyole. Odun 1944 lo wo ileewe naa, o si kuro nibe ni 1950, nigba to ka a de Standadi tuu’ (Standard Two). Oko ni Lam ati iya re n gbe ki iya naa too ku, nigba tiyaa ku tan l’Aremu dero igboro Ibadan. Ileewe to lo nibe ni won n pe ni St.

Luke’s Demonstration School, ni Molete, sugbon nitori pe ileewe yii ko de ipele kefa, omodekunrin to feran eko naa gbiyanju lati wole iwe mi-in toruko re n je St. Davies, n’Ibadan, nibe, n lawon iyen ba tun ko lati gba a wole, won ni tori pe ki i se elesin kristeni, esin musulumi to n se yen ko dodo awon.

Bee ni tododo, Lamidi mowe pupo, o jafafa, o si gbon bi kinla. Ileewe ti won ti ko ti won ko gba a yii, ipo keji lo se ninu idanwo asewole to fee fi wobe, sugbon nitori pe eke ti daye tipe, tawon elesin mejeeji si ti fi ikorira han laarin ara won, won ko gba Lam sileewe naa.

Abalo ababo e, St. Patrick’s Catholic School, Oke-Padi, lo ti kawe ohun tan, iwe karun-un lo si wa tawon alase ileewe naa fi ni ko bawon to wa niwee kefa sedanwo asewole si girama nitori pe o je omo to mo tifun tedo iwe. Aremu sedanwo naa, o si yege, bo se wole sile eko girama Katoliiki niyen lodun 1954, to si pari e lodun 1959. Ileewe Katoliiki igba naa lo yi oruko pada to di Loyola College, to je gbajugbaja loni-in. Nibe naa ni Lam ti sedanwo oniwee mewaa re, awon paadi to n dari ileewe naa ko fi dandan mu un pe ko dara po mo esin igbagbo, bo tile je pe awon elegbe re mi-in ti won je musulumi tele pada yi esin won pada si ti kristeni. Lam jewo omo musulumi ododo, ko yi esin re pada, oun nikan si lo je musulumi ninu awon egbe re mokanlelogun ti won jo setan. O sedanwo naa, o si yege pelu esi idanwo to wuyi.

Iwe mewaa igba naa ko jo ti iwoyi, o see fi sise to jiire, Lamidi naa si fiwe eri e sise die ko too te siwaju ninu eko re lo si yunifasiti. Akowe ijoba ibile, akapo pelu ayewe-owo lo loo ba won se nileese ijoba ibile Ibadan, ni Mapo. Odun kan atosu mefa lo fi sise ohun. Lati ibi yii lo ti n fiwa ododo re to ni han, nitori Onaolapo ree, ko feran ka kowo ilu je tabi ka maa figba kan bokan ninu, gbogbo awon ti won jo n sise ni won si mo on nibe nigba naa.

Bo se n sakowe naa lo n yewe owo awon ileese wo, ise ti won kuku gbe le e lowo ni, oun naa so iriri re lenu ise yii. O ni lojo kan ti oun loo yewe oga ileewe alakoobere kan wo, oun ri i pe Ogbeni naa ti kowo ileewe ohun je tan, awon owo to n wole loun n da sapo tie, o ni tokunrin naa ba si wo seeti ati sokoto to maa n wo tan, ki i lo beliti, okun ni i fi gbe sokoto naa duro, enikeni ko si le fura si i pe o n kowo je.

Nigba to si je pe Lam ko gba igbakugba, ko beru eeyan, ko si mo bi won ti n fowo bo ibaje mole, o so fun Eedimasta naa pe owo re ko mo, afi dandan ko de odo oga oun lati loo tanran to da. Bee lawon eeyan mo Lam pelu iwa otito, akikanju ati ijafafa re, nigba ti yoo si fi kuro nibi ise naa lodun 1961, o ti satunse to han gbangba lenu ise oba.

1961 yii naa ni Lam Adesina wole sileewe giga Yunifasiti Naijiria ni Nsukka (University of Nigeria) nibe lo ti kekoo gboye nipa itan to ti sele seyin, eyi to n sele lowo atawon ohun to see se ko sele lojo iwaju (History). Omo Asabi ko file eko naa sile lai je kawon eeyan mo pe eni kan n be to n je Lamidi to laya bii kinniun, to mowe re to si ko ireje.

Kinniun lawon akeko Yunifasiti Nsukka maa n pera won nigba yen, inagije ti Lam funrare nigba naa a si maa je, ‘kinniun irele’. Lasan kuku ko lo gboruko yii, nitori iwa akin to ni ni, toju re si tun waa tutu bii adaba, to tun waa leyinju aanu. Akawe meji ti ko jora won ni inagije Lam yii, sugbon nitori pe o laya bii kinnun, ko gberegbe, ko si sohun kan to n ba a leru bo ti wu ko tobi tabi buru to ni ti kinnun se waye, irisi re to tutu to si ni irele ati iteriba lo je ki won ba a fi ‘irele’ kun kinniun.

Enugu, nile Ibo lohun-un ni Yunifasiti Nsukka wa, nigba to si debe, isesi gbogbo to ri lohun-un yato si tile Yoruba to ti n bo, ko pe rara to fi mo pe eleyameya a maa sele nibi teeyan ko ba ti reni foju jo, sugbon ko pe tara re fi mole, nibe naa lo si ti koko bere si i sohun to jo mo oselu sise ati ijangbara.

Lam Adesina lo da Egbe Olope sile logba Yunifasiti Nsukka, egbe Awolowo ti won n pe ni Action Group nigba yen ni Egbe Olope. Lamidi megbe naa wo ogba, o pe e leka tawon akekoo. Bi ifehonu-han tabi iwode kan ba si fee sele nileewe, oun ni i saaju, oun kan naa laare egbe akekoo, ipo yi ko si si fomo ojo afi akoni okunrin bii omo Adesina naa, odun 1964 lo joye ohun, bee lo n sasoju awon egbe re lori oro gbogbo to ba ni i se pelu ilosiwaju won.

Lodun 1964 yii kan naa ni Lam Adesina ko awon egbe akekoo sodi, ni won ba gbale-ejo lo lori awuruju to waye ninu eto idibo gbogbo-gboo ti won di ni Naijiria lodun naa. Nje ta ni won pe lejo lodun naa lohun-un, Dokita Nnamdi Azikwe to je olori orile-ede nigba naa ati Tafawa Balewa toun je olootu ijoba ni. Won lawon eeyan naa lejo i je. Bi ko ba si se eni to laya bii kinniun naa, omoleewe a je gbe olori orile-ede lo ile-ejo, Sugbon Lam niyen, akoni okunrin. Awon ologun to gbajoba laipe sigba tawon baba naa n jejo lowo ni ko je ki won gba idajo, oju won ko ba ri nnkan lowo omo inu won. Bee Lamidi ko ti i pari eko re to fi n se gbogbo eyi, omo yunifasiti lasan si ni.

Ni gbogbo asiko ti Lam wa nileewe giga yii lo ti n pongbe ati mo Awolowo, o feran baba naa nitori o ri i bii eni kan to nifee ododo bii toun, to si feran araalu. Awolowo ni Lam n wo bii awokose lenu oselu tileewe re to je olori fun, nigba ti won si ju Awolowo sewon, ibanuje dori Lam kodo, ko ni igbagbo ninu eto ijoba Naijiria mo, ero re ni pe niluu ti won ti n mu eni to n ja fetoo mekunnu to si n soselu ododo ju satimole, eto ijoba ilu naa ti kuna ni tododo. Sugbon sibe, ko yee nifee baba naa, nigba to si jade lewon, Lam Adesina loo ki i nile re ni Ikenne. Nibe l’Awolowo ti mu un bii omo re ninu oselu; bi Lam ba si fee mo nnkan to ru u loju, a a sa to agba oloselu naa lo.

Bi nnkan si se wa niyen titi t’Awolowofi ku, omo egbe Awolowo si ni Lam, ko peyinda bee ni ko yi ileri rere re pada lori ife ilu ati siso ododo.

Lodun 1965, Lam Adesina pari eko re ni Yunifasiti Nsukka, o si loo gbase tisa nileewe girama Lagelu, n’Ibadan, nitori pe o nifee eko, o feran omode, o si maa n dun mo on lati tun omo ro ni ti daadaa.

Odun meje lo fi sise tisa ni Lagelu, osu keje, odun 1972 lo kuro nibe. Bo se kuro nibe lo gba ileewe Girama Ibadan lo, o di olori eka eko isesi ati awujo (Social Studies) ki won too gbe e kuro nibe lodun 1975 lo si ileewe girama Nawarudeen, Obantoko, l’Abeokuta, nibi to ti je igbakeji oga agba yan-an-yan. Osu mefa pere ni Lam lo l’Egbaa ti won tun fi gbe e lo s’Ondo, Okeluse Anglican Grammar School nileewe ohun n je, ko si jinna pupo siluu Owo.

Nibe lo ti je oga agba pata(Principal),oun naa si ni prinsipa akoko fun ile iwe naa.

Odun kan lo fi sise nibe ki won too tun gbe e pada s’Ibadan, Lam gba Ibadan pada si ilu Iwo, nibi to ti se prinsipa won fodun meji gbako. Ahmadiyya loruko ileewe naa n je nigba yen, ko too wa pada di Anwar-ul-Islam to n je doni. Nibe ni Lamidi ti kowe fipo e sile lodun 1979.

Bee lo je pe odidi odun merinla gbako ni Onaolapo fi sise oluko, sugbon ni gbogbo igba to n se tisa yii lo ti n da si oro oselu Naijiria nipa kiko ero re atohun to ye gbogbo sinu iwe iroyin.

Lam ni abala tie to maa n ko oro apileko si ninu iwe iroyin Tribune. Nibe lo ti maa n toka awon iwa jegudujera ati mokaruuru tawon to n sejoba maa n dawole gbogbo.

Aremu ko ti i wonu oselu ti won ti n gbe e ju satimole nitori awon ohun to maa n ko sinu iwe iroyin, eemeta otooto lo gba kueri nibi ise tisa to n se. Gomina ologun to wa lori aleefa l’Oyoo nigba naa a maa je Colonel David Jemibewon, oun lo ranse pe Lam si ofiisi re, o ni ko sora gidi lori ohun to n ko nipa ijoba, paapaa julo tipinle Oyo toun n dari. Jemibewon ni ki Lamidi maa ranti pe osise ijoba loun, ijoba lo n sanwo osu fun un nibi to ti n se tisa, ko si saaye a n ko iranu oro kan sinu iwe iroyin bi ko ba fe ki gboro gbe oun. O ni ko ro nnkan miin ti yoo maa ko tabi ko tie ma ko nnkan mo. Sugbon Aremu ko gba, nise lo n fi gege; re dawon lekun a-n-se-kanndu.

Lodun 1979 to fi ise oluko sile lawon alajose e gba a niyanju lati dije dupo asoju nile igbimo asoju ijoba apapo. Lam Adesina ko koko fee gba lati dije, sugbon nigba to tun un ro, o gbe apoti ibo labe egbe oselu UPN (Unity Party of Nigeria) lati soju ijoba ibile Guusu Ibadan, o si wole. Bee ni Onaolapo di asofin. O si sise naa lati inu osu kewaa odun 1979 titi dosu kesan an, odun 1983.

Bo se di pe Oloogbe naa wonu oselu ni perewu niyen, won si mo asiko to di asofin nile igbimo naa yato. Koda won fun un loruko inagije kan ledee oyinbo, Misita Pointi (Mr. Point of order) iyen Ogbeni to meto, to tun meto;. Lamidi mo agbekale oro nile igbimo, ki i ba won woran nibe lai so sohun to n lo, ki i soro ti ko nitumo, awon asofin to ku naa si gba fun un tori pe o logbon inu, o si gbo lohun bii oje. Lam Adesina dabaa eko ofe lati alakoobere de yunifasiti nile igbimo< o ni ki won je kawon akoroyin naa lominira lati ko ohun ti won ba ri gbogbo. Sugbon oloooto ilu naa losika ilu loju awon to wa nipo, won ko kobi ara sohun ti Lamidi wi gbogbo.

Bee lo n ba eto naa lo titi di odun 1989, ko yise pada lori jije omo eyin Awolowo, ati nini ife iran Yoruba pelu Naijiria lapapo. Nigba to di 1991 ni Lam dije pe ki egbe awon fa oun kale lati dupo gomina ni ipinle Oyo, egbe oselu SDP (Social Democratic Party) legbe won.

Sugbon won ko fa Lam kale, Oloogbe Kolapo Isola lo ja mo lowo, okunrin naa lo si je gomina ijoba alagbada eleeketa nipinle Oyo.

Nigba to di 1992 ni won da egbe Afenifere sile, Lam Adesina lakowe akoko ti egbe naa yan.

Eka kan ninu NADECO (National Democratic Coalition) ni egbe Afenifere. Ohun ti egbe mejeeji naa wa fun naa ni ijangbara, isokan ati ilosiwaju iran Yoruba pelu ijoba awa-ara-wa.

Ile Oloogbe Bola Ige ni won ti bere ipade Afenifere, lara awon to si tun wa ninu egbe naa nigba yen ni Oloogbe Abraham Adesanya, Oloye Ayo Adebanjo, Oloye Bisi Akande atawon mi-in bee ti won jo je omoleyin Awolowo, ti won si nigbagbo ninu jija fetoo mekunnu ati ododo. Nigba ti egbe oselu SDP kase nile, AD (Alliance for Democracy) lawon Lam tun da sile, labe asia egbe AD naa lo si ti dije dupo to fi wole gege bii gomina ipinle Oyo lodun 1999. Bee ni Lam duro de asiko tie, oun lo si je gomina ijoba awa-ara-wa eleekerin.

Sugbon ki Lam Adesina too di Gomina, o to ka mo ohun toju e ri lowo Abacha, olori Naijiria to n se ijoba agbara lati odun 1993 titi wo 1998 ti iku yowo re nipo waye ninu eto idibo gbogbo-gboo ti won di ni Naijiria lodun naa. Nje ta ni won pe lejo lodun naa lohun-un, Dokita Nnamdi Azikwe to je olori orile-ede nigba naa ati Tafawa Balewa toun je olootu ijoba ni. Won lawon eeyan naa lejo i je. Bi ko ba si se eni to laya bii kinniun naa, omoleewe a je gbe olori orile-ede lo ile-ejo, Sugbon Lam niyen, akoni okunrin. Awon ologun to gbajoba laipe sigba tawon baba naa n jejo lowo ni ko je ki won gba idajo, oju won ko ba ri nnkan lowo omo inu won. Bee Lamidi ko ti i pari eko re to fi n se gbogbo eyi, omo yunifasiti lasan si ni.

Ni gbogbo asiko ti Lam wa nileewe giga yii lo ti n pongbe ati mo Awolowo, o feran baba naa nitori o ri i bii eni kan to nifee ododo bii toun, to si feran araalu. Awolowo ni Lam n wo bii awokose lenu oselu tileewe re to je olori fun, nigba ti won si ju Awolowo sewon, ibanuje dori Lam kodo, ko ni igbagbo ninu eto ijoba Naijiria mo, ero re ni pe niluu ti won ti n mu eni to n ja fetoo mekunnu to si n soselu ododo ju satimole, eto ijoba ilu naa ti kuna ni tododo. Sugbon sibe, ko yee nifee baba naa, nigba to si jade lewon, Lam Adesina loo ki i nile re ni Ikenne. Nibe l’Awolowo ti mu un bii omo re ninu oselu; bi Lam ba si fee mo nnkan to ru u loju, a a sa to agba oloselu naa lo.

Bi nnkan si se wa niyen titi t’Awolowofi ku, omo egbe Awolowo si ni Lam, ko peyinda bee ni ko yi ileri rere re pada lori ife ilu ati siso ododo.

Lodun 1965, Lam Adesina pari eko re ni Yunifasiti Nsukka, o si loo gbase tisa nileewe girama Lagelu, n’Ibadan, nitori pe o nifee eko, o feran omode, o si maa n dun mo on lati tun omo ro ni ti daadaa.

Odun meje lo fi sise tisa ni Lagelu, osu keje, odun 1972 lo kuro nibe. Bo se kuro nibe lo gba ileewe Girama Ibadan lo, o di olori eka eko isesi ati awujo (Social Studies) ki won too gbe e kuro nibe lodun 1975 lo si ileewe girama Nawarudeen, Obantoko, l’Abeokuta, nibi to ti je igbakeji oga agba yan-an-yan. Osu mefa pere ni Lam lo l’Egbaa ti won tun fi gbe e lo s’Ondo, Okeluse Anglican Grammar School nileewe ohun n je, ko si jinna pupo siluu Owo. Nibe lo ti je oga agba pata (Principal),oun naa si ni prinsipa akoko fun ile iwe naa.

Odun kan lo fi sise nibe ki won too tun gbe e pada s’Ibadan, Lam gba Ibadan pada si ilu Iwo, nibi to ti se prinsipa won fodun meji gbako. Ahmadiyya loruko ileewe naa n je nigba yen, ko too wa pada di Anwar-ul-Islam to n je doni. Nibe ni Lamidi ti kowe fipo e sile lodun 1979.

Bee lo je pe odidi odun merinla gbako ni Onaolapo fi sise oluko, sugbon ni gbogbo igba to n se tisa yii lo ti n da si oro oselu Naijiria nipa kiko ero re atohun to ye gbogbo sinu iwe iroyin. Lam ni abala tie to maa n ko oro apileko si ninu iwe iroyin Tribune. Nibe lo ti maa n toka awon iwa jegudujera ati mokaruuru tawon to n sejoba maa n dawole gbogbo.

Aremu ko ti i wonu oselu ti won ti n gbe e ju satimole nitori awon ohun to maa n ko sinu iwe iroyin, eemeta otooto lo gba kueri nibi ise tisa to n se. Gomina ologun to wa lori aleefa l’Oyoo nigba naa a maa je Colonel David Jemibewon, oun lo ranse pe Lam si ofiisi re, o ni ko sora gidi lori ohun to n ko nipa ijoba, paapaa julo tipinle Oyo toun n dari. Jemibewon ni ki Lamidi maa ranti pe osise ijoba loun, ijoba lo n sanwo osu fun un nibi to ti n se tisa, ko si saaye a n ko iranu oro kan sinu iwe iroyin bi ko ba fe ki gboro gbe oun. O ni ko ro nnkan mi-in ti yoo maa ko tabi ko tie ma ko nnkan mo. Sugbon Aremu ko gba, nise lo n fi gege; re dawon lekun a-n-se-kanndu.

Lodun 1979 to fi ise oluko sile lawon alajose e gba a niyanju lati dije dupo asoju nile igbimo asoju ijoba apapo. Lam Adesina ko koko fee gba lati dije, sugbon nigba to tun un ro, o gbe apoti ibo labe egbe oselu UPN (Unity Party of Nigeria) lati soju ijoba ibile Guusu Ibadan, o si wole. Bee ni Onaolapo di asofin. O si sise naa lati inu osu kewaa odun 1979 titi dosu kesan an, odun 1983.

Bo se di pe Oloogbe naa wonu oselu ni perewu niyen, won si mo asiko to di asofin nile igbimo naa yato. Koda won fun un loruko inagije kan ledee oyinbo, Misita Pointi (Mr. Point of order) iyen Ogbeni to meto, to tun meto;. Lamidi mo agbekale oro nile igbimo, ki i ba won woran nibe lai so sohun to n lo, ki i soro ti ko nitumo, awon asofin to ku naa si gba fun un tori pe o logbon inu, o si gbo lohun bii oje. Lam Adesina dabaa eko ofe lati alakoobere de yunifasiti nile igbimo o ni ki won je kawon akoroyin naa lominira lati ko ohun ti won ba ri gbogbo. Sugbon oloooto ilu naa losika ilu loju awon to wa nipo, won ko kobi ara sohun ti Lamidi wi gbogbo.

Bee lo n ba eto naa lo titi di odun 1989, ko yise pada lori jije omo eyin Awolowo, ati nini ife iran Yoruba pelu Naijiria lapapo. Nigba to di 1991 ni Lam dije pe ki egbe awon fa oun kale lati dupo gomina ni ipinle Oyo, egbe oselu SDP (Social Democratic Party) legbe won. Sugbon won ko fa Lam kale, Oloogbe Kolapo Isola lo ja mo lowo, okunrin naa lo si je gomina ijoba alagbada eleeketa nipinle Oyo.

Nigba to di 1992 ni won da egbe Afenifere sile, Lam Adesina lakowe akoko ti egbe naa yan.

Eka kan ninu NADECO (National Democratic Coalition) ni egbe Afenifere. Ohun ti egbe mejeeji naa wa fun naa ni ijangbara, isokan ati ilosiwaju iran Yoruba pelu ijoba awa-ara-wa.

Ile Oloogbe Bola Ige ni won ti bere ipade Afenifere, lara awon to si tun wa ninu egbe naa nigba yen ni Oloogbe Abraham Adesanya, Oloye Ayo Adebanjo, Oloye Bisi Akande atawon mi-in bee ti won jo je omoleyin Awolowo, ti won si nigbagbo ninu jija fetoo mekunnu ati ododo. Nigba ti egbe oselu SDP kase nile, AD (Alliance for Democracy) lawon Lam tun da sile, labe asia egbe AD naa lo si ti dije dupo to fi wole gege bii gomina ipinle Oyo lodun 1999. Bee ni Lam duro de asiko tie, oun lo si je gomina ijoba awa-ara-wa eleekerin.

Sugbon ki Lam Adesina too di Gomina, o to ka mo ohun toju e ri lowo Abacha, olori Naijiria to n se ijoba agbara lati odun 1993 titi wo 1998 ti iku yowo re nipo.
 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Wednesday, December 19 @ 00:16:53 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin:
Buhari Omo Musa Sa Kuro Nibi Ayeye Igbeyawo Saidi Osupa: Lehin Ti Alfa Muri Fun


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin

"Igbesiaiye Ati Iku Oloselu: Bi Lamidi Onaolapo Adesina Lo Nile Yii, Omo Ayisatu" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: