Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
[ Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu ]

·Iwosi Yii Si Ti N Po Ju Fun Yoruba, Ibi Ti Won Ba Wa De Ree O
·Bo Se Daa Niyen... Sugbon Kan Naa Lo Wa Nibe
·Bi Iro Ba Lo Logun Odun...
·Sebi Eyin Naa Gbo Ti Dino Melaye Ni Kogi
·Won Ni Alaga PDP Ku Sori Asewo N'Ipokia
·Awon Asofin Ni Kijoba Apapo Se Afara Elese Si Osodi-Apapa
·E Gbo! Kin Ni Fayose Wa Lo Si China?
·E Ko Sekeseke Si Won Lowo Jare
·Bee Ni Buhari Ko Wi Nnkan Kan

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Taani Iku Kan? O Ti Kan Olusola Saraki - Oloye Abu-Bakar Baba-N-Kwara Ti Jade La
 
 
Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
Lati Owo Yemi Ogunjobi

Taani Iku Kan? O Ti Kan Olusola Saraki - Oloye Abu-Bakar Baba-N-Kwara Ti Jade Laiye: Taani Iku Ko Ni Kan?

Odun marun-un lo fi gbe kinni ohun ja, aisan kansa lo kolu u, sugbon opo awon araalu ko mo, won ko mo pe nnkan to to bee ni Baba Oloye n gbe mora.

Baba Oloye, Abubakar Olusola Saraki ni won n pe bee, okunrin kan ti ko ni i se e gbagbe niluu Ilorin, ni Kwara, ati ni gbogbo Naijiria lapapo. Ohun tawon ero se n ro girigiri lo si papa-oko-ofurufu niyen obinrin, okunrin, omode, agba ati gbogbo oloselu ile yii, ohun ti won n fee mo ni boya loooto ni Saraki ti ku abi ko ti i ku, o ya won lenu pe okunrin naa le se bee ko gborun lo. Awon obinrin alasalatu ati awon okunrin musulumi, gbogbo won saa n sare lo si papaoko-ofurufu naa. Ko sajoji pe won n se bee yen lo o, bi won ti maa n sare loo pade e tele niyen, ti won yoo si ba a dele, won si ti mo pe ti awon ba ti ba a dele bee, ebun nla lawon yoo gba jade.


Sugbon ti Ojoru, Wesde, ojo kerinla, osu kokanla yii le ju bee lo, gbogbo awon ti won n sare lo sibe yii, koko loju won le. Erin ko pa ereke enikeni, awon mi-in paapaa tile ti bu sigbe ki won too debe rara, ko ye won pe Saraki yoo se bee yen ja Ilorin ati Kwara ju sile, won ko mo pe bee yen ni yoo se fi gbogbo awon eeyan re sile lo. Se awon mi-in ko mo pe agbalagba to ti pe omo odun mokandinlogorin (79) ni, bee lawon mi-in ko si mo pe odun karun-un ree ti arun jejere ti won n pe ni kansa ti n ba a finra. Won ko mo pe opo igba lo ti tori arun naa lo siluu oyinbo, won ti wo o titi ti ko san, bee ni won ko mo pe aisan naa ni ko je ko yo si won ni Kwara latigba pipe, to je ile re lo wa n’Ikoyi, l’Ekoo, ti ki i fi bee ba won da si oro oselu rara. Ohun to se ya won lenu nigba ti won gbo ariwo lojiji pe iku ti mu un lo niyen.

Loooto oro naa ko se ajoji si awon kan o, paapaa awon omoose re, awon ti won sun mo on pekipeki. Awon wonyi ti mo pe aisan jejere naa ti wo Baba Oloye lara, eni ti kansa ba si n ba ja, ko si bi tohun ti le loogun to, kinni naa yoo gbemi e gbeyin ni, abi nigba to ba ti je tifun-tedo re, kinni tohun yoo maa fi mi, ona wo tun ni tohun yoo maa gba jeun ti ko ni i pa a lori gbeyin. Bi eleyii ba si ti sele, ko si kinni kan nibe, orun ni taara. Eyi lawon ti won sun mo Saraki ti mo pe ko si bi awon ti le se e, iku ni yoo gbeyin aisan naa. Igba to tile waa di odun Ileya to koja yii ti Saraki ko le wa s’Ilorin, nigba naa lawon agbaagba ibe ti mo pe aisan okunrin naa ti ba ona mi-in yo. Idi ni pe lati bii ogoji odun seyin, boya ni odun kan wa ti Saraki ko ni i se Ileya niluu Ilorin, odun ti gbogbo araalu ti maa n gbadun re ju ni.

Sugbon bi nnkan ba n sele nile olowo, awon mekunnu ati araalu ki i tete gbo, ohun ti ko je kawon mi-in niluu Ilorin mo pe kinni ohun le ju bi awon ti ro o si lo niyen. Afi nigba ti won gbo pe Olusola Saraki ku lojiji. Omo re, Laolu, so pe iku naa ya awon lenu die. Idi ni pe nigba ti okunrin naa ji laaaro ojo to ku yii, o se adura re bo ti se maa n se e, o si ba awon omo re to ti ji nigba naa soro, afi bo se tun pada lo sori ibusun to si di pe nnkan yiwo, ti won ko rojutuu e mo, ere ni abi awada ni, bee lo se ku mo won lowo. Ni deede aago mefa owuro ni, ko si senikan ninu awon omo ati iya won to wa nibe to le sare se ohunkohun si i, nitori loju won bayii ni iku se mu un lo.

Lesekese ti ariwo iku re jade sita lawon oloselu atawon eeyan nla nla ile yii bere si i fori gbari. Aare Goodluck Jonathan lo koko soro, o ni ko si iru Saraki nile yii mo, bee ni David Mark, olori ile igbimo asofin agba so pe erin nla kan lo wo yen. Tambuwal ti i solori ile igbimo asofin kekere paapaa so pe gbogbo awon lawon dorikodo nitori oun ko ro pe awon yoo tun ri egba bii o¯osun ninu igbo mo.

Kia lawon gomina bere si i ro girigiri gba ona ile re, iyawo Jonathan si ba iyawo Saraki daro, o ni ko pele iku oko re, ko saa ri kinni ohun bii amuwa Olorun.

Bola Tinubu gbera, o di ile awon Saraki, oun ati Lai Muhammed, pelu Dele Belgore to dupo gomina Kwara lasiko ibo to koja ti ko wole, won ba won kedun nibe gan-an ni. Bee ni Abubakar Atiku, bee ni Ibrahim Gambari, bee ni Babangida, ati Abdulsalami Abubakar, pelu Yakubu Gowon, gbogbo won lo saa n daro pe akoni ti lo.

Sugbon awon ara Ilorin gan-an ni won mo pe nnkan ba awon lara. Nise laafin oba ilu naa, Zulu Gambari pa lolo, igba kan ko lu igba, bee ni awo kan ko lu ara won. Ohun gbogbo pa kanrin-kese. Bo o yi sibi, oro iku okunrin alagbara oloselu yii ni won n so, bo o yi sohun-un, oro iku to pa Baba Oloye naa ni won n so. Afi awon obinrin ti won ranti ojo, won ranti bi won ti maa n rin loo pade Saraki bo ba n bo nile, n ni gbogbo won ba mura, ero repete lona eepootu Ilorin, won n ro girigiri lo. Nigba ti won yoo fi gbe oku naa de, nise ni gbogbo agbegbe naa kun bii igba ti won waa pade aare orile-ede nla, sugbon igba ti won gbe posi Baba Oloye so kale ni nnkan se gan-an. Gbogbo awon obinrin to wa nibe bu gbamu leekan naa sekun, won n ke papo bii eni to so funra won. Awon okunrin ti ko laya paapaa bere si i ke, ko si senikan to so fun awon oloselu to je omo leyin re ti won fi n fi aso nuju, nitori omi to n se welewele jade loju won Bayii ni ero repete tele posi Baba Oloye, bi won si ti wo aarin ilu bee lawon ero mi-in n ya tele won. Awon mi-in ti sare won loo duro de oku re nile, won n reti ki won gbe e yo. Sugbon Yidi ni won koko gbe e lo taara, nibe ni Olori Aafaa n’Ilorin ti saaju awon aafaa to ku, ti won si kirun si i lara. Nigba ti won yoo fi gbe oku re de, isoro gidi ni fawon to gbe e lati ribi gbese le, awon eeyan n gba oku naa lowo ara won ni. Bi won si ti gbe e kale ni won mura lati sin in, bee ni gbogbo awon omo-kewu to wa nibe n pariwo, “Allau Akbar, Allau Akbar,˜ titi ti won fi gbe oku Olusola Saraki si saare ni deede aago mefa koja oogun iseju, ti gbogbo awon ti won wa nibe si tun bu sigbe.

Igbe ti won ke nijo naa ko tan sile awon Saraki, titi ti kaluku fi dele won ni won n sunkun, kaakiri ibi gbogbo tawon obinrin si ti n soro Saraki yii ni omi ti n bo loju eni gbogbo. Afi bii igba pe omode lo ku, oku naa ko yato si oku ofo loju awon eeyan, bee Saraki ki i somode, oku e, oku eko ni. Ki lo kuku de tawon eeyan feran okunrin naa to bayii@ Bawo ni Saraki se je si won n’Ilorin to bee, ki lo pa oun atawon obinrin Kwara po ti ko se senikan to fe ko ku ninu won@ Eyi ni itan igbesi-aye okunrin Saraki yii ni soki.

Se e ri Saraki, omo ilu Ilorin ponbele ni. Loooto lo ba won tan nile Yoruba nitori omo Iseyin ni iya re, Humuani, sugbon Fulani lawon baba baba re, Mali ni won ti wa siluu Ilorin. Bi won ti de ilu Ilorin ni won fidi kale saduugbo ti won n pe ni Agbaji, ibe naa ni won si bi Olusola Saraki si ni ojo ketadinlogun, osu karun-un, odun 1933. Kinni kan ni o, olowo ni Saraki agba, iyen Baba Olusola. O lowo lowo gidi ni o, oruko ti awon ara Ilorin igba naa si maa n pe e ni Aya-won-lowo-to-ke-to-ke, nitori pe awon eeyan maa n waa ya owo lodo re, bo ba si ya won lowo naa, yoo tun fun won ni oke ti won yoo fi di owo naa si. Onisowo ni, o si maa n ra oja lati Ilorin titi wolu Eko, titi de Accra nile Ghana, ati Abidjan nile Ivory Coast. Kaakiri ibi gbogbo ni won ti mo on bii onisowo, latigba tomo re si ti kere lo ti maa n mu un lo si irin-ajo gbogbo to ba n lo.

Sugbon aanu ti Saraki agba maa n fi owo re se yii lo je ko di gbajumo ni gbogbo adugbo won ati kaakiri ilu Ilorin. Yato si tawon eeyan to maa n saanu fun, to n fun won lowo ti won ba wa ninu isoro, oun nikan naa ni i fawon eeyan lowo ti ki i gba owo-ele lori re, owo to ba ya won naa ni yoo gba pada nigba ti won ba ri i. Ki i se iyawo kan lo fe, se bowo ba ti to niyawo i to laye ojo naa, ohun ti ko si je ki Olusola tete mo iya re gan-an niyen. Odo Iyaale iya re kan toun ko bimo ni i wa ni gbogbo igba, eni naa loun si n pe ni Iya oun, o ti di omo odun mejila, lasiko to fee lo siluu oyinbo lati loo kawe si i lo too mo eni ti iya re je gan-an. Obinrin yii lo to Olusola Saraki dagba, iya re ko lo to o rara.

Leyin ti Olusola ti ba baba re gbe to si kawe niluu Ilorin, Eko lo lo lati kawe girama, igba naa lo si lo si Eko Boys High School. Ni gbogbo igba ti omode naa wa niluu Ilorin, Abubakar lawon eeyan te mo on lori gege bii oruko re, sugbon Olusola lawon ti won ba je Yoruba maa n pe e ni tiwon. Igba ti yoo lo sileewe Eko yii, Olusola lo fi sile nibe, nitori awon ileewe elesin nigba naa ki i fee gba awon musulumi sileewe won, afi omo musulumi to ba ti setan lati yi esin re pada, ti won yoo si fun un ni oruko tuntun. Oro yii lo pada waa di wahala sorun Saraki, tawon eeyan kan fi maa n so pe eletan ni, nitori nigba to ba wa laarin awon ara Ilorin ati awon ara ile Hausa, Abubakar ni yoo maa pe ara re, sugbon to ba ti de odo awon Yoruba, yoo so pe oun Olusola. Sugbon nigba naa, oro esin lo fa a to fi n pe ara re ni Sola, nitori ko le ri ileewe re lo ni.

Nigba ti Saraki pari iwe re ni Eko Boys High School, gbogbo ohun ti oun ti gbojule ni pe ko le nira foun lati ri anfaani eko-ofe gba, o fe ki ijoba ile Hausa igba naa ran oun ni ileewe niluu oyinbo, eko-ofe lo fee ba lo. Se o kawe, o si se daadaa nidii eko re. Baba re ti koko so fun un pe ko waa kawe lati di injinnia, sugbon Olusola ko fe bee, o si salaye fun baba re.

O ni idi ti oun ko fi fee kawe lati di injinnia ni pe oun fe ohun ti oun yoo se ti oun yoo fi le pada waa maa toju iya to to oun yii, iyen iyaale iya re. Obinrin naa ko bimo, Saraki kekere si fe ko se pe bi oun ba ti le kawe de, obinrin naa ni oun yoo maa toju ju gbogbo eeyan lo. Nje iru eko wo ni Olusola fe, o ni dokita loun fee ki oun maa se. Bee ni baba re si gba si i lenu. Sugbon ijoba ile Hausa ko fun un ni anfaani eko-ofe, won ni omo mekunnu nikan ni kinni naa wa fun, sugbon olowo ni baba tie, ki oun naa ran omo re lo. Bee ni baba naa si se, o ran Olusola relu oyinbo.

Olusola Saraki wa niluu London, omo odun metadinlogun pere si ni nigba to lo siluu naa lodun 1950. Ile-eko giga Chatham College of Technology lo koko lo, leyin to si kuro nibe lo lo si University of London, bo ti kawe tan to nimo ise isegun nibe lo tun lo si St George’s Hospital, nibe lo si ti ko eko dokita gidi. Nise lo ye ko duro die ko tubo tun sise lohun-un, sugbon ko le duro mo nitori iyawo re to fe lohun-un n yo o lenu pe afi ki oun mo awon eeyan re ni Naijria, bee lo se je pe lodun 1962 leyin to ti lo odun mejila o din losu kan pere niluu oyinbo, okunrin naa pada dele. Asiko naa ni Naijiria, asiko to je pe oga lenikeni to ba n se dokita ni, gbogbo ibi ni won ti n wa won. Idi ni pe ni gbogbo Naijiria nigba naa, eeyan le ka iye awon dokita ti won wa, won ko to nnkan rara ni, iyen ni ijoba se maa n wa won kaakiri.

Ijoba ile Hausa lo koko gbo pe omo awon kan ti de, se won ti nigbagbo pe omo won ni Saraki nigba to ti je omo ilu Ilorin, bi won si ti gbo pe omo won naa ti di dokita lati London, won ranse si i pe ise wa nile fun un ti yoo se lodo won lohun-un, ko maa bo ni Kaduna tabi ibikibi to ba ti fe ni gbogbo ile Hausa. Sugbon Saraki taku ko da won lohun, o ni nigba ti oun fee lo sileewe, sebi won ni omo olowo loun, won ko si le ran omo olowo ni eko-ofe, ki waa ni won n wa oun kiri fun nigba ti oun ti kawe oun jade. Awon ijoba ile Hausa igba naa be e sugbon ko da won lohun, o ni oun ko ni i wa loun so yen, ki won ma pe oun mo. Bee ni ko se ba won se ise nile Hausa. Sugbon awon naa taka si i, won ti mo pe won yoo mu un nijokan, oun paapaa ko si mo ibi ti won yoo ti ba mu oun.

Loro kan, Saraki gba ise ni ileewosan gbogbo-gbo, iyen General Hospital, l’Ekoo, nibe lo ti n sise, ti won si so o di oga kekere. Ko pe naa to fi kuro nibe to bo sileewosan Creek Hospital, l’Ekoo, yii kan naa.

Ni gbogbo asiko yii, ko seni to mo pe Saraki yoo pada waa di oloselu, dokita lawon eeyan mo on si, eni tara re ko ba ya lo n toju ni tie. Sugbon kinni kan maa n sele si i, iyen ni pe to ba ti n fese rin lo sileewosan to ti n sise, yoo maa ri awon onibaara kan ti won yoo saa maa toro owo, igba to ba si sun mo won to wo won daadaa, yoo ri i pe awon onibaara obinrin naa, omo Ilorin lo po ninu won. Ki lo le fa iru eyi, lojo kan lo ba gbera lati lo si Ilorin, o si lo si agboole won ni Agbaji. Lojo naa lo gbo pe omo obinrin kan bayii ku. Nje ki lo pa a. Won ni omo naa ko jeun lo sileewe, ebi si n pa a gidi to ti n lonu mole nigba to de, sugbon iya re ko ri omi ti yoo fi se ounje fun un. Lo ba ni ki omo naa loo fa omi wa ninu kanga, n lomo ba ja si kanga, to si ku.

Oro naa dun Saraki pupo, o si beere lowo awon araadugbo naa, won ni isoro kan tawon ni laye yii, isoro omi ni. Won ni awon ki i ri omi se ounje, ko si senikan to lowo lati se omi fun won mu. Igba ti Saraki tun waa ni ki ore oun kan je ki awon jo lo si ibudoko oju irin ilu Ilorin, iyen ibi tawon reluwee igba naa maa n duro, ohun to ri nibe ya a lenu. Iru awon obinrin to maa n ri ni ilu Eko nni, iru won naa ni won po ni ibudoko yii, o si waa ri i pe omo Ilorin ni won loooto. Ohun ti won se ni pe won n toro baara nibe ni o, won n waa gba owo lowo awon ti won ba wa ninu reluwee. Nibe ni Saraki ti waa ri i pe oro naa ki i se kekere, o si n wa ohun ti oun le se funra oun lati le din isoro awon obinrin wonyi ku. Igba to si wo o titi lo ri i pe ko si ohun ti oun le se ju ki oun wa ninu ijoba lo, ki oun ba won se oselu, oselu nikan loun le se lati le ran awon eeyan oun lowo. Saraki funra e so pe ohun to gbe oun de idi oselu niyen.

Lodun 1964 lo koko jade, iyen odun keji pere to de, ti oun si wa ni omo odun mokanlelogbon nigba naa. Won n seto ibo lati lo sile igbimo asofin apapo ni, oun si fee lo lati adugbo won n’Ilorin. Sugbon Saraki ko lagbara tawon ti won wa nibe yen, won kan mo baba re ni, won si mo oun naa pe dokita ni, sugbon ki i se oloselu rara. Egbe to wa ni gbogbo agbegbe naa nigba naa ni egbe NPC, iyen egbe awon Sardauna, awon eeyan naa si beru Sardauna debii pe ohun to ba fe ki won se ni won maa se. Saraki loun fee lo sile igbimo, oun si fee dupo naa. Sugbon leekan naa ni Sardauna pase lati Kaduna pe awon ti won ti wa nipo naa tele ni won yoo tun wa nibe o, awon ko fe eni tuntun kan ti yoo ba won dupo naa, won ni ki iru awon eeyan bii Saraki yii loo jokoo jee.

Saraki ko, o ni oun ko ni i jokoo jee, kaka bee, oun yoo jade gege bii eni ti ko ni egbe oselu kan ni.

Sugbon yeye lawon oloselu igba naa fi Saraki se. Awon ti won wa nibe lagbara ju u lo, awon bii Alaaji Saadu Alanamu ti won n pe ni Gbogbo Iwe, okunrin to je oun ni Waziri ilu Ilorin nigba naa, oun ni Baba Iya Dele Belgore to dupo gomina loruko ACN lodun to koja o. Bee naa lawon Buhara Edun, awon wonni ti lokiki nidii oselu Ilorin, ko si saaye kan ti won yoo fi Saraki ha si.

Bee, oun fee wole si won lara. Won wa n fi i se yeye, won ni ewe-eko ni won yoo ko sinu apoti idibo fun un. Loooto si ni, leyin ti won dibo naa tan, bii igba to je ewe-eko ni won ko si apoti idibo re ni, nitori ibo re ko debi kankan ninu ohun to wa nile naa, awon alatako re lo wole, awon omo Sardauna. Saraki si n mura pe oun yoo tun ipo naa du lasiko ibo to ba tun n bo, sugbon nise lawon soja le awon ti won wa nibe danu, ni won ba gbajoba lowo won.

Asiko naa ni Saraki waa jewo fun awon oloselu Ilorin gbogbo. Leyin ti won ti gbajoba lowo awon oloselu, Saraki pada si Eko o n sise dokita re, o ti loo ba baba re, o si ya egberun mewaa owo pon-un lowo baba naa, owo nla gidi ni eleyii nigba naa. Sugbon baba re ya a nitori Saraki so pe oun fee loo da ileewosan toun sile ni. Bee ni Saraki gba owo yii, o si da ileewosan tire sile, ileewosan naa si n pa owo nla wole fun un. Gbogbo awon ileese nla nla bii ECN, NPA ati NICON lo je odo re lawon osise won ti n waa gba itoju, awon ati awon ebi won. Bee lowo nla bere si i wole fun Saraki. Bee ni Saraki se to je lasiko yii ni oun ri owo to po ju, nitori o maa n pa owo to to bii egberun lona eedegbeta laarin odun kan.

Ohun to waa se ni pe o lo siluu Ilorin, o waa se awon ero nla nla ti awon araalu naa yoo ti maa ponmi. Idi ero yii lo ti ni ki awon eeyan naa maa ponmi, omi ero, omi to da bii omi ijoba. Sugbon Saraki ni ijoba yii, oun lo fa omi sidii ero, o si n sanwo fun ileese olomi ijoba. Bee lo di pe gbogbo adugbo pata ni won ti n ri omi pon, omi ti ki i se ti odo tabi seleru, omi ti ko si ni arun kankan to le ko ba enikan. Bayii lawon araalu mo pe enikan wa to n gbeja awon, to si n ran awon lowo, paapaa awon obinrin. Yato si ti omi yii, bi Saraki ba ti lo si Eko, yoo ko aso ati awon nnkan mi-in waa fun won n’Ilorin. Ohun to fa a niyi to fi di pe awon obinrin maa n wo lo sile re to ba ti di pe won gbo pe o n bo nile, agaga bo ba je asiko odun, igba mi-in si wa ti won yoo loo pade re ni Ote, won yoo si maa tele moto re titi ti yoo fi wo ilu Ilorin. Nigba naa, oselu eleekeji ko ti i bere rara, sugbon Saraki ti mo ibi to n lo.

Saraki waa ni moto kan o, Citron ni won pe moto naa. Asiko ti won fi joye lo gbe moto naa wolu Ilorin, ko si si meji re. Sanni Okin lo ku, oun ni Turakin Ilorin, okiki Saraki si ti kan ni gbogbo asiko naa, gbogbo obinrin Ni gbogbo asiko yii, ko seni to mo pe Saraki yoo pada waa di oloselu, dokita lawon eeyan mo on si, eni tara re ko ba ya lo n toju ni tie. Sugbon kinni kan maa n sele si i, iyen ni pe to ba ti n fese rin lo sileewosan to ti n sise, yoo maa ri awon onibaara kan ti won yoo saa maa toro owo, igba to ba si sun mo won to wo won daadaa, yoo ri i pe awon onibaara obinrin naa, omo Ilorin lo po ninu won. Ki lo le fa iru eyi, lojo kan lo ba gbera lati lo si Ilorin, o si lo si agboole won ni Agbaji. Lojo naa lo gbo pe omo obinrin kan bayii ku. Nje ki lo pa a. Won ni omo naa ko jeun lo sileewe, ebi si n pa a gidi to ti n lonu mole nigba to de, sugbon iya re ko ri omi ti yoo fi se ounje fun un. Lo ba ni ki omo naa loo fa omi wa ninu kanga, n lomo ba ja si kanga, to si ku.

Oro naa dun Saraki pupo, o si beere lowo awon araadugbo naa, won ni isoro kan tawon ni laye yii, isoro omi ni. Won ni awon ki i ri omi se ounje, ko si senikan to lowo lati se omi fun won mu. Igba ti Saraki tun waa ni ki ore oun kan je ki awon jo lo si ibudoko oju irin ilu Ilorin, iyen ibi tawon reluwee igba naa maa n duro, ohun to ri nibe ya a lenu. Iru awon obinrin to maa n ri ni ilu Eko nni, iru won naa ni won po ni ibudoko yii, o si waa ri i pe omo Ilorin ni won loooto. Ohun ti won se ni pe won n toro baara nibe ni o, won n waa gba owo lowo awon ti won ba wa ninu reluwee. Nibe ni Saraki ti waa ri i pe oro naa ki i se kekere, o si n wa ohun ti oun le se funra oun lati le din isoro awon obinrin wonyi ku. Igba to si wo o titi lo ri i pe ko si ohun ti oun le se ju ki oun wa ninu ijoba lo, ki oun ba won se oselu, oselu nikan loun le se lati le ran awon eeyan oun lowo.

Saraki funra e so pe ohun to gbe oun de idi oselu niyen.

Lodun 1964 lo koko jade, iyen odun keji pere to de, ti oun si wa ni omo odun mokanlelogbon nigba naa.

Won n seto ibo lati lo sile igbimo asofin apapo ni, oun si fee lo lati adugbo won n’Ilorin. Sugbon Saraki ko lagbara tawon ti won wa nibe yen, won kan mo baba re ni, won si mo oun naa pe dokita ni, sugbon ki i se oloselu rara. Egbe to wa ni gbogbo agbegbe naa nigba naa ni egbe NPC, iyen egbe awon Sardauna, awon eeyan naa si beru Sardauna debii pe ohun to ba fe ki won se ni won maa se. Saraki loun fee lo sile igbimo, oun si fee dupo naa. Sugbon leekan naa ni Sardauna pase lati Kaduna pe awon ti won ti wa nipo naa tele ni won yoo tun wa nibe o, awon ko fe eni tuntun kan ti yoo ba won dupo naa, won ni ki iru awon eeyan bii Saraki yii loo jokoo jee.

Saraki ko, o ni oun ko ni i jokoo jee, kaka bee, oun yoo jade gege bii eni ti ko ni egbe oselu kan ni.

Sugbon yeye lawon oloselu igba naa fi Saraki se. Awon ti won wa nibe lagbara ju u lo, awon bii Alaaji Saadu Alanamu ti won n pe ni Gbogbo Iwe, okunrin to je oun ni Waziri ilu Ilorin nigba naa, oun ni Baba Iya Dele Belgore to dupo gomina loruko ACN lodun to koja o. Bee naa lawon Buhara Edun, awon wonni ti lokiki nidii oselu Ilorin, ko si saaye kan ti won yoo fi Saraki ha si.

Bee, oun fee wole si won lara. Won wa n fi i se yeye, won ni ewe-eko ni won yoo ko sinu apoti idibo fun un. Loooto si ni, leyin ti won dibo naa tan, bii igba to je ewe-eko ni won ko si apoti idibo re ni, nitori ibo re ko debi kankan ninu ohun to wa nile naa, awon alatako re lo wole, awon omo Sardauna. Saraki si n mura pe oun yoo tun ipo naa du lasiko ibo to ba tun n bo, sugbon nise lawon soja le awon ti won wa nibe danu, ni won ba gbajoba lowo won.

Asiko naa ni Saraki waa jewo fun awon oloselu Ilorin gbogbo. Leyin ti won ti gbajoba lowo awon oloselu, Saraki pada si Eko o n sise dokita re, o ti loo ba baba re, o si ya egberun mewaa owo ponun lowo baba naa, owo nla gidi ni eleyii nigba naa. Sugbon baba re ya a nitori Saraki so pe oun fee loo da ileewosan toun sile ni. Bee ni Saraki gba owo yii, o si da ileewosan tire sile, ileewosan naa si n pa owo nla wole fun un. Gbogbo awon ileese nla nla bii ECN, NPA ati NICON lo je odo re lawon osise won ti n waa gba itoju, awon ati awon ebi won. Bee lowo nla bere si i wole fun Saraki. Bee ni Saraki se to je lasiko yii ni oun ri owo to po ju, nitori o maa n pa owo to to bii egberun lona eedegbeta laarin odun kan.

Ohun to waa se ni pe o lo siluu Ilorin, o waa se awon ero nla nla ti awon araalu naa yoo ti maa ponmi. Idi ero yii lo ti ni ki awon eeyan naa maa ponmi, omi ero, omi to da bii omi ijoba. Sugbon Saraki ni ijoba yii, oun lo fa omi sidii ero, o si n sanwo fun ileese olomi ijoba. Bee lo di pe gbogbo adugbo pata ni won ti n ri omi pon, omi ti ki i se ti odo tabi seleru, omi ti ko si ni arun kankan to le ko ba enikan. Bayii lawon araalu mo pe enikan wa to n gbeja awon, to si n ran awon lowo, paapaa awon obinrin. Yato si ti omi yii, bi Saraki ba ti lo si Eko, yoo ko aso ati awon nnkan mi-in waa fun won n’Ilorin. Ohun to fa a niyi to fi di pe awon obinrin maa n wo lo sile re to ba ti di pe won gbo pe o n bo nile, agaga bo ba je asiko odun, igba mi-in si wa ti won yoo loo pade re ni Ote, won yoo si maa tele moto re titi ti yoo fi wo ilu Ilorin. Nigba naa, oselu eleekeji ko ti i bere rara, sugbon Saraki ti mo ibi to n lo.

Saraki waa ni moto kan o, Citron ni won pe moto naa. Asiko ti won fi joye lo gbe moto naa wolu Ilorin, ko si si meji re. Sanni Okin lo ku, oun ni Turakin Ilorin, okiki Saraki si ti kan ni gbogbo asiko naa, gbogbo obinrin Ilorin pata, atawon odo ilu naa lo n fe tire. Nitori bee ni won se mu un, won ni oun ni won yoo fun ni oye naa. Bee ni Saraki di Turakin Ilorin, awon eeyan si n royin moto re to gbe wa. Won ni moto re maa n lo soke, o si maa n lo sile funra re, won ko ri iru re ri jare. Bi Saraki se gbile niyi o, o si di eni ti awon obinrin maa n loo pade re lona bi won ba ti n gbo po n bo niluu Ilorin. Nigba ti yoo fi di 1975 paapaa, awon oloselu atijo ti sinmi sara, opolopo won ko jade mo, awon pupo ninu won si ti feyinti, Saraki nikan lo ku to lenu. Asiko naa ni won dibo ijoba ibile, eni ti Saraki si wa leyin re lo wole. Nise ni oruko Saraki ti wo iwe oselu nla niluu Ilorin.

Nigba ti yoo fi di odun 1978, ko senikan to le duro koju Saraki, ohun to je ki won yan an lati loo soju gbogbo adugbo naa nibi ipade apero ofin ile wa niyen. Bee ni won jo lo sibi ofin naa, nibe ni won si ti pada de ti won da egbe NPN sile. Saraki wa lara awon ti won fee dupo Aare, oun ati Shehu Shagari, Adamu Ciroma, Lawal Kaita, Umaru Dikko, Maitama Sule atawon mi-in bee. Sugbon nigba ti won dibo naa tan, Shagari lo wole ninu egbe won, oun naa ni won si fa kale pe ko du ipo aare. N ni won ba ni ki Saraki loo du ipo Seneto, iyen asofin agba lati Kwara, won si ni ko fa eni ti yoo se gomina ipinle naa kale. n ni Saraki ba fa Adamu Attah kale, won si dibo fun un bii gomina, oun naa si wole gege bii omo ile igbimo asofin. Bee ni Attah di gomina, Saraki naa si wo ile igbimo asofin lo. Nile igbimo paapaa, nise ni won fi Saraki se Asaaju omo ile igbimo, iyen Senate Leader.

Lasiko naa ni oruko Saraki wo ilu yii gan-an. Se oun ni olori omo egbe oselu to po ju nile igbimo, o si lagbara daadaa niluu Ilorin ati gbogbo Kwara, nigba to je oun lo fi gomina to wa nibe sori oye. Sugbon ko pe ti wahala fi bere, Akanbi Oniyangi naa wa ninu egbe NPN, omo ilu Ilorin loun naa, ko si fi bee gba ti Saraki, n ni ija ba de. Ede aiyede yii ni Adamu Attah paapaa fi kewo, lo ba ni Saraki n yo oun lenu, ko ma daamu oun mo. Bee ni ija yii bere, lo ba di rannto o, Attah taku, o ni oun ko ba Saraki se mo se, o ni awon araalu lo ku ti oun fe maa ba se. Bee ni Attah ko foribale fun Saraki, won si pari ija naa titi won ko ri i yanju o. Nigba ti ibo n bo, n lawon asaaju egbe NPn ba dibo, ni won ba fa Attah kale, nitori pe Oniyangi wa leyin won. Kin ni Saraki waa fee se bayii o!
Lojiji ni Saraki jewo pe oloselu nla loun, ati pe oun ju awon Akanbi Oniyangi lo. Ohun to se ni pe nise lo yi biri kuro ninu egbe NPN. Ki i se po fi egbe naa sile o, o kan so fun awon omoleyin re pe ki won ma dibo fun Attah lojo idibo ni o, o ni Cornelius Adebayo ti egbe UPN, egbe awon Awolowo fa kale ni ki won dibo fun. Bee naa ni won si se o, awon ara Kwara ko dibo fun Attah, Adebayo ni won dibo fun, n ni iyen ba di gomina lodun 1983 o. Inu bi awon asaaju egbe NPN, won ni awon yoo fiya je e fun ohun to se, o gbe ipinle won fun egbe oselu mi-in. Sugbon nibi ti won ti n se eyi ni ohun ti won ko ro sele, awon soja gbajoba ninu osu kin-in-ni, odun 1984, ni won ba ro gbogbo awon oloselu ti mole. N ni kutakuta ba pin.

Igba ti oselu tun bere lodun 1990, Saraki tun fa Shaba Lafiagi kale, oun naa si di gomina ni 1992, sugbon ija naa lo tun pada de laarin won. Nigba naa ni Baba Oloye tun fee di Aare, sugbon Shehu Musa Yaradua lo la gbogbo won mole, iyen ninu egbe SDP igba naa. Ija tun de laarin Lafiagi ati baba re, iyen Olusola Saraki, igba ti won yoo si fi pari re, wahala ibo June 12 ti sele, n lawon Saraki ba tun gbe jee. Oun ati Abacha ko fi bee gba tara won, won ti jo n se tele, nigba ti ko si gbamoran, won jinna sira won. Leyin ti Abacha ku ni won tun bere oselu, Saraki atawon kan si da egbe APP sile, oun lo ni egbe ohun atawon eeyan kan. Nigba tegbe naa yoo jade, Saraki ni ki won fa Muhammed Lawal sile, won ni ko waa se gomina Kwara. Saraki ti koko so poun ko fe aloku soja, sugbon nigba ti won so fun un pe Lawal lo gba maaki ju ninu gbogbo awon ti won jo fee dije naa, lo ba fowo si i.

Ko pe rara ti oro fi tun dija laarin won. Lawal ni owo lo daja sile, Saraki ni Lawal ko fee mo agba lagba mo ni, n ni ija naa ba tun de, ija naa si le. Gbogbo eeyan ti ro pe Lawal yoo reyin Saraki lasiko yii, sugbon iro ni, lojiji ni Baba Oloye fa omo re kale, nigba ti won yoo si dibo tan, Bukola Saraki lo wole o, Baba Oloye tun jewo pe oun ni oga oloselu gbogbo ni Kwara. Ohun to waa fo gbogbo e loju ni igba ti Bukola fee se gomina tan, ti Baba Oloye tun ni oun yoo fa Gbemisola sile, ni Saraki kekere ba feyin Saraki agba janle, n loro naa ba pesije. Sugbon ni gbogbo igba naa, ko seni to mo pe Baba Oloye ti n lo, won ko mo pe aare kan ti wa lara baba naa, ati pe aiyaara naa lo je ki Saraki kekere le gbe Saraki nla subu.

Ni bayii ni gbogbo eeyan mo pe ohun to sele ree o, Olusola Saraki ti ku, o ti lo laarin Ilorin.

Sugbon ohun to han gbangba ni pe ko si enikan ni gbogbo ilu Ilorin, ati Kwara lapapo ti yoo so poun ko gburoo Saraki ri, bee naa ni ko si oloselu kan ni Naijiria ti yoo ni oun ko mo Baba Bukola, Oloselu lati ilu Ilorin. Sugbon ko si beeyan yoo ti se e titi ti ko ni i dagba, bi ojo ori ba de ko soogun fun un. Saraki ti se tire nibe o lo bayii, awon to ba ku nibe ni ko saye ire.
 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Wednesday, December 19 @ 01:02:19 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin:
Buhari Omo Musa Sa Kuro Nibi Ayeye Igbeyawo Saidi Osupa: Lehin Ti Alfa Muri Fun


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


"Taani Iku Kan? O Ti Kan Olusola Saraki - Oloye Abu-Bakar Baba-N-Kwara Ti Jade La" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: