Gbagede Yoruba
 



Nitori Odun Oroko To N Bo Awon Idile Lajomo Ti Seleri Lati Gbe Omooba To Ba Ba A
 
Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
Lati Owo Florence Babasola, Osogbo

Nitori Odun Oroko To N Bo Awon Idile Lajomo Ti Seleri Lati Gbe Omooba To Ba Ba Ataoja Osogbo Lasepo Lo Sile-ejo

Bi ayeye odun Oroki ti ilu Osogbo se ku dede bayii, awon idile olomooba Lajomo ni awon ti pinnu lati gbe enikeni to ba pe ara re ni molebi awon, sugbon to n foribale fun Ataoja tilu Osogbo, Oba Jimoh Olanipekun, lo sile ejo.

Lakooko ipade kan ti agbarijo awon olomooba ilu Osogbo se laipe yii ninu eyi ti won ti fenuko pe idile Olude ati Aderohunmu nikan ni won je ojulowo idile olomooba Lajomo loro yii waye. Awon idile olomooba Lajomo salaye pe ijoloju lo je fawon pe awon kan ko ara won jo, ti won si so pe awon je idile Lajomo ati pe ohun gbogbo ti Oba Olanipekun ba se lawon fowo si.



Gege bi awon agbaagba ile Gbaemu se so, ko si ariyanjiyan nipa awon agboole to n joba niluu Osogbo, se lawon yen kan n tan Oba Olanipekun.

Alhaji Nasiru Oyeniyi lo soju ile Oluawo-Oba, Pa Claudius Fayoyiwa soju ile Sogbo, Matanmi ni Alhaji Asiru Oyewole soju fun, nigba ti Pa Salami Mogaji soju Lahanmi.

Awon baba yii ni, “Awon ti won ko ara won jo gege bii ile olomooba Lajomo kan n se bee lati lu Olanipekun ni jibiti ni nitori bi oro re se je, a si n fi akoko yii so fun gbogbo awon eeyan pe awa ko mo won ri, ati pe ile Olude ati Aderohunmu nikan la mo gege bii idile Lajomo ti won n joba niluu Osogbo.” Awon olori ile Aderohunmu ati ti Olude, Pa Liasu Olateju ati Pa Samotu Olaboye gbosuba fun awon idile olomooba to ku fun ipinnu won lati ma se ba itan ilu Osogbo je nipa diduro lori otito.

“Awa mo pe ko si enikeni lori ipo Ataoja ti ilu Osogbo bayii gege bi ile-ejo giga tilu Osogbo se so fun wa, a si faramo ohun gbogbo ti awon idile yooku ba ti so pe ka se lori oro naa titi digba ti otito yoo fi farahan. A wa n fi akoko yii so pe ti a ba tun ri enikeni to n pe ara re ni idile olomooba Lajomo sugbon ti a ko da a mo niluu Osogbo yii, onitohun yoo foju baleejo.”


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Monday, January 21 @ 05:45:24 PST Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin:
Buhari Omo Musa Sa Kuro Nibi Ayeye Igbeyawo Saidi Osupa: Lehin Ti Alfa Muri Fun


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin



"Nitori Odun Oroko To N Bo Awon Idile Lajomo Ti Seleri Lati Gbe Omooba To Ba Ba A" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com