Gbagede Yoruba
 



Oladejo Fesun Agbere Kan Iyawo E, Niyen Ba Ge Nnkan Omokunrin E Je Nibi Ti Won T
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara
Lati Owo Bisi Adesoye, Ilesa

Oladejo Fesun Agbere Kan Iyawo E, Niyen Ba Ge Nnkan Omokunrin E Je Nibi Ti Won Ti N Ja

Eyin ni Arabinrin Titilola Oladejo to n gbe lagbegbe Idifi, n’Ilesa, fi ge nnkan omokunrin oko re je, bee lo tun da omi-gbigbona lu u lakooko tawon mejeeji n ja l’Ojoru, Wesde, ose to koja. Nigba ti iyaale ile naa ri i pe iwa toun hu yii ko daa lo fese fe e. Esun ti Ogbeni Oladejo fi kan iyawo re ni pe nise lawon oloselu to wa n’Ilesa maa n gun un bii esin. Eni ti oro naa soju e, Ogbeni Fakayode, lo fi isele naa to Iwe Iroyin Yoruba leti l’Ojoru, Wesde, ose to koja.

Ninu iwadii t’Iwe Iroyin Yoruba se ni Ogbeni Fakayode ti ni Arabinrin Titilola je osise ijoba ibile kan ni ekun Ilesa, o si bimo kan toruko re n je Temilola, iyen leyin odun marun-un toun ati oko re se igbeyawo won.



Bee lo ni Titilola je eeyan kan to feran lati maa kopa ninu ipade egbe oloselu woodu keji.
Ogbeni Fakayode ni orisiirisii esun loun ti gba lori iwa agbere tiyawo Oladejo gun le lodo awon omo egbe oloselu naa. O te siwaju pe opo igba ni oko re maa n fi ejo re sun oun, toun si maa pe e lati ba a so eyi to n je ooto oro, kaka ko gbo, nise lo ko eti-ikun si gbogbo ibawi oun.

Nigba ti Iwe Iroyin Yoruba n ba Ogbeni Oladejo soro nileewosan kan nibi to ti n gba itoju lori nnkan omokunrin re ati bi omi-gbigbona se bo o ni gbogbo ara lo salaye fun akoroyin wa pe oun ko ti i le soro kankan lakooko naa, afi toun ba gbadun ti nnkan omokunrin oun ba si pada sipo to wa tele. Sugbon o fi ibi ti Titilola ti da omi-gbigbona lu u ati ibi ti dokita ti ran nnkan omokunrin re pelu bandeji funfun ti won we mo on han akoroyin wa. Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jo, ko seni to mobi ti Arabinrin Titilola wa, bee ni ko si nibi ise re, eyi to je kawon eeyan so pe o see se ko padanu ise re nijoba ibile to ti n sise.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Monday, January 21 @ 06:16:44 PST Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara:
Asiri Nla Alaaji Amosa So Itan Igbesi Aye Re, O ni: Anjonnu Ni Mo Fe Niyawo


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara



"Oladejo Fesun Agbere Kan Iyawo E, Niyen Ba Ge Nnkan Omokunrin E Je Nibi Ti Won T" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com