Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo
[ Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo ]

·E Waa Wo Simia To Pa Oree Re L'Osogbo o
·Nitori Foonu, Baale Ile Meji Jabo Sinu Konga, Loju Ese Ni Won Ku
·Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
·Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
·O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
·Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
·Grace Atale Re Pa Oko e N'Iyana-Ipaja
·Oro o, Iku Gbigbona Leleyi o! Nibi Ti Johnson Ti n Taja Loju Titi L'Akure N
·O Ma Se O! Dauda To n Tun Redio Se Gan Mona L'Osogbo

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Wahala Egbe Onimoto n’Ibadan, Akinsola Tokyo Pariwo, O Ni: E Ba Mi Be Gomina Aji
 
 
Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Wahala Egbe Onimoto n’Ibadan, Akinsola Tokyo Pariwo, O Ni: E Ba Mi Be Gomina Ajimobi Ati Oga Olopaa Ipinle Oyo Pe Ki Won Tele Ase Ile-ejo, Ki Won Da Mi Pada Sipo Mi

Nigba ti iroyin gba ilu kan l’Ojoru, Wesde, ojo karun-un, osu yii, pe won ti mu alaga egbe awon awako lorile-ede yii (NURTW), eka tipinle Oyo, Alhaji Abdulateef Akinsola Oloruntoki tawon eeyan tun mo si Tokyo, gbogbo aye lo n fe mo idi ti won se gbe e so sinu ahamo ati ibi ti oro naa yoo fori so.

Orisiirisii aheso lo n lo nigboro lori isele ohun.

Awon kan ni o jo pe ija nla ti be sile laarin Tokyo ati Go mina Isiaq Abiola Ajimobi tipinle naa ni, bee lawon mi-in ni nitori o n gbero lati fipa gbajoba egbe awako latari bi ijoba Ajimobi se ko lati tele ase ile-ejo pe ki won da a pada sipo e gege bii alaga egbe awon awako ero nipinle Oyo ni, atawon oro mi-in.Eyi lo mu ki Iwe Iroyin Yoruba wa baba naa kan lati mo ohun to sele gan-an ati ibi ti oro akoso egbe NURTW n lo. Ninu iforowero ohun ni Tokyo ti salaye irin-ajo e si ahamo awon olopaa n’Iyaganku, n’Ibadan atawon oro mi-in ti opo eeyan ko ti i gbo lenu e ri.

Iwe Iroyin Yoruba: Iroyin to mi ilu titi lose to koja ni iroyin bawon olopaa se mu yin so satimole, bawo lo se je?

Tokyo: Won o waa mu mi ninu ile mi o, olopaa ko waa mu mi ninu ile o, mo fi ese ara mi rin lo sibe ni, emi ati looya mi la jo lo. Emi ni mo lo sibe funra mi lati loo so awon awijare mi lori awon esun ti won fi kan mi.

Iwe Iroyin Yoruba: Bawo wa loro se pada ja si ti atimole?

Tokyo: Nigba ti mo debe, oga agba olopaa so pe, ‘Se iwo ni won n pe ni Tokyo?’ Mo ni bee ni. O loun maa areesi mi, ki n gbe owo mi wa. Mo gbe owo fun won, won si so ankoobu si mi lowo, won ti mi sinu oko ti won maa n gbe lo si oju ija. Won gbe mi lo si Iyaganku, won si se iwadii oro lenu mi; awon logaa logaa lenu ise olopaa ni won fi oro wa mi lenu wo, awon igbakeji oga agba olopaa meta. Won ni oro rogbodiyan to sele ni Iwo Road (ija to waye laarin awon iko egbe awako NURTW, ninu eyi ti opo emi ati dukia ti sofo lodun to koja), ki ni mo mo nipa e. Mo so fun won bi oro se je, bo se je pe mi o si nile lojo yen, lojo kin-in-ni, lojo keji, Eko ni mo wa, mi o si ran eeyan loo fa wahala. Won ni awon wo ni mo fura si pe won lo sibe, mo si so o fun won. Esun yen ki i se temi rara, emi ki i si i se odaran; mi o ni ibon, mi o mo ibon i yin. Aafaa nla ni mi o, omo aafaa si ni mi.

Iwe Iroyin Yoruba: Awon esun wo lawon olopaa fi kan yin?

Tokyo :: Esun orisii meta ni, won si ri i pe ko mo mi lowo, ko mo mi lese. Esun ija Iwo Road pelu ti Too Geeti ati ti awon ode to n so ile Eleweomo (okunrin ti oun naa ti figba kan je alaga egbe NURTW lasiko ti won le Tokyo kuro nipo naa lona ti ko bofin mu). Won ti gbe mi lo si kootu lori e, ejo iyen si n lo ni kootu, won ko saa le pe eeyan lejo leemeji lori esun kan soso. Ti Iwo Road naa, mo ni eri lowo to fi han pe mi o si nibe, bee ni ti Too Geeti naa, mo ni gbogbo awon eri ti won fi da mi lare lori gbogbo e lowo. Mo saa salaye gbogbo e fun won, won si ni ki n wa oniduuro meji wa, mo si wa won. Won ni ki n maa lo, mo si wale. E je ki n fi asiko yii dupe lowo awon olopaa fun bi won se farabale se iwadii lori awon esun ti won fi kan mi ati bi won se n se iwadii lori oro rogbodiyan Iwo Road yen. O fi han pe oga agba patapata fawon olopaa lorile-ede yii, (MD Abubakar) ti mu ayipada rere ba ise olopaa, awon eeyan ko si ni i gbagbe ise takuntakun ti oga agba olopaa nipinle Oyo (Mbu Joseph Mbu) naa se lori iwadii esun yen. Ise nla ni won n se.

Iwe Iroyin Yoruba: Ki waa ni awijare yin lori esun ti won fi kan yin nipa iku awon ode ile Eleweomo?

Tokyo: Akoba lasan ni. Won kan mo-on-mo fee fi oro yen koba mi ni. Eje maalu ni won da sinu ogba ile Eleweomo nigba yen, won waa gbe awon ode yen pamo. Sugbon nigba ti asiri abosi won maa tu, awon eeyan mi ri awon ode yen ni Too Geeti, igba yen la too mo pe won ko ku, Eleweomo kan fee fi esun yen koba mi ni, lati igba yen lo ti le wa kuro lofiisi. Mo si lo si kootu, mo gba idajo nibe pe ki n pada si ofiisi mi; o di idajo bii meta ti mo gba pe ki n pada si ofiisi mi to je pe awon eeyan n di wa lowo, won o je ka lo. Mi o si fee so o dija, mi o fee ja nitori mi o le ja, mi o lagbara ija. Nitori e la fi n be oga agba awon olopaa ipinle Oyo pe ki won tele ofin, ki won da mi pada si ipo mi. Mo si n be Gomina Ajimobi naa ko je ka tele ofin nitori ofin lo gbe oun naa de ipo to wa yen, ko je ki ofin to da emi naa pada si ipo mi sise. Emi ki i se oniwahala eeyan, sugbon a ko le gbe idajo kootu si egbe kan, idajo ileejo ko se e fi oju pare. Ka waa so pe awon kiateka kan ni yoo maa sakoso egbe lo, ko se e se bee.

Iwe Iroyin Yoruba: Lojo Eti to koja ni Ogbeni Dauda Kolawole ti i se alukoro egbe oselu ACN lu ileese olopaa logo enu fun mimu ti won mu yin ti won si tun gba won niyaju lati pe yin lejo lori ija to waye laarin awon omo egbe awako kan ni Iwo Road lojo kerin ati ojo karun-un, osu kejo, odun 2011. Ki le ri so si i?

Tokyo: Dauda Kolawole to n soro, to ni nise lo ye ki won gbe mi lo sile-ejo, nibo loun wa nigba ti awa n ja fun ijoba awa-ara-wa, emi ati Baba Lam.

Won jo mu wa ti mole logba ewon laye Abacha ni nitori pe a n ja fun ijoba awa-ara-wa, iyen nigba ti gbogbo omo Naijiria dibo yan MKO Abiola gege bii Aare orile-ede yii, sugbon ti won ko je ko de ipo yen. Iyen lawa n ja fun nigba yen ti Abacha to je Aare tori e mu wa ti mo ewon. Ewon Agodi kan naa ni won ti emi ati Baba Lam mo nigba yen. Ajo wa ninu egbe NADECO(egbe to n ja fun ifeserinle ijoba alagbada nile yii laye ijoba ologun) nigba yen ni pelu Ogbeni Ola Oni ati Adeoti to wa nileese iwe-iroyin The Sun bayii, won jo mu wa lo sewon nigba yen ni. Leyin igba yen ni Baba Lam jade to loun fee se Gomina, gbogbo wa la jo gbaruku ti i ta a polongo ibo fun un to fi wole. Ba a se dibo gbe Ajimobi naa wole niyen to fi se saa keji nipo Seneto.

Oun nikan naa fee ni Seneto to wole loruko egbe AD nigba yen. Gbogbo nnkan ti Dauda Kolawole n so yen, Ajimobi gan-an ko le so iru e si mi nitori o mo pe eeyan mi loun. Boya ise owo ti won fun Kolawole lo n je yen, nitori o se e se ko je awon oloselu lo gbe ise yen ran an. Kin ni oun mo nipa oselu? O kan fee te awon oloselu to n fun un lowo lorun lasan ni.

Ki lo mo nipa ba a se gbe Ajimobi wole Seneto labe egbe AD? Nje oun mo ipa ti mo ko lori bi Ajimobi se di Gomina? O ye ka bi Kolawole leere pe ki ni oro egbe osise se ni i se pelu egbe oselu. Nje oun mo pe egbe kan ti se iwadii won, leyin iwadii ni won si ko leta si ile-ejo giga pe mi o mowo-mese lori esun ti won fi kan mi nipa rogbodiyan to waye ni Iwo Road?

Iwe Iroyin Yoruba: E ni e ti Seneto Ajimobi leyin lati wole ibo Seneto nigba naa lohun-un, ipa wo le ko lori ibo Gomina to koja, ibo le fi si?

Tokyo: Mo polongo fun un, mo duro ti i. Gbangba ni mo so fun awon mekaniiki, awon alata, awon eleran, awon onimoto ati gbogbo araalu pata pe Ajimobi la n ba lo.

Iwe Iroyin Yoruba: Iyen lawon eeyan se ro pe logan le maa pada sori ipo gege bii alaga egbe awako bo ba fi le wole ibo, ki lo waa de ti ko pada ri bee mo@ Tokyo: Gbogbo aye lo n reti e. Emi o waa mo ohun to n sele. Nnkan ti emi ro ni pe awon eeyan lo n si i lona. Awon adarugudu-sile, awon afe-a-je-ma-fe-a-yo, awon ni won n si i lona. Omoluabi ni Gomina, ki i se pe o ni iwa buruku lowo, eeyan daadaa ni, sugbon awon eeyan n si i lona. Oun naa si ti dagba, o ye ko mo pe awon eeyan kan n si oun lona ni. Awon kan ni won fee da wahala sile laarin emi pelu e bayii lori oro ise tiwa. Awon idajo ta a gba nile-ejo pe ki won da mi pada si ipo mi gege bii alaga NURTW ti te ijoba lowo, o ti te Aare wa lowo, o ti wa lowo igbakeji Aare, won mo pe mo ni idajo lowo.

Iwe Iroyin Yoruba: Ona wo le wa fee to lati ri i pe idajo yen fese mule@ Tokyo: Ko si ona ta a fee gbe e gba naa ju pe ki ijoba tele idajo kootu. Ki oga olopaa ipinle Oyo mu mi lo si ofiisi mi, ka si kilo fun awon omoleyin mi, ki onikaluku pada si ipo re nitori o ni ipo ti kaluku wa tele. Ohun to ku naa ni ki n pada si ofiisi, ki n le raaye se ijoba temi ti won da mi lare le lori.

Iwe Iroyin Yoruba: Atie gbo pe Gomina Ajimobi ko fee faaye gba ohun to n je egbe awako nipinle Oyo, nitori e ni won se fee fun yin ni ipo oselu, ti won maa yan yin gege bii okan ninu awon oludamoran fun Gomina.

Tokyo: Ko le so pe oun ko fe egbe NURTW mo nitori egbe yen ko si labe ijoba, a ko si labe egbe oselu kankan. Egbe osise ni wa, abe egbe osise orile-ede yii ti won n pe ni NLC la wa.

Nitori naa, won ko le so pe awon ko fe e mo. Gbogbo e naa wa lara ejo ti mo gbe lo si kootu, kootu naa si so pe ki ijoba ma da si oro egbe wa mo< kootu ti wo o pe Gomina o lagbara lati gbese le egbe onimoto. Ojo karun-un, osu karun-un, odun yii, ni mo gba idajo yen. Mo ti koko gba okan tele laye ijoba Akala, sugbon ti Bolanta (Baba Adisa Bolanta to je oga agba olopaa ipinle Oyo nigba yen) ko tele idajo naa. Igba ti Ajimobi fee se Gomina lo so fun mi pe oun maa gbe mi de ipo yen ti oun ba wole, o si wole bayii, ko mu ileri e se la n reti bayii lati odun kan aabo, to ti n lo bii odun meji bayii. Sugbon ki i se pe ko fee se e, awon kan lo n gbe igbekugbe si i lokan nipa mi, molebi kan naa si ni wa.

Iwe Iroyin Yoruba: Oro ipo oludamoran ti won ni won fee fun yin nko@ Tokyo: Ki ni mo fee fi S.A(oludamoran pataki) se.

S.A. Gomina, ki ni mo fee fi se, hee!

Iwe Iroyin Yoruba: Se pe molebi Gomina Ajimobi ni yin?

Tokyo: Aburo e ni iyawo mi. Ana ni Ajimobi je fun mi.

Iwe Iroyin Yoruba: Se a waa le so pe Gomina dale yin ni bayii?

Tokyo: Emi o so pe o dale mi o. Awon eeyan ni won n fun un ni imoran ti ko daa, ki i se pe o dale mi. Mo si nigbagbo pe o maa da mi pada si ipo mi gege bii alaga egbe awako, a si maa fowo-sowo-po pelu awon araalu ati ijoba.

Iwe Iroyin Yoruba: Se loooto ni pe awon agba egbe oselu PDP pe eyin ati Alhaji Mukail Lamidi tawon eeyan mo si Auxilliary lo si Abuja lati pari ija to wa laarin yin?

Tokyo: Isokuso niyen. Ojo kan wa ti oga agba awon olopaa lorile-ede yii ko leta si mi pe ki n wa, mo si loo ba won. Won kilo fun wa gidi pe ka loo fowo-sowo-po, ka ma je ki ija maa wa; Auxilliary naa wa nibe. Igba ti mo si mo pe mi o jebi awon esun ti awon olopaa ipinle Oyo fi kan mi naa, mo lo sodo won, PDP kankan o pe mi. Eni to tun le maa pe mi bayii to le maa ba mi soro ni iru Lam Adesina, nitori inu iko kan naa la wa ninu egbe ACN. Se awon PDP ta a ti ja, awon ni won yoo pe mi ti ma a tun loo da won lohun? Igba ti Lam si ti ku bayii, ninu egbe ACN bayii, awon ta a tun le so pe won je asaaju fun mi ni iru Michael Koleoso yen to je akowe ijoba ipinle Oyo tele, awon bii baba wa Bisi Akande niluu Ila, iru awon Tinubu. Tinubu gan-an funra e, mo fee le so pe inu egbe kan naa la jo wa ta a fi loo dibo Abiola ni Jos, nitori naa Tinubu naa ki i se eeyan buruku si mi, bii tegbon taburo lemi pelu won, ore ni wa.

Mo lo sile tiwon naa pe ki won ba mi ba Ajimobi soro ki n le pada sipo mi. Ipinnu mi ni pe ki n lo saa mi to ku ki n seto idibo mi-in. Ipo yen ki i se oro a n yan eeyan sibe bii ipo oselu to je pe Gomina yoo yan eni to ba fe sipo kan labe e, ibo la n di de ipo egbe tiwa. Eni to ba si wole ibo naa ni yoo maa sakoso egbe lo, emi naa yoo waa jokoo nile bii baba. Ipinnu mi niyen, ki Olorun Oba fun mi se.

Iwe Iroyin Yoruba: Eyin pelu baba Adedibu le gbe Otunba Akala wole sipo Gomina ipinle Oyo, omo egbe oselu PDP lawon yen, e si ni ojulowo omo egbe ACN ni yin lati ibere pepe, bawo lo se je@ Tokyo: Igba to di saa keji niyen. Nigba ti Ladoja fee se saa keji, oun naa fesun kan mi pe mo wa lodo Lam, pe mi o se toun. Oun naa ba puro mo mi pe enikan ti won ji gbe l’Ogbomoso, pe emi ni mo ji i gbe. Oro yii, ori Ladoja lo ti bere; Ladoja gan-an lo n da ilu yii ru, oun lo si da egbe wa ru, o gbe Wasiu Tawa pon lati maa tako wa. Wasiu Tawa ki i si i se omo ilu wa nihinin, omo Iwo ni, omo Ibadan si lawa. Iya mi, baba mi, Ibadan ni won. Ladoja gan-an wa ninu awon to n si Ajimobi lona pe ki n ma de ori ipo yii, sugbon Ajimobi gan-an ki i se omode, o ti le leni ogota odun, o ye ko mo ohun to to ati ohun ti ko to.

Nisin-in-in gan-an bayii, agba egbe ti kan an nitori pe eni to je agba egbe naa lo ti ku yen, eni to si tun kan to tun le je agba egbe naa ni oun Ajimobi yen. Majiyagbe Akoko ni won so Lam lasiko ijoba won nigba aye won, emi ni Majiyagbe Keji. Igba ti Ladoja gba ijoba lowo Lam tan to ti mi mole ni Baba Adedibu saanu mi ti won se kokari bi mo se jade lewon. Eyin igba yen ni mo waa gbe Tawa lo si kootu, kootu waa gba ijoba mi pada fun mi lowo e. Idi ti mo fi fara mo Baba Adedibu niyen ta a fi jo gbe Akala sipo Gomina. Nigba ti Akala naa si gbe owo tie to gbe, ti ko fe imi mi laatan mo, to ni nise loun maa wo ile egbe wa ta a fi owo wa ko le mi lori ni mo kuro lodo e, mo pada sinu egbe oselu mi ti mo wa tele, iyen AD ti a n pe ni ACN loni-in.

Iwe Iroyin Yoruba: A gbo pe nigba ti e si wa lori isakoso egbe awako, ti Otunba Akala wa nipo Gomina, won n gbero lati loo se ipolongo ibo fun saa keji nitosi ile egbe yin laduugbo Olomi, n’Ibadan, won si ti kan atibaba ti won maa gun ba awon eeyan soro sile, sugbon iyalenu lo je fun awon ero to n reti Gomina nigba ti ko papa lo sibe. Won ni nitori yin ni Gomina Akala se yi ipinnu re pada nitori e ti kilo fun un pe won ko gbodo waa polongo ibo ni akata yin. Se loooto ni?

Tokyo: So waa wa? So waa wa? Ko le wa nigba ti aarin emi pelu e ko gun, yoo waa se kampeeni nita mi, nijoba ibile mi. Ibi to si ti fee se kampeeni to fee kan pako si, iwaju ita mi gan-gan ni, iwaju ita ile mi ni. So se e se bee? To ba je pe ti ojo ni, emi ki i se ojo o.

Iwe Iroyin Yoruba: Bawo ni ibasepo yin pelu Alhaji Oyerinde Fele ti i se alaga igbimo ti ijoba Seneto Ajimobi yan lati maa sakoso egbe NURTW se ri?

Tokyo: Ko si ibasepo kankan laarin wa. Bi Gomina tie se fi se kiateka, bi oun se debe bayii, moto mi lo koko le jade. Oko boosi bii marun-un ni mo ni ni garaaji, o koko le gbogbo e jade. Gbogbo ibi ti mo ti n ri toro kobo gba, o dina mo on. Mo si pe won pe e wa, won ki i se aye bayii, bi e ba fe ka jo se papo, e waa ba mi ka jo so o, ke e so nnkan te e ba fe maa gba lowo mi; iro ni, ko gba.

Ninu awon to si da egbe awako yii sile lodun 1978, iwe ase iwako mi wa ninu awon nnkan ta a lo ti won fi fowo si i pe ka da egbe NURTW sile kaakiri orile-ede yii nitori ipinle Oyo yii ni egbe NURTW ti bere ko too kari gbogbo ipinle to wa lorile-ede yii.

Iwe ase iwako mi pelu awon nnkan mi-in la fi ri iwe ase egbe yii gba nipase Baba Akinjide (Amofin Agba Richard Akinjide) ti won je alakoso eto idajo lorile-ede yii nigba yen. Egbe yii, a jo da a sile ni, se emi waa ni ko ye ki oko mi maa lo sibi ise? Awon ti o mo ko ni i se e, awon ti mo gba sinu egbe ni won waa le mi jade nipase Fatai Ibikunle, awon ni won jo n sepade ote ti won fi le mi.

Iwe Iroyin Yoruba: Bawo ni o se waa rorun fun yin to pelu ona ije yin te e so pe won di yii?

Tokyo: Nnkan ko rorun, mi o ri owo ileewe awon omo san. Odun keta aabo ree ta a ti wa lori laalaa-kookoo yii. Ajimobi ta a tun waa gbekele, oun naa tun wa n se wa bakan-bakan.

Iwe Iroyin Yoruba: Ti e ba wo iru awon iriri tee ti ni saaju, paapaa pelu bi e se so pe Gomina Akala paapaa dale yin nigba tiwon naa, nje iyen le mu ki e so igbagbo nu ninu awon oloselu debii ti e ko fi le se adehun pelu won mo bi?

Tokyo: Ti mo ba tie maa ba oloselu kankan se adehun po, a jo maa towo bowe ni, a jo maa jokoo se adehun ti yoo si fi owo siwee fun mi ni. O ni lati salaye anfaani ti emi naa maa je ninu ijoba re. A o kan le maa se wahala lasan ka maa jiya, a jiya pupo lori ibo to gbe Ajimobi wole, emi pelu Alaafin ati Aare Arisekola, emi ko si ri anfaani kankan je lodo ijoba rara ju iya lo. Bi mo pe Gomina, ko ni i gbe foonu mi; bi mo wa a lo sile, ko ni i da mi lohun. Ki waa ni mo se, ki ni ese temi gan-an niwaju Ajimobi bayii. Mi o si fa ijangbon, mi o bu u. Iya e ku, mo wa nibe, a jo sinku iya e ni. Mi o si ki i se eeyan buburu.

Iwe Iroyin Yoruba: Pelu bi e se n reti ki ileese olopaa ipinle Oyo mu ase ile-ejo se lori ipadasipo yin, nje e ni i lokan lati gbesan ohun ti Alhaji Fele se fun yin bi?

Tokyo: Olorun loba elesan. Mi o le gbesan lodo eni kankan, emi ki i gbesan, Olorun temi lo ni ki n ma gbesa. Olorun nikan loba elesan ti yoo gbesan lowo kaluku to ba se aidaa.

Iwe Iroyin Yoruba: Ki ni imoran yin fun ijoba atawon alatileyin yin?

Tokyo: Ki awon alatileyin mi te siwaju lati maa je ki alaafia joba gege bi won se n se lowolowo.

Imoran mi fun ijoba ni pe ki won maa se itoju araalu, ki won ma je ki ebi pa awon eeyan. Awon ti won se atileyin fun won ti won fi de ori ipo, ki won fun won lounje, ki won ma se gba ounje lenu won rara, ki won fun kaluku letoo re. Emi naa, o ye ki n maa je ninu ijoba, ki won gbe ise agbase fun mi tabi ki won fi ona ti ma a ti maa jeun han mi. Sugbon pe ki emi wa loo se S.A Gomina, rara o. Mo ti ju iyen lo, mi o le se e, ki ni mo fee fi se.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Monday, January 21 @ 06:37:30 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin:
Buhari Omo Musa Sa Kuro Nibi Ayeye Igbeyawo Saidi Osupa: Lehin Ti Alfa Muri Fun


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin

"Wahala Egbe Onimoto n’Ibadan, Akinsola Tokyo Pariwo, O Ni: E Ba Mi Be Gomina Aji" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: