Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Abiru Ki Leleyii? Nitori Ija To Wa Laarin Jelili Atawon Ore E, Won Si Fibinu Lu
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Florence Babasola, Osogbo

Abiru Ki Leleyii? Nitori Ija To Wa Laarin Jelili Atawon Ore E, Won Si Fibinu Lu Iya E Pa

Afaimo ni kawon omokunrin mefa kan, Saka Abbas, omo odun mokanlelogun, ti agboole Imale-Falaafia; Kadiru Lapade, omo odun mokanlelogun; Muritala Opeyemi, toun naa je omo odun mokanlelogun, to si n gbe lojule kin-in-ni, lagbegbe Olapade, niluu Osogbo; Lateef Owolabi, omo ogun odun, Sodiq Adigun, omo odun mokandinlogun, to n gbe ni nomba 24, Oke Baale, niluu Osogbo ati Lateef Owolabi, toun naa n gbe niluu Osogbo, ma sodun tuntun ti a n wo loookan yii ninu ogba ewon lori esun ipaniyan ti won fi kan won.

Inu buruku la gbo pe o bi awon eeyan yii, eyi to je ki won fibinu lu iya ore won, Arabinrin Sidikatu Tajudeen, ti won jo n ja lalubami, ti obinrin naa si je ipe Olorun leyin ojo keta.Gege bi alukoro ileese olopaa nipinle Osun, Arabinrin Folashade Odoro, se salaye fun Iwe Iroyin Yoruba, ojo kesan-an, osu kejila, ti a wa yii nisele naa sele ni nnkan bii aago meje ale.

Ede-aiyede kan lo sele laarin awon omokunrin mefeefa naa pelu Jelili Tajudeen, won ja titi tawon eeyan agbegbe ohun fi da won lekun. Sugbon oro naa ko tan ninu won, idi si niyi ti won tun fi pe ara won jo, ti won si fori le ile awon okunrin naa.

Ibinu pe awon ko ba Jelili nile la gbo pe won fi pinnu lati fi ami sile de e, ti won si na iya re ti won ba nile lalubami. Awon araadugbo lo gbe obinrin naa digbadigba lo sileewosan nitori bi eje se n da lara re.

Bo tile je pe ojo tisele yen sele ti won si ti gbe iya eni ogota odun naa lo sileewosan ni won ti setoju re, sibe obinrin naa ko ni ilera pipe.

Nigba to si dojo keta isele naa, iyen ojo kokanla, osu kejila, ti a wa yii, Arabinrin Sidikatu jade laye.

Okunrin kan toruko re n je Owolabi Kazeem, to n gbe lojule kefa, lagbegbe Owolabi, nikorita Alie, niluu Osogbo, lo loo fisele naa to awon agbofinro leti. Bi awon agbofinro se gbo ni won ti koja sagbegbe naa, leyin iwadii finni-finni ti won se lowo te awon omokunrin yii, won si ti n ran awon olopaa lowo lori iwadii won.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Wednesday, January 23 @ 03:50:05 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Abiru Ki Leleyii? Nitori Ija To Wa Laarin Jelili Atawon Ore E, Won Si Fibinu Lu" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: