Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Segun Sa Ibrahim Ladaa Yannayanna L’Osogbo, Oro Obinrin Lo Fa Wahala
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Florence Babasola, Osogbo

Segun Sa Ibrahim Ladaa Yannayanna L’Osogbo, Oro Obinrin Lo Fa Wahala

Ileese olopaa ipinle Osun ti gbe omokunrin eni odun mejilelogun kan, Oseni Segun, lo sileejo lori esun pe o sa Abdulazeez Ibrahim ladaa lori ati legbee.

A gbo pe se ni Segun atawon ore re ya lo sile ti Ibrahim n gbe nidojuko Technical School, lagbegbe Dada Estate, niluu Osogbo, ni nnkan bii aago mejo ale ojo kefa, osu kin-in-ni, odun yii, ti won si se Ibrahim lese.

Pelu eje to si n jade legbee re, Ibrahim salaye fawon oniroyin lagbegbe kootu pe omokunrin kan tawon jo n gbe to n je Ayobami ni Segun atawon toogi re wa wa lale ojo naa, sugbon ti won ko ba a nile.O ni ariwo won loun n gbo latinu ile toun fi jade sita lati wo nnkan to n sele sugbon boun se jade bayii ni won bere si i sa oun ladaa lori ati legbee lai-besu-begba.
Ibrahim ni leyin isele naa loun too gbo pe orebinrin kan lo da wahala sile laarin awon toogi Segun ati Ayobami.

Agbejoro fun ileese olopaa, Inspekito Fagboyinbo Abiodun salaye fun ile-ejo pe olujejo naa koja aaye re, igbese re naa si le da wahala sile nitori nise lo kuro nijoba ibile Osogbo to n gbe lati loo ba eeyan ja nijoba ibile Egbedore.

Esun meji otooto ti ijiya won wa labe ofin iwa odaran tipinle Osun ni won fi kan olujejo, sugbon to so pe oun ko jebi won. Agbejoro fun olujejo, Bola Abimbola Ige, ro ile-ejo lati faaye beeli sile fun onibaraa re niwon igba ti ile-ejo ko ti i so pe o jebi awon esun ti won fi kan an.

Ige fi kun oro re pe tile-ejo ba fun onibaara oun ni beeli, ko ni i sa lo ati pe o setan lati pese awon oniduuro ti won loruko.

Nigba to n gbe idajo re kale, Adajo Majisreeti naa, Arabinrin H.O Basiru, gba beeli olujejo pelu egberun lona ogorun-un naira ati oniduuro meji ni iye kan naa.

Arabinrin Basiru ni awon oniduuro naa gbodo je osise ijoba ti ipo won gbodo wa ni ipele kefa soke. Leyin eyi lo sun ejo naa siwaju si ojo kefa, osu keta, odun yii.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Wednesday, February 13 @ 18:14:49 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Segun Sa Ibrahim Ladaa Yannayanna L’Osogbo, Oro Obinrin Lo Fa Wahala" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: