Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan, Olopaa Pa Agbofinro Egbe E L’Ondo
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Solomon Adewoye, Akure

Nitori Oro Ti Ko To Nnkan, Olopaa Pa Agbofinro Egbe E L’Ondo

Gbogbo awon ara adugbo Ejankole, lagbegbe Okerowo, niluu Ondo, loro naa si n ya lenu titi di akoko yii pelu bi olopaa kan, Ogbeni Kazeem Shehu, se sadeede yinbon pa agbofinro egbe e, Ogbeni Adekunle Lawal, lopin ose to koja lori oro ti ko to nnkan.

Gege bi iwadii se so, Ogbeni Adekunle Lawal to je olopaa ni tesan won to wa ni Yaba, niluu Ondo, ni ojugba re, Ogbeni Kazeem Shehu yinbon pa lojo Satide ose to koja nile igbafe kan to wa ni Ejankole Ninu oro tawon to wa nile igbafe naa ba awon oniroyin so, won ni nise ni Kazeem to je olopaa ni tesan won ni ilu Ajagba, nijoba ibile Irele, je ore timotimo fun Lawal, nise lokunrin naa wa lati ilu Ajagba lati waa ba a sere opin ose niluu Ondo tawon mejeeji si pinnu lati loo se faaji nile igbafe kan ki wahala too sele laarin won.Nibi ti Kazeem ati Lawal ti n takuroso ni ede aiyede ti waye laarin won, bee lawon to wa nijokoo gbiyanju lati ba won pari ija sugbon oro naa ko loju. Opo so pe nise lawon ro pe awon mejeeji jijo n sere ni pelu bi won se n pariwo mo ara won ko too di pe won bere si i se epe nla nla le ara won. Asiko yii ni Kazeem fa ibon pelebe kan yo to si yin in mo Lawal.

Loju-ese ni Lawal subu lule, ti opo eje si n jade lara re. Awon araadugbo naa so pe nise ni Kazeem fee sa lo ni kete to ri i pe Lawal ko le ye ogbe ibon naa, opelope awon to wa nibe ti won mu un, ti won si fi lulu se tie, n leje ba bere si i jade lara oun naa.

Nigba ti akoroyin wa de ago won to wa ni Yaba, nise lawon olopaa egbe Lawal to ku ko le pa ibanuje naa mora pelu bi oro iku re se ka opolopo won lara, bee ni ko seni to mo idi pataki ti Kazeem fi pa ore re timotimo yii.

Akoroyin wa ko ba oga awon olopaa to wa nibe, Ogbeni Adegoke Alani, ni ofiisi won so pe o ti jade lo lori isele naa. Bakan naa ni gbogbo akitiyan akoroyin wa lati ri igbakeji Komisanna awon olopaa, Ogbeni Hamzat Ameyi, tun ja si pabo. Sugbon okan lara awon olopaa to n sise ni tesan naa so fun akoroyin wa pe isele naa ba awon to ku lojiji nitori pe ore timotimo ni won.

Osalaye pe won ti gbe oku Lawal lo si mosuari ijoba to wa niluu Ondo, nigba ti Kazeem to je apaniyan naa ti wa latimole awon, bee lo ni awon ti gbe ejo naa lo si olu ileese won niluu Akure fun iwadii to peye.

Ninu oro alukoro awon olopaa ipinle Ondo, Ogbeni Wole Ogodo, o salaye pe loooto ni isele naa sele ati pe awon ti fi panpe oba gbe Ogbeni Kazeem toun naa je oga olopaa to hu iru iwa bee. Owaa so o di mimo pe iwadii to peye ti bere lori isele naa.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, February 28 @ 04:40:32 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Nitori Oro Ti Ko To Nnkan, Olopaa Pa Agbofinro Egbe E L’Ondo" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: