Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Ofo Emi Kan Ree O! Won Pa Eniafe Sinu Oko E N’Ilawe-Ekiti
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Stephen Ajagbe, Ado-Ekiti

Ofo Emi Kan Re! Won Pa Eniafe Sinu Oko E N’Ilawe-Ekiti

O ma se o Won pa Eniafe sinu oko e n’Ilawe- Ekiti*Owo olopaa ti te awon afurasi Ni nnkan bii aago mesan-an aaro ojo Satide to koja yii ni won sadeede ba oku okunrin ohun, Oluropo Eniafe, ninu oko e, ko si senikan to ti i mo eni to seku pa a. Isele ohun sele laduugbo Afunremu, lagbegbe Oke-Imedo, niluu Ilawe-Ekiti.

Ninu iwadii Iwe Iroyin Yoruba la ti gbo pe awon eeyan mo oloogbe naa si onisowo koko nla, to si gbajumo daadaa. Oko re lo lo laaaro ojo buruku yii to fi salabaapade iku aitojo. Koda, won ni oloogbe naa sese ko lo sile e tuntun to pari ninu osu kejila, odun to koja yii, ni.Loju-ese lawon to wa lagbegbe naa ta awon olopaa ilu Ilawe-Ekiti lolobo, nigba tawon olopaa yoo de ibi isele naa, oku okunrin ohun ni won ba ninu agbara eje pelu opolopo ogbe lara e. Won gbe e lo sileewosan gbogbogbo tijoba niluu Ilawe fun ayewo lati mo iru iku to pa a, bakan naa lawon agbofinro tun da agbegbe naa si ti won si sekilo fawon araalu lati ma rin ni bebe ibe.

Iyawo oloogbe naa, Arabinrin Eniafe, salaye pe oko oun ko ni wahala tabi ija pelu eni kankan, jeje e lo si maa n lo< bee, awon omo merin ni oloogbe naa fi saye lo.Okan lara awon aburo oloogbe naa, Ogbeni Boluwaji Eniafe, to ba akoroyin wa soro so pe nigba tawon reti re lati ojo Fraide to ti lo soko tawon ko ri i ko de lawon gba ibe lo, sugbon nigba tawon yoo de oko, ipo tawon ti ba a buru jai. Se ni won fi ada sa a lagbari, bee leje n san soro-soro lara e.Ogbeni Boluwaji salaye pe ko too digba naa lawon Fulani daran-daran kan ti n yo awon eeyan lenu ninu oko, o si se e se pe lasiko ti oloogbe naa wa ninu oko lo salabaapade won ti won si seku pa a. O ni oloogbe naa ko ba enikeni ni gbolohun-aso rara ko too di pe isele naa sele. Nigba ti akoroyin wa beere pe nje gbogbo eya ara oloogbe naa pe pere lasiko ti won ri oku e, Ogbeni Boluwaji ni ko si eya ara e kankan to sonu, gbogbo e lo pe.Awon ebi oloogbe yii waa ro awon agbofinro lati wadii isele naa daadaa ki won si fiya to to je awon to wa nidii isele buruku naa.

Akoroyin wa tun gbo pe ko too di igba ti won ri oku okunrin naa, awon araalu kan ke gbajare lo saafin oba ilu Ilawe, nibi ti won ti so pe awon Fulani daran-daran kan wa si agbegbe oko awon ti won si n yo awon lenu. Gbogbo oro yii ni won n yanju lowo laafin ko too di pe won sadeede gbo iroyin iku baale ile naa.

Alawe tilu Ilawe, Oba Adebanji Ajibade, gba awon araalu niyanju lati fokan bale, ki won gba awon agbofinro laaye lati sise won, ki won si yago fun wahala.

Lasiko to n fidi isele ohun mule, agbenuso ileese olopaa nipinle Ekiti, Victor Babayemi, so pe awon si n sewadii lati mo awon to seku pa okunrin naa, sugbon owo awon ti te awon afurasi meji kan tawon si ti n po won nifun po ki won so ohun ti won mo nipa iku oloogbe naa.O waa fokan awon araalu bale lati maa ba ise won lo nitori ko sewu rara. O gba won niyanju lati ran ileese olopaa lowo ti won ba ni iroyin ti yoo se awon agbofinro lanfaani lona ati fi panpe oba mu awon onise ibi naa.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Wednesday, March 20 @ 03:14:05 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Ofo Emi Kan Ree O! Won Pa Eniafe Sinu Oko E N’Ilawe-Ekiti" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: