Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Nitori Oro Ile, Won Fi Toogi Le Awon Ara Abule Adunbi, Ni Ewekoro, Kuro Niluu
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Johnson Akinpelu, Abeokuta

Nitori Oro Ile, Won Fi Toogi Le Awon Ara Abule Adunbi, Ni Ewekoro, Kuro Niluu

nka nko fi bee senuure fawon eeyan to n gbe ni abule kan ti won n pe ni Adunbu, nijoba ibile Ewekoro, nipinle Ogun pelu bawon toogi se ya bo won lojo Aje, Monde, ose to koja ti won si le won kuro labule won.

Titi di akoko ti a n ko iroyin yii, se ni abule naa da bii ibi ti ofo ti se nitori gbogbo won ni won ti sa asala femii won, tawon toogi si gbakoso pelu awon ohun ija oloro bii ibon, ada atawon nnkan mi-in.Gege bi Iwe Iroyin Yoruba se gbo, lakooko tawon egbe idagbasoke abule naa n se ipade lowo lawon toogi naa ya bo won ti won si bere si i da seria fun won. Awon ti won so pe won saaju awon omoota naa wa ni Alimi Muraina Solabi, Fasasi Solabi, Kazeem Solabi, Waidi Solabi ati Alaaji Amoo Solabi.

Won lo ti pe toro ile ti n da wahala sile laarin awon idi igi marun-un ti won ni abule naa, awon naa ni: Enitinwa, Ogunjobi, Ikudaisi, Falola ati Solabi. Sugbon won ni awon Enitinwa so pe opo ile ni won ti gba mo awon lowo, ati pe won ki i fawon letoo awon bo se to.

Awon ebi Enitinwa yii ni won loo darapo mo awon toogi ti won si loo kogun ba awon to wa labule, ti won si le won jade nibe.

Awon ara abule naa fesun kan awon olopaa, won ni won ledi apo po mo awon toogi naa lati da ilu ru. Iwe Iroyin Yoruba tun gbo pe won ti koko mu Baale ilu naa, Oloye Olalekan Ogunjobi, ati akowe e, Oloye Ranti Falola atawon meta mi-in satimole awon olopaa ni Eleweran ko too di pe won ni ki won gba beeli won.

Akoroyin wa tun salabapade awon ara abule naa topo won je obinrin nileese ijoba ibile Ewekoro, nibi ti won ti fee ri alaga naa, Ogbeni Dele Soluade, lati gba won lowo awon to le won kuro nile won lojiji.

Ninu oro ti Arabinrin kan, Mujidat Dauda toun naa n gbe labule naa ba Iwe Iroyin Yoruba so, o ni iyalenu ni isele naa si n je fawon. Osalaye pe o ti le logbon odun toun ti n gbe labule naa tiru nnkan bee ko si sele ri.

Mujidat te siwaju pe Kazeem wa lara awon to da wahala naa sile lojo yii. Adura lo ni won n se lowo nibi ipade tawon toogi yii fi de ti won ni kawon duro, kawon too wi nnkan kan, ija nla ti bere, awon o si le duro tilekun tawon fi sa kuro nile.

Nigba ti iya agbalagba kan, Amuda Ogunjobi, to ti le logota odun n ba Iwe Iroyin Yoruba soro pelu omije loju, iya naa ni bi ki i baa se opelope Olorun, oun ko ba ma si i laye mo nigba tawon Kasimu ko wahala won de. Oni inu igbo kan lawon sun mojumo ojo keji.

Sugbon Baale ilu naa, Oloye Olalekan Ogunjobi, ti ro ijoba ipinle Ogun pe ki won jowo gba awon lowo awon onise ibi naa. Oni opo awon ara abule naa ni won ko le pada sile won mo, nitori won ko mo nnkan to tun le sele, bee ni awon omoleewe naa ti gbolude apapandodo.

Baale so pe ogbon ati gba awon nnkan ti ki i se tiwon lawon eni to wa n da wahala sile yii n da, sugbon Olorun ko ni i gba fun won.

Iwe Iroyin Yoruba tun gbo pe awon to n fa wahala naa ko fe kawon oniroyin gbo soro ohun, gbogbo ona lati pa a mole ni won n wa, bee ni won n hale mawon kan ninu abule naa pe won ko gbodo ba oniroyin kankan soro.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Wednesday, March 20 @ 03:22:38 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Nitori Oro Ile, Won Fi Toogi Le Awon Ara Abule Adunbi, Ni Ewekoro, Kuro Niluu" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: