Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun
[ Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun ]

·Gbigba Kadara Gbo - Al-Imaan Bi-l-Qadar (Ayanma Tabi Akosile)
·Umaru Gbe Oogun Wo Kootu, Ladajo Ba Da Igbejo Duro Kia
·Fasasi Ko Iyawo e Sile N'Ibadan, O Ni Ko Ro Amala Fun Baba Oun
·Adajo Ni Ki Won Fi Emmanuel, Ayederu Looya, Sogba Ewon Kirikiri
·Alake To Fee Ko Oko Dero Ewon N'Ilorin
·Yekeen Fee Ko Munira n'Ilorin, O Ni Latigba Tawon Ti Fera Loun Ti n Ru, Tou
·Adajo Ni Kawon Ebi Oko Medinat Da Ogun Oko Re Pada Fun un
·Igbeyawo Ogun Odun Daru L'Osogbo
·Lori Oro Ti Ko To Nnkan, Awon Olopaa Fibon Fa Femi Lorun Ya, Ni Won Ba Sa Lo

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Awon Oloselu Te E Fee Tori Won Para Yin Ree O: Ebele Jonathan, Olusegun Obasanjo
 
 
Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
Lati Owo Adewale Adejare

Awon Oloselu Te E Fee Tori Won Para Yin Ree O: Ebele Jonathan, Olusegun Obasanjo, Nasiru El-Rufai - Eri Nwon Bi?

Nigba ti mo ri foto akoko yii, erin ni mo rin, mo rerin-in iyangi. Olusegun Obasanjo niyi ninu soosi Aso Rock to n gbadura fun Ebele Jonathan. Bee eni ti ko ba mo ni ko mo, eni ti ko si gbo ni ko gbo, aarin awon mejeeji ko dun rara. Bi enikan ba n so fun yin pe ko sija laarin ara won, ati pe gbogbo ohun ti e n gbo awon oniroyin lo kan n so o, e ma da tohun lohun, eni to so bee kan n tan awon araalu je lasan ni. Sugbon kinni kan to wa nibe ni pe ija to wa laarin won ki i seja nitori mekunnu, ija tawon oloselu n bara won ja nitori lati gba agbara lowo ara won ni. Ki i se ija kan to kan araalu, ko si soore kan tija bee yoo se fenikan, afi ara won nikan.

Bi eeyan ba ka asiri kan ti Nasiru El-Rufai, okan ninu awon omo Obasanjo sese tu sinu iwe to ko, to so pe nigba ti won fee dibo odun 2011, Obasanjo funra e mo pe Jonathan ko ni i se daadaa nile ijoba, nitori niwon igba ti Yaradua ku to fi sejoba, o ti fi han pe ko ni i laseyori gidi kan. Baba naa ti ri eleyii, o si so pe kawon wa ona lati fa elomiiran kale, kawon omoose toun le wa nile ijoba. O so fun El-Rufai ko loo ba Muhammadu Buhari, ko si so fun un pe ti Buhari ba ti le gba koun fa Okonjo Iweala kale gege bii igbakeji re, oun yoo ran an lowo lati di aare, oun yoo si seto bi egbe Labour atawon Bola Tinubu paapaa yoo se gba tie, nitori awon yoo so fun Tinubu ko fa eni ti yoo solori ile igbimo asofin agba kale, bo ba si je oun funra re lo fee se e, nipa bee, Buhari legbe ACN yoo dibo fun. El-Rufai lo tu asiri yii sita.N ko ba ti gba oro naa gbo rara, nise ni n ba kan so pe oro awon oloselu ti won n wa ona lati ba oruko Obasanjo je ni. Sugbon mo ti wa nibi kan tawon agbaagba Yoruba kan pe Pasito Tunde Bakare lati waa salaye idi to fi gba lati se igbakeji Buhari, oro ti Bakare so nibi ipade naa ko yato lese kan bayii sohun ti Rufai so. O ni Rufai yii lo waa pe oun nigba toun taku pe oun ko se igbakeji Buhari, o ni kawon jo lo sodo Buhari nitori oun nise pataki kan, ati pe loju oun lo ti so fun un pe Obasanjo loun yoo je ki Buhari di aare to ba ti le gba koun fa Okonjo kale bii igbakeji re, o ni inu oun dun nitori oun ti mo pe iyen yoo yo wahala lorun oun ni, afi nigba ti Buhari taku pe oun Bakare loun fe, nitori Obasanjo ko se e gbarale bi oro ba ti doro oselu, nitori lojiji ni yoo tun pada leyin oun.

Sugbon ki i se pe Obasanjo deede sohun to n se nigba naa, o n ba Jonathan ja nitori oro ija to n lo lowo laarin oun ati Gbenga Daniel, ti Jonathan si n feyin pon Daniel atawon egbe e debii pe ile-ejo kan ti dajo pe awon omo Obasanjo ko le dupo kankan loruko egbe PDP ipinle Ogun ni. Sugbon lojuese ti Jonathan ti ribi tina oro n jo lo, to ti dogbon ki adajo to so iru oro bee sawon omo Obasanjo pe ki won wa orin mi-in ko, tawon yen ti da oro awon omo Daniel nu, ti won si gbe agbara PDP Ogun le Obasanjo lowo pada, baba fi Jonathan lorun sile, o si so fawon ElRufai pe ki won fi Jonathan sile, ohun tawon yoo se ni lati ko awon eeyan awon to po sabe re, awon ni yoo si maa ba a se ise ti ko le se. Sugbon nigba ti agbara de owo Jonathan tan, awon araalu re ni ko le Obasanjo legbee re, nibi ti wahala ti de niyen.

Lojoojumo ni Obasanjo n bo sita to n tako gbogbo igbese Jonathan, bee lawon omo eyin re ti won ba a sejoba tele n dana gidi mo okunrin olori Naijiria yii labe. Eni tawon alagbara ba fee hale mo, ti won ba fee ko se kinni kan ti ko ti i se e, ni won maa n se bee yen fun.

Kenikeni ma se ro pe oro ilu lo ka Obasanjo lara to bee, awon kinni kan wa to fe ki Jonathan se ti ko se ni, paapaa nitori pe iyen ti yo opolopo awon eeyan re nise, ti ko si fi awon omo Obasanjo tele sipo gidi kan. Bi Obasanjo ba fee fun Jonathan nimoran, bo ba gbe foonu re, ko seni ti won bi daadaa ti yoo ni ko ma ba Jonathan soro, bee ni Jonathan paapaa ko tile ni foonu kan t«Obasanjo ko mo, bi Obasanjo si fee wo Aso Rock ri Jonathan, ko seni to to bee ti yoo da a duro, iyen naa lo se to ja wo Aso Rock lojiji, to ba Jonathan wo soosi.

Gbogbo ohun ti mo fee so lori foto akoko yii lo pare mo mi ninu nigba ti won tun fi foto keji yii han mi, nibi ti mo ti ri awon agbaagba meta to je die lo ku ki won da ipinle Ondo ru lenu ojo meta yii. Tabi e ko ri Bola Tinubu, e ko ri Rotimi Akeredolu, e ko ri Olusegun Mimiko, awon meteeta ni won jo n rerin-in yii o. Bee ko ti i ju osu meta lo ti Tinubu duro si ikorita-meta niluu Akure, to n won epe nla nla fun Mimiko, to so pe alaimoore ni. Bee ni Mimiko naa n da esi pada pe ko sibi toun ti gbowo tabi kinni kan lowo Baba alaaanu ti won n pe ni Tinubu, epe to si n se kiri yen ko ni kinni kan ti yoo se foun. Oro naa le debii pe bi awon mejeeji ba pade ara won nigba naa, ohun tawon eeyan n ro ni pe won yoo yobon sira won ni gbangba.

Tiwon ko tile soro bii tawon omoleyin won, bi won ti n gbe ada rin, ni won n gbe ibon rin, bee oro tawon asaaju won n so sinu iwe iroyin ati inu redio ni won n tele, won ti gbo pe Tinubu koriira Mimiko, o si ti so pe gbogbo ona ni ki won wa lati da a duro, awon omo eyin Mimiko naa ti mo pe Tinubu ni igi woroko to fee dana ru mo oga awon lori, won si mura ija, eni to ba si le ku ko ku, eni temii re yoo ba sofo ko sofo, eni ti iku ba fee pa ko tete pa.

Bo se ri nile yii niyen, awon oloselu yii kan n so awon araalu dota ara won lasan ni. Won a maa ba tawon omode ati odo ilu je, awon yoo maa gbebon nitori won, won yoo maa paayan nitori won, won yoo maa da ilu ru. Bee awon eeyan yii gbon, bi won ba pade ara won erin ni won yoo maa rin. Ko sohun meji to n pa won lerin-in ju pe won n fi awon araalu ti ko mo nnkan kan se yeye lo. Se won kuku jo mo pe awon n tan won je lasan ni, won si mo pe bi awon ba ti n rowo ko fun won, won yoo maa para won lo sa ni, awon yoo si raaye jokoo sile ijoba lati maa kowo araalu je, ki won si maa lo agbara ijoba le won lori. Bi enikan ba wa n tori awon oloselu Naijiria yii bewu sile to n gbe apere wo, o see se ko je eni bee ko lopolo kankan rara, tabi koun naa je onijekuje bii tiwon. Bi enikan ba para re nitori awon oloselu ile yii, orun apaadi lo n lo!

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Wednesday, March 20 @ 03:45:28 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu:
Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

"Awon Oloselu Te E Fee Tori Won Para Yin Ree O: Ebele Jonathan, Olusegun Obasanjo" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: