Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
O Tan, Ile-ejo Ko-te-mi-lorun Naa Koyin Si Pasito Refurendi King, Won Ni Afi Ki
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Adewale Adejare

O Tan, Ile-ejo Ko-te-mi-lorun Naa Koyin Si Pasito Refurendi King, Won Ni Afi Ki Won Yegi Fun un

Beeyan ba n yole i da, ohun abenu a maa yo o se. Bee si ni ironu ologbon atawon onilaakaye ki i yato, tomugo eeyan nikan ni ki i jora won. Nje e ti gbo pe ile-ejo Ko-te-mi-lorun paapaa koyin si Refurendi King, Pasito ti won fesun ipaniyan kan lodun bii meje seyin, tile-ejo giga Ebute-Meta dajo iku fun lodun 2006, to si se bee to pejo ko-te-mi-lorun lori idajo yii, gbogbo kukukeke ti fee pin bayii, nitori ile-ejo naa lawon fowo si idajo iku yii, ki Pasito naa maa lo sibi to ran omo ijo re lo.

Lojo Jimo to koja yii naa ni, iyen lojo kin-in-ni, osu keji, ti a wa yii, nile-ejo Ko-te-milorun to fikale sipinle Eko, ti Onidajo Fatimo Akinbami n dari re, ka a si Pasito toruko re gan-an n je Chukuemeka Ezeugo tawon eeyan mo si Reverend King leti pe, “Leyin tile-ejo naa ti jokoo lori esun ti won fi kan an ati idajo akoko ti Adajo Joseph Oyewole da fun un pe ki won yegi fun-un, abajade ayewo kootu yii atawon igbimo e ni pe o jebi esun ipaniyan ti won fi kan an, ko si gbodo lo lai jiya, afi ki won yegi fun-un.” Bee ni owo Pasito naa bo, ejo to ti wa nile latodun 2006, ti won ti ju u satimole, toun n ti ogba ewon kan de omi-in kaakiri ilu Naijiria, toun si tori e pejo ko-te-mi-lorun, to tun waa se bee to fee ja si pabo, a je pe okun iro kan gun ni, ki i pee ja.Ijo kan ti won pe oruko re ni Christian Praying Assembly ni Pasito yii n dari e lona kan to ya gbogbo eeyan lenu, to si tun lodi si eko Olorun tawon eeyan n ka ninu Bibeli gege bii onigbagbo. Ojule kefa, laduugbo kan ti won n pe ni Canal View, Ajao Estate, nipinle Eko, ni soosi naa wa, nibe ni Refurendi King gege bi won se maa n pe e ti dana sun awon omo ijo re meje, ti okan si se bee ku lara won. Esun tokunrin naa fi kan won ni pe won sagbere pelu ara won, iwa agbere lodo Pasito Emeka ko si ni ibawi mi-in ju ki won dana sun eni to ba dan an wo lo, bo se di pe lojo kejilelogun, osu keje, odun 2006, ni deede aago mejo aabo aaro, Pasito naa ko awon eeyan meje naa da sinu agbala re, o ran okan ninu awon omo ijo re lati loo gbe epo bentiroolu wa, o si se bee sona si won lara.

Isele yii lo gbe okunrin naa dele-ejo, nitori awon amofin fidi e mule pe iwa to lodi sofin orile-ede yii, to si nijiya iku ni. Esun meji pataki ninu mefa ti won ka si Pasito naa lese ni> igbiyanju lati paayan ati ipaniyan gan-an. Sebi ko too di pe omobinrin to gbemii mi nipase ina ti Emeka so si won lara yii ku ni tie, awon mefa to ku naa wa lori boya won yoo ku tabi won yoo ye ni, iyen lo je ki won fesun igbiyanju lati gbemi eeyan yii kan an.

Bee lo je pe ninu osu kejo, odun 2006 yen naa ni won gbe e lo sile-ejo fun igba akoko, won ka esun re si i leti, won si je ko di mimo fun un pe okan lara awon to dana sun toruko re n je Ann Uzoh ti jade laye. Sugbon okunrin naa loun ko jebi esun ipaniyan, bee lagbejoro re to gba naa sare dide, to si so pe onibaara oun ko jebi esun naa rara, koda ko si nibi ti won ti dana sun awon eeyan yii, o leni to ku gan-an fenu ara e so fawon dokita ko too ku pe ijamba ero jenereto loun ni, enikeni ko dana sun oun. Olalekan Ojo ni Loya naa n je, o si salaye pe esun to se e gba beeli e lonibaara oun se, nitori ko ti i di arufin afigba tile-ejo ba too fidi e mule leyin iwadii, nitori naa, ki won yonda re o jare. Looya naa ko si da wa o, awon agbejoro nla nla mefa mi-in lo tun ko sodi ti won gbenuso fun Refurendi King, won ni ki

won je kawon gba beeli e pelu awon omoose re meji mi-in ti won jo mu, iyen Donatus Chiazor ati Kelechi Chikere.

Sugbon Williams Abass Ochogwu, agbenuso fun ijoba lori ejo naa ko foro fale, o ni kile-ejo ma gba oro awon eeyan naa yewo rara nitori yato si eni to ku yii, awon meje mi-in wa lese kan aye ese kan orun, esun naa ki i sesun kekere, bee ni ayewo dokita tun fidi e mule pe won ti fere na won pa ki won too sana si won lara, o lohun to ye ki won fi won satimole fun ni.

Nigba t’Adajo agba to n gbejo naa yoo gbe idajo re kale sa, o loun faaye beeli awon eeyan naa sile, ti won ba ti le san milionu meji naira enikookan pelu oniduuro meji ti won je omoluabi tooto, ti won nise gidi lowo, ti won si nile pelu ile lagbegbe gidi. Gbogbo eto yii ni Emeka atawon eeyan e se kiakia, n ni won ba gba beeli won, sugbon laarin iseju meloo kan naa ni won tun mu un pada, o dogba ewon. Won ni ese to se kuro ni nnkan ti won n fowo pa ni lori.

Igbejo mi-in tun waye lojo kerindinlogbon, osu kesan-an, odun 2006 kan naa, nibi ti looya King ti faake kori, nigba toro naa ko si yipada, ti Pasito si wa logba ewon Kirikiri, looya re ba pejo ko-te-mi-lorun to waa fidi won janle yii, lojo kerindinlogun, osu kin-in-ni, odun 2007, iyen leyin tile-ejo ti ni ki won yegi fun un lojo kokanla, osu kin-in-ni, odun 2007.

Bejo naa se n lo lowo ni won n paaro ewon fun olori ijo CPAyii, won ko si deede maa gbe e kiri bi ko se nitori awon iwakiwa to n hu nibe. Ogba ewon Kirikiri ni won koko gbe e lo nipinle Eko, nibi to ti n gbalejo obinrin olokan-o-jokan to n ba sun, won ni anfaani wa fun un lati gbalejo to ba wu u di aago meje ale, iwa agbere to loun n tori e da seria fawon omo ijo loun naa gun le lewon. Esun ibani-lopo ti won fi kan an ni Kirikiri lo so o deni ti won tun n gbe lo si Kuje, l’Abuja. Nigba to si tun sora re d’Olorun kekere mo awon elewon ibe lowo, tawon iyen tun n josin fun un, ti won si n fa whala logba ewon ni won ba tun gbe e lo si Kaduna, nibi to ti n reti abajade esi ejo ko-te-mi-lorun to pe, ko too waa di pe esi re jade ganboro lojo Eti to koja.

Bee eni ti ko ba mo ipile oro Reverend King le maa ro pe ki lo de toro re fi ri bayii, beeyan ba gbo ohun tawon omo ijo re so pe o foju awon ri, tohun ko ni sai lanu. Gege bi eri tomobinrin kan to n gbe pelu Pasito naa latodun 2000 je nile-ejo giga ti won ti gbejo re lasiko tigbejo naa n lo lowo, obinrin naa to pe oruko re ni Onuorah Susan Chizobar salaye pe Pasito Emeka ti pa oun lase pe omo odo oun loun gbodo maa se titi lai, bee ni ihooho loun gbodo maa wa toun ba ti fee gbe ounje foun.

Susan loun ko yi ase re pada ri fodun meje toun fi wa nibe, ihooho gedegbe loun ti n se gbogbo nnkan fun un. O salaye bori se ko o yo lowo Pasito lojo to dana sun awon meje yen, o loun gan-an lo fesun agbere kan, o si ti da epo bentiroolu soun lara pelu awon to ku, bee lo sana si i, eledaa oun lo koun yo toun ko fi jona ku, sugbon okan ninu awon to n je Ann ko ye e, ewu ina ti Pasito so si i lara lo gbemi e, bee ni Ann Uzoh ku, boun se sa jade lojo naa loun kuro ni soosi naa, toun ko si pada sibe mo.

Ni bayii sa, ile-ejo Ko-te-mi-lorun ti ni ki won yegi fun Reverend King, boya yoo tun waa gba ile-ejo to ga julo lo lenikan ko ti i le so.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Wednesday, March 20 @ 04:14:56 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"O Tan, Ile-ejo Ko-te-mi-lorun Naa Koyin Si Pasito Refurendi King, Won Ni Afi Ki" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: