Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Won Sawari Ibi Ti Won Ti N Wa Epo Bentiroolu nN’Idi Iroko
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Johnson Akinpelu, Abeokuta

Won Sawari Ibi Ti Won Ti N Wa Epo Bentiroolu nN’Idi Iroko

Bo tile je pe ojoojumo lawon ti won n ji epo bentiroolu wa n po si i, tijoba ko si fi won lokan-bale, Oba alaye ilu Idi Iroko, Oba John Olakunle Ojo, ti mu un da awon ti won lowo lowo laarin ilu loju pe iru nnkan bee ko ni i sele bi won ba le waa da ileepo bentiroolu sibi il e kan tawon sese sawari pe epo robi yii wa nibe, nitori awon yoo pese aabo to nipon fun won.

Oba John Olakunle Ojo, Oniko t«Ikolaje, Idi Iroko, salaye oro yii lakooko to n ba oniroyin wa soro laafin e lose to koja. Oni lati nnkan bii ogbon odun lawon ti sawari ile ti won ti n wa epo naa to wa ni Tongeji, sugbon se lawon n ba ijakule pade lorisiirisii. Ni bayii, o lawon Oba alaye mewaa to wa ni Ipokia lo ti fowo-sowo-po lati ri i pe won bere ise lori ibe. Oni anfaani nla ni yoo je bi won ba bere ise naa fun awon araalu, yoo si tun je kawon ti ko nise lowo deni to nise.Oba yii ni nibi tawon ti sawari epo naa, o ku die korile-ede Benin ti won jo mule tira won gba a mo awon lowo, sugbon ti Olorun ko gba. Bakan naa lo so pe akoko kan wa ti Oloogbe MKOAbiola gba lati waa bere ise nibe ko too di pe wahala oselu ko je ko raaye titi to fi dagbere faye.

Gege bi Kabiyesi se so, E joo, mo n fe ifowo-sowo-po ijoba apapo, tipinle Ogun ati ijoba ibile Yewa lapapo lati je ki ise bere kiakia. Awa naa si ti setan lati sise po pelu won nitori bise naa ba pari, gbogbo wa ni yoo gba ogo nla.

Anfaani nla ni yoo tun je fawa eeyan Yewa ti won ti pa ti tele, sugbon ti Olorun fee fi epo bentiroolu yii gbe wa ga. Ke e le mo pe awa naa ko mu oro yii ni kere rara, igbimo eleni mewaa ti Alagba Isaac Odunfa je olori won la gbe kale, ti won si ti n sise nipa bi gbogbo e yoo se lo deede.

Bi a ba bere si i wa epo Togeji, nibi ta a so pe kinni ohun wa, ijoba yoo mo pe ile Yewa ki i se ibi tawon to n ji epo wa le raaye sapamo si nitori lati ile lawa naa ti mu eto aabo ni pataki. Oba Oniko waa ni ki i se nitori imotara-eni loun se n gbiyanju bi ko se ife araalu ti won gbe oun dori oye, bee lo ni awon to nile naa yoo ri eto won gba lai fi dun won.

Nigba to n so bo se dori oye, Kabiyesi yii ni nnkan bii ogbon odun o le die ni won ti fi oun joba niluu Idi Iroko. Ojulowo awon to wa lati Oyo lawon n se. Bee lo ni idile merin lo n joba niluu yii, awon naa ni Kogbekeloye, Atewogboye, Atinloye ati idile Ipoku ti oun ti wa.

Oso pe ki i se pe won kan maa n deede fawon joba ni, leyin ti won ba ti mo idile toba kan tan, won a waa difa, eni tifa ba mu lawon ilu si maa n fi joye.

Nigba ti Alagba Isaac Odunfa to je olori igbimo eleni mewaa ti won ni ki won sise lori bise yoo se bere ni pereu nibi ti won ti n wa epo naa n ba Iwe Iroyin Yoruba soro, o ni nigba ti Oloogbe Bisi Onabanjo je gomina ipinle Ogun lo ni kawon loo sabewo si Tongeji, ero okan won ni pe boya won fee se biriiji elese ni, sugbon iyalenu lo je nigba naa lohun-un bi won se sakiyesi ibi ti won ti n wa epo, latigba naa lawon ti wa lenu e.

Oso pe okan lara nnkan to mu ifaseyin ba won nipa ise naa ni ainifee, ainigbagbo ati ainifowo-sowo-po, awon nnkan yii lo mu ijakule ba won, sugbon ni bayii, Oba Oniko ti fi won lokan bale pe gbogbo e ni yoo di ohun igbagbe, nitori awon Oba ile Ipokia ti n gbiyanju lati ri i pe anfaani naa ko fo won da.

Alagba Odunfa to sese feyinti lenu ise ologun te siwaju pe opo ileese lo ti dide tele lati waa bere ise, sugbon iberu awon Boko Haraamu atawon to n ji epo wa lo mu won fa seyin.

Sugbon ni bayii, awon kan ti wa nile ti won ti gba lati sise pelu awon, sugbon awon si fee foruko ileese naa pamo nitori idi kan pataki.

Bakan naa lo menuba awon mewaa ti won jo wa ninu igbimo ohun, awon ni: Alagba Bola Isaac Odunfa, Ogbeni Emmanuel Olugbenga, Alagba Nathaniel Babatunde Enitan, Ogbeni Peter Odunfa, Ogbeni Idowu Olufemi, Ogbeni Abiodun Fagbohun, Ogbeni Oluwaseun Fagbohun, Arabinrin Bukola Fagbohun ati Pasito Oluwamuyiwa Fagbohun. Awon eeyan yii ni won jo maa n rin irinajo kaakiri lati ri i pe erongba won bo si rere. Oni Oba Oniko ti waa ki awon laya pe kawon maa ba ise lo, ko ni i sewu.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Saturday, April 13 @ 02:08:54 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Won Sawari Ibi Ti Won Ti N Wa Epo Bentiroolu nN’Idi Iroko" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: