Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Wahala De! Ile-ejo Ni Ki Won Ju Onijoko Ota Satimole Osu Meji Nitori O N Pe Ara
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Johnson Akinpelu, Abeokuta

Wahala De! Ile-ejo Ni Ki Won Ju Onijoko Ota Satimole Osu Meji Nitori O N Pe Ara E Loba

Bi nnkan se n lo yii, afaimo ki wahala ma be sile ni IjokoOta, nipinle Ogun, nitori bi ile-ejo giga kan niluu Ota se pase pe ki won loo fi Ogbeni Lasisi Kolapo Ogunseye satimole osu meji nitori pe o ko lati tele ofin ile-ejo pe ko yee pe ara e loba ilu naa mo.

Ase yii waye lose to koja nigba ti Adajo Mobolaji Ojo tileejo giga kan niluu Ota sagbekale e lori ejo ti Oba AbdulFatai Matanmi pe Ogunseye lojo ketadinlogun, osu karun-un, odun 2012, nibi to ti ro ile-ejo pe pelu gbogbo bi oun se n jare lori ipo Oba Onijoko Ota, se ni alatako oun yoo tun pe ara e loba, bee lo tun n jade sawon ayeye to je mo ti oba.Pelu ibinu ni adajo naa fi gbe idajo kale lojo naa. O ni Lasisi Ogunseye ro pe oun koja ofin, laimo pe ko si agbara teeyan le ni ti ofin ko ni i sise le e lori. Nitori naa, eni to n pe ara e loba yii ti te ofin loju, dandan si ni ko ri pipon oju ijoba.

Adajo Mobolaji ni, “ Mo pa a lase pe ki awon agbofinro loo gbe Lasisi Ogunseye ki won si fi si atimole fun ogota ojo.” Bee lo tun pase pe ki won loo fun komisanna awon olopaa nipinle Ogun ati ileese eto idajo ni eda iwe naa, ki won si ri i pe owo te e.

Ko too gbe idajo e kale ni Ogbeni S. Ola, to je agbejoro fun Oba Fatai Matanmi ti ro ile-ejo pe gbogbo bi Ogbeni Lasisi Ogunseye se n pe ara loba leyin tile-ejo ti so pe ko letoo je nnkan ti ko bojumu. O ni okunrin naa n se bii eni to koja ofin, pelu gbogbo iwe tile-ejo fi le e lowo, se lo ko eti ikun. Bee ni ko tun yoju lakooko ti won ni ko wa.A o ranti pe oro ija oba niluu Ijoko Ota ti bere tipe. Olowu tilu Owu, Oba Adegboyega Dosunmu, lo fi Lasisi Ogunseye je Oba lakoko naa, ohun ti won si n so ni pe okan lara ile Owu ni agbegbe naa ati pe Olowu lo letoo lati fi eeyan joba.

Kekere ko ni wahala toro naa da sile, aimoye igba lawon eeyan Ogunseye ati Matanmi ti doju ija ko ara won, topo emi ti sofo.

Sugbon lodun 2010, nigba ti Otunba Gbenga Daniel fee gbe ijoba kale lo fowo si i pe ki Alake tile Egba, Oba Adedotun Gbadebo fun awon baale kan nigbega si ipo Oba, lara won ni Oba AbdulFatai Matanmi, to si gbe ade le e lori, eyi lo je ki oba di meji niluu kan soso, eyi ti ko si ye ko ri bee gege bii ofin ile Yoruba.

Latigba naa lawon mejeeji ti gbe ara won lo sile-ejo, sugbon a gbo pe gbogbo bi ejo naa se n lo, Oba AbdulFatai Matanmi lo n bori.

Lati le gbo tenu eni ti won ni ko ma pe ara e loba mo, Lasisi Ogunseye, eemeeji otooto la pe nomba e lojo Abameta, Satide, ose to koja, omo re okunrin kan lo si n gbe e, ohun to so ni pe awon ko ti i setan lati soro nitori awon n gbe awon igbese kan lowo.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Saturday, April 13 @ 02:24:19 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Wahala De! Ile-ejo Ni Ki Won Ju Onijoko Ota Satimole Osu Meji Nitori O N Pe Ara" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: