Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Ori Ko Koburu Olopaa Yo Lowo Awon Adigunjale N’Ibadan
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Ori Ko Koburu Olopaa Yo Lowo Awon Adigunjale N’Ibadan

Iko awon ogbologboo afurasi adigunjale eleni marun-un kan ko ba awon olopaa ro-o-re lojo Abameta, Satide, ojo kerindinlogun, osu keji, odun yii, pelu bi won se doju ija ko won ti okan ninu won to n je Ajayi Joki si farapa.

Sugbon owo awon olopaa te okan ninu awon ole ohun.

Ilu Osogbo la gbo pe awon afurasi igaara olosa ohun, Nze Chidozie, Ganiyu, Kunle atawon oloruko kan naa meji ti won n je Ikechukwu ti dira ogun wa s«Ibadan fun idigunjale ti won fi ko sowo awon olopaa ni abe biriiji Iwo Road, n«Ibadan, nibi ti awon agbofinro ohun ti n mojuto aabo ilu gege bii ise tiwon tosan-toru.Gege bi Iwe Iroyin Yoruba se gbo, bi awon olopaa se da won duro ni won dibon bii omoluabi eeyan, won so kale ninu moto, won si salaye pe ibi inawo kan lawon ti n bo niluu Osogbo, sugbon oko awon to baje loju ona lo je ki awon fi oru wolu bee. Won ko si ti i so eyi tan ti eyi ti won n pe ni Ganiyu ninu won ti fa ayederu iwe oko ayokele ti won wa ti nomba e je AU 690 APP yo.

Oro tutu ti won gbero ati fi tu awon olopaa je ree, sugbon awon yen jewo fun won pe won kere si nomba awon. Gbogbo bi won se n ko awijare pale yii, awon agbofinro n ba won kaaanu, bee naa ni won si n mura lati ye inu moto won wo finni-finni.

Ko pe rara ti won tule kan ibon ilewo kan, n lawon afurasi olosa naa ba da a si ogboju, ni won ba doju ija ko awon olopaa, nibe ni won si ti se Koburu Joki lese. Sugbon awon agbofinro yii ko sinmi ija sibe, nigba naa lawon jagunlabi sa kuro loju ija, gbogbo won fere ge e. Sugbon awon olopaa tun gba ya won, won si ri okan ninu won mu. Nigba tawon agbofinro tun tu inu moto naa wo, won ba ibon nla nla meji mi-in nibi kolofin kan ninu oko naa pelu opolopo ota, n ni won ba mu Chidozie lo si ago won ni Akobo, n«Ibadan.

Lojo Aje, ojo kejidinlogun, osu keji, odun yii, iyen Monde, ose to koja nileese olopaa safihan Chidozie fawon oniroyin gege bii afurasi adigunjale. Nibe lokunrin omo bibi ilu Aguata, nipinle Anambra, yii ti so pe ki i se oko ole lawon n lo lojo naa bi ko se pe awon n ti ibi ikomo egbon ore awon kan bo l«Osogbo ni, bo tile je pe o pada jewo pe ogbologbo ole ti i ja losan-an gangan loun i se.

Gege bo se so, Eko ni mo n gbe tele ki n too ko lo si Sagamu. Ole ni mo n ja l«Ekoo loooto, sugbon mi o seesi fi ojo kan bayii jale n«Ibadan ri. Kunle lo pe mi sibi ikomo egbon e l«Osogbo, emi pelu e naa la si jo lo sibe lati Sagamu. A kuro ni Sagamu ni nnkan bii aago meji osan, a de Osogbo laago meje ale. Nibi ikomo yen la ti pade Ganiyu atawon Ikechukwu mejeeji. Eyi to kuru ninu awon Ikechukwu mejeeji lo gbe moto wa, Kunle si so pe ki won maa gbe wa lo ti won ba ti n pada si Sagamu.

Oru la wo Ibadan. A pade awon olopaa labe biriiji Iwo Road. Won ni ka si buutu moto, Ikechukwu to ni moto si so kale, o si i fun won. Leyin iyen ni Ikechukwu giga dogbon so fawon olopaa pe oun fee loo ra akara, oun ati Kunle ni won si jo lo. Awon olopaa beere awon iwe oko, Ike kukuru ko iwe sita sugbon ko ni iwe ase oko wiwa. Ganiyu na tie si won, won ba ni ayederu ni ati pe irin wa mu ifura dani. Bi won se ni awon yoo tu inu oko wo niyen.

Bi Ikechukwu se sa lo niyen. Okan ninu awon olopaa le e lo, okan n wo inu moto wo, omi-in si di emi mu. Lojiji ni eyi to n tu inu oko wo pariwo pe, ∆Eru ofin kan wa nibi o! Won saa ba ibon ati ota nibe, bi won se mu mi lo si tesan niyen. Bo tile je pe Chidozie so pe oun ko mo nnkan kan nipa awon ibon naa, sibe o jewo fawon oniroyin pe oun gbo ti Ikechukwu giga n so fun Kunle pe oun ra ibon kan ni Bayelsa, ole ni won si n fi awon ibon yen ja.

Nigba to n royin itu ti oun paapaa ti pa pelu ise ole l«Ekoo, o ni, Mo maa n jale l«Ekoo.

Ni gbogbo agbegbe Pako Aguda, ni Surulere, ta a ba ri eni to gbe owo lowo, a maa n ja a gba, emi pelu Kunle. Kunle lo maa n toka si eni ti owo gidi ba wa lowo e fun wa. To ba ti so pe eni to n lo yen lowo lowo o, a kan maa ja baagi e gba ni, a a si sa lo. Chidozie so pe onisowo gidi loun tele, awon eya ara moto loun n ta ni Ladipo ko too di pe obinrin kan labule waa fi oogun abenu gongo pa okoowo naa run, ohun to je koun di adigunjale niyen.

Oga-agba awon olopaa nipinle Oyo, Ogbeni Mbu Joseph Mbu fidii isele yii mule, ati pe loju-ese ni won ti gbe olopaa to farapa naa lo sileewosan ijoba kan n«Ibadan, fun itoju.

Mbu so siwaju pe ileese olopaa ti fa Chidozie le awon olopaa to n topinpin esun idigunjale ti won n pe ni SARS lowo. Oni iwadii ti bere lori bi owo yoo se te awon merin yooku ti won sa lo.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Saturday, April 13 @ 03:22:12 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Ori Ko Koburu Olopaa Yo Lowo Awon Adigunjale N’Ibadan" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: