Gbagede Yoruba
 



Awon Odo Ya Bo Aafin, Won Ni Afi Ki Kabiyesi Fipo Sile
 
Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere
Lati Owo Stephen Ajagbe, Ado-Ekiti

Awon Odo Ya Bo Aafin, Won Ni Afi Ki Kabiyesi Fipo Sile

Oro di bo o lo o yago laaaro Ojobo, Tosde, niluu EmureEkiti, nigba tawon odo ilu ya bo aafin E lemure, Oba Emmanuel Adebayo, ti won si ni dandan ni, o gbodo kuro lori ite.

Nnkan ti won lo fa rogbodiyan ohun ko ju bi awon odo ilu naa se n fi ojoojumo ku, ti Kabiyesi ko si ri nnkan kan se si i.

Iwe Iroyin Yoruba gbo pe se lawon odo ohun ti ko niye kora won jo siwaju aafin Oba yii, bi won se n gberin, bee ni won n sun taya, ti gbogbo awon oloja si n sare ko gbogbo oja won, gbogbo agbegbe naa lo daru patapata. Se loro di eni ori yo, o dile, nigba tawon oloye ilu yo gbogbo ileke orun won, ti won si bere si i sa asala femi-in ara won, ti awon mi-in tile sa kuro niluu patapata.



Ni gbogbo asiko tisele ohun n sele ni Kabiyesi jade si won lati tu won ninu, sugbon gbogbo arowa to n pa fun won, eyin eti won lo n bo si. Akoroyin wa gbo pe ni kete ti Oba naa yoju si won lawon eeyan yii ti bere si i ju u loko, ti won si n so omi inu ora, pio-wota, lu u.

Ohun to fa a ko ju pe awon odo ohun so pe oro ti baba naa so ko te awon lorun, won lo ye ki Kabiyesi tete wa nnkan se si bi awon odo se n fi gbogbo igba padanu emi won ninu niluu naa. Won lawon fee mo ipa ti Oba atawon ijoye re n sa lori isele naa. E o ranti pe lojo Tosde ose to koja ti i se ojo ayajo-ololufe lawon omo ilu Emure meji kan padanu emi won ninu isele ijamba okada, nigba ti tirela kan te won pa lagbegbe Okesa, niluu Ado-Ekiti.

Bakan naa lawon meta kan ku lojo Wesde to koja ninu ijamba moto to sele laarin Ikere si Ise-Emure, lasiko ti moto Mazda ti won wo kolu oko akeru Toyota Dyna kan. Gege bi enikan to se e fokan tan niluu naa se so, o ni laarin ose meji si akoko yii, o ti to bii awon odo mejila to ku niluu Emure, eyi lawon odo ilu se pe fun ifura ati igbese kiakia lati dekun isele buruku naa. O salaye pe bo tile je pe awon olopaa de sibi isele ohun, sibe se lawon odo koju ija si won, ti won si le won danu.

Agbenuso ileese olopaa, Victor Babayemi, so pe loooto nisele ohun sele, sugbon awon ti fi okan awon araalu bale pe ki won maa ba ise won lo lai sewu.

Lasiko to n fidi isele naa mule, alaga-afunniso nijoba ibile Emure-Ekiti, Ogbeni Adewale Febisola, so pe oun ti ba awon odo ilu soro, oun si ti tu won ninu lati fopin si rogbodiyan naa, pe Kabiyesi pelu awon oloye re yoo wa opin si isoro ti won dojuko ohun.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Saturday, April 13 @ 03:27:06 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· EsinIslam Media Yoruba
· Die sii Nipa Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere:
Oye Okere Tilu Saki, Ile-ejo Ni Mogaji Ko Gbodo Gbe Igbese Kankan Bayii


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere



"Awon Odo Ya Bo Aafin, Won Ni Afi Ki Kabiyesi Fipo Sile" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com