Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
L’Ondo, Awon Araalu N Binu Si Baale, Won Ni Afi Ko Fori Oye Sile
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Taofeek Surdiq, Ondo

L’Ondo, Awon Araalu N Binu Si Baale, Won Ni Afi Ko Fori Oye Sile

Awon araalu Laosho, to wa nijoba ibile Iwo-Oorun ipinle Ondo, tu jade lose to koja, won si fori-le aafin Oba Adesimbo Kiladejo, Osemawe tilu Ondo, pelu ebe ati ileri pe ko jowo ko dahun si ebe awon lati yo baale ilu naa, Kola Fadoju, bii eni yo jiga lori esun sise owo idagbasoke ilu naa basubasu ati didari owo ohun sapo ara re.
Awo n esun miiran ti won tun fi kan an ni tita ile to je tilu naa fawon eeyan ti ki i se omo ilu lai de fi to awon araalu leti, dida nikan sejoba ilu, gbigbe eto ipari ejo ilu ohun fun iyawo re, Sikiratu Fadoju, se ati gbigba owo lai nidii lowo alejo atawon araalu.Iroyin to te Iwe Iroyin Yoruba lowo lori isele naa fi han pe igbese tawon araalu Laosho gbe yii je igbakeji ti won yoo gbe e. Saaju akoko ti won tun fehonu han si Baale won yii ni won ti koko gbe e lo siwaju Osemawe lodun 2002, nigba naa ni Kabiesi be won pe ki won fowo wonu, eyi ti won si gba si i lenu. Oba si yo o nipo nigba naa, ko too di pe won da a pada sori oye lodun 2009.Yiyo ti won yo baale nipo nigba naa ni won se nilana ofin pelu bi won se fi iwe gbele-re ranse si i, ti won si ni ko buwo lu iwe tawon igbimo kan ti Osemawe gbe kale lakooko naa.

Eda iwe ohun ti Oloye Giga Odunwo tilu Ondo ati Olabanji Akingbule buwo lu ni won fi han akoroyin wa lati le fidii eri won mule.

Ko pe sigba naa ni wahala mi-in tun be sile laarin Fadoju atawon araalu yii, ti gbogbo won si tu sita lati fehonu han. Gbogbo ipa ti Oloye yii sa lati mu ki alaafia joba laarin awon eeyan wonyi lo ja si pabo, nitori eyi lo se taari won lo saafin Osemawe.

Ni kete ti Oba si ti ri iwe esun ti won fi kan baale lo ti gbe igbimo eleni-merin dide. Awon omo igbimo naa ni; Oloye Ayadi Olubusade, Odole Ajisafe, Basamegha Awosika ati Ligbo Akinkunmi.

Ninu oro ti asoju awon agbaagba ati odo ilu, Ogbeni Solomon Alatise ati Philip Akinbanjo ti won fehonu han so laafin niwaju awon igbimo naa, won ni latigba ti won ti da baale naa pada sori oye ni bii odun die seyin ni alaafia ko ti joba mo laarin ilu. Won salaye pe afi ti baale naa ba fi ori oye sile ni alaafia too tun le pada sinu ilu naa.

Ninu oro Baale Kola Fadiju ti won fesun kan lo ti ni ko sooto kankan ninu esun tawon araalu fi kan oun ati iyawo oun, o ni iro pata gbaa ni won pa mo oun ati pe awon to fee gba ipo oun ninu ilu ni won wa nidii isele naa.

Leyin igba tawon igbimo ti teti si awijare awon araalu, baale ati iyawo re, alaga igbimo naa, Oloye Ayadi Olubusade gba awonaraalu niyanju lati je ki alaafia joba titi digba ti Oba Osemawe yoo fi buwo lu iwe abajade igbimo naa.

Bakan naa lo ni igbimo naa yoo kowe si awon araalu ati baale ohun lati le je ki won mo abajade iwadii tawon ba se, bee lo seleri pe awon yoo se idajo to ni otito ninu.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, June 13 @ 02:17:17 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"L’Ondo, Awon Araalu N Binu Si Baale, Won Ni Afi Ko Fori Oye Sile" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: