Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Aye Ti Baje O! Awon Omo Iya Meta Lu Oga Ileewe Won L’Akure
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Solomon Adewoye, Akure

Aye Ti Baje O! Awon Omo Iya Meta Lu Oga Ileewe Won L’Akure

Awon omo iya meta kan pelu ore won ti won fesun kan lose to koja pe won lu oga ileewe won ni won ti foju bale-ejo bayii. Afaimo kawon omo naa ma sewon pelu iwa ailekoo ti won hu naa. Awon ti won fesun kan ohun ni: Olumide, omo odun metalelogun; Damilola, omo odun metala ati Olokose, omo odun mejila. Oruko ore won n je Olusola Catherine, omo odun meeedogun loun. Bee ni Arakunrin Emmanuel Ogunleye ati Arabinrin Nike Ogunleye to je baba ati iya awon omo yii.

Ileewe Alakure High School, nisele naa ti sele lojo Isegun, Tusde, to koja. Gege bi olopaa to je olupejo se so nile-ejo, o salaye pe nise ni okan ninu awon omo naa, Olokose, wo aso ileewe yii lona ti ko to, bee lo n rin awon irin ti ko ye ki omo ileewe maa rin, eyi lo mu ki oga re, Arabinrin Obasuyi Oluwayemisi, pe e lati ba a wi sugbon nise lomo naa pe awon egbon re ti won jo n kawe nibe, tawon iyen naa si pe awon obi won. Nise ni won da seria iya fun oga naa pelu awon oga meji miiran to da soro ohun, iyen Arabinrin Olajesu ati Arabinrin Akinnade Olajumoke.


Baba awon omo naa je agbase-se, nigba ti iya won je osise nileewe girama ijoba apapo to wa l’Akure. Nigba ti won beere oro lowo omo to fa wahala ohun, iyen Olokose, o salaye pe, Won ni mo n sako, mo de tun woso lona ti ko to, mo si so fun won pe mi o sako rara, sugbon nise ni oga yen bere si i lu mi, idi niyi ti mo fi pe awon egbon mi atawon obi mi.≈ Se eni ti yoo ba paro ni yoo so pe elerii oun wa lorun.

Esun ti awon oga naa fi kan omodekunrin ohun to je omo odun mejila pere to si wa nipele akoko (Jss1) lo tun pada hu nile-ejo. Eyi lo mu ki inu bi adajo, to si so fun omo yii pe esun ti won fi kan an naa lo tun n hu niwaju adajo, ati pe to ba n se bee lo, oun ko ro pe ojo ola re le daa rara, bee ni ko daju pe oun atawon egbon e yoo jade nileewe naa pelu iwa buruku owo won. Alaga awon obi ati oluko ile iwe naa, Arakunrin Williams Olajire, binu sawon obi omo naa fun iwa alainitiju ti won hu ohun.

Oni nise lo ye kawon eeyan naa koko pe oun ki won too maa loo ja lojo naa nitori oro ti ko to nnkan. Owaa ro won lati mase ba ile-eko naa loruko je. Awon agbejoro won, Arakunrin Kehinde Akintelure ati Adelanke Akintara ro ile-ejo lati gba beeli won nitori ese ti won se naa ko le to ohun ti won le so won si ogba ewon si, o ni awon yoo yanju e labele.

Ninu idajo re, Onidajo Akin Akintoye pase pe ki awon omo naa loo be awon oga won, ki won si jejee pe won ko ni i hu iru iwa bee mo, bee ni won tun gbodo san egberun mewaa naira eni kookan fawon oga naa lati le fi toju ara won nileewosan. Owaa sun ejo naa si ojo ketadinlogun, osu yii.
 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, June 13 @ 02:43:22 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Aye Ti Baje O! Awon Omo Iya Meta Lu Oga Ileewe Won L’Akure" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: