Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Oba Fatai Matanmi Pariwo: E Gba Mi O, Ojoojumo Lawon Hayakila N Lepa Mi
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Johnson Akinpelu, Abeokuta

Oba Fatai Matanmi Pariwo: E Gba Mi O, Ojoojumo Lawon Hayakila N Lepa Mi

Wahala to n sele niluu Ijokoo-Ota, nijoba ibile Ado OdoOta, nipinle Ogun, tun beyin yo lose to koja nigba ti Oba ilu naa, Oba Abdul Fatai Alani Matanmi, pariwo sita pe ki gbogbo awon omo orile-ede yii gba oun nitori bi won se n ran hayakila soun lati gba emi oun.
O soro yii lakooko to n ba awon oniroyin soro niluu Abeokuta lose to koja. O ni latigba ti wahala oro oba ti be sile, tile-ejo to ga julo si ti da oun lare pe oun loun letoo lati wa nipo naa ni won ko ti fi oun lokan bale, ti won si n wa ona lati pa oun.O so pe aimoye igba lawon hayakila naa ti gbidanwo, sugbon t’Olorun ko gba fun won pelu bo se ko oun yo. Gbogbo awon to si ye koun foro naa to leti loun ti so fun, o fi kun un pe nigba toun ko mo nnkan toun tun le se loun se pariwo sita.
Nipa wahala to n sele niluu Ijokoo, Oba naa so pe awon kan ti won wa nipo agbara ni won ko je ki idajo ile-ejo sise. Bee lo tun fesun kan awon olopaa lori ipa ti won ko lori oro naa.

O ni ejo kan ti nomba e je HCT/88/2006 toun pe Ogbeni Lasisi Ogunseye atawon merin kan ni kootu kan niluu Ota, ni Adajo M.O. Ojo ti koko da pe ki Ogunseye yee pe ara e ni Oba Onijoko. Sugbon o ni kaka ko gboro sile-ejo lenu, se lo tun n yan fanda, to n se bii Kabiyesi.

O ni awon ijoba to ye ki won gbe igbese le e lori, se lawon naa tun n se atileyin fun un.

O ni nigba ti won sun oun kan ogiri loun tun pada lo sile-ejo, eyi ti won da lojo kerinla, osu keji, odun yii, nibe lo ti ni adajo pase pe ki won loo ju Ogunseye satimole osu meji nitori pe ko tele ase ile-ejo.

O ni gbogbo ilana to ye atawon iwe ni won ko sawon olopaa lati loo gbe Ogunseye ayederu oba naa, sugbon se lawon oga olopaa so oro naa di awada, ti won n so pe awon ko le ri i, bee ni won ko kede sita pe awon n wa a.

Oba Matanmi so pe eni to n rin bo se wu u laarin igboro ni won so pe awon n wa. Opo igba lo ni awon oga olopaa ti won je Komisanna ti fee gbe igbese lori ase ile-ejo, sugbon to ba ya, won a ni awon ko le se e mo nitori ase latoke ni.

Lori esun tawon ti won jo n ja lori oro olobade fi kan an pe o ji eeyan gbe, o ni iro buruku gbaa ni nitori eni ti won so pe oun ji gbe naa, oun ko mo on ri, bee loun ko da a mo, iyalenu lo si je foun nigba tawon olopaa waa gbe oun ni kootu.

Lori iwa agabagebe to ni Komisanna foro ijoba ibile ati oye jije, Basorun Muyiwa Oladipo, hu, o ni okunrin naa to ye ko yanju wahala ohun, nise loun naa tun n da kun un. O ni titi di akoko toun n soro yii, igbese tijoba pariwo pe awon yoo gbe lati dekun wahala naa, won ko gbe e, ariwo ori afefe ni won fi n se.

Oba yii tun so pe ni ipade lobaloba ti won n se nijoba ibile Ifo ati Ado-Odo, oun ni won gba gege bii ojulowo oba lati Ijokoo-Ota, O ni ki lo waa de tijoba ko tele ofin ile-ejo. Bee lo tun ni aimoye igba ni Oloye Obasanjo ti pe awon, toun si ti so awon ipa toun n ko lori oro ilu naa.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, September 08 @ 17:13:23 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Oba Fatai Matanmi Pariwo: E Gba Mi O, Ojoojumo Lawon Hayakila N Lepa Mi" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: