Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara
[ Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara ]

·Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
·Arungun Loko Mi, Gbogbo Irinse Mi Lo Ti Baje, Mi O Fe e Mo Abigail
·Oko Mi Fi Pata Mi Soogun Owo Philomina
·Emi Atoko Mi Ko Ja, Nitori Omo Lawon Ebi Re Se Fee Le Mi Jade - Rafia
·Latodun Merin Seyin Loko Mi Ko Ti Ba Mi Lasepo, Mi o Se Mo - Folasade
·Odo Ni Wolii Moses Ti Ni Ki David Loo We Iwe Isegun, Lo Ba Fogbon Ji Moto Re Gbe
·Oro Buruku Toun Terin: Awon Omo Poli Ojere Mefa Daku Lakooko Ti Won Fee Sedanwo
·O Sele L'Egba! Seun Bimo Kan Fokunrin Meji L'Abeokuta
·Babalawo Fewon Jura Lori Esun Aini Salanga L'Ondo

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Awon Ohun Ti Oju Eni To Ba Fee Sise Fun Yoruba Maa N Ri Ree
 
 
Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise
Lati Owo Ademola Adejare

Awon Ohun Ti Oju Eni To Ba Fee Sise Fun Yoruba Maa N Ri Ree

Se e ri i, gbogbo iwe ti e n ko si mi ni mo n ri ka o, gbogbo ooto ti e si n so naa lo n ye mi daadaa. Sugbon mo fe ki n salaye, ki n si so gbogbo ohun taburo wa to ni Iwe Iroyin Yoruba yii so fun mi ko too di pe mo fesi ni. Idi ti mo fi n se bayii ni pe idi ti omodekunrin naa fi so fun mi pe oun ko le ba wa da si oro asaaju Yoruba yii se pataki, mo fe ki gbogbo wa ka a ko ye wa, mo si fe ka fi oro re yii se arikose ati arikogbon ninu gbogbo igbese ti a ba fee gbe ninu oro wa. Gbogbo awon atejise yin ni mo n toju, n o si fesi si won ni kinni-kinni bi mo ba ti salaye oro yii tan.

Ibi ti mo ba oro de ni ibi ti Iwe Iroyin Yoruba ti ro ejo fun mi pe awon fe se iwuye fun Bola Tinubu l’Ekoo, nipa odun Asa ati Ise Yoruba tawon fee se, awon pe Ooni, oba naa wa sugbon awon eeyan kan fi ote ba a je, Alaafin to si ti so pe oun n bo ko wa mo, bee ni gbogbo owo ti oun san lati fi gba ibi ti won yoo de si fun won wole poo, e je ka maa ba oro re lo.

Aburo wa yii so pe ki i i se pe oun da eto yii se o, o ni gbogbo awon bii Raufu Aregbesola, Kayode Fayemi (awon mejeeji ko ti i di gomina nigba yen) Gani Adams, Fredrick Faseun atawon agbaagba Yoruba mi-in lawon jo wa nibi eto naa, ti gbogbo won si fowo si i pe nnkan to dara gbaa loun n se.


O ni Aregbe ati Fayemi so foun pe ki awon tete pari eto tawon n se naa, nitori ekeji iru e tawon yoo ba tun se, awon yoo ti di gomina nigba naa, odo awon loun yoo si ti se e. Sugbon Iwe Iroyin Yoruba so pe nigba ti eto naa pari, wahala tuntun lo ba oun.
Akoko ni pe gbogbo awon gomina ile Yoruba ti oun ti pe won yoo wa lati jo ko eto naa jade ko wa, bee ni awon oba ko to nnkan, bi eto naa yoo ba si je ti Yoruba, afi ki gbogbo won yii fowo si i ki won si so ni gbangba pe eto ti awon fe ki gbogbo awon omo Yoruba se niyen.

Ohun to je ki won ronu lati loo ko eto naa jade lodo Ooni ni Ile-Ife ree o, won ni nigba ti ibe je orirun Yoruba, gbogbo awon eeyan yii ni yoo fee peju.

Iwe Iroyin Yoruba ni bawon se di igba di agbon ree o, ti awon tun lo si IIe-Ife lodo Ooni, ti awon si pe gbogbo oba ile Yoruba pata, atawon gomina won. O ni oun ko mo pe pelu eto toun n se yii, boun ti n lo ni oun n fa wahala sorun oun. Akoko ni pe awon gomina ati agbaagba kan nile Yoruba ti bere si i binu pe won fi Bola joye, ohun ti won si n so kiri ni pe oun Iwe Iroyin Yoruba loun fee fi Bola se asaaju Yoruba, oun si ti gbowo lowo e ni. O ni nigba tawon

de ile Ife, Oyinlola to n se gomina ipinle Osun ba oun lodo Ooni lojo ti eto naa ku ola, nibe ni Oyinlola si ti so poun ko ni i wa, sebi awon ti won fi Bola se asaaju Yoruba ree, ti won ko pe awon to ku si i, ki won maa se e ka maa ri i. Iwe Iroyin Yoruba ni nibe loun ti so pe oro naa ko ri bee, ti awon si bo segbee kan, ti oun salaye gbogbo bi oro se je fun un. Oyinlola so poun ko gba, afi boun ba le de gbangba koun si so pe loooto ki i se pe oun gba owo kan lowo Bola, nitori iroyin tawon n gbo kaakiri niyen pe Iwe Iroyin Yoruba ti gbowo lowo Bola Tinubu.

Iwe Iroyin Yoruba ni bayii lawon soro naa, sugbon eyi to tun buru ni pe awon gomina mi-in ko tun wa, Oyinlola nikan lo wa nibe, awon Bola ti awon jo bere eto naa l’Ekoo ti oun si salaye gbogbo ohun ti oun fee se ko ba oun lo, bee lo jo pe won si ti n fi ogbon pada leyin oun. Loooto ni ero po lodo Ooni, ti awon oba nla nla bii Alake ile Egba, Olowu Owu, Owa Obokun Ijesa, Ataoja Osogbo, Ewi Ado, Osemowe Ondo, Olowo tile Owo, Deji Akure, Ajero Ijero, Olugbo Ugbo atawon oba nla bee wa, sugbon Alaafin ko wa o, bee ni ko si Awujale, bee ni ko si oba Eko, bo tile je pe gbogbo won pata loun pe. Awon gomina ile Yoruba to ku naa ko wa sibe, ohun ti kaluku saa n so ni pe oun ti fi Bola se asaaju Yoruba, eyi to si dun oun ju nibe ni ariwo ti won n pa pe oun ti gba owo lowo okunrin naa ni, awon kan soro naa debii pe milionu lona eedegbeta ni won gbe foun. O ni oro yii n gba omi loju oun nitori gbogbo ayeye tawon se naa, owo ara awon lawon na o.

O ni bi oro ti se je ni pe nigba ti awon dana eto naa, oun atawon eeyan oun ti mo pe eto yii ko ni i na awon ju milionu marun-un pere lo, awon si ti seto bawon yoo se ri iru owo bee lati ileese awon, sugbon nigba tawon ara Eko gbo pe won yoo se nnkan fun Bola, won da si i, won ni nnkan naa ko gbodo je ti seresere, won lawon gbodo se orisiirisii nnkan lati fi han pe gomina atijo niluu Eko lawon se nnkan fun, awon yoo se kalenda, awon yoo se iwe nla atawon orisiirisii nnkan mi-in bee lati fi sami ayeye yii, bayii ni won gbe igibmo dide, igbimo awon eleto naa atawon asoju ijoba Eko, won si si owo ti won fee na, owo naa si je milionu metala ati aabo. Iwe Iroyin Yoruba ni oun beere bi won yoo ti se ri owo yii, won si so foun pe ijoba ipinle Eko ti so pe gbogbo iye ti won ba fee na ba je, ki won kowe e foun. O ni bayii lawon n ba eto naa lo, nigba ti eto si ku die, ti owo kankan ko ti i jade, oun to Bola lo pe boro ti je ree o.

Iwe Iroyin Yoruba ni Bola ni ki oun maa lo, bi ijoba Eko ba ti ni won yoo se e, won yoo se e naa niyen. O ni ko ju ose kan lo leyin eyi ti oun ati gomina Eko, Fasola de odo Bola, oun ati gomina naa si jokoo lodo Bola, Bola naa si wa laarin awon, awon si je meta pere, Olorun si sikerin awon, Fasola si so foun nibe bayii pe, ‘Egbon, mo ti fowo si owo ti won gbe waa ba mi pe e fee na, e loo ri Mista Ojo ni Alausa, o maa yanju e fun yin.’’ Iwe Iroyin Yoruba ni Bola waa so foun pe, ‘Alao, se o ri i ti o kan n daamu ara e lasan.’ Aburo wa yii ni idunnu loun fi kuro toun si pe awon tawon jo n se komiti feto naa lati loo ri Mista Ojo ni ojo keji, sugbon ohun ti yoo ya oun lenu ni pe awon ko ri owo naa gba lati odun 2008 naa titi di odun 2011. O ni nigba ti awon yoo rowo naa leyin odun meta yii, iye tawon ri gba je milionu meji, yato si milonu merinla tawon na funra awon.

Ati pe nigba ti eto naa fee daru ti oun ko ri owo gba, oun pada lo sodo Bola, Bola si fun awon ni milionu kan, awon lawon si wa owo to ku jade.

O ni ohun to waa n ba oun ninu je gan-an niyen, ki oun se wahala to to bee, ki oun na owo oun, ki awon kan si jokoo sibi kan, ki won ni oun gba owo lowo Bola ati ijoba Eko. O ni pelu e naa, oun n beto ohun lo, awon ara Eko ko fi taratara wa si Ile-Ife, bee ni awon gomina ko wa, oun si n fee ko gbogbo gomina Yoruba jo sibi kan, nitori bi won ko ba fowo si eto naa, yoo soro i se fawon nitori ona ti awon fee gbe kinni naa gba lati ko gbogbo awon Yoruba to wa lagbaaye wa si ile Yoruba nibi. O ni Erelu Abiola Dosunmu lo ri gbogbo wahala toun n se laafin Ooni, oun lo si gbe oro naa loo so fun Olusegun Obasanjo, ni Obasanjo ba ranse soun pe koun waa ri oun. O ni bee loun lo si ile Obasanjo ti oun si ba a, Obasanjo si soro foun pe: E wo o, ose to n bo ni a oo maa ba oro naa lo, bi emi naa ti n so o lo n ka mi lara funYoruba.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, September 08 @ 17:31:07 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise:
Orin Ewi ni Yoruba - Yoruba Poems: Awon Owe Yoruba Proverbs Alo Oro


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

"Awon Ohun Ti Oju Eni To Ba Fee Sise Fun Yoruba Maa N Ri Ree" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: