Gbagede Yoruba
 



Oogun Ki Awon Onile Sun Fonfon Ti Won Ba Fee Wole Won Ni Saliu Atore E Fi N Jale
 
Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Oogun Ki Awon Onile Sun Fonfon Ti Won Ba Fee Wole Won Ni Saliu Atore E Fi N Jale N’Ibadan

Bi eeyan ba n gbe koto ota e, ko ma gbe e jin, nitori o le je oluwa e gan-an ni yoo ko sinu koto naa. Oro awon agba yii lo see se ki okunrin afurasi ole kan fi se arikogbon pelu bi oun funra e se lugbadi oogun to gbojule to fi n ja awon eeyan lole, eyi lo si sokunfa bi owo se te e wooro nitori laduugbo ibi to ti jale naa lo sun si ti owo awon agbofinro fi to o.

Ole bii ka yo ero ibanisoro lapo awon eeyan tabi ka ja baagi gba ni titi ni okunrin eni odun mejidinlogun naa, Sunday Saliu ati ore e to n je Lukman Sunday fi bere. Sugbon leyin ti won se eyi fun odun meji ni won pinnu lati tesiwaju lenu ise aibofinmu naa; won wa ookan kun eeji, won gba ile onisegun lo.



Oogun buruku kan ni baba naa gbe le Saliu ati Sunday ore e lowo< agadagodo ni. O ni bi won ba de ibikan ti won ti setan lati sise, nise ni ki won ti agadagodo naa pa, nipa bee, orun asun- hanrun ni gbogbo awon ara adugbo ohun yoo sun to bee ti enikeni ko ni i ta putu titi ti won yoo fi ba tiwon lo.

Sugbon lojo Abameta to lo lohun-un, iyen ojo kewaa, osu yii, ni esuro pa idi da to n le aja nigba ti Saliu sun lo laduugbo to ti jale. Inu ile ahoro kan ti oun paapaa si ti n hanrun lawon agbofinro iko alaabo ijoba ipinle Oyo ti won n pe ni Operation Burst ti ri i mu ti won si so o si gbaga.

Gege bi oga awon Operation Burst, Ogagun Laz Ilo, eni ti igbakeji e, CSP Elijah Bawa, soju fun se so fawon oniroyin lolu ileese won l’Agodi, n’Ibadan, okan ninu awon ara adugbo ti won n pe ni Ayegun ni Odo-Ona Elewe lo ta awon lolobo pe awon ole kan waa yo awon lenu. O ni logan lawon iko alaabo ilu yii ti kan won lara, nibi ti won si ti n tu gbogbo korokondu ni won ti ri okunrin afurasi ole naa nibi to fi orun ko si ninu ile kan ti won n ko lowo.

Lara awon nnkan ti CSP Bawa so pe won ka mo Saliu lowo ni obe, awon ero ibanisoro, awon nnkan eso ara atawon nnkan mi-in, bee lo jewo pe oun ati Lukman jo n jale ni, sugbon won ko ti i ri oun mu.

Nigba to n ba Iwe Iroyin Yoruba soro, Saliu to pera e leni odun mejidinlogun salaye pe, “Mi o ti i nise kankan lowo. Ipinle Kogi ni won bi mi si, sugbon mi o mo iya mi nitori kekere ni mo wa ti won ti ko baba mi sile, ipinle Kogi ni won si n gbe. Odo egbon mi kan to je Kristeni ni mo n gbe ni Kogi ki n too wa s’Ibadan. Baba mi ti ku, ise aafaa ni won n se tele. Won fi mi si ile keu, sugbon okan mi ko si nibe nitori keu ko wu mi i ke.

“Leyin ti mo pari iwe mefa ni mo tele awon ore mi lo si Eko nibi ti mo ti ko ise birikila, oun ni mo si n dogbon se labe awon eeyan ti mo fi n jeun. Ore mi Sunday to ti sa lo yen lo maa n pe mi si ise nigbakigba ti ise ba wa, ti ko ba si si lo maa n pe mi pe ki n waa ba oun n’Ibadan ka jo loo jale. Odo-Ona Elewe ni Sunday n gbe, emi n gbe Eko, mo si maa n waa ba a lati jo ji owo ati foonu awon eeyan. Emi naa maa n pe e lo s’Ekoo ti mo ba ri ibi kan ta a ti le ri nnkan ji daadaa. “Odun keji ree ta a ti bere ise ole. Awon adugbo ta a ti saaba maa n jale n’Ibadan ni Challenge, Ayegun ati Odo-Ona Elewe. Sugbon l’Ekoo, irin wa ki i ju awon agbegbe Ikorodu ati Yaba lo.

“Ore mi lo mu mi loo se oogun yen ni Saki. A so fun baba onisegun yen pe ise awon omo onile la n se, a maa n ja ija ile, ohun ni won se se oogun yen fun wa niyen. Baba yen ni ta a

Saliu, ole to maa n kun awon eeyan lorun ba fee gba ile lowo eeyan, ka ti i pa, nise ni gbogbo awon eeyan yen maa sun lo. Egberun mewaa naira ni won gba lowo wa, egberun marun-un lenikookan si san.

“Osu yii naa la se oogun yen, a a ki n lo oogun jale tele. Igba yen gan-an, a ki i wo ile onile, baagi lasan la maa n ja gba lowo awon eeyan kiri oju titi. Leyin igba ta a soogun yen la bere si i wo ile onile.” Saliu to n gbe ni opopona Owonikoko, Mushin, l’Ekoo tun fi kun oro re pe, “ Nigba ta a soogun yen tan naa ni Sunday so pe ka loo dan an wo. Ni nnkan bii aago mewaa ale ojo Satide, oju windo la gba wole yen, awon eeyan si ti sun lo. Ekeji mi lo wo inu ile, a si ji awon ero ibanisoro atawon ohun eso ara obinrin.” Nigba to n salaye bi owo se te e to fi dero ahamo awon agbofinro, Saliu ni omo Ibadan ni Sunday, o loo sun sile e, oun si loo sun ile kan ti won n ko lowo laduugbo ohun nitori awon ki i jo loo sun ile tawon ba setan.

Ibi ti won ti ri oun niyen.

“Inu baagi ni mo gbe kokoro oogun yen si, mo waa gbe baagi yen korun. Nibi ti mo ti n sun lowo ni won ti waa mu mi. Iresi tutu ti mo gbe lowo pe ma a maa se je ninu ile yen naa wa lowo mi nigba naa.”

Sa, awon iko alaabo Operation Burst ti seleri lati mu Sunday to je enikeji Saliu nidii oran naa.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, October 27 @ 20:45:50 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise:
Orin Ewi ni Yoruba - Yoruba Poems: Awon Owe Yoruba Proverbs Alo Oro


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise



"Oogun Ki Awon Onile Sun Fonfon Ti Won Ba Fee Wole Won Ni Saliu Atore E Fi N Jale" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com