Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue
[ Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue ]

·Afise Loroo Benjamen Yi O, Leyin To Jade Lewon Lo Tun Loo Ji Telifisan Pasito
·Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
·Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
·E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
·Milionu Merin Pere La Ri Latigba Ta a Ti n Lu Awon Eeyan Ni Jibiti - Hussein
·Friday Paro Pe Won Ja Tanka Epo Gba Lowo Oun, Lo Ba Loo Ta a Sona Jebba
·Tunmise Ji Kaadi ATM Ore e Ni Saki, Owo Nla Lo Fi Wo Jade
·Olusiro-owo Gbe Owo Awon Osise Sa Lo L'Akoko
·Dereba Bisoobu Fipa Ba Eni To Ja Lole Lo Po, Ladajo Ba Ran an Lewon N'Ilori

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


E Ma Je Kawon Eeyan Yii Tun Lu Wa Ni Jibiti L'eekan Si Mo O
 
 
Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
Lati Owo Sherifat Okoya, Ibadan

E Ma Je Kawon Eeyan Yii Tun Lu Wa Ni Jibiti L'eekan Si Mo O

Eyi ti mo tun fee so yii, afaimo ni awon kan ko tun ni i so pe ki n mori wa ki n forun sile, tabi ki awon miiran tile binu titi ki won bo ewu sile ki won gbe apere wo, won le ni mo n bu awon tabi pe n ko fe ki won jaye ori won ni. Sugbon a ko gbodo ri ooto oro ka ma so o, bi a ko ba so o, aye yoo da wa lebi, nigbeyin gbeyin, Olorun paapaa a si da wa lebi. Oro awon egbe oselu ti won n pera won ni APC bayii ni mo fee so, ati bi oro naa ti se kan oro asaaju Yoruba ti a n so.

Sugbon oro ki i ye awon omo wa to n soselu boro, ibi ti won n lo ni won yoo dojuko ti won ko si ni i ronu boya oro naa yoo pada mu iparun ba gbogbo Yoruba lapapo ati idile won paapaa. Ti mo ba n ka oro awon omo wa yii lori ero ayelujara, erin a si pa mi titi, gbogbo ohun ti won ni lokan bayii ni pe egbe APC yoo gbajoba Naijiria, bi egbe naa ba si ti gba a tan, awon bo saye niyen. Iro gbuu! O see se ki egbe APC gbajoba Naijiria, o see se daadaa. Sugbon lojo ti APC ba gbajoba ile yii naa ni owo kilanko awon omo Yoruba to wa ninu egbe naa yoo yo danu, lojo naa ni awon Hausa yoo so fun won pe bi oro ba doro oselu, awon gbon ju won lo daadaa, ati pe awon kan lo awon eeyan wa lasan ni.Bee ni, won yoo lo gbogbo awon omo Yoruba inu APC lati fi gba agbara to bo lowo won pada, won yoo lo awon omo Yoruba inu PDP lati fi fo egbe naa kanlekanle, ko si ni i sona meji tawon egbe nla nla mejeeji yoo gba ju ki won fa Hausa kale lo. Oro naa yoo si da bii oro Olu Falae ati Olusegun Obasanjo ni odun 1999, to se pe ati otun, ati osi, Yoruba ni. Sugbon laisko yii o, bi owo Hausa ba tun te ijoba Naijiria, yoo soro gan-an ki akoso orile-ede yii too tun bo sowo eya mi-in, ko ni i je oro ogbon odun paapaa sasiko ti a wa yii.
Awon toro Naijiria ko ba ye yoo so pe mo tun de pelu isokuso mi, awon ti won ko si naani a n soro kasa segbe baba won le so pe won sese fun mi lowo tuntun ni. Sugbon bee ko, imo ati ete pelu ogbon oselu yato si imo nipa Naijiria. Bi eeyan ba ro pe oun logbon oselu, ti ko ba logbon nipa Naijiria, nigbeyin ni yoo ye e pe oun ko mo kinni kan. Emi pelu awon agbaagba kan ti soro yii, ohun ti won si so fun mi ni pe Bola Tinubu to n ko Yoruba lo saarin awon Hausa gbon ju bee lo, bi won ko ba fi i se igbakeji aare, won yoo fi i solori ile igbimo asofin, nibe ni yoo si ti maa pase fun eni to ba solori Naijiria. Yato sibe, won ni Yoruba bii Bisi Akande ni yoo si maa se alaga egbe APC yii. Erin ni mo bu si. Tabi ilu ko la wa nigba ti Obasanjo so Atiku di korofo bii igbakeji, tabi igbakeji gomina meta ko ni Bola funra re lo ko too setan, tabi awon eeyan yii gbagbe iye alaga egbe PDP ti Egbon Segun lo ko too fipo aare sile ni.


Ohun to sele ni Naijiria ni pe eni to ba wa nipo aare ni gbogbo agbara wa lowo re, ati igbakeji, ati igbaketa, ojo keji oja lasan ni won, ofo ni. Iyen lawon Hausa se koriira ki awon wa nipo keji tabi ipo mi-in to ba ti yato sipo aare tabi ipo olori ijoba ologun. Ko si sohun ti won ko le se lati depo naa, sugbon nigba ti ipo naa ba to won lowo, apa enikan ko ni i ka won mo. Nitori e lo se je pe nigba ti Iyaloja patapata, Oloye Abibatu Mogaji ku nijosi, ti mo ri Babangida to mu Abubakar dani ti won ni awon n loo ki Bola, ara fu mi aya mi si ja. Igba ti mo si tun ri awon mejeeji ti won waa ki Tunde (Fasola) fun ti baba re to papoda, ifura naa legba kan si i. Kin ni won n wa kiri? Ki awon oloselu kankan nile Yoruba ma se ro pe ife ti won ni sawon mejeeji yii lo fa a ti won fi waa ki won o, ohun ti won n wa ni won n wa, won yoo si gba kinni ohun dandan.

Ko seni ti ko mo ibi ti agbara oselu ile Yoruba wa loni-in, awon naa si mo pe owo Tinubu lo pin si, sugbon igba wo ni Babangida doree Bola, igba wo lo di baba-isale fun Tunde, se ife to ni si won l’Ekoo lo po to bee.

Rara. Sebi awon egbe APC kan ti n so pe okan ninu awon ti awon gbojule ninu APC niyen, awon si jo fee le PDP lo ni. Ki i se PDP lawon asaaju Hausa wonyi fee le kuro nipo, Jonathan ni won fee le kuro nibe, bi PDP ba fa omo Hausa kan kale loni-in, loju-ese ni gbogbo won yoo pada sibe, won ko si ni i ba Yoruba tabi enikeni se mo. Ona lati le Jonathan kuro lawon asaaju Hausa se gbese yii funra won, ti won si fee lo Yoruba lati ri i pe awon pada sile ijoba. Eleyii ki i se igba akoko o, eni ti ko mo ni ko mo, eni ti ko gbon ni ko gbon, gbogbo ijoba tawon Hausa ba fee doju e dele, awon Yoruba ati egbe won ni won yoo maa lo, awon ni won yoo maa pariwo pe ijoba naa ko dara, tabi pe eni to n sejoba naa ko sunwon. Awon eeyan wa ko mo idi tawon Hausa wonyi fi koriira Jonathan to bee, won ko mo rara. Ohun to fa a ni pe ninu ijoba ti won ti n je ni Naijiria, ijoba Jonathan nikan nijoba akoko ti ki i se awon olori Hausa wonyi ni won fa a kale. Yato si pe gbogbo awon olori Naijiria latile, omo won ni won, Obasanjo ti ki i se omo Hausa to sejoba Naijiria, awon Hausa wonyi ni won fa a kale funra won. Sugbon Yoruba lo ti Obasanjo subu funra won, awon ni won n so fun gbogbo aye pe ko je nnkan kan, ati pe awon lawon je babara, awon ti won n segbe oselu mi-in leeyan gidi. Gbogbo iyi ti Obasanjo iba gba gege bii olori Naijiria, awon oloselu wa nile Yoruba ti won n se mo-gbon-tan-mo-mo-tan ni ko je, oun ni gbogbo won fi n tayi;n, gbogbo ibi ti won ba duro si ni won ti n bu u ki oro ti won fee so le dun lenu won. Awon naa ni won n lo fun Jonathan yii o, Hausa n lo Yoruba lati ba ti Jonathan je ki won le gbajoba.

Tabi awon eebu buruku tawon oloselu n bu Yoruba yii, awon oro to ni akosile ti won ni Lai Muhammed n so, o di oloselu omo Hausa meloo ti won ka oro buruku bee mo lenu. Nigbeyin, awon asaaju Hausa yoo jade, won yoo ni awon Yoruba lo n bu u, awon ni won so pe ijoba re ko dara, eyi lawon se gbajoba lowo re.

Loooto, o see se ki Jonathan ma dara, tabi ko ma tile ni laakaye, sugbon awon Hausa ti won n sejoba latojo yii wa, meloo ni laakaye tiwon naa, ki lo de to je Yoruba lawon eeyan yii n lo lati gbajoba. Nigba aye UPN, awa yii wa ninu awon ti a n pariwo pe afi ki Shagari lo, ijoba re ko dara, ijoba ologun san ju ijoba re lo, ko si sohun meji ti a fi n pariwo ju pe ijoba naa ko bo sowo asaaju tiwa lo, pelu igbagbo pe a mo nipa eto idagbasoke ilu ju tire lo. Sugbon nigba tariwo wa po, awon soja Hausa gbajoba lowo e, won si ro gbogbo omo Yoruba ati Ibo sitimole, won ti awon eeyan tiwon naa mole o, sugbon iya to je won ko to tawon ti ki i se Hausa.

Bi e ba wo ija tawon oloselu Yoruba n ba Jonathan ja yii, e oo ro pe oro naa ki i se ti oselu nikan ni, e oo ro pe ogun ni won n ja ni. Bee ki i se ogun ni won n ja, oro oselu ni. Sugbon ohun to n dun mi nibe ni pe Hausa n lo won ni, won n fogbon mu won, won n ro pe awon gbon, bee awon asaaju Hausa yii gbon ju won lo.

Nigba ti wahala oro oselu bere ni 1962 titi di 1965, t’Awolowo si wa lewon, awon eeyan wa ti ko le mura duro, ti won sa pada loo ba awon Hausa yii, oro kan wa ti won maa n so fun won. Oro naa ni pe, “Sebi eyin le n so pe e ko le dobale fun gambari, se e ti waa setan lati dobale fun gambari bayii? Ohun to sele nigba naa la tun n fa lese yii o. A oo maa soro naa lo lose to n bo.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, October 27 @ 21:14:45 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin:
Buhari Omo Musa Sa Kuro Nibi Ayeye Igbeyawo Saidi Osupa: Lehin Ti Alfa Muri Fun


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin

"E Ma Je Kawon Eeyan Yii Tun Lu Wa Ni Jibiti L'eekan Si Mo O" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: