Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo
[ Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo ]

·Ilu Kan, Oba Marun-Un: Oba Ni Egba Ake, Egba Owu, Egba Agura, Oke Ona Ati Ibara
·Eyi Ni Bi Owo Se Te Alao To Fi Khadija Omo Igbakeji Mimiko Soogun Owo L'Aku
·Itan Bi Ladoke Akintola Se Di Aare-Ona-Kakanfo Ile Yoruba
·Eni Ba Fibi Soloore, Iya Ni Yoo Je Ku
·Akanni She Ayederu Iwe INEC, O Lashofin Loun, Lo Ba Fi Gba Awon Eeyan Repete
·L'Oshogbo, Awon Omo Egbe Okunkun Ti Won Fesun Ipaniyan Kan Foju Bale-ejo
·O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
·Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
·Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Adelabu Fesun Kan Awolowo Pe O Fee Ro Olubadan Loye, Lawon Ladoke Akintola Ba N
 
 
Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
Lati Owo Yemi Ogunjobi

Adelabu Fesun Kan Awolowo Pe O Fee Ro Olubadan Loye, Lawon Ladoke Akintola Ba N Sare Kiri

Ki oju ma ribi, gbogbo ara loogun re, ese ni won fi n wa a. Ladoke Akintola pelu awon omo I badan bii Adisa Akinloye, S.O. Lanlehin atawon to ku bee sare pada sodo oga won, Obafemi Awolowo, won si salaye fun un pe bi awon ko ba wa nnkan se si oro Adegoke Adelabu yii, okunrin naa yoo ba nnkan je fawon koja atunse. Won ni bi oro ti n lo yii, Adelabu yoo koyin awon si gbogbo awon ijoye Ibadan titi dori Olubadan ti i se oba won, bi awon ba si ti gba a laaye to ba se eleyii ni aseyori, bi ibo kankan ba de lojiji, ko si ariwo ti awon le pa lasiko ipolongo, ko si si ohun ti awon le wi rara ti awon ara Ibadan yoo dibo fawon. Won ni Adelabu ti fi ipade to se ni ojo kerindinlogbon, osu kesan-an, odun 1953, nibi ti Olubadan ti se alaga ra gbogbo awon ijoye naa pa.

Oro naa ka Awolowo paapaa laya, won si n wa ona ti won yoo fi mu Olubadan, Oba Sunmonu Igbintade. Sugbon won koko fee mo boya o n se tawon loooto tabi ko se tawon, won fee mo boya nigba ti awon pepade ti ko fi wa lakooko, boya ara re ko ya bo ti wi ni, won si fee mo boya ipade ti Adelabu pe to si lo yii, o fee fi han pe eyin okunrin onijangbon naa loun wa ni.Ni Ladoke Akintola ati awon eeyan re ba da a labaa pe ko sohun ti awon le se, afi ki awon tun sare pe ipade mi-in si Oke Mapo, ki awon si tun fi Olubadan se alaga ipade ohun gege bi Adelabu ti se. Bo ba wa si ipade naa, a je pe ara re ko ya nigba ti awon pe ipade akoko ni, ati pe eyin awon lo wa, o kan lo sipade Adelabu lati fi tan an je ni, sugbon ti ko ba wa sipade won, a je pe o ti ba Adelabu lo pata niyen o.
N ni won ba seto ipade o, won si fi ipade naa si ojo keje, osu kewaa, odun 1953, won ni ki Olubadan Igbintade waa se alaga awon. Kin ni ipade naa da le lori. Ki i se ipade to da le kinni kan pato, ipade oselu lasan ni, sugbon Awolowo ati awon eeyan re ko pe e bee, won ni ipade ti awon fee fi salaye awon ohun to n lo fara ilu ni. Bayii ni won dajo ti ojo ipade naa pe, gbogbo awon kanselo, gbogbo awon oloye ninu egbe Action Group, Egbe Olope, ati awon ti won jo n sejoba Western Region ti wa lori ikale, won ti la gbogbo eto ipade kale, ipade ohun si ti fee bere leseese. Sugbon won ko ri Olubadan, Oba naa ko wa sibi ipade itagbangba awon egbe Olope, bo tile je pe Ladoke Akintola ti i se igbakeji olori egbe ati awon eeyan bii Akinloye loo ba a lati salaye ipade won fun un.

Kaka ki Olubadan wa, nise lo ran awon eeyan wa o, sugbon awon eeyan gidi lo ran wa.

Awon meta lo ran lo. O ran Asipa Balogun, bee lo ran Iyalode, o si ran omo re okunrin pe ko siketa won, iyen Daodu Igbintade. O kan je pe awon ti oba yii ran lo sipade yii ko te awon Egbe Olope lorun rara, awon adari Action Group naa si binu gidi. Adisa Akinloye lo koko soro nibi ipade yii, o si rojo rojo lori awon ohun ti Adelabu n so kaakiri, o ni omo Ibadan loun naa, oun ki i se omo ale Ibadan, oun ko si le si ninu egbe ti won yoo fi Olubadan wole, tabi egbe kan ti yoo ba ilu Ibadan yii je. O ni egbe ti awon n se, egbe to ko gbogbo eeyan mora ni, ko si si ibaje kan ti egbe naa yoo se si ilu Ibadan. Bi oun ti soro tan ni Ladoke Akintola bo sibe lati salaye oun to n lo.

Oba I.B. Akinyele, Otun Balogun Ibadan ati adajo ibile to pada waa di Olubadan

Nitori pe oun gbon ogbon owe pupo, o si gbo Yoruba gidi, ati ohun re to dun, pelu awon orin to mo on ko, ogooro awon eeyan ti won wa nibe ni won n patewo, ti oro re si ye won ju ti Akinloye paapaa lo. Bo ti n soro to n jo, to si n powe, ti oun naa si je onila-loju bii ti opolopo omo Ibadan, awon mi-in ko tile tete mo pe ki i se omo Ibadan gan-an. Eleyii je ki oro re wo won leti daadaa, awon kan si ri i bii eni to kapa Adelabu, eni to le fi oro, orin ati ijo tako oselu kan soso naa ti won mo ni Ibadan to tun le se gbogbo nnkan bee yen.

Awon omo Adelabu ti won wa nibe paapaa n miri, won ko si mo eyi ti won yoo so si oro naa leyin ti Akintola soro re tan, bo ba si je ohun tawon eeyan gbe lo kuro ni ipade Egbe Olope nijo naa niyen, nnkan yoo yipada fun egbe won.

Sugbon Awolowo funra re lo boro je. Okunrin oloselu naa ki i se eni to n faaye gba palapala tabi ti yoo maa fi oro si abe ahon so, bee ni ko feran iro tabi ka maa pe ole ni oruko mi-in, gbogbo ohun to ba wa lokan oun loun yoo so. Nitori bee, bi o ti kan an lati soro bayii, ko fi oju aanu tabi oju rere wo Olubadan, o kuku la gbogbo e mole pe egbe oun ko feran awon ohun ti Oba naa n se. O ni o ti han gbangba bayii pe Oba Igbintade fee maa gbe leyin Adelabu lati di ise ijoba Ibadan lowo ni, eleyii ko si se aponle kankan fun un nitori oun lo ye ko ba won tun ilu naa se, ati pelu, Oba ki i da soro oselu, bi ti Olubadan se fee je ni ko ye awon. Awolowo ni ki Oba naa fi awon oloselu sile ki awon yanju oro awon, bi bee ko, ohun to ba tidi e yo, ki oun naa faramo on.

Bii igba ti awon omode ode-oni ba n dasa pe, ‘Ki la gbe ki le ju’ loro naa ri loju awon opolopo omo Ibadan, o si fi han won pe bi Adelabu ti n so pe Awolowo ri bee lo ri, pe o gberaga, ko si ka Olubadan si kinni kan, o fee fi oba awon wole, o ro pe oun lagbara ju u lo nitori pe o wa nile ijoba. Nigba ti won ti kuro ni ipade naa ni awon ti won mo agbara ijoba ti n so pe afaimo ki Olubadan ma jiya lati owo ijoba, nitori oro ti Awolowo so ni gbangba yii, won ni oro ibinu ni, oro to fi han pe bi Olubadan ko ba tete pada loo tuuba, yoo ba ara re nibi ti ko fe ni. Eeyan ko mo bi ihale Awolowo paapaa se ri lokan Olubadan paapaa, nitori awon ti won mo Awolowo mo pe asorose ti ki i soro danu ni, bi oro ba da bayii to si leri ni gbangba, eni to ba mo iwon ara re ko tete gbori sa ni. O da bii pe Olubadan yoo ranse abele sile ijoba pe tiwon loun n se.

Adelabu Adegoke ki i se eni ti i duro ki won fi pampe oselu mu oun bee. Kaka ko duro ki awon Awolowo se ohun yoowu ti won ba fee se, ona eyin lo gba yo si won. Se ojo keje, osu kewaa, ni awon Awolowo se ipade tiwon, nigba to si di ojo kesan-an, osu naa, iyen ni ojo keta ipade yii, ariwo buruku kan bere kaakiri gbogbo ilu Ibadan, ariwo naa si ni pe awon Awolowo ti se iwe Olubadan pari, won fee yo o loye lojo naa gan-an. Ko seni to mo ibi ti oro yii ti wa, ko si seni to mo boya iro ni tabi ooto ni, sugbon ohun ti won n gbe kiri ni pe ijoba ti seto pe ki Adisa Akinloye ati S.A Akinyemi wa awon kan ti won yoo loo da wahala sile ni aafin Olubadan, ati pe bi wahala naa ba ti n lo lowo, bee ni ijoba yoo ko awon olopaa pupo wa, won yoo si so pe wahala to sele ni aafin naa ko dara, won yoo si tori re yo Olubadan Igbintade nipo, won yoo si fi eni ti won ba fe si i.

Kia ni ariwo yii ti gbale to si n ja ran-in ran-in kiri Ibadan, oro naa si le debii pe opo awon eeyan nla ilu Ibadan jade, bee ni Adelabu ko awon omo egbe Olowo-ori re jo, gbogbo won loo duro siwaju aafin Olubadan, ati awon odo, won si n pariwo pe bi awon ba ri Akinloye tabi Akinyemi to sun mo itosi aafin Olubadan, pipa lawon yoo pa won. Oro naa ka ijoba Western Region laya debii pe nise ni won sare jade, ti won si se ikede pe ko senikan to fee yo Olubadan, ko senikan to ni i lokan lati yo o, nitori Olubadan yii ko se kinni kankan fun ijoba. Ikede naa salaye pe ki awon omo Ibadan sora fun awon oloselu, ki won ma je ki awon oselu kankan koyin won sijoba, tabi ki won je ki won da wahala sile lori oro ti ki i se ooto.

Won ni awon so o, awon tun un so o, ko si enikan ti yoo yo Olubadan nipo re, Oba naa yoo pe nipo oba kanrin kese.

Ko senikan to le so eyi to je ooto ninu isele naa, koda titi di bi a se n wi yii. Boya Awolowo pelu awon omo-eyin re bii Akintola ati Akinloye fee seto loooto lati wa ona yo Olubadan ni nitori iyonu to n fun won, ti won si ti pari eto lati yo o lojo naa, tabi ko je pe Adelabu gbon ju gbogbo won lo, o si saaju eleede peede, o ba awon Awolowo nibi ti won ko ti reti pe yoo ba yo si won. Eyi o wu ko je sa, ohun to han ni pe awon Adelabu lo gbe oro naa jade, awon ni won wa nidii e, awon naa ni won si seto gbogbo ti won lo si aafin Olubadan lati duro nibe, ti won ni awon n reti Akinloye tabi Akinyemi, tabi enikeni ninu Egbe Olope ti yoo ta ragbaragba de aafin naa ki awon le foju re ri mabo. Igbese ti won gbe yii ka awon Akintola ti won n kiri igboro lowo ko, nitori nise ni won tun bere si i sare lo saarin ilu lati so pe iro ni Adelabu n pa mo Awolowo, ati pe Awolowo ko koriira awon ara Ibadan.

Sugbon oro naa ko wo awon ara ilu yii leti nitori ohun ti Awolowo ti fenu ara re so ni gbangba pe ki Olubadan sora re, bi bee ko, ohun to ba tidi e yo fun un ko maa ran an ni. Awon oloselu ki i jawo ninu nnkan bee yen sa o. Kia lawon Akintola tun pade, won si ni ohun to dara ki awon se ni lati da egbe mi-in sile ti won yoo fi maa koju egbe yoowu ti Adelabu ba da sile nigbakigba. Egbe yii ni won pe ni Ibadan Emergency Group, egbe ti won fe ko ri si oro wahala Ibadan ni kiakia. Awon omo Ibadan ni won ko kun inu re, sugbon awon bii Ladoke Akintola naa wa nibe, bee si ni won sa opo omo Egbe Oduduwa jo pe ki won maa bo ki won maa waa ba awon ore won ati awon eeyan won ti won je omoobadan soro, ki won ma da awon da Adelabu nitori bi awon ko ba tete ka a lowo ko, yoo da nnkan ru mo awon lowo o.

Kinni kan ti Adelabu n lo fun awon eeyan wonyi ti won ko mo ni oro awon oloye ilu Ibadan. Oro ija oye to maa n sele ni Adelabu maa n gunle lati fi tako ijoba ati egbe awon Awolowo, bo ba si ti n tako won ni awon omo Ibadan, titi dori awon oba ati ijoye yoo maa wa leyin re, nitori won yoo ni ija awon lo n gbe, oro awon lo n da si, ko fe ki iya tabi aburu kan ba awon omo ilu Ibadan ni. Eleyii naa ni ki i je ki apa awon Awolowo ka a, nitori opo ofin atunse ti awon Awolowo n se nigba naa, wahala ati idaamu lo n ko ba awon oba ati ijoye, nitori e ni won se n so pe awon Awolowo fee gba gbogbo agbara lowo awon, bee ni o fee di awon ona ti awon fi n jeun. Adelabu mo pe awon ofin tuntun yii ki i se lodo awon nikan lo ti n sele, ofin oyinbo to fee gba ipo lowo awon ofin ti a ti n lo tele ni. Sugbon ko je so bee, kaka bee, yoo wi fun awon eeyan pe Awolowo fee maa fiya je won ni, ohun ti ko si se niluu mi-in lo n se fun won n’Ibadan.

Nibi ti won ti n fa oro won fee yo Olubadan won ko yo o yii ni nnkan mi-in ti sele lojiji ni ilu nla naa.

Salami Agbaje lo ku lojiji. Ogbonjo, osu kewaa, odun 1953 ni, bee Salami Agbaje yii ni Balogun Ibadan, oun lo ye ko je Olubadan bi Igbintade to wa nibe ba gbese, sugbon nigba ti oun ti waa ku yii, dandan ni ki won yan Balogun tuntun. Eni to si ye ki won yan ni Otun Balogun. Sugbon Otun Balogun yii, I.B. Akinyele, okan ninu awon omoleyin Awolowo ni, omo Egbe Olope ni o, bee osise ijoba ni. Nibe lawon Adelabu ti yari, won ni laye yii, Akinyele ko ni i je Balogun ilu Ibadan, bi yoo ba je balogun, afi ko lo si apa ona Ijebu, nibi to ti n ba won se. Oro yii gan-an lo si di wahala tuntun ti apa awon Awolowo ati awon Akintola ti won n soro awon omo Ibadan ko tun ka mo o.

E maa ka a lo lose to n bo.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, October 27 @ 21:15:14 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu:
Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

"Adelabu Fesun Kan Awolowo Pe O Fee Ro Olubadan Loye, Lawon Ladoke Akintola Ba N" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: