Gbagede Yoruba
 



AWON LETA TI O WAFUN AWON ALHAJI ATI AWON ONI UMRA
 
Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin
AWON LETA TI O WAFUN AWON ALHAJI ATI AWON ONI UMRA -- Lati Owo DR. SHEIK YAHYA BIN IBRAHIM ALYAHYA

Lati owo

DR. SHEIK YAHYA BIN IBRAHIM ALYAHYA

Olutumo re si ede Yoruba ni:Abu Maalik N. Alimaam

بسم الله الرحمن الرحيم

NI ORUKO OLOHUN ALANU JULO OBA ONI IKE.

Ope ni fun Olohun Oba gbogbo aye,mo njeri pe kosi eniti oye ki a josin fun ni toto ayafi oun, ore awon eni rere, mosi tun jeri wipe Anabi Muhamad eru Olohun ni ojise re si ni, asiwaju (ALGURRUL MUAJJALIIN) awon ti gbogbo orike ara won yo maa tan imole ni ojo Al qiyamo, O jise tiwon ran,osi pe adehun pelu,koda ose waasi ati ikilo fun ijore,o si fiwa sile lo lori imole gbo,ti oru re da bi osan re,enikankan kowa le sonu mo ayafi olori kunkun(eni iparun).ki Olohun se ike fun ati ara ile re pelu awon Sabe re lapapo,bakanaa ki ikeyi tun lo ba gbogbo eniti o ba pepe si oju ona re,ti o si ntele ilana re,titi di ojo esan,lehin naa:

Omo iyami Alhaji,iwo ti Olohun sa lesa lati wasi ile Olohun laarin ogunlogo awon musulumi,mo nbe Olohun ti o ga pe ki o duro ti o ni aye ati ni orun,ki o si se o ni alalubarika nibi yowu ti o bawa.

Omo iya mi alaponle:se bi iwo naa ni o farada opolopo wahala,ati isoro pelu inawo ,ti o si tun fi ile ati ara ati omo sile, o se gbogbo eleyi titori ki o le se ise Haji Oranyan ni,mo wa nbe Olohun ki o se Haji re ni atewogba,ki o si se aforiji ese re,ki o si bo asiri asise re.

Omo iyami Alhaji alaponle: ife ti moni si o,ati idunu mi si didere ni alaafia ni o mu mi ko awon leta yii si o,ati lati se die ninu ojuse mi si o,leyiti o je oranyan,bakanaa ni itele ase Olohun ti o sope:

(وتـواصـوا بالـحـق وتـواصــوا بـالصــبر) العـصـر /3

(Won si ma nso asotele ododo ati suru sise) Al-asr /3.



Mosi tun nfi eleyi ti mose yi tele ase Ololufe wa,asiwaju wa,awokose wa,Anobi wa Muhammed- salalahu alaehi wassalam- nigbati o so wipe:

(مثل المؤمنين في توادهم وتراحمهم وتعاطفهم كمثل الجسد الواحد إذا اشتكى منه عضو تداعى له سائر الجسد بالسهر والحمى).

(Apejuwe awon Olugbagbo ododo ni ibi inife ara awon ati mi ma ke ara won,pelu aanu,won da gegebi ara kan ti orike kan ninu ara naa bati se aisan,gbogbo orike yoku naa yo si ma ba se aare ati aisun).

O tun so wipe - salalahu alaehi wasalam - .

(المـؤمـن لـلـمـؤمـن كالبنيان يشد بعضه بعضا).

(Mumini si Mumini da gegebi ile ti amo,ti apakan re diro mo apakan).

Mo njeran ki iwo omo iyami Alhaji teti si awon leta omo iyare ti o ni ife re,ti o si ni aanu re loju, ki Olohun jeki o se o ni anfaani.

LETA KINNI

Omo iyami Alhaji,mase gbagbe wipe tori oun ti o fi fi ilure sile ni ise Haji,ki o si lo mo amodaju wipe ise Haji yii ati gbogbo ise rere,kole je atewogba ti yoo fi ni awon mojemu meji yii ninu: Sise nitori Olohun nikan

(وما أمروا إلا ليعبدوا الله مخلصين له الدين)البينة/5

(A ko pa won lase ju pe ki won njosin fun Olohun lo, ki won fo esin mo fun U) Albayyinah /5, ki o ba suna Ojise Olohun mu - salalahu alaehi wasalam - ,oun naa ni o sowipe :

(من عمل عملا ليس عليه أمرنا فهو رد)

(Enikeni ti o base ise kan ti kosi ba ilana wa mu iru ise naa koni je atewogba).

Kio ya riwipe gbogbo ero re nipe nje ise re je atewogba abi ko je atewogba?.

Anobi - salalahu alaehi wasalam - ti so nipa ise Haji wipe :

(خذوا عني مناسككم )

(E mu ise Haji yin lati odo mi).itumo re niwipe :e ko nipa bi mo sese Haji mi,ki eyin naa si se bee,kie mase se adadasile kankan nibe,ko wa si ona ti eniyan le gba se ise Haji yii ju ki o se gegebi o se wa lati odo Ojise Olohun lo,ki eniyan le baari ife Olohun ati aforijin re,Olohun ti o ga sope:

(قل إن كنتم تحبون الله فاتبعوني يحببكم الله ويغفر لكم ذنوبكم...) آل عمران :31.

(Wipe :Bi enyin ba je eniti o feran Olohun e tele mi, Olohun yio feran nyin, yio si fi ori awon ese nyin jin nyin).Aal-imran/31

O di owo ire omo iyami Alhaji alaponle lati ko nipa ise Haji,ki o si bi awon onimimo leere re,ki o to bere ise naa,nibayi,maa so die fun o nipa ise Haji ati Umrah,kiba dara ki o lo ka lekunrere nipare ninu tira miran.

BI ATI NSE UMRAH

(1) - Ti o ba de (Miiqoot)- ibugbe arami- we iwe bi o ti ma nwe iwe janaba,fi lofinda si ara re, wo aso arami re;(iro ati idabora funfun),Obinrin yo wo oun ti o ba wu ninu aso,sugbon ki o mase je aso oso tabi aso bi aso Okunrin,da aniyan ki o si sowipe :(Labbaika Umrah)ti o ba jewipe ise umrah lo fe se,lehin naa ki o maa se (Labbaeka), (Labbaika Allaummo labbaika,labbaika laa sheriika laka labbaika, innal amda wanni'imotalaka wal mulka ,laa sherika laka).

(Mo nje ipe re Olohun,mo nje ipe re,mo nje ipe re kosi si orogun fun o,mo nje ipe re,ope ati idera ati ola ti Ire ni,kosi orogun fun O.)

Dida aniyan ni miiqoot je oranyan, ko leto ki eniti o fe se ise Haji tabi Umrah koja re laida aniyan.

( 2)- Ti o ba ti da aniyan, awon nkan wonyi ti di eewo fun o lati se :

* Mimu irun kuro ni ara, tabi rire ekana owo ati ese,Olohun ti o ga sowipe :

)ولا تحلقوا رؤوسكم حتى يبلغ الهدي محله) سورة البقرة /196.

(Ki e ma si se fa(irun) ori yin titi ti ore na yio fi de aye re).Albaqorah/196

*Fifi lofinda si ara ati aso ati onje,bakanaa ko leto fun pe ki o wo nkankan ti lofinda yi,Ojise Olohun - Salalahu alaehi wasalam - sope :

(لا تحنطوه ولا تخمروا رأسه).

(E mase lo lofinda fun,e si mase bo ori re).

*Ibalopo,eleyi ni o lagbara ju ninu awon nkan wonyi,toriwipe ti eniyan ba danwo ki o to se tawaaf Haji,Haji re ti baje patapata,o si je dandan fun ki o maa ba ise Haji naa lo,bakanaa oranyan ni fun ki o tun Haji naa se ni eemi (odun ti o tele e),atiwipe yo pa eran Rakumi kan fun itanran.

Bakanaa o di eewo ki Okunrin fi ara po Obinrin niti igbadun,tabi pipan enu ara eni la.

Bakanaa ko gbodo fe iyawo,kosi gbodo fe fun eniyan,Ojise Olohun sowipe :

(لا يَنكِح المحرِم ولا يُنكح ولا يَخطب).

(Oni ise Haji ati Umrah ko gbodo fe iyawo, won kosi gbodo fe fun,koda ko gbodo ba Obinrin soro fife).

*Okunrin ko gbodo wo aso tiwon ran gegebi ewu,sokoto,awotele,bakanaa ko gbodo de fila,lawani,ate tabi akete,ati beebe lo.

*Eewo ni fun okunrin ati Obinrin pe ki o pa eran ori igbe,koda ko gbodo ran eniti o fe pa lowo,tabi ki o lee si.

*Obinrin ko gbodo bo oju re,beesini ko gbodo lo ibowo tori wipe Ojise Olohun - salalahu alaehi wasalam - sope :

(لا تنتقب المرأة المحرمة ولا تلبس القفازين)

(Obinrin ti o bati gbe arami ko gbodo bo oju re [nigbati o ba dawa tabi o wa pelu oni eewo re] bee sini kogbodo lo ibowo). sugbon yo maa bo ojure nigbati o ba wa laarin awon Okunrin ti kiise eni eewo re.Aisha-ki Olohun yonu si i-sowipe :

(كان الركبان يمرون بنا ونحن مع رسول الله صلى الله عليه وسلم فإذا حاذونا سدلت إحدانا جلبابها من رأسها على وجهها, فإذا جاوزونا كشفناه).

(Awon arin irin ajo ma ngba odo wa koja nigbati a ba wa pelu Ojise Olohun - Salalahu alaehi wasalam - ti won ba se deede wa, onikaluku wa yo si da iboju re ti o wa ni ori re- bo oju re, tiwon ba koja lo tan,ao si tun si pada).

(3)- Ri wipe o nse labaika daada titi o fi de moka ti iwo yo si fi bere tawaaf kahba.

Poyi ile Olohun ni eemeje ,ki o si maa bere ni ibi okuta dudu,(Ajarul aswad)ki o si maa pari re sibe bakana,lehin eleyi ki o kirun opa meji lehin maqaamo Ibrahim,ni tosi re ni tabi ibiti ojina si,sa tise eyiti o ba rorun fun o.

(4)- Lehin irun opameji yi: Mura lati lo sa safa ati morwah ni eemeje,yo bere lati safa yo si pari re si moriwah,safa si moriwah ni alakoko,moriwah si safa ni elekeji,bayi ni ao maa ka titi yo fi pe meje ni moriwah.

(5)- Lehin eleyi fa irun ori re tabi ki o ge gbogbo re,sugbon fifa ni oni olaju,pelu eleyi ni ise umrah fi pari,osi ti di eto fun o lati bo aso arami,ki o si wo ewu ati sokoto re…

(6)- Ti o ba je wipe Haji nikan ni o fe se, (Ifraad) nigbati o ba de miiqoot sowipe: (LABBAIKA HAJAN),ki osi mase labaika lopolopo titi ofi ju oko ni (JAMARATUL AQOBAH) NI ojo odun,ti o ba de kabah,se tawaaf (qudum) lemeje,ti oba le sa safa ati morwah, ni igbayi oti dipo sisa Safa ati morwa Haji niyen sugbon o ko gbodo ge nkankan nibi irun ori re,ki iwo yo si wa ninu aso arami re titi di ojo odun.

(7)- sugbon ti oba je wipe o fe se Haji pelu umrah ni (Qiraan) : nigbati o ba de meeqot iwo yo sowipe (Labbaika umrah wa hajjan), ki osi maase labbaeka daada titi ofi ju oko ni ojo odun,iwo naa yo si mase gegebi eniti o nse Haji nikan se nse.

AWON ISE HAJI

(1)- Ni iyaleta ojo - kejo (Dhul-ijjah) osu kejila odun Hijrah,we iwe igbe arami,ki o si gbe arami re, sowipe (Labbaika Hajjan) ,ki o si maase gbolohun(Labbaika Allahumo….) daadaa titi iwo yio fi ju oko ni ojo odun,ao maase gbogbo nti aso yi ti o baje wipe eniti nse Haji pelu umrah (TAMATU'U)ni.

(2)- Sugbon ti oba je Haji pelu umrah (QIRAAN) tabi Haji nikan soso(IFROOD) ni o nse,iwo koni bo aso arami re sile.

(3)- Ni ojo yii losi mina,ki irun aila ati alasari ni opa mejimeji,ki irun mogribi ni opa meta ati ishai ni opa meji,bakanaa ki irun Asuba ni opa meji re,iwo yo maa ki awon irun yi ni asiko won ni.

(4)- Ti orun bayo ni ojo Arafa ti se ojo kesan osu Dhul ijjah,lo si Arafa ki o si maase labbaika daada,ti obade Arafa tan,ki irun Aila ati Alasari papo ni asiko irun Aila,ni opa mejimeji,ao sipe irun lekan soso,sugbon iqoomo kookan ni owa fun iru kookan,kio wa ni Arafa yi titi orun yo fi wo,kio si se adua ati iranti Olohun daadaa, pelu pe kio koju si Qiblah.

Ri daju pe inu arafa ni owa,ki osi sora gidigidi lati kuro ni Arafa ki orun to wo.

(5)- Ti orun ba wo tan daadaa,gbera kuro ni Arafa losi Muzdalifa ni pelepele,ati suru,ti o ba de ibe, ki irun Mogribi ati Ishai papo pelu irun pipe kan,ati iqoomot meji,ki Mogribi ni opa meta re,Ishai ni opa meji,ti o ba tun di asunba,ki irun Asunba nibe,ki osi maase iranti Olohun ati adua kikan kikan lehin irun yi titi orun yio fi fe yo.

(6)- Gbera kuro ni Muzdalifah ti orun ba ku die lati yo,kio si kori si Mina pada,ti o bade Mina se awon ise ti nbo yi :

(A) Ju oko meje ni sisentele mo Jamaraat keta si mina kio si maase(Allau Akbar) nigbati o ba nju oko kookan,ri daju pe awon oko yi nbo si inu koto ti owa nibe.

(B) Lo du eran Hadayah re, je nnu re, si se sara fun awon alaini.

Oranyan ni pipa eran yi je fun eniti nse Haji (TAMATU'U) tabi (QIRAAN),ayafi ti iwo koba ni agbara, nigbayi ni o to le gba awe meta ni asiko ise Haji, ati meje nigbati o ba pada de ile re.

(D) Fa irun ori re tabi kio ge irun re,fifa yi ni oni ola julo,Obinrin yio ge deede ori omonika nibi irun ori re, (ko si nii fa'a).

O dara ti o ba le to awon ise meteeta yi bayi : jiju oko - didu eran - fifa ori. kosi laifi nibe ti ko ba le to bayi.

Ti o bati ju oko tio fa ori re,o ti leto fun o lati bo aso arami re sile,koda gbogbo awon nkan ti odi ewo fun o tele tidi eto fun o ayafi Obinrin nikan ni ki o mase sunmo.

(7)- Lehin eleyi koja si moka,kio si se tawaaf Haji lemeje,sa Safa ati Morwa,ti o baje wipe Haji (TAMATU'U) ni,ti o batise eleyi tan,ko laifi fun o lati sunmo Obinrin re.

(8) - Amo ti o baje wipe Haji nikan ni o nse tabi Haji (Qiraan)- iwo yo se tawaf ati sisa safa Morwah,ayafi ti o ba se wipe o ti sa safa Morwa tele ni igbati o se tawaf akoko se (quduum) ni igbati o wo ilu Moka, nikan ni o koni tun sa mo.

(9)- Lehin tawaf ati sisa safa morwa, seri pada si mina ki o si sun ibe ni oru meji tele ara won.Oru ojo kokanla ati ojo kejila.

(10)- Iwo yo maa ju oko mo (Jamaraat) meteta ni ojo keji odun ati ojo keta re,lehin ti orun bati ye atari, jujure yo bere nibi (Jamaraat) akoko oun sini o jinna ju si moka, lehin re ju jamarat keji naa,bakanaa ni iketa, oko mejemeje tele arawon ni iwo yo maa ju mo ikokan re, iwo yo si maase Allahu akbar bakanaa,se adua lehin ti o ju ti akoko ati ekeji tan ki o si koju si Qiblah, ko leto ki eniyan ju awon oko yi siwaju ki orun to ye atari ni awon ojo mejeeji yi.

(11)- Ti o ba nkanju o le fi mina sile lehin jiju awon oko ti aso yi.sugbon oranyan ni ki o kuro ki orun ojo naa to wo, ti o basi wu o lati lo ojo kan si,toriwipe oun ni oni ola julo, ki o sun ni mina, ti orun ba ye Atari ni ojo keji, ju oko yi gegebi o ti ju ni ana.

(12)- Ti o ba fe pada si ilu re,riwipe o se tawaaf idagbere ni eemeje,sugbon Obinrin ti nse eje nkan osu tabi ibimo koni se tawaaf idagbere.

SISE ABEWO ILU MODINAH
Omo iya mi alaponle : Mo dajudaju pe sise abewo Mosalasi Anabi ti o wa ni Medinah ni asiko Haji tabi asiko miran ba Sheria mu,toripe Anobi - salalahu alaei wasalam - so wipe :

(لا تشد الرحال إلا إلى ثلاثة مساجد,المسجد الحرام ومسجدي هذا والمسجد الأقصى)

(Ko leto ki eniyan se irin-ajo ijosin losi ibi kankan ayafi losi Mosalasi meta:Mosalasi Kahabah,ati Mosalasi mi yi,(Mosalasi

Modinah) ati Mosalasi Qudus).

Ti o bade ilu Medinah,yara tete losi mosalasi yi lati kirun nibe toriwipe irun eyokan nibe lola ju egberun irun ti eniyan ki ni ibomiran lo,Anobi - salalahu alaei wasalam - sowipe :

(صلاة في مسجدي هذا أفضل من ألف صلاة فيما سواه إلا المسجد الحرام)

(Irun eyokan ni mosalasi mi yi ni ola ju egberun irun ti eniyan ki ni ibomiran lo,ayafi eyiti eniyan baki ni mosalasi kahbah nikan).

Lehin eleyi lo salamo si Ojise Olohun - salalahu alaei wasalam - ati Abu Bakri,ati Umar,- ki Olohun yonu siwon- ni ibiti won sin won si.

Bakanaa o dara ki o se abewo Mosalasi Qubah ki o si kirun nibe toriwipe Anobi - salalahu alaei wasalam - sowipe :

(من خرج حتى يأتي هذا المسجد- يعني مسجد قباء- فيصلي فيه كان كعدل عمرة)

(Enikeni ti o ba wasi mosalasi Qubah ti osi kirun ni ibe laada ti yo gba se deede umrah sise).

Bakanna o leto fun o lati se abewo (Baqee) (Ibiti won nsin oku si ni Medinah) ati ibiti won sin awon Shuadah uhd si,lati se adua ati lati toro aforijin fun won, toriwipe Anabi - salalahu alaei wasalam - a ma se abewo won, a si ma wipe :

(السلام على أهل الديار من المؤمنين والمسلمين وإنا إن شاء الله بكم للاحقون)

(Alaafia fun eyin ti ewa ni aye yi, ni Mumini ati Musulumi ni agbara Olohun awa naa nbo wa bayin).

Iwo omo iya mi alaponle : - ki Olohun bami la o kuro nibi gbogbo aburu - awon aaye ti aso yi nikan ni o leto lati se abewo re ni ilu Onise Olohun- salalahu alaei wasalam - gbogbo aye yowu ti o bati yato si eyiti a daruko yi,ko leto lati se abewo re tabi kirun nibe rara,toriwipe ti ore bawa nibe ni,Anobi- salalahu alaei wasalam - ki ba salaye re fun wa,gbogbo wa ni a si jeri wipe, o jise pe perepere o sipe adehun,koda o se ikilo fun awa ijo re,o si fiwasile lo lori imole taara, ti oru re dabi osan,enikan koni sonu nibe ayafi olorikunkun eda,ani Olohun ko gba emi Anobi yi ti esin re fi pe perepere,Ike Olohun mi,Ola re,ore ajenjetan re ko maa baa ati awon ara ile re pelu awon sabe re ni apapo.

LETA KEJI
Iwo Alhaji alaponle,aimokan tabi igbagbe tabi aini akasi manje ki awon asise kan sele si awon Alhaji kan,maa so die nibe fun o,ki o leba jina sii,ki Hajji re si leba pe perepere pelu iyonda Olohun.

ALAKOKO : AWON ASISE TI O MA NSELE NI IBI ASO ARAMI ATI DIDA ANIYAN.

1.Mimo gbe arami ni miiqoot.

2.RirowIpe ko leto ki eniyan wo bata mo ti ko ba wo lasiko ti o ndaniyan lowo.

3.Rirowipe ko leto ki eniyan paro aso arami si omiran ni asiko ise Haji tabi Umurah.

4.Pi pakaja aso arami,eleyi ko leto ayafi nigbati o ba fe se tawaaf alakoko se.

5.Nini igbagbo wipe oranyan ni ki eniyan ki irun kan nigbati o ba gbe arami.

ELEKEJI: AWON ASISE TI NBE LARIN MIQOOT SI KAABAH.

1.Gbigbe gbolohun labbaika ju sile laise losi ibi orokoro eyiti o wa buru julo ni mima lo asiko yi fun awon nkan ti ko leto gegebi gbigbo ilu ati orin.

2.Sise gbolohun labbaika ni apapo.

ELEKETA: AWON ASISE TI O MA NSELE NI IGBATI O BA FE WO MOSALASI KAABAH.

1.Nini igbagbo pe oranyan ni ki eniyan wole lati oju ona kan gbogi,besini oro kori bee,ki iwo Alhaji mase daamu ara re lati maa beere oju ona umrah tabi fatih, ati beebeelo,amo ki o wole lati ibiti o ba rorun lati wole,sugbon o dara ti o ba wole lati oju ona (BANI SHEIBAH ) toriwipe ibe ni Anobi- salalahu alaei wasalam - gba wole.

2.Sise esa adua kan pato fun wiwo mosalasiyi, oro koribe tori wipe adua ti Anobi- salalahu alaei wasalam - ko wa pe ki amaa se wa fun gbogbo Mosalasi ni,leyiti mosalasi kaabah naa je okan nibe oun naa si niyi :

(بسم الله, والصلاة والسلام على رسول الله, رب اغفر لي ذنوبي وافتح لي أبواب رحمتك)

(Ni oruko Olohun,ike ati ola fun Ojise Olohun,fi ori ese mi jinmi Olohun,ki o si la ona ike re fun mi).

ELEKERIN : AWON ASISE NIBI TAWAAF.

1.Fifi ahon wi aniyan pe (iwo Olohun mofe se tawaaf ile ni igba meje)eleyi kosi ninu esin,Anobi- salalahu alaei wasalam - ko se e, beenaa sini awon sabe re,okan ni a fi nda aniyan.

2.Ki eniyan ma se bere tawaaf ni ogangan ibi ti okuta dudu wa,ti eniyan base be koni tawaaf naa.

3.Mima ti ara eni ni itikuti ni idi okuta dudu ati(rukunul yamaanii)origun ti a o kan ki a to kan okuta dudu,toriwipe a fee ponla tabi fi owo pa a.

4.Li lero wipe pipon okuta dudu la di tulasi,oro ko ribe sunnah ni lila, koda ti oba rorun ni.

5.Pipon origun ti a o kan ki a to kan origun okuta dudu la.

6.Pi posese nibi gbogbo tawaaf mejeje ,eleyi ti o je sunnah ni piposese yi nibi tawaaf meta akoko,koda fun awon Okunrin nikan ni.

7.Sisa adua kan lesa fun ipoyi kokan,gegebi awon kan ti won man mu iwe pelebe kan lowo ti yosi maa ka nti ko mo itumo re ni ibe.

8.Wiwo inu faranda kekere kan ti owa legbe Kahbah ni igbati o ba ntawaafu lowo,eleyi ma nba tawaaf je toriwipe ara kahbah ni faranda yi wa.

9.Gbigbe Kaabah si egbe otun tabi iwaju tabi eyin re ni igbati oba ntawaafu lowo,gegebi awon tiwon ma ndigaga bo awon Obinrin won ti ma nse,iru isesiyi le ba tawaaf je,tori wipe ninu majemu re ni ki eniyan gbe Kaabah si egbe osi re.

10.Mimo fi owo pa gbogbo awon origun kaabah.

11.Mimo pa ariwo soke nibi adua sise ni idi Kaabah,eleyi yo maa mu iberu Olohun lo,ko sini bu iyi kun Kahabah,koda idinilowo loje fun awon ti nse tawaaf lowo eleyi kosi dara rara.

12.Riro wipe dandan ni ki irun opa meji tawaaf waye ni idi makoomo ibrahim,tori eleyi ni yowa maa di awon tinse tawaaaf lowo yo si maa sewon ni suta ti ko kere.

13.Bakanaa ki eniyan fa irun opa meji tawaaf yi gun,ko ba sunnah mu rara,toriwipe Ojise Olohun- salalahu alaei wasalam - ma nkii kiakia ni,atiwipe fifa irun yi gun yo maa je idiwo fun awon ti won nse tawaaf lowo,ati awon miran ti awon naa fe ki iru irun yi ni aye yi.

14.Si se esa adua kan pato fun makaamo Ibrahim,eyiti o tun wa buru julo ni ki a mase adua yi ni apapo.

15.Fi fi owo pa ara makaamo Ibrahim yi,kosi eri fun rara.

ELEKARUN : AWON ASISE NI IBI SISA SAFA ATI MORWAH.

1.Fifi ahon wi aniyan,beesini okan ni afi da'a.

2.Fifi ere sisa sile laisa laarin ina alawo ewe mejeji fun awon Okunrin nikan.

3.Ki eniyan ma sare saa nibi lilo bibo re larin safa ati morwah,koda awon aburu ti o wa nibe po; titako sunnah,gbigbe emi gbona,kiko inira ba awon eniyan yoku,eyiti o wa buru julo niki eniyan maa sare yi titori ki ohun leba tete pari ijosin yi,ti o si jewipe idunu ati iberu ni o yeki eniyan fi maase ijosin.

4.Kika ayah:

(إِنَّ الصَّفَا وَالْمَرْوَةَ مِنْ شَعَائِرِ اللَّهِ فَمَنْ حَجَّ الْبَيْتَ أَوِ اعْتَمَرَ فَلا جُنَاحَ عَلَيْهِ أَنْ يَطَّوَّفَ بِهِمَا وَمَنْ تَطَوَّعَ خَيْراً فَإِنَّ اللَّهَ شَاكِرٌ عَلِيمٌ) (البقرة:158)

(Dajudaju Safa ati Marwa wa ninu awon ami Olohun,enikeni ti o ba rin irin ajo lo si ile na ni asiko Haj tabi ti o lo be e wo ni igba miran,kosi ese fun u,bi o baro kiri ka won.Eniti o ba si finufedo se rere nitoto.Eni ti nsan ore ni Olohun,Olumo si ni.) Albaqorah/158. nigbogbo igba ti eniyan bati gun oke safa ati mariwah,eyi ti oni ese ni ile ni ki eniyan ka a ni igba akoko bere ni oke safa toriwipe bayi ni Anobi - salalahu alaei wasalam - tise lati bere ni ibiti Olohun ti bere,O sowipe :

(أبدأ بما بدأ الله به) (إِنَّ الصَّفَا وَالْمَرْوَةَ مِنْ شَعَائِرِ اللَّهِ فَمَنْ حَجَّ الْبَيْتَ أَوِ اعْتَمَرَ فَلا جُنَاحَ عَلَيْهِ أَنْ يَطَّوَّفَ بِهِمَا وَمَنْ تَطَوَّعَ خَيْراً فَإِنَّ اللَّهَ شَاكِرٌ عَلِيمٌ) (البقرة:158)

(Maa bere pelu nti Olohun fi bere :(Dajudaju Safa ati Marwa wa ninu awon ami Olohun, enikeni ti o ba rin irin ajo lo si ile na ni asiko Haj tabi ti o lo be e wo ni igba miran,kosi ese fun u,bi o baro kiri ka won.Eniti o ba si finufedo se rere nitoto.Eni tin san ore ni Olohun,Olumo si ni).

5.Sisa esa adua kan pato fun lilo bibo ni safa ati moriwah.

6.Bi bere ni morwah.

7.Li lero wipe ipoyikan ni ki eniyan lo lati safa pada si safa,pelu eleyi yowa poyi re ni igba merinla(14),besini eemeje pere ni won ni ki a poyi.

8.Sisa safa morwah fun eniti kose umrah tabi Haji lowo,pelu ero wipe oun naa da gegebi tawaaf.

ELEKEFA : AWON ASISE TI O WA NI IBI ORI FIFA TABI GIGE IRUN

1.Fifa apakan ori fi apakan sile.

2.Gige irun diedie ni abalakan ni ibi ori,eleyi tako oro Olohun

( مُحَلِّقِينَ رُؤُوسَكُمْ وَمُقَصِّرِينَ) الفتح: من الآية27

(ti e o si fa ori nyin tabi ki e re irun yin mole). Alfat’i/27

3.Fifa ori tabi gige,lehin ti o ti wo aso re tan.

ELEKEJE : AWON ASISE OJO AKOKO NINU AWON OJO ISE HAJI.

1.Nini igbagbo pe oranyan ni ki aki irun opa meji fun gbigbe arami ati wipe oranyan ni ki eniyan lo aso arami tuntun.

2.Pi pakaja aso arami yii.

3.Nini igbagbo pe aki fi aso arami ti afise umrah se ise Haji.

4.Fifi gbolohun (labbaika allaumo…) sile laise nigbati o nlo si mina.

5.Lilo Arafah tara ni ojo yi.

6Jijoko pa si maka lai losi mina.

7.Pipa awon irun po ni mina.

8.Kiki awon irun pe ni mina.

ELEKEJO : AWON ASISE TI O MA NWAYE NIGBATI WON BA NLO SI ARAFA ATI DIDURO NIBE

1.Fifi gbolohun (Labbaika Allaumo…) sile laise nigbati o ban lo si Arafa.

2.Diduro si ibiti kise Arafah,lehin ti orun ti ye atari.

3.Ki koju si oke arafa nigbati o ba nse adua.

4.Li lero wipe oranyan ni ki eniyan gun oke lo.

5.Li lero wipe Arafah wa ninu ile aram,pelu eleyi eniyan ko gbodo ja igi ibe tabi ki o ge.

6.Nini igbagbo wipe oke Arafah ni anfani kan ti o lese fun ni,atiwipe titori re ni won fi ngun, ti won si ndiro mo awon igi ibe.

7.Jijade kuro ninu Arafah ki Orun to wo.

8.Fifi asiko rare ni ojo naa,papa julo lilo awon asiko yi si ibi nti Olohun se ni eewo gegebi : Yiya foto,gbigbo ilu ati orin,siso oro kobakungbe,sise awon eniyan ni suta.

ELEKESAN :AWON ASISE TI O MA NWAYE TI WON BA NLO SI MUZDALFAH.

1.Kikanju ju bi o tise ye lo.

2.Si sokale ki o to de Muzdalifah.

3.Kiki irun Mogribi ati Ishai ni oju ona kio to de Muzdalfah.

4.Fifi irun Mogribi ati Ishai yi fale titi asiko re yo fi lo tan,(oun naa sini idaji oru). nitoriwipe a koti de Muzdalfah,asise gbaa ni eleyi je,oranyan ni kiwon ki irun yi ni ibiyowu tiwon ba wa titori ki asiko re ma baa se lo.

5.Kiki irun Asunba ki asiko re to wole,ti awon Alhaji kan bati ngbo ohun irun pipe,bee naa sini won yo ma ki irun yi lai bikita.

6.Kikuro ni Muzdalfah loru,ati mimo sun ni ibe.

7.Sise aisun ni oru Muzdalfah pelu oro won ni wonpe,tabi pelu awon nkan eewo.

8.Diduro si Muzdalifah titi Orun yo fi yo.

9.Nini igbagbo wipe oranyan ni sisa oko lati ibe.

ELEKEWA : AWON ASISE TI O MA NWAYE NI IBI OKO JIJU.

Ojise Olohun - salalahu alaei wasalam - ti se alaye idi Pataki ti afi nju oko yi pelu oro re ti o lo bayi :

( إنما جعل الطواف بالبيت وبين الصفا والمروة ورمي الجمار لإقامة ذكر الله لا لغيره)

(Idi Pataki ti afi n tawaaf kaabah,ti asi fi nsa safa ati moriwah,ti asi fi nju oko - ni lati fi se iranti Olohun nikan ni.).

Eleyi ni die ninu awon asise ti o ma nwaye nibi oko jiju :

1.Fifo oko nu tabi fifi lofinda si.

2.Riro pe ibi ti a nju oko yi mo ni esu laalu gan wa,ero kero ni eleyi je,toriwipe a nju oko yi nitori iranti Olohun ni ati lati fise ijosin fun ni,awon aburu oniran iran ni o wa nibi erokero ti a so yi,ninu re ni:

-A ma je ki eniyan wa si ibi oko yi pelu ibinu ti o lagbara,ti yo si maa se awon eniyan ni suta ni ibe.

-A ma jeki eniyan gbagbe wipe oun nfi oko jiju yi sin Olohun ni,ni iwo yio fi maa ri apakan awon eniyan ti yo maa ju awon okuta rigidirigidi,ati igi ati bata.

3.Li lero wipe Oranyan ni ki okuta yi ba opo kan ti o naro ni ibi ti a nju oko mo,besini ti oko yi bati bosi inu koto ti o wa nibe,oti to.

4.Bi ba eniyan ju oko yi laikoni idi Pataki kan.

5.Li lerowipe oko ti a sa ni Muzdalfah nikan ni a ma nju,besini kosi oko ti ako le ju..

6.Jiju oko yi ni pasi payo tabi bi bere re lati ipari.

7.Jiju oko yi ki asiko re tooto.

8.Jiju oko yi din ni emeje.

9.Sise alaimaduro lehin ti a ju oko Jamarah alakoko ati elekeji tan.

10.Jiju oko yi le,yala onka re ni abi iye igba.

ELEKOKANLA : AWON ASISE TI O MA NSELE NI MINAH.

1.Fifi mina sile lai sun,loo sun moka tabi adugbo tiwo npe ni AZIIZIYAH.

2.Fifi mina sile ni ojo kejila osu Haji ki Orun to ye Atari.

Ni ipari,iwo omo iya mi alaponle :Oran kan wa ti awon apakan Alhaji ma nkosi,oun naa niwipe,won ki bikita rara si owo ti won fi wa se ise Haji,iwo yo maa ri apakan won ti ojewipe owo araamu ni o muwa se Haji,oun siti gbagbe pe:

(إن الله تعالى طيب لا يقبل إلا طيبا)

(Olohun oba ti o ga,Oba ti o mo ni,kosi nigba ju nti o mo lo).

Bee naa ni awon Alhaji miran ma nra awon nkan araamu losi ile fun awon eniyan won,gegebi : keseti orin ati ilu,ati awon eroja tabi oun elo orin,eleyi tiwon nse yi tako idupe idera Olohun,koda eru ti nbawa fun iru enibe nipe,ko ma wa jewipe ise re yi ntumosi pe Olohun ko gba Haji re lowo re,yara se ojukokoro iwo omo iyami alaponle losibi mimu owo alali wa se Haji,ki osi ra awon nkan ti yo wulo fun awon ara ile re ati omo re,gegebi tira(iwe) ti o dara, kaseti ti o wulo.

LETA KETA

Ki Olohun la iwo omo iyami nibi gbogbo aburu ati awon ese,mofe ki o mowipe Esu kosun kowo titori ki o le so awon musulumi nu,ati sise aburu loso fun won.Olohun ti oga so nipa re wipe:

(وقال لأتخذن من عبادك نصيبا مفروضا) النساء/118

(o wipe: Emi yio ko apakan ti a yan ninu awon erusin Re.) Annisaa/118.

O tun so nipa re wipe :

(قال فبما أغويتني لأقعدن لهم صراطك المستقيم ثم لأتينهم من بين أيديهم وعن أيمانهم وعن شمائلهم ولا تجد أكثرهم شاكرين) الأعراف/ 17

(Esu) wipe : Nitoripe O tipe mi ni eni anu,emi yio ba de won ni oju ona Re ti o to tara,Lehinaa dajudaju emi yio ma wa ba won lati iwaju won ati lehin won ati lati owo otun won ati lati owo osi won,O ko si ni ri opolopo won ti nwon yio je oluse ope).Al-a`araaf/17.

O tun so nipa jijina si awon ilana esu ti o ma nmu eniyan de ibi iparun:

(يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لا تَتَّبِعُوا خُطُوَاتِ الشَّيْطَانِ وَمَنْ يَتَّبِعْ خُطُوَاتِ الشَّيْطَانِ فَإِنَّهُ يَأْمُرُ بِالْفَحْشَاءِ وَالْمُنْكَرِ وَلَوْلا فَضْلُ اللَّهِ عَلَيْكُمْ وَرَحْمَتُهُ مَا زَكَى مِنْكُمْ مِنْ أَحَدٍ أَبَداً وَلَكِنَّ اللَّهَ يُزَكِّي مَنْ يَشَاءُ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ) (النور:21)

(Enyin onigbagbo ododo, e mase tele awon oju ona ti esu atipe enikeni ti o ba tele awon oju ona ti esu,dajudaju on (esu na) yio ma ko (nyin) ni iwa ibaje ati iwa buburu.Bi ko basi ore-ajulo ti Olohun ti mbe lori nyin ati anu Re,enikan ninu yin ki ba ti mo lailai.Sugbon Olohun ma nfo eniti O ba fe mo. Atipe

Olohun naa ni Olugboro,Onimimo). Annuur/21.

Eleyi ti oburu julo ni igbiyanju esu lati mu omo eniyan se ebo pelu Olohun,toriwipe esu yi mo amodaju wipe Olohun koni se aforijin re lailai,Oba ti ola re ga sowipe :

(إِنَّ اللَّهَ لا يَغْفِرُ أَنْ يُشْرَكَ بِهِ وَيَغْفِرُ مَا دُونَ ذَلِكَ لِمَنْ يَشَاءُ) (النساء: من الآية48)

( Dajudaju Olohun ki yio forijin eniti o ba da nkan po mo O,sugbon yo saforijin ese miran yato si eyi fun enikeni ti O ba fe ).Annisaa /48.

Mofe ki iwo omo iyami alaponle mo wipe Esu ti a nwiyi koni so taara wipe ki eniyan se ebo,sugbon pelu ete ati sise awon ise ti o le mu eniyan se ebo loso ni, sebi ona ti o kuku gba mu ebo wo arin awon ijo Anobi Nuhu niwipe : nigbati awon eni rere ijo naa ku,ni Esu ba sofun won pe kiwon o ya aworan awon eni naa lati maa ranti imo ati ise rere won,ki awon sile maa se bii won,bayi ni wonse nbaalo titi awon iran miran fide lehin won,ti Esu ti a nwiyi si sofun won pe : Awon Baba yin ya aworan awon eni rere yi lati maa wa iranlowo lati odo won ni asiko awon isoro ati ni igba ipanju,bayi ni won se nba lo kerekere titi won fi di eniti nbo awon ere yi lehin Olohun.

Laisi iyemeji nibe,ogunlogo awon eniyan ni won ti kosi inu awon ese nlanla ti o si ti so won di elebo,sugbon tiwon ko fura rara,gegebi awon kan se maa nsope : Mope iwo asiwaju mi Usain, tabi iwo siti Zainab,tabi iwo Badawi,tabi iwo Matbuuli, tabi mope iwo asiwaju mi lagbaja,gbami,lami, ranmilowo, wo alaisan san,jeki nri nkan mi ti o sonu,fun mi ni omo,jeki njeja lori awon ota mi ati awon ti won yan mi je.

Ninu apejuwe naa nii : Fifi ori bale fun sare,tabi kiki irun ni idire,tabi ki o riwipe kikoju si sare ki irun ni ola ju kikoju si Qiblah lo,tabi ti tawaaf sare ju ti tawaaf

Kahbah lo.

Iwo omo iyami alaponle ki Olohun so o - gbogbgo awon nti a ka yi tidi mimo fun tile toko pe ebo nla ni,nje ni owa rorun fun oni lakaye kan pe ki o ma wa ona abayo tabi iranlowo lodo oku bi !!,toriwipe ti oku yi ba ni agbara kan ni kibatiku,atiwipe se wollii yi tabi enirere yi ju Ojise Olohun lo ni - salalahu alaei wasalam - eniti kosi eda bi tire lori ile besini kosi si ni abe sanmo,se bi oun naa Olohun pa lase wipe ki o so fun awon ijo re wipe :

(قُلْ لا أَمْلِكُ لِنَفْسِي نَفْعاً وَلا ضَرّاً إِلَّا مَا شَاءَ اللَّهُ وَلَوْ كُنْتُ أَعْلَمُ الْغَيْبَ لَاسْتَكْثَرْتُ مِنَ الْخَيْرِ وَمَا مَسَّنِيَ السُّوءُ إِنْ أَنَا إِلَّا نَذِيرٌ وَبَشِيرٌ لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ) (الأعراف:188)

(Wipe : Emi ko ni agbara anfani kan funra mi bakanaa ni nko ni agbara inira kan ayafi ohun ti Olohun ba fe.Ti o ba se pe mo mo ohun ti o pamo,nba wa opolopo oore funra mi,buburu ko ba si ti ba mi.Ko si ohun ti emi je ju olukilo ati olufunni ni iro idunnu fun awon enia ti nwon ni igbagbo ododo).Al-a`araaf/188.

O tun so bakana pe :

(قُلْ إِنِّي لا أَمْلِكُ لَكُمْ ضَرّاً وَلا رَشَداً قُلْ إِنِّي لَنْ يُجِيرَنِي مِنَ اللَّهِ أَحَدٌ وَلَنْ أَجِدَ مِنْ دُونِهِ مُلْتَحَداً) (الجـن:21-22)

(Sope : Dajudaju emi ko ni agbara lori aburu kan tabi ore kan fun nyin,Sope : Dajudaju ko si enikan ti o le gba mi sile lodo Olohun, emi ko ri eniti mo le sadi lehin Re) .Aljinn/21-22

Nigbati amo wipe Ojise Olohun - Salalahu alaei wasalam - ko ni ikapa ore tabi aburu kankan,be sini enikankan ko le gba sile lowo Olohun, nje ni o wa tile ba ojumu, ki eniyan ni igbagbo si enikankan lehin re pe o ni ikapa oore kan, tabi titi aburu kan bi !!

Koje jebee ki Musulumi kan ni iru igbagbo be rara. Olohun ti o ga sope :

(وَيَعْبُدُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ مَا لا يَضُرُّهُمْ وَلا يَنْفَعُهُمْ وَيَقُولُونَ هَؤُلاءِ شُفَعَاؤُنَا عِنْدَ اللَّهِ قُلْ أَتُنَبِّئُونَ اللَّهَ بِمَا لا يَعْلَمُ )(يونس: من الآية18)

(Atipe nwon nsin lehin Olohun ohun ti ko le se inira fun won ti ko si le se won ni anfani,awon so pe : Awon wonyi ni olusipe wa ni odo Olohun.Wi pe E o ha fun Olohun niro ohun ti ko mo)Yuunus/18. ,eleyi gan ni ise ati ise awon osebo pelu awon orisa won,nje ni o ba ojumu ki Musulumi ko ise awon osebo bi?!.ki osi maa wa ebe lowo wolii ati awon eni rere lehin tiwon ti ku !!

Olohun tun nse alaye nipa awon osebo tiwon nwa awawi wipe awon ko bo awon wolii ati awon orisa yi bikose wipe lati fiwon se akaso losi Odo Olohun ni.O sope :

(وَالَّذِينَ اتَّخَذُوا مِنْ دُونِهِ أَوْلِيَاءَ مَا نَعْبُدُهُمْ إِلَّا لِيُقَرِّبُونَا إِلَى اللَّهِ زُلْفَى إِنَّ اللَّهَ يَحْكُمُ بَيْنَهُمْ فِي مَا هُمْ فِيهِ يَخْتَلِفُونَ إِنَّ اللَّهَ لا يَهْدِي مَنْ هُوَ كَاذِبٌ كَفَّارٌ)(الزمر: من الآية3)

(Atipe awon eniti nwon mu alafehinti lehin Olohun (nwon yio ma sope) : A wa ko sin won bikose pe ki nwon le sun wa mo Olohun ni pekipeki. Dajudaju Olohun ni yio se idajo ni arin won nipa ohun tin won nyapa enu si.Dajudaju Olohun na ko ni to eniti o je opuro alaigbagbo sona).Azzumar/3 , nje ni owa sese ki ari musulumi kan ti o gba oro Olohun gbo denu ki o situn maa pe nkan miran lehin Olohun,bi awon wolii tabi enirere,ki osi maafi oro awon osebo se eri?.

Olohun si ti salaye pe gbogbo nti won npe lehin Olohun ofurugbada niwon,Oba mimo sope :

(وَالَّذِينَ تَدْعُونَ مِنْ دُونِهِ لا يَسْتَطِيعُونَ نَصْرَكُمْ وَلا أَنْفُسَهُمْ يَنْصُرُونَ) الأعراف /197

(Awon eniti enyin npe lehin Re ko ni agbara iranlowo fun nyin,beni nwon ko le ran ara won lowo).Al-aaraaf/197. ,nigbati Olohun sope won ko le ran yin lowo,koda won ko le ran arawon lowo,nje ni owa sese ki mususlumi ti Ori re pe tun ni igbagbo pe won le ran oun lowo lehin Olohun ? enikeni ti o ba sobe tipe Olohun ti oga ni iro,eniti o ba sipe Olohun ni iro tidi keferi,koda ki iru enibe maa kirun, gba awe,ti o si npe ara re ni musulumi.

Se nigbati Oga awon Ojise, asiwaju omo Adamo - salalahu alaei wasalam - eniti yo sipe ni ibuduro gbogbo eda ni ojo igbende,eniti gbogbo eniyan yo wa labe re asia re,Koda ati gbogbo awon Anabi ati awon Ojise,gbogbo eleyi ribe tori iyire ti o buaya, ati ipo re ti o ga, ati aaye re ti o Pataki,pelu gbogbo eleyi Anabi yi ko ni ikapa nkankan fun awon alasunmo re.

Abi oti gbagbe pe nigbati o gun oke Safa lo gegebi o se wa ninu egbawa Imam Bukhari ninu tira re(Sahihu) lati enu omo Abbaas ati Abu Hurairah won sowipe :Ojise Olohun - salalahu alaei wasalam- so nigbati Olohun ti o tobi ti o si kanka so aya yi kale :

(وَأَنْذِرْ عَشِيرَتَكَ الْأَقْرَبِينَ) (الشعراء:214)

(Ati ki ose ikilo fun awon ara ebi re ti o sunmo o julo.) Asshuaraa/214.

O sope :

(قَالَ يَا مَعْشَرَ قُرَيْشٍ أَوْ كَلِمَةً نَحْوَهَا اشْتَرُوا أَنْفُسَكُمْ لَا أُغْنِي عَنْكُمْ مِنْ اللَّهِ شَيْئًا يَا بَنِي عَبْدِ مَنَافٍ لَا أُغْنِي عَنْكُمْ مِنْ اللَّهِ شَيْئًا يَا عَبَّاسُ بْنَ عَبْدِ الْمُطَّلِبِ لَا أُغْنِي عَنْكَ مِنْ اللَّهِ شَيْئًا وَيَا صَفِيَّةُ عَمَّةَ رَسُولِ اللَّهِ لَا أُغْنِي عَنْكِ مِنْ اللَّهِ شَيْئًا وَيَا فَاطِمَةُ بِنْتَ مُحَمَّدٍ سَلِينِي مَا شِئْتِ مِنْ مَالِي لَا أُغْنِي عَنْكِ مِنْ اللَّهِ شَيْئًا)

(Mope eyin Quraish-tabi gbolohun kan ti o jobe- e gba arayin sile ,emi kole gbayin sile lodo Olohun,eyin omo Abdu Manaaf,emi kole gbayin sile lodo Olohun,iwo Abbas Omo Abdul Mutolib emi kole gba o sile lodo Olohun,iwo sofiyyah omo iya baba Ojise Olohun emi kole gba o sile lodo Olohun,Iwo Fatimoh Omo Muhammad bimi lere nti oba wu o ninu owo mi, emi kole gba o sile lodo Olohun.).

Nigbati ti o jewipe Anabi yi - salalahu alaei wasalam - kole gba omo iya baba re lokunrin ati lobinrin sile, lodo Olohun, koda omo bibi inure, kiwa ni ki a so nipa elomiran ti o yato siwon ! ? Ire omo iya mi mo fe ki o ronu si oro yi daadaa.

Nigbati Ojise Olohun fe ma toro aforijin fun omo iya baba re tinje (Abu- Toolb) sababi pe o duro ti osi fa mora,sebi Olohun re ko fun pe ki o mase danwo osope :

(مَا كَانَ لِلنَّبِيِّ وَالَّذِينَ آمَنُوا أَنْ يَسْتَغْفِرُوا لِلْمُشْرِكِينَ وَلَوْ كَانُوا أُولِي قُرْبَى مِنْ بَعْدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمْ أَنَّهُمْ أَصْحَابُ الْجَحِيمِ)التوبة/113

(Ko to si Annabi ati awon ti won gbagbo ni ododo pe kin won toro aforijin fun awon osebo,bi o fe bi nwon je ebi ti o sunmo woon,lehin ti o ti han si won pe dajudaju awon (osebo) ni ero ina.)Attaoba/113.

Olohun ti o ga tun sofun nigba ti ori ojukokoro re si ki omo iya baba re (Abu Toolb) yi ki o mona:

(إِنَّكَ لا تَهْدِي مَنْ أَحْبَبْتَ وَلَكِنَّ اللَّهَ يَهْدِي مَنْ يَشَاءُ وَهُوَ أَعْلَمُ بِالْمُهْتَدِينَ) القصص / 56

(Dajudaju ire ko le fi ona mo eniti o feran,sugbon Olohun lo nfi ona mo eniti O ba fe,atipe Oun lo mo ju nipa awon ti nwon mona.)Alqosos/56.

Odi owo iwo omo iyami alaponle ,mase jeki bi awon alaimokan se npe elomiran yato si Olohun tan o je

(وَتَوَكَّلْ عَلَى الْحَيِّ الَّذِي لا يَمُوتُ)الفرقان /58

(Atipe ki o gbekele (Olohun) Alaaye Eniti ko ni ku) Alfrqoon. ,Mase pe ju Olohun lo,masi se gbara le ju Olohun lo,bakana mase wa abayo,masi se wa iranlowo ayafi lati owo Olohun,ki osi mo pe Olohun ti o ga sunmo o ju gbogbo nkan lo, O sope :

(وَإِذَا سَأَلَكَ عِبَادِي عَنِّي فَإِنِّي قَرِيبٌ أُجِيبُ دَعْوَةَ الدَّاعِ إِذَا دَعَانِ) البقرة /186

(Nigbati awon erusin Mi ba bi o lere nipa Mi, dajudaju Emi mbe ni tosi; Emi nje ipe olupe-ipe nigbati o bape Mi)Albaqorah/ 186.

Iwo omo iyami - ki Olohun bami so o - tele asotele Ojise Olohun - salalahu alaei wasalam - fun omo Iya Baba re tise Abdulah Omo Abaas nigbati o sofun pe :

"إذا سألت فاسأل الله، وإذا استعنت فاستعن بالله، واعلم أن الأمة لو اجتمعت على أن ينفعوك بشيء لم ينفعوك إلا بشيء قد كتبه الله لك، وإن اجتمعوا على أن يضروك بشيء لم يضروك إلا بشيء قد كتبه الله عليك، رفعت الأقلام وجفت الصحف "

(Ti oba fe toro nkan toro lodo Olohun,ti o ba fe wa iranlowo odo Olohun ni ki o ti wa,mo pe ti awon eda ba gbimo po lati se o ni anfani kan,ko le sese fun won,ayafi ti o batiwa ninu akosile Olohun,Bakanaa ti won ba si gbimo po wipe awon yo ko suta kan ba o,won ko le rise ayafi tio batiwa ninu akosile ni,toriwipe gege ti ko tan,koda takaida tigbe furufuru).

Iwo omo iya mi tooto,Olohun yo so o kuro nibi gbogbo aburu,mofe ki o mo wipe awon adua nlanla nbe ti Ojise Olohun - salalahu alaei wasalam - ma nko awon sabe re,awon adua yi wulo pupo,odi owo re pe ki o ko nipa re,ki o si ha si ori,ki osi maa lo, ninu re ni :

(اللهم إني أعوذ بك من جهد البلاء ودرك الشقاء وسوء القضاء وشماتة الأعداء)

(Iwo Olohun,mo sa dio nibi adantan,ati aleba oriburu ati kadara buru,ati irerin ota).

"اللهم أصلح لي ديني الذي هو عصمة أمري، وأصلح لي دنياي التي فيها معاشي، وأصلح لي آخرتي التي فيها معادي، واجعل الحياة زيادةً لي في كل خيرٍ، واجعل الموت راحةً لي من كل شرٍ"

(Iwo Olohun bami tun esin mi se ,toriwipe oun ni akori oro mi,bami tun aye mi ti mo wa se,bami tun Orun mi ti mo npada bowa se,fi aye mi se alekun gbogbo nti nje ore fun mi,ki o si se iku ni isinmi fun mi nibi gbogbo aburu).

"اللَّهُمَّ إِنِّي أَسْأَلُكَ مِنْ الْخَيْرِ كُلِّهِ عَاجِلِهِ وَآجِلِهِ مَا عَلِمْتُ مِنْهُ وَمَا لَمْ أَعْلَمْ وَأَعُوذُ بِكَ مِنْ الشَّرِّ كُلِّهِ عَاجِلِهِ وَآجِلِهِ مَا عَلِمْتُ مِنْهُ وَمَا لَمْ أَعْلَمْ اللَّهُمَّ إِنِّي أَسْأَلُكَ مِنْ خَيْرِ مَا سَأَلَكَ عَبْدُكَ وَنَبِيُّكَ وَأَعُوذُ بِكَ مِنْ شَرِّ مَا استعَاذَ منِهِ عَبْدُكَ وَنَبِيُّكَ اللَّهُمَّ إِنِّي أَسْأَلُكَ الْجَنَّةَ وَمَا قَرَّبَ إِلَيْهَا مِنْ قَوْلٍ أَوْ عَمَلٍ وَأَعُوذُ بِكَ مِنْ النَّارِ وَمَا قَرَّبَ إِلَيْهَا مِنْ قَوْلٍ أَوْ عَمَلٍ وَأَسْأَلُكَ أَنْ تَجْعَلَ كُلَّ قَضَاءٍ قَضَيْتَهُ لِي خَيْرًا"

(Iwo Olohun,mo nbe O,fun mi ni gbogbo oore,ti aye ati ti alqiyaamo,eyiti momo ati eyiti emi ko mo,motun nsadio lami kuro nibi gbogbo aburu,ti aye ati alqiyaamo,eyi ti mo mo pe aburu ni ati eyiti emi ko mo,Iwo Olohun fun mi ni gbogbo oore ti eru re,Anabi re- salalahu alaei wasalam - toro re lodo re,Bakana motun sadio nibi gbogbo aburu ti eru re,Anabi re- salalahu alaei wasalam - sadi o nibe,Iwo Olohun fun mi ni Aljanah, tun bun mi ni oro tabi ise ti o ma nmu eniyan sunmo Aljanah,bakana lami nibi Ina,ati oro tabi ise ti mu eniyan sunmo an, mo tun nbe o pe ki o se gbogbo kadara ti o ko fun mi ni rere).

"اللهم احفظن

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Monday, November 25 @ 05:08:54 PST Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin:
Oorun didun igi ododo ti orewa nipa ajulo awon iya awon olugbagbo ododo


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin



"AWON LETA TI O WAFUN AWON ALHAJI ATI AWON ONI UMRA" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com