Gbagede Yoruba
 



Ki La Tun N Duro De
 
Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Ki La Tun N Duro De

Se e ranti obinrin ti won n pe ni Oby Ezekwesile, obinrin kan bayii to se minisita laye Obasanjo, to tun loo sise ni banki agbaye gege bii oga agba. Oro kan wa to n ja ran-in ran-in bayii, obinrin naa lo si da a sile, koda oro ohun ti fee dija laarin oun ati awon asofin.

Ohun ti obinrin yii n tenumo ni pe oriburuku to ba Naijiria bayii, ti nnkan wa ko to wa i je, ti iya n je mekunnu, awon asofin lo n fa a, nitori owo buruku ti awon nikan n gba, owo ti ko see fenuso ni, bee ni won na inakunaa, nitori laarin odun merin pere ni won fi na owo to le ni tirilionu kan, owo nla gbaa leleyii, owo to ju bilionu lo ni.

Obinrin naa ni bi nnkan ba n lo bayii, Naijiria ko ni i gberi laelae, nitori ko si orile-ede kan ti awon asofin won ti n fee je araalu pa bii ti Naijiria yii, bee lawon asofin naa ko lojuti.



Oro ti obinrin naa so ree o, n lawon asofin ba n binu. Won n binu gan-an ni, won ni isokuso lobinrin naa n so, won ni awon yoo pe e wa siwaju ile igbimo, nibe lawon yoo ti ni ko waa so tenu e, bi oro re ko ba si je mo eyi to te awon lorun, seria to ba ye lawon yoo da fun un, nitori o gbodo mo pe awon ni asofin Naijiria.

Erin lobinrin naa fi won rin, o ni oun ko wa sile igbimo lodo won, sugbon bi oro naa ba ka won lara, ti won ba mo pe iro loun n pa, ki won sa ara won jo, ki won je ki awon jo pe ipade itagbangba, ki awon oniroyin gbogbo wa nibe, ki oun waa so bi won ti n gbowo ati iye ti won n gba fun won, o ni nigba naa ni gbogbo aye yoo foju ri i, eni to ba si je alaseju ninu awon tabi opuro, kaluku yoo mo.

Kia lawon asofin ti so pe awon naa ti redi, won ni awon ti setan, ki awon kuku pade ni gbangba. Ohun to tun waa n da won duro bayii ni ko ti i senikan to mo o. Awon araalu fee woran, won fee mo ibi ti won wa, boya awon asofin Naijiria naa n ba tiwon je ni abi won n tun tiwon se.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Monday, November 25 @ 06:09:55 PST Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu:
Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu



"Ki La Tun N Duro De" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com