Gbagede Yoruba
 



N’Ilorin, Awon Sifu Difensi Ti Won Fi So Opa Epo Loo Ji Bentiroolu Nibe
 
Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun
Lati Owo Idris Alooma, Ilorin

N’Ilorin, Awon Sifu Difensi Ti Won Fi So Opa Epo Loo Ji Bentiroolu Nibe


Afi bii ki ile lanu ko gbe awon osise ajo Sifu Difensi marun-un towo awon olopaa te laipe yii min. Esun pe won n ji epo bentiroolu fa lopopo Asa Dam, n’Ilorin, ni won tori e mu won. Nise lawon eeyan n so pe aye ti baje nitori awon agbofinro to n pese aabo naa lo tun n ji epo fa. Awon marun-un ohun ni: Adebayo Toyin, Muritala Jimoh, Imam Olororo Abdulraheem, Adisa Ponnle ati Hassan Abdulwaheed.

Paipu epo ajo NNPC tawon ole maa n ji fa ni won fi won so, sugbon dipo aabo to ye ki won maa pese lagbegbe ohun, nise ni won maa n ko opolopo ike jerika lo sibe ti won si maa n fa epo naa lati loo ji i ta.



Gege bi alaye alukoro awon olopaa Kwara, Ogbeni Femi Fabode, o so pe ni deede aago mewaa ale Ojoru, Wesde, to koja lawon omo ajo Sifu Difensi marun-un ohun ko ike to to aadota sinu awon moto, ti won si loo fa epo naa nibi tawon opa epo ti be lopopona Asa Dam.

Awon araalu lo ta awon olopaa lolobo lori isele naa ti won fi lo sibe, ti won si ri won mu bo tile je pe won fee sa lo. O ni nigba tawon olopaa naa so pawon yoo yinbon fun won ni won bere si i bebe.

Fabode ni bawon olopaa se mu won tan ni won bere si i bebe, ti won si so pe awon fee da awon epo tawon n gbon ohun sinu moto awon ni. O ni ibeere tawon eeyan yii bi won ni pe se eyi ti won fee da sinu oko naa lo mu ki won ko keegi to fee to aadota sinu awon moto meji ti won gbe wa sibe, lakooko yii gan-an ni won ko le so nnkan kan mo. O ni moto tawon Sifu Difensi oniwa ibaje ohun gbe wa sibe ki i se tibi ise won rara, tara won ni, nomba ara awon oko naa ni AG 820 LEM to je Toyota Camry ati moto Rover AG 801 LFF. Okunrin yii ni awon eeyan ohun jewo pe awon sise ibi naa, sugbon ki won dariji awon.

Alukoro yii so pe meji pere lo wa lenu ise ninu won lakooko naa, nigba ti okan ninu won wa ni isinmi. O ni lati tan araalu je pe enu ise lawon wa ni gbogbo won se n wo aso Sifu Difensi.

Siwaju si i, Fabode so pe awon ti foro naa to oga agba patapata ajo olopaa ni Naijiria leti, o si ti so pe kawon se iwadii finnifinni lori e.


Nigba ti a beere lowo e pe se o see se ki won gbejo naa lo si kootu, o so pe leyin tawon ba pari iwadii awon, awon yoo kowe si ajo Sifu Difensi lori oro ohun, olu ileese won lo ni won yoo ti se idajo to ba ye fun won.

Ninu oro alukoro awon ajo Sifu Difensi ni Kwara, Ogbeni Olanrewaju Quadri, o so pe awon ti n wadii nipa oro ohun nitori awon osise yii wa lenu ise nigba naa, ati pe awon ti ko leta si ajo olopaa ipinle Kwara lori re.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Monday, November 25 @ 06:22:15 PST Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun:
Onka Yoruba - Numbers In Yoruba: Figures And Counting, Kika Ni Yoruba Computes


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun



"N’Ilorin, Awon Sifu Difensi Ti Won Fi So Opa Epo Loo Ji Bentiroolu Nibe" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com