Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Lati Ilu Ede Ni Najimu Ti Waa Ji Omo Gbe L’Ogbomoso, Owo Ti Te E O
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Abayomi Akanni, Ogbomoso

Lati Ilu Ede Ni Najimu Ti Waa Ji Omo Gbe L’Ogbomoso, Owo Ti Te E O

Ile mo ba arakunrin kan to pe ara e ni Najimu Ibrahim to wa lati ilu Ede, nipinle Osun. Adugbo Papa Ajao, l’Ogbomoso, lowo ti te e nirole Ojoru, ose to koja, lasiko to n rin gberegbere kiri.

Gege bi awon tisele naa soju won se so fun Iwe Iroyin Yoruba, won ni o ti to bii ojo meta tawon ti n sakiyesi ogbeni naa pe ajoji ni, idi ree tawon fi n so o kowo too te e. Won ni ile kan to wa laarin opopona marose tijoba apapo n se lowo lo n gbe, ona to je ile ohun lo je kawon to ni i ko kuro ko too di pe Najimu Ibrahim so ibe dile nitori ise ibi to fee se.Nigba ti won tu awon eru re ni won ba orisiirisii awon iwe, lara re ni iwe ayewo eje ti aworan pelebe wa lara re ati eda risiiti owo ile-eko, to fi mo eda iwe ise teeyan yan laayo nile-eko, eyi to je ti Ogunlade Modupeola to je akekoo ile-eko giga olukoni agba onipo kin-in-ni niluu Oyo, (SPED). Bee ni won tun ri iwe isanwo (Teller) ti Ecobank tiye e je egberun lona ogoje naira; kaadi ile-eko to je ti Ogbeni Oladokun Gift ti ile-eko aladaani kan to wa lagbegbe Odokoto, l’Ogbomoso ati oruka gbigbona kan.

Nigba to n soro, Ibrahim so pe oun ki i se were, ilu Sagamu loun ti n bo, ilu Ede loun si n lo, omo kan to sonu loun n wa, ati pe oun ko mona mo lo mu oun bale si adugbo Papa Ajao, l’Ogbomoso, ki won too mu oun. Nigba ta a beere lowo re pe bawo ni gbogbo iwe naa se de owo re, ko ri esi kankan fo jade. A tun ni ta lo n wa gan-an, o ni enikan ni sugbon ko tun mo oruko re.

Nigba ti a beere iwulo oruka gbigbona ti a ba ninu eru e ati eni to fun un, o ni enikan lo fun oun laduugbo Oke Elele, niluu Ilorin. O salaye pe tona ba fee diju toun ba ti fi oruka naa sowo, ona yoo la. Koda enikan to fi owo re mu oruka naa ko lo to iseju meji tara ko fi ro o mo, afigba ti won wa epo pupa fun un lara re too bale. Isele yii lo mu kawon eeyan so pe o ni lati je pe gbomogbomo ni, to si n wa omo ti yoo ji gbe.

Iko agbofinro to n gbogun ti aso iwokuwo ati iwa jagidijagan nipinle Oyo, ekun Ogbomoso (Operation Burst) lo gbe e lo sagoo won, ki won too taari re si ago olopaa to wa lagbegbe Arowomole fun iwadii to peye.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Monday, November 25 @ 06:26:37 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Lati Ilu Ede Ni Najimu Ti Waa Ji Omo Gbe L’Ogbomoso, Owo Ti Te E O" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: