Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose
[ Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose ]

·Won Ni Akeem Pa Sajenti Opeyemi Iyawo Re, O Ti N Se Faaji Lewon Bayi
·Eyi Ni Bi Pasito Se Gbe Majele Je Ni Ipinle-Ogun
·Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
·Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
·Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
·Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
·Orekunrin Bukola Fee Fi i Soogun Owo N'Ibadan
·Nitori Wahala Ojoojumo, Igbeyawo Odun Mefa Tuka L'Osogbo
·Won Ti Ran Oga Ileewe To Fipa Ba Akekoo Re Lo Po Lewon Odun Mewaa L'Ekiti

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


E Ma Je Kawon Eeyan Yii Tun Lu Wa Ni Jibiti O (Apa Keji)
 
 
Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

E Ma Je Kawon Eeyan Yii Tun Lu Wa Ni Jibiti O (Apa Keji)

Gege bi mo ti wi lose to koja, nigba ti mo ti gbe enu le oro yii ni mo ti mo pe bii igba ti mo tun tanna wa oro buruku ni. Mo mo pe bi eeyan ba wa ninu egbe oselu kan nile Yoruba nibi, won ki i fe kenu kun won rara. Bi awon miiran ti n so pe awon ti mo pe oloselu ni mi, bee ni won n gba mi nimoran pe ki n tete loo foruko egbe oselu temi sile ki Jega too tilekun, nitori bo ba tilekun, n ko ni i le foruko egbe naa sile ninu iwe ijoba. Awon kan ko ri ohun to kan Bola ninu e, won ni mo kan koriira re lasan ni, won ni bi Babangida ati Abubakar ba waa ki i, ki lo kan mi ninu iyen, se emi ko mo pe Bola ni okun to fee so Yoruba ati Hausa papo mora won ni, ati pe Bola n fogbon tan awon Hausa koun naa le gbajoba ni, nitori Yoruba ko le da gbajoba Naijiria, afi ki won ba awon Hausa se. Oro ni kaluku so, bo si ti ye won to naa ni won n so yen.

Lakooko, n ko koriira Bola, ko sohun ti mo le ri gba ninu ki n koriira re bi n ba koriira re, a je pe n ko fe daadaa fun ile Yoruba ni. Sugbon n ko le se ki n ma soro kan Bola nitori agbara oselu Yoruba wa lowo e loni-in, sugbon gbogbo oro ti mo n so, lati to o sona ni. Mo ti so nigba kan pe n ko le se Minisita mo, ka ma ti i so pe Komisanna, n ko le sare tele gomina kan leyin, bee ni n ko le se alaga ise ijoba nigba ti n ko ba mo itumo ohun ti won n se.


Sugbon ko seni to le da sere boolu daadaa to eni toun naa ti gba boolu ri, to ti ko awon agbaboolu ri, to ti wa dagba sidii e, to waa duro segbee fiidi to n woran. Bo ti n woran ni yoo maa ranti igba toun naa n gba boolu, yoo si maa so pe bo ba se pe lagbaja gba a bayii ni, boolu naa iba wole. Eleyii soro fun eni to ba wa lori papa to n gba boolu naa, iba die lohun to le ri, nigba mi-in, nibi to ti n sare lo, ko ni i ri koto to wa niwaju re rara, tabi alatako re to fee re e lepa. Bi oro oselu papa se ri niyen.
Kin ni iba dara to ki egbe APC gbajoba loooto, ki akoso egbe naa si wa lowo awa Yoruba.

Omo ale Yoruba nikan ni yoo ni inu oun ko ni i dun si i, koda ko je inu egbe oselu mi-in lo wa. Sugbon oro oselu Naijiria ko ri bee, ohun temi mo ni mo n so n ni. Nigba ti gbogbo agbara wa lowo Baba Obafemi Awolowo, ti gbogbo Yoruba si n tele e, awon Hausa mura lati da ile Yoruba ru mo on lori, nigba ti won ko si mo ona kankan ti won yoo gba, won ba odo Akintola ti i se igbakeji re wole. Bo ba se pe Akintola ko ni atileyin Sardauna, Ahmadu Bello ti i se olori ijoba ile Hausa ni, iba die ni iba sagidi pelu oga re mo. Sugbon leyin ti Sardauna ti mo pe bi oun ba ti mu Akintola, oun yoo mu Awolowo, gbogbo agbara to ni lo sa lati koyin won sira won. Akintola naa mo pe gbogbo agbara ijoba apapo, agbara olopaa ati opolopo owo wa lowo won, nitori bee lo se faramo won. Ohun ti won fi ba ile Yoruba je nigba naa niyen o.

Nigba tawon soja Hausa fibon gbajoba ni 1966, Babatunde Ogundipe ni eni ti oye re ga julo ninu ise soja ni Naijiria nigba naa, oun si ni igbakeji Ironsi tawon Muritala ati Danjuma fogbon pa. Bakan naa ni Adewale Wey to dagba ju gbogbo won lo wa nibe, ipo re si ju tawon omo Hausa gbogbo lo. Adeyinka Adebayo ni olori gbogbo soja tele, gbogbo awon wonyi ni won si wa nibe nigba tawon soja omo Hausa keekeekee ti ipo won jinna si tiwon fibon gbajoba lowo Ironsi, ohun tawon soja yii si jo parowa fun gbogbo aye ni pe awon n lo, awon n lo, sugbon nigba tawon baba won so fun won pe ki won ma lo, ki won so fun Yoruba pe awon ko ni i gba kenikeni je olori Naijiria afi awon, bee naa ni won si se e, ti won fi mu Yakubu Gowon to je omo kekere gbaa se olori Naijiria, bo tile je pe awon Yoruba meta lo wa nibe to ye ki won mu.

Ki i se pe won deede mu Obasanjo lati je olori Naijiria leyin ti Muritala ku ni 1976, awon Alani Akinrinade ti won wa nibe ni won ko je, ati nitori pe enu ti n kun won tele pe Danjuma ni won fee gbe e fun. Awon ti won si mo eto naa mo pe ni gbogbo igba ti won fi n sejoba, ase ti Danjuma ati Yar«adua ba pa ni Obasanjo yoo tele nile ijoba, nitori ko fe ki won pa oun bi won ti pa Ironsi. Nigba ti won si fi Alani Akinriade je olori awon soja patapata, laarin osu meta ti Shehu Shagari debe lo ti yo o kuro, to si fi omo Hausa si i. O fi Akinrinade se olori awon ologun gbogbo, sugbon ko lo ju osu mefa lo naa nibe ti won fi yo o danu, won si feyin re ti laipe ojo rara. Ore kan ko gbodo ju eyi ti Abiola ati Babangida jo ba ara won se yen lo, sugbon nigba ti oro di oro agbara ijoba, Babangida koyin si ore re, o dale e, won si run Abiola pelu gbogbo ohun to ni.

Nigba ti Sanni Abacha yoo gbajoba, Oladipo Diya lo ti saaju, oun lo n ran sawon asaaju Yoruba ti won n binu nigba naa, oun lo n ko awon ti won ba fee tako awon baba Afenifere jo, oun lo n pe awon egbe NADECO ni agbako, ohun to si se n se bee ni pe ko lero pe Abacha yoo da oun. Sugbon Hausa ko ri oro agbara bee, nigba ti won ti lo Diya tan ti ese ijoba re si ti mule, ona lati fi Diya rubo lo ku ti won n wa, ohun ti won si se fun un gbeyin naa niyen. Bi ko je ti yiyo Olorun, Diya iba ti wa ninu ihoole bayii, won ti sewe e pe ki won yinbon pa a ni. Awon Babangida pelu Atiku ni won seto bi won se yo Obasanjo lewon ti won si n pariwo pe oun lawon fe ko waa se olori Yoruba, ti Danjuma si so pe bi won ko ba je ki Obasanjo sejoba, oun yo ko kuro ni Naijiria, ti awon Dangote si n gbe owo nla kale nitori ki Obasanjo le ri owo na.

Awon eeyan ti ko mo oro oselu Naijiria nigba naa ro pe nitori ife tawon eeyan naa ni si Obasanjo ni, sugbon nigba t«Obasanjo wole to koko le awon soja ti won ti ba awon oloselu sejoba ri atawon ti won ti se gomina danu, to si je omo Hausa lo po ninu won, lesekese nija ti bere, ija naa si di ranto titi ti Obasanjo fi gbe ijoba sile. Oun ati Babangida ko re mo, oun ati Danjuma ja, bee ni oun pelu Atiku si di ota ara won. Idi ni pe oto ni ohun tawon asaaju Hausa yii fee lo Obasanjo fun, nigba ti won ko si ti ri i se ni won se so o dota, ti won si ri i pe leyin to kuro nile ijoba, ko wulo kankan nidii oselu ile Yoruba yii mo. Loju won bayii ni Atiku ti n loo da egbe oselu tire sile, nigba ti won si n mura lati ba ti Obasanjo je yii, awa omo Yoruba naa ni Atiku mu mora lati da egbe AC sile. Sugbon nibo ni Atiku wa loni-in, ki lo de to tun pada sinu PDP, awon ibi ti Yoruba gbodo ti maa fura niyen.

Gbogbo ohun ti mo n so yii ni lati fi han bi awon Hausa ti n lo Yoruba lojo to ti pe lati gbajoba lowo won ni, ati pe nigba ti won ba ti lo Yoruba ti ijoba te won lowo tan, won yoo fi won sile ki won maa ba tiwon lo.

Ona ti won n gba latojo yii wa naa ni won tun n gba lori oro APC yii, ti won yoo maa se bii eni pe gbogbo agbara ti wa lowo Yoruba, ti won yoo si maa gbe awon asaaju wa gun esin aayan. Won yoo gbe koto sile, won yoo te aso le e lori, won yoo waa gbe aga onide si i tabi aga onigoolu, eni ba si ri i yoo ro pe olola nla ni. Sugbon bi ohun ti won n wa ba te won lowo tan, won yoo ye aga naa mo awon ti won ba wa nibe nidii, yakata ni tohun yoo si subu sinu koto. Ohun ti mo n so niyen pe ki APC laju sile, ki awon Bola sora se, ki Bisi kan yee rerin-in kiri lasan bii eni pe gbogbo nnkan n lo deede, ki won ro o daadaa ki won too tun ko wa lo sinu oko eru awon Hausa o.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Monday, November 25 @ 06:40:53 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin:
Buhari Omo Musa Sa Kuro Nibi Ayeye Igbeyawo Saidi Osupa: Lehin Ti Alfa Muri Fun


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin

"E Ma Je Kawon Eeyan Yii Tun Lu Wa Ni Jibiti O (Apa Keji)" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: