Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Owo Ti Te Tosin To Fee Ji Omo Odun Merinla Gbe L'Ado-Ekiti
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Stephen Ajagbe, Ado-Ekiti

Owo Ti Te Tosin To Fee Ji Omo Odun Merinla Gbe L'Ado-Ekiti

Bi ki i baa se ti ajo aabo eni laabo ilu to tete gba afurasi eni odun meeedogbon kan, Tosin Ajayi, lowo awon eeyan to gba a mu lasiko to gbiyanju lati ji omo odun merinla kan, Benjamin Okizi, gbe, boya oku e ni won o ba gbe nibe.

Isele ohun waye laarin ose to koja lagbegbe Adebayo, niluu Ado-Ekiti, eyi to da sun-kere-fa-kere oko sile pelu bi ogooro eeyan to n gbe lagbegbe naa, paapaa julo awon olokada se pejo siwaju abawole ofiisi ajo Civil Defence to wa lopopona naa, nibi ti won gbe afurasi ohun pelu Benjamin to fee ji i gbe naa lo.Tosin to n gbe ojule keji, opopona Idemo, niluu Ado-Ekiti, ni won ti gbe e lo si olu ileese ajo Civil Defence to wa ni Afao, niluu Ado-Ekiti bayii.

Ninu alaye iya omo ohun, Arabinrin Rachael Okizi, so pe oun loun ran Benjamin lati loo duro foun nibi ipade kan to ye koun wa sugbon toun ko le lo, ipade ohun lo waye ni aago mesan-an aaro, lagbegbe Ori Apata, ni Adebayo.

Lasiko ti omo naa n pada lo sile ni Tosin pelu ore re kan tiyen ti na papa bora bayii da a duro niwaju ileewosan ekose Fasiti ipinle Ekiti, EKSUTH, ti won si bere si i hale mo on.

O ni, “Benjamin salaye fun mi pe okunrin yii pelu ore re ye gbogbo apo oun wo, ti won si ko ogorun-un marun-un din ni ogbon naira to wa nibe.”O salaye pe awon olokada to jokoo lagbegbe naa lo sakiyesi ohun to n sele ti won si sunmo won, won beere lowo Tosin ati ikeji re idi ti won fi da omo naa duro. Se ni won lawon eeyan ohun paro pe aburo awon ni Benjamin, ati pe foonu awon lo ji, awon si fee gbe e lo sagoo olopaa ki won le ba a wi.

Lasiko tawon eeyan yii n gbe omo naa lo ni iya onile won toun n koja lo ni tire ri won, oju-ese lo da okada ti won fi gbe e duro, bee lo ke gbajare sawon eeyan to wa nitosi, nibi ti okan ninu awon eeyan yii ti na papa bora niyen, se lo kan lugbe, sugbon awon araadugbo naa ya bo Tosin, die lo ku ki won si dana sun un.

Lasiko yii lawon eso Sifu Difensi, eyi ti adari eka to wa lagbegbe ohun, Ogbeni Ojo Lawanson, ko sodi de sagbegbe naa, ti won si gba Tosin lowo awon to fee dana sun un.Oga agba ajo NSCDC l’Ekiti, Ogbeni Augustine Obiekwe, to fidi isele ohun mule so pe iwadii si n lo lowo lori esun naa.
 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Saturday, January 25 @ 01:07:16 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Owo Ti Te Tosin To Fee Ji Omo Odun Merinla Gbe L'Ado-Ekiti" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: