Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga
[ Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga ]

·Eyi Ni Bi Enu Se Ko Ba Bobrisky, Okunrin To N Se Bii Obirin: Won Ni Awon Olopa D
·O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
·Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
·Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
·Owo Te Wahab Nibi To n Ti n Se'Kinni' Fomo Odun Mewaa Legbee Ogiri
·Mumini Lu Magun Lara Iyawo Oloye Ilu n'Iyana-Offa
·Imeh Ha Sowo Olopaa L'Ekoo, Aburo Iyawo e Lo Se Kinni un Fun
·Aliyu Fipa Ba Omo Odun Metala Lo Po n'Ilorin, Lo Ba Doyun
·Adebowale Atawon Egbe e Fipa Ba Omo Odun Metala Lo Po

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Idi Tawon Omooba Ofa Fi Koju Ija Sira Won
 
 
Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere
Lati Owo Alabi Adeola

Idi Tawon Omooba Ofa Fi Koju Ija Sira Won

Bi ilu kan ba wa to n toro, awon oloselu ibe ni ke e bi o. Bi ilu kan ba si wa ti ko toro, awon oloselu ibe naa ni ke e bi. Gbogbo omo Yoruba to ba gbo ohun to n sele ni ilu Ofa lati bii odun meta bayii, nibi ti awon omo oye ti n bara won ja sipo olofa, ti oro naa si di ohun ti won n gbe lo sile-ejo lorisiirisii, ko ma wadii oro naa wo pe titi, ohun ti awon ti won n se oselu da sile ni ilu naa lati bii odun merindinlogota seyin ni ko tan nile, oro naa lo si n da gbogbo nnkan ru. Sebi ki i se pe ilu Ofa sese wa ni, bee ni ki i se pe won sese n joye Olofa.

Lati odun 1397, iyen bii egbeta odun seyin ni won ti n je Olofa, Olofa akoko to si je funrare naa ni Olalomi Olofa-gangan, eni to wa lori oye naa fun odidi aadota odun. Ode nla ni, okan ninu awon omooba ni Ife ati l’Oyoo ni. Leyin toun ni awon omo re ati omo omo re bere si i joye Olofa, ti ko si si wahala kankan fun won.Bi e ba n gbo ti awon kan a n so loni-in pe idile kan lo n je oye Olofa ki i se idile meji, ohun ti won n wi gan-an ree, nitori latigba iwase, Olofa kan naa lo koko wa, lara re ni gbogbo awon ti won tun n je oba ilu Ofa ti dide. Ohun ti ko je ko si wahala kankan niyen, to je bi Olofa kan ba ti waja, kia lawon omo oye naa yoo sa ara won jo, gbogbo awon ti won ba fee joye yoo si mu oruko won wa, won yoo si gbe ifa lele, eni ti ifa ba si mu ninu won naa ni. Ki i sija, nigba to se pe omo iran kan naa ni gbogbo won. Bi ohun gbogbo ti n lo niyi o, afi nigba to di odun 1957 ti nnkan yi biri, lati ojo naa ni eku ko si ti ke bii eku mo, ti eye paapaa ko dun bii eye nidiile awon omo oye to n je oba ilu Ofa, latigba naa ni oye olofa si ti di ohun ti won n gba bii eni gba igba oti, lati igba naa ni ko ti si isinmi laafin, paapaa nigbakigba ti oba kan ba ku ti oba mi-in si n mura atije. Lati igba naa ni oro yii ti di rudurudu o, opo eeyan ni ko si mo bi oro naa ti ri, kaluku kan n fi atamo mo atamo ni.

Ohun kan to daju ni pe ko too di odun 1957 yii, ko sija ajaku-akata nidii oye Olofa, bo tile je pe igba kan wa ti awon kan dide pe awon lomo okunrin ti awon mi-in si so pe awon lomo obinrin ati pe ko si ohun to de ti omo okunrin yoo fi joye ti omo obinrin ko ni i je, sibe oro naa ko mu laasigbo iru tasiko yii dani, nitori bi won ti n ja to nni, won n ranti pe omo baba kan naa lawon n se, boya okunrin ni o, boya obinrin ni o, lati odo Olalomi yii naa ni gbogbo won ti se wa. Afi nigba ti oselu yii de o, ti won si tibe dori ohun gbogbo kodo, ti nnkan ko si niyanju titi di asiko yii wa. Lasiko naa, abe Ilorin ni awon ilu bii Ofa ati awon ile Igbomina gbogbo wa, nibe ni won ti n pase ohun gbogbo ti won yoo se, labe Oba Ilorin yii naa si ni gbogbo oba ile Yoruba agbegbe naa wa, bee Ilorin yii, okan lara awon ile Hausa ni awon ijoba oyinbo igba naa ka a si, oro naa si wa bee titi doni paapaa. Bee, ohun to fa wahala ganan

niyen.


Sugbon nitori pe awon Yoruba adugbo naa ki i fe ki awon Hausa tabi Fulani yii je gaba lori won, gbogbo ohun ti ijoba Fulani ba n se lawon ki i fee se, nigba ti oselu si de, opolopo ibi ti awon Yoruba wa ni won ko feran ki awon wa ninu egbe oselu awon Hausa. Lojo naa lohun-un, egbe oselu Northern People Congress (NPC) lo ko gbogbo ile Hausa dani, Sardauna Sokoto, Ahmadu Bello, si ni olori won. Bi enikan ba waa ni oun ko gba, wahala ni iru eni bee n fa lese, bo je oba bo si je ijoye, ohun ti oju iru eni bee yoo ri ko ni i see so. Sugbon opolopo awon oba Yoruba ati awon olaju adugbo naa ki i fee gba, won ko si ko ohun ti olopaa ijoba tabi awon ajele yoo se fun won. Ohun to ko wahala ba Olu Ajase Ipo ree ti won fi ti Oba naa mole fungba pipe nitori pe o pe ipade awon oba Igbomina nibi ti won ti fee so pe ki won yo awon kuro labe Ilorin.

Oro naa ko wahala ba won ni Oke-Ode, Oro-ago ati ile Igbomina gbogbo.

Sugbon Olofa Wuraola Isioye lo koko kan oba ilu Ilorin leewo lodun 1950, ikanra oro naa lo si pada waa koba Olofa yii, oro ojo naa lo si di ohun to da wahala nla sile niluu Ofa titi dola ode.

Wuraola Isioye lo ko leta nla kan si Ooni Adesoji Aderemi, oun nikan ko lo si fowo siwee naa, gbogbo awon baale agbegbe ati olori abule Ofa ni, gbogbo won lo fowo si iwe ti won fi ranse si Ooni Ife. Ki i se Ooni Ife ni won kowe si, won kan ni ki oun ba won mu iwe naa de odo eni ti won ko o si gan-an ni. Eni ti won kowe yii si ni gomina ile Naijiria igba naa, John Macpherson.

Ohun ti Oba Isioye ko sinu iwe naa ni pe kijoba Naijiria tun eto won se, ki won yo Ofa kuro labe Ilorin nitori Ofa ki i se ilu fulani, ki won da awon pada si abe akoso ati ijoba ile Yoruba ni Western Region. Ki i se pe Ooni Aderemi fi leta naa jise fun Macpherson nikan ko, nibi ipade apero ti won n se lori ofin Naijiria tuntun nipari osu kin-in-ni, odun 1950 yii, Ooni so nibe pe kijoba sofin ti yoo ko awon Yoruba kuro labe Fulani lagbegbe Ilorin.

Oro kan ko le bi Oba ilu Ilorin ninu to ohun ti Wuraola Isioye se yii, inu si bi Oba Abdul Kadiri, o si leri pe oun yoo je Olofa naa niya, ara re yoo ko ohun ti oun yoo se fun un. Akoko ni pe oun yoo fo gbogbo ilu to wa labe Ofa si wewe, oun yoo yo won kuro labe Olofa, oun yoo si so Oba Isioye di oun nikan. Bee ni Oba Ilorin yii pase loooto, o si yo Igbanna, Ahogbada, Ira ati Inaja kuro lara Ofa, o ni kawon wonyi maa da se ijoba ara won, ki won ma si bowo tabi bu ola kankan fun Olofa mo. Bee naa lo tun yo Ijagbo, Igosun, Erin-Ile ati Ipe kuro labe ijoba ibile Ofa, o ni ki awon naa maa se tiwon loto o jare. Ki i se iyen nikan ni Oba Ilorin se fun Olofa yii, o tun yo o kuro ni ipo Olori agbegbe (District Head), o si fi i se olori abule lasan. Bi oro ti wa niyi ko too di pe awon egbe oselu bere ibo didi ni odun 1951, ti won si ti da egbe Action Group sile nigba naa, ti opolopo awon Yoruba to wa labe Ilorin si mura lati ba egbe oselu to je ti awon omo Yoruba naa lo. Nibi ti ija nla ti bere ree o, ti oro naa si kan Sardauna.

Nigba ti won fee dibo ni odun 1951 yii, ijokoo meji ni won fun agbegbe Ilorin nile igbimo asofin, iyen ni pe omo ile igbimo meji ni yoo ti ibe jade. Awon Yoruba agbegbe yii, Ofa, Igbomina ati Ekiti, pawo-po, won dibo fun A.B. Oyediran, won ni oun ni awon fe ko lo sile igbimo asofin. Sugbon nigba ti oro naa de eti Oba ilu Ilorin, to si ranti pe omo Ofa ni Oyediran, o gbe igi dina fun un, o si yan awon omo ilu Ilorin meji lati lo sile igbimo naa. Eleyii bi awon omo Yoruba adugbo yii ninu, ni won ba loo da egbe kan sile, won pe e ni Egbe omo Yoruba ile Hausa, won si bere si i ko awon omo Yoruba jo ni Kaba ati Ilorin, bee ni won n pariwo fun ijoba pe ki won ko awon kuro labe Ilorin o, awon n loo ba awon omo iya awon ti won wa nile Yoruba. Nigba ti wahala yii po, olopaa ijoba ile Hausa igba naa mu awon asaaju egbe naa meta> Y.S. Giwa, J.G. Ekunrin ati Daniel Atolagbe. Osogbo ni won gbe won lo ti won ti sejo won, won si da won lebi pe won fee da oju ijoba de, won si so won sewon olojo gbogboro.

Ni odun 1955 ni won dibo ijoba ibile ni gbogbo agbegbe to wa labe Ilorin, ifa ibo naa ko si fo rere rara fun egbe Sardauna Ahmadu Bello. Ki i se pe egbe naa ko wole o, egbe naa lo mu gbogbo ile Hausa, sugbon Egbe Action Group lo ni omo igbimo to po julo ni gbogbo agbegbe Ofa, Igbomina ati Ekiti titi de Kaba, apeere buruku si ni eleyii jo loju olori egbe NPC naa. Sugbon kekere ni eleyii nni, nitori nigba ti won yoo fi waa dibo awon omo ile igbimo asofin ile Hausa ni odun 1956, Egbe Action Group atawon egbe ti won jo n se papo ni omo ile igbimo asofin mokanla, egbe naa si ni alatako nla fun egbe NPC ni ile igbimo naa. Eyi to dun Sardauna ju ni ibo ilu Ofa, nibi ti won ti dibo fun Sunday Olawoyin gege bii omo ile igbimo asofin ni gbogbo adugbo naa. Eleyii bi Sardauna ninu gan-an, o si fesun kan Oba Wuraola Isioye pe atileyin ti oba naa n se fun awon egbe alatako lo je ki won wole ni gbogbo agbegbe naa, nitori ohun ti Oba Ilorin so fun un niyen.

Nitori idi eyi, ko ti i ju osu meji lo leyin idibo naa, nigba ti ijoba Ahmadu Bello, Sardauna Sokoto da seria lile fun Oba Wuraola Isioye. Ni ogunjo, osu keji, odun 1957 ni, ojo buruku ti ko wopo bii ojo ree. Lojo naa, leta ibanuje kan de si Ofa lati odo Oba ilu Ilorin, ohun ti leta naa so ni pe won ti feyin Oba Wuraola Isioye ti gege bii Olori agbegbe Ofa pata. Idi ti won fi feyin Olofa yii ti ni pe won ni o ti dagba ju, ati pe ara re ko fi bee le mo. Loooto nigba naa, Oba Wuraola ti wa ni omo odun merinlelaaadorun-un (94), sugbon ko si ohunkohun to se e lara, ati pe ko senikan to n fi eyin oba ti, oba Yoruba n je titi ti won yoo fi ku ni, bi oba ko ba si ku logun odun ewe, baba enikan ko le gbe e sin. Ati pe ohun meji lo n sele pelu leta ifeyinti yii< akoko ni pe oye meji ni Oba Wuraola ko papo> oye Olofa ti ilu Ofa ati oye olori agbegbe Ofa. Osise ijoba ni eni to ba wa ni ipo olori ijoba agbegbe Ofa, eleyii ki i se oba, sugbon oba ni Olofa ilu Ofa. Ijoba lo n yan eeyan sipo olori ijoba ibile nigba naa, sugbon awon araalu ni won n fi oba won je ki ijoba too fowo si i.

Ohun ti eyi tumo si ni pe ijoba le feyin olori ijoba agbegbe ti, sugbon ijoba ko le feyin oba ti, afi ti won ba fi tipatipa le oba naa nipo nikan ni. Ati pe bo tile je pe eni to ba je Olofa naa le wa nipo olori ijoba ibile agbegbe naa gege bi won ti n se lasiko naa, eni to ba je olori ijoba agbegbe ko le di Olofa, nitori ise won yato sira won. Ohun to koko fa wahala ni ti leta ti Oba Ilorin ko si Olofa ree o, se Olofa lo feyin re ti ni, abi Olori ijoba agbegbe Ofa, nitori Oba Isioye lo di ipo mejeeji mu titi di ogunjo, osu keji, odun 1957, ti won kowe naa si i. Eleyii ni won n fa titi, nitori ko sohun ti Oba Ilorin le se, won ko le le Olofa kuro laafin re, oun naa ni Olofa, bee ni won ko si le gbe olori ijoba agbegbe mi-in wa, nigba ti won ko ti i ri oro Oba Wuraola Isioye yii yanju. Bi won si ti n fa oro yii lo yii, odun kan ti koja, odun keji tun lo, asiko ibo nla miin si ti n wole de, iyen ibo odun 1959.

Ki i se pe ijoba Sardauna ko mo ohun ti won le se tabi ohun ti won fee se fun Olofa naa, nise ni won n ro pe Oba naa yoo ronupiwada, yoo si maa se gbogbo ohun ti awon ba fe ko se, won mo pe ti awon ba ti ni atileyin Olofa yii, gbogbo ibo adugbo naa ni yoo maa je ti egbe awon, iyen NPC, iru itiju ti awon si ni ni 1956 yen ko tun ni i ba awon mo. Sugbon Olofa yii ko ronupiwada, iyen ni pe ko fi awon eeyan re sile ko ma se ohun ti ijoba Hausa atawon Fulani n fe, kaka bee, nise lo ni oun ti dagba, ojo iku lo ku ti oun n duro de, oun ko si ni i dale awon eeyan toun, ati pe gbogbo ohun tijoba yii ba foju oun ri, deede ara oun lo se.

Nigba naa ni inu bi Sardauna ati awon omo eyin re gbogbo, bi ibo si ti n sunmole si ni inu tubo n bi won si i, eyi o si je ki won ronu ohun ti won yoo se fun Oba Wuraola Isioye, won ni ki awon kuku yanju oro re leekan. Ni ojo kejidinlogbon, osu karun-un, odun 1959, ijoba ile Hausa kowe si Olofa lati Kaduna, won ni awon yo Oba naa kuro ni oba Ofa, bee ni awon ko fe ko duro ni agbegbe ilu Ilorin mo rara.

Se bi eniyan ba n wa ohun to le ya omooya meji lesekese, ko so pe ki awon mejeeji jo maa du ipo kan naa, tabi ki won jo maa wa nnkan kan naa, abi ko so pe ki awon oloselu ko si won laarin, nibe ni aarin awon mejeeji yoo ti daru kia. Nigba tijoba ile Hausa fi n daamu Wuraola Isioye lati ilu Ilorin yii, okan ninu awon omooba Ofa kan naa wa ni ilu Ilorin to ti n sise, ti oun si je ore awon eeyan ijoba. Nitori bee, ki ojo ti won yoo yo Olofa Isioye too de ni won ti ba oun soro, ti won si so fun un pe awon n gbe e lo siluu Ofa, oun ni yoo si di ipo olori ijoba agbegbe naa mu. Mustapha Keji loruko omo oba naa. Bee lo je pe bi awon olopaa ti n mu iwe ti won yoo fi gbe Wuraola lo seyin odi, bee naa ni awon mi-in n gbe Mustapha Keji wolu, pelu opolopo olopaa leyin re, ti won si so pe oun ni olori agbegbe Ofa gbogbo. Nibi yii ni Ijoba NPC ni ile Hausa, Oba ilu Ilorin ati awon oloselu ti ko wahala ti ko tan l’Ofa titi doni yii sile o.

Idi ni pe nigba ti won n mu Mustapha Keji bo, ati nigba ti won gbe e de ilu Ofa, won ko pe e ni Olofa, bee ni won ko jawe oye le e lori nigba to de ilu Ofa, won kan gbe e wolu gege bii Olori agbegbe naa ni. Gege bi ofin igba naa, olori agbegbe yii ni yoo maa ri si oro owo-ori, ti yoo si maa ri soro ise ijoba gbogbo, ka saa so pe oun ni olori awon osise ijoba ibile labe ofin. Sugbon nigba ti won gbe Mustapha Keji de, ti awon kan si ti fi ogbon gbe Wuraola lo siluu Ibadan, ko si elomiran ti yoo ba Keji du ipo naa, oun funra re si seto lati maa pase bii oba, ati lati da ise olori agbegbe po mo ti Olofa, niwon igba to si je ore ijoba ni, ati pe ohun to ba se gbodo te ijoba ibe lorun nitori ohun ti awon n wa, ijoba yi oju si egbe kan, won ko so pe ohun ti Mustapja Keji n se ko dara tabi pe o dara. Sugbon inu awon araalu ko dun nigba naa, won ko si fi pamo pe Keji ki i se oba awon.

Oro naa di ibinu fun Keji funra re, o si fi ehonu re han sijoba ninu leta to ko sijoba ile Hausa yii ati oba ilu Ilorin lojo kerin, osu keje, odun 1959. Ninu leta yii ni Omooba yii ti koko pe ara re ni Olofa ilu Ofa, bo tile je pe ijoba ile Hausa naa ko mu un wa si ilu Ofa lati jawe oye le e lori, awon kan fee lo Omooba yii fun oro ibo lasan ni, ki i se nitori ife ilu Ofa, nitori ife ara won ni. Iyen ni awon araalu ko se mu Olofa tuntun yii ni oba won, won gba pe Olofa ti oba ilu Ilorin ati awon Sardauna yan sipo ni, ki i se Olofa ti ilu awon. Eyi lo mu ki Mustapha Keji kowe si ijoba, pataki ohun to si so nibe naa ni pe awon araalu naa n ri oun fin, bee ni gbogbo awon ti oun n pe sipade ko wa, bi awon kan ba si pade oun lona, won ki i dobale foun bii oba. Nitori bee, Mustapha Keji ni ki ijoba ile Hausa naa fun oun lase ki oun tu igbimo apase ijoba ibile agbegbe Ofa ka lesekese, ki won si ba oun gbe opolopo awon olopaa agbegbe Ofa kuro lesekese, ki won si ko awon olopaa tuntun wa foun. Oba tuntun naa ni oun fe ki won ko opolopo olopaa foun, nitori awon onijangbon, ki won si ba oun fofin de ariwo tawon egbe oselu n pa kiri igboro.

Sugbon gege bi oro awon oloselu, to je bi won ba ti ba nnkan je, kinni ohun ki i yaa tun se boro, leyin ti Sardauna ti ri i pe Mustapha Keji ko ni agbara pupo lori awon eeyan Ofa ati agbegbe re, ati pe awon nnkan ti won ro pe yoo sele nidii oselu ibe ko sele, kaka ki ariwo si role, ariwo naa n po si i ni, Sardauna tun ero re pa. Bo se sele ni pe nigba ti ibo miiran tun n bo lona, iyen ibo odun 1964, ti awon oloselu egbe NPC agbegbe naa titi de Ilorin si n so fun un pe lojoojumo lawon eeyan n kuro ninu egbe oselu awon, ati pe bi nnkan ba n lo bayii, bi ibo naa ba waye, awon ko ni i ri ipo kankan mu ni awon adugbo ile Yoruba yii mo, Ahmadu Bello beere pe ki lo le se ti awon ara agbegbe Ofa ati adugbo tawon Yoruba po si yoo fi yonu soun, awon eeyan naa ni won si gba a nimoran pe bo ba fee yanju oro yii pata, Wuraola Isioye to yo kuro loye ni ko da pada siluu, ko si fi i sipo re pada, ko je ko maa se

ijoba re lo titi ti yoo fi ku.

Bayii ni Sardauna de lasiko ipolongo ibo si ilu Ofa ni 1964 yii, to si so fun awon ara Ofa pe lojo naa gan-an loun gbese kuro lori ofin ti awon fi le Olofa kuro niluu, ati gbogbo ase to ro mo ofin naa, ati pe Olofa le pada wa siluu lesekese, ko si ofin kankan to de e mo. Ariwo nla so nibi ipade naa, okiki si kan jakejado ilu naa pe won ti da Olofa pada, o si di ohun ti awon araalu n tori e gba ilu ti won n jo kaakiri. Ibi ti wahala wa niyi o, nibi ti awon oloselu si ti n so irun iwaju po mo tipako niyen. Won ko so pe Mustapha Keji ni Olofa, nitori won ko fi i joye naa, nigba ti won si tun ni ki Wuraola maa bo yii, won ko so pe bo ba ti de ko maa waa joye re lo, won kan ni gbogbo ofin ti awon fi de e ti kase kuro lori e ni. Sugbon Sardauna ko yee fi han gbogbo eeyan pe ijoba oun ti dariji Olofa naa ati pe gbogbo ohun ti Oba atijo naa ba fe lawon yoo se fun un. Ohun to fa a to je ni gbara ti Olofa pada de siluu, Sardauna so pe oun yoo mu un lo si Meka niyen. Bee ni gbogbo igba naa, awon oloselu yii ti da ilu si meji, awon eeyan ko si mo boya Mustapha Keji ni Olofa ni o, tabi Wuraola Isioye, bo tile je pe awon eeyan laaanu Isioye nitori iya ti ijoba ti fi je e.

Nigba ti Sardauna so pe oun fee mu Wuraola Isioye lo si Meka yii, Oba naa ni oun ki i se musulumi, bawo ni yoo waa se mu oun lo si Meka. Sugbon Sardauna ni ko sohun to le ninu iyen, o le yipada ko di musulumi nigbakigba to ba fe. Bayii ni won yi oruko Olofa Isioye pada si Yesufu, toun naa si n kirun. Lodun naa lo si lo si Meka, awon ti won si ba a lo ni Alaaji Bakare Adeyemi, ti won n pe ni Baba Alata, Suberu to n fun kakaki re ati Alaaji Sanni Aba Balogun to je asaaju egbe NPC l’Ofa nigba naa, awon wonyi ni won ba Sardauna atawon eeyan re lo si Meka lodun naa. Awon omo ilu Ofa ti won wa ni Kaduna, Zaria ati Kano ko je ki Olofa rin geere nigba to n lo si Kaduna lodo Sardauna lati gbera Meka yii, nise ni won n da a duro ti won n se e lalejo, ti won yoo si tun yan awon eeyan repete le e lati sin in de Kaduna, ki won le mo pe oba nla ni. Bee naa lo si ri nigba ti Olofa naa n pada bo, nitori lati ilu Ogbomoso ni awon omo Ofa ti loo pade re, won si sin in wolu pelu ariwo ati ijo repete.

Bi nnkan si ti se wa niyi leyin odun kan aabo ti Wuraola pada s’Ofa tawon ologun fibon gbajoba, ti won si

pa Sardauna atawon oloselu mi-in gbogbo. Sugbon ohun to baje ti baje, bo tile je pe awon oloselu ti won da wahala ilu Ofa sile ti ku, sibe ko senikan to le ri oro naa yanju. Mustapha Keji wa nibe, bakan naa si ni Wuraola Isioye, ko si seni to mo eni ti won yoo maa pe ni Olofa ninu won nitori gbogbo ohun to ti rekoja lo.

Sugbon nigba ti won pin ile Naijiria si mejila ninu osu karun-un, odun 1967, oro oye ati ija ipo Olofa naa tun bere lakotun. Idi si ni pe lasiko yii, won ti tun afin ti Wuraola fee gbe inu re ko tan, oun si ko pada sibe, sugbon Gomina tuntun ti won yan nigba naa toun naa je omo adugbo yii, David Bamigboye, pase pe ki Wuraola Isioye pada sibi to n gbe tele, ko maa lo sibi ti aafin Oba wa.

Ohun ti Gomina yii se so pe oun se eyi nigba naa ni pe ejo naa ti wa ni kootu, oun naa si ni lati so eni ti Olofa n se gan-an. Gomina yii fe ki ejo naa foriti sibi kan ki oun too waa mo ohun ti oun yoo se, sugbon bi Wuraola ba ti ko lo sinu aafin, a je pe o ti so ara re di Olofa niyen, nigba ti ejo oro naa ko si ti i yanju. Nidii eyi, ni ojo keji, osu kejo, odun 1967, Wuraola Isioye kowe si Gomina Bamgboye, o si so pe ohun ti oun fee so fun un ni pe ile baba oun ni aafin ti oun n ko lo, niwon igba tijoba si ti gba Mustapha Keji laaye lati maa gbe ile baba tire, ko si idi ti won yoo fi ni ki oun ma gbe agboole baba oun, bo tile je pe aafin wa nibe. Baba naa salaye pe omo odun merin-le-logorun-un loun nigba naa, ko si si ohun kan soso to ku toun n toro lowo Olorun ju ki oun ku sinu ile baba oun lo. Ninu leta ti Wuraola Isioye ko, ko pe ara re ni Olofa o, Alhaji Wuraola Isioye lo pe ara re, eyi to fi han pe oun naa ko mo boya oun ni Olofa tabi oun ko, bee ni gbogbo igba naa, Olofa ni Mustapha Keji n pe ara re nibikibi.

Ni ojo kokanla, osu kejila, odun 1969, Adajo Muhmamed Bello dajo ni ile-ejo giga ilu Ilorin pe ko seni ti i ba yimiyimi dumi o, Oba Wuraola Isioye ni Olofa ti ilu Ofa, ki i se Alaaji Mustapha Oyewunmi Keji rara.

Adajo ni loooto Keji ni olori ijoba ibile agbegbe Ofa, sugbon osise ijoba loun, ko si si ohun to ye ko wa de ipo Olofa, nitori ipo naa, ti Wuraola Isioye ni, oun lawon eeyan yan bii Olofa Ofa, ki i se Keji rara. Adajo naa pase pe ki Mustapha ma se da si oro ile tabi ti asa ilu naa mo, nitori ojuse Oba ni, ojuse Olofa ni, Isioye si ni Olofa labe ofin. Sugbon bo tile je pe won da ejo naa bee, oro naa ko ti i ri bee lodo ijoba, ijoba wo wahala ti oro naa yoo da sile bi won ba so pe ki Mustapha Keji kuro lori oye, ati pe oro naa ti tun lowo oselu ninu, nitori oro ti fee di ija akoso ilu laarin awon Hausa, Fulani ati awon Yoruba. Ofa yii si ni aaringbungbun ibi ti ija naa ti le gan-an.

Nigba toro ri bayii, awon omo ilu Ofa funra won dide lati gbe igbimo ti yoo yanju oro naa kale, bee ni won fa awon akekoo omo ilu naa si i ki won le jo fikun-lukun lori bi oro naa yoo se yanju patapata. Leyin ti won ti jiroro tan ti won si ti dabaa orisiirisii, won gbe ipinnu won naa jade ni odun 1967 yii kan naa, awon ipinnu nla nla ti won se si je meje. Lara won ni pe awon gba ki gbogbo ilu naa si gba pe Alaaji Mustapha Keji ni olori ijoba ibile agbegbe Ofa, ki awon si maa ti i leyin. Ati pe niwon igba to je nise ni won ni awon fi eyin Oba Wuraola Isioye ti gege bi olori ijoba ibile Ofa nitori ojo ori re, ati pe niwon igba ti ise oba ko la wahala kankan lo, ki won je ki Isioye maa je oba re lo, ki gbogbo ilu si gbaruku ti i lati se ise ti oba ba n se. Bee ni won fowo si i pe ipo olori ijoba ibile ki i se ipo Olofa, won ko si gbodo fi won we ara won laelae. Igbimo yii ni ki ijoba da Olofa Isioye pada saafin re kia, ki won si fofin si i pe ki won ma fun kakaki ni ile Mustapha Keji, nigba ti ki i se oba tabi Olofa ilu Ofa.

Sugbon pelu gbogbo eyi, ijoba ko ti i mo igbese ti won yoo gbe sa, won ni awon fee yanju oro naa leekan.

Nibe ni won ti gbe igbimo kan dide, igbimo naa ni won si fe ko wadii oro oye Ofa ati awon ohun to ye ki won se. Igbimo Sawyer ni igbimo naa, nitori oruko eni to se olori igbimo naa niyen. Igbimo yii lo bere iwadii won, won si sise fun bii odun kan o le. Ni ojo kejo, osu keje, odun 1969, ijoba kede abajade iwadii awon igbimo yii ati aba ti won fowo si fun gbogbo ilu pata. Akoko ninu aba won ni pe ki Alaaji Mustapha Keji fi ipo re sile bii Olofa ti ilu Ofa, won ni ki i se Olofa, olori ijoba ibile ni. Lojo naa gan-an ni oba naa si kuro lori oye, ti ko si senikan to pe e ni Olofa mo, nitori ijoba ti so pe ki i se Olofa, bee ni ile-ejo ti so bee, oro naa si ti kari ibi gbogbo.

Sugbon kinni kan tawon ti won wadii oro naa se, to si di ohun to n fa wahala loni-in yii ni pe lodun naa ni won pin idile ti yoo maa joye ni ilu Ofa si meji, ti won ni Anilelerin ati Olugbense ni, ti won si so pe awon Anilelerin ni won yoo koko je leyin naa ni awon Olugbense yoo tun pada waa je, koda ijoba fowo si i pe Mustapha Keji tun le waa pada du ipo oba bi oba to wa nibe ba gbese. Ijoba ati awon ti won wadii oro naa ko tele itan ati alakale bi won ti n joba tele ni ilu Ofa, ohun tawon n se ni bi won yoo se mu alaafia wa si aarin ilu Ofa lasiko ohun, ati bi awon yoo se ni eto idajo ti ko ni i bi Mustapah Keji ninu, oun atawon ti won n tele e, ati awon alatileyin re gbogbo. Idajo ti won si da naa ko le bi i ninu nigba ti oun naa ti mo pe latigba naa ni idile oun yoo ti maa joba, bi oun ko tile ri oba naa je mo. Bee ni oro naa ko le bi awon Anilelerin paapaa ninu nigba to se pe won ni ki awon ti bere si i joba lesekese, iyen ni pe ki won mu oba tuntun mi-in jade wa. Oro naa ko pari ija Ofa, o kan fi i pamo titi doni yii ni.

Idi ni pe nigba ti won yoo fi gbe abajade yii bo sita, ti ijoba yoo si pase le e lori, Oba Wuraola Isioye ti ku, oun ti ku ni ojo kin-in-ni, osu karun-un, odun 1969, abajade naa ko si soju re. Ojo gan-an ti won n se ogoji ojo oku Olofa yii ni won gbe abajade naa sita, lati fi petu si awon omo Ofa ninu, ati lati je ki inu won dun pe ijoba ti yanju isoro won gbogbo. Oro naa si dun mo opolopo eeyan ninu nigba naa o, boya ni enikan tie wa nibe ti ko dunnu si i. Eyi lo fa a tijoba paapaa ko fi duro mo, nitori losu to tele e, iyen lojo kin-in-ni, osu kejo, odun 1969, won kede Mustapha Olawoore Olanipekun Ariwajoye Keji gege bii Olofa tuntun, nigba to si di ojo kokanlelogun, osu kin-in-ni, odun 1970, won gbe ade le Olofa tuntun naa lori. Omo ile Anilelerin ni. Oba Ariwajoye yii lo waa fi odidi ogoji odun joba, to si sese ku lodun 2010.

Igba ti Oba naa waja ni wahala bere yii o. Abdurauf Adegboyega Keji ti i se omo Mustapha Oyewunmi Keji ti oun ati Wuraola Isioye jo fa walala ni aadota odun seyin so pe oun ni ipo naa to si, nitori Mustapha Keji funra re ti ku lojo karun-un, osu kin-in-ni, odun 1976. Omo Keji yii ni oun loba naa kan, nitori ofin ti ijoba Ogagun Bamgboye se. Sugbon Mufutau Gbadamosi Esuwoye bo sori oye nitori oun lawon afobaje mu lati ile Anilelerin, ohun ti awon si n tenumo ni pe ki i se idile meji lo n joba ilu Ofa, idile kan naa ni, eni ti ifa ba si mu ninu won ni.

Won ni eyi ti awon ijoba se lodun gbogboro to koja seyin yen, oselu ni, won fee fi da eto oye jije ilu Ofa ru ni, awon ko si ni i gba ki eyi sele, nnkan gbodo pada si bo ti ye ko ri gan-an. Ohun ti won so pe awon se n so eyi ni pe bi awon Keji lati Olugbense se letoo si oye yii, bee ni awon idile mi-in bii mewaa tabi ju bee lo ni eto lati so pe awon naa fe ki won maa yi oye Olofa po ni, nitori omo baba kan naa ni gbogbo awon. Bawo waa ni won yoo se da awon Olugbense nikan yo, nigba ti ki i se Olugbense ati Anilelerin nikan ni awon omo oye ti Olalomi se saye, ati pe ki Olugbense akoko too joba ni 1726 si 1789, awon Olofa meje lo ti je ko too kan oun. Awon ti won waa je ko too kan oun nko, awon ti won si je leyin ti oun tun je nko, sebi omo Olalomi-gangan kan naa ni gbogbo won. Ohun to fa wahala yii ree o, to si di ohun ti won n gbe ara won lo sile-ejo.

Won ti da ejo naa nile-ejo giga Ilorin logunjo, osu keje, odun 2012, Adajo da Oba Mufutau Gbadamosi, Esuwoye II lare. Awon Keji gbe ejo naa lo sile-ejo Ko-te-mi-lorun, nibe ni won ti da Mufutau lebi lojo kesan-an, osu keje, odun 2013, ti won si ni ko fipo oba sile.

Mufutau ti waa gbe ejo re lo sile-ejo to ga julo bayii o, ojo kewaa, osu keje, odun 2013, lo gbe ejo naa lo sodo won, idajo naa lo si ku ti gbogbo Ofa n reti. Bee ki i se gbogbo Ofa nikan lo n reti idajo yii, gbogbo aye

ni. Sugbon o, ko senikan to mo ibi ti oro naa yoo fori so.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Saturday, January 25 @ 02:12:37 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· EsinIslam Media Yoruba
· Ekunrere Nipa Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere:
Oye Okere Tilu Saki, Ile-ejo Ni Mogaji Ko Gbodo Gbe Igbese Kankan Bayii


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

"Idi Tawon Omooba Ofa Fi Koju Ija Sira Won" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: