Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
L’Ondo, Iyabo Dana Sun Yara Awon Ayelegbe Baba Re, O Ni Won N Di Oun Lowo
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Taofeek Surdiq, Ondo

L’Ondo, Iyabo Dana Sun Yara Awon Ayelegbe Baba Re, O Ni Won N Di Oun Lowo

Akolo awon olopaa ni omobinrin eni ogbon odun kan, Iyabo Kolegbaje wa bayii lori esun pe o fina si yara awon ayalegbe baba re to wa laduugbo Oretu, l’Ondo, to si jo gbogbo dukia won.

Gege bi iroyin to te Iwe Iroyin Yoruba lowo lori isele naa, a gbo pe Iyabo ti figba kan ri lo sile oko n’Ibadan, sugbon ko duro sibe nitori awon iwa owo re, nise lo pada waa dalemosu si okan ninu awon yara to wa nile ti baba e ko yii.Won ni kete ti omobinrin yii ti pada de lati odo oko e lo ti bere si i gbogun ti toko-tiyawo kan, Ogbeni Ibrahim Rahman ati Damilola, to je onisowo eja yiyan niluu Ondo.

Won ni Iyabo maa n so fun Abileko Damilola pe ko gbodo dana eja si eyinkule, afigba ti baba e ba a da si i ko too gba pe ki obinrin yii dana eja re. Iwe Iroyin Yoruba tun gbo pe oko ati iyawo yii je enikan to feran oun osin bii aja ati adie pupo.

L ojo ti won ni isele yii waye, Baba Iyabo pe omo e pe oun ti gbowo osu mefa miiran lowo Abileko Damilola atoko re, bee lo ki omo e nilo pe ko jawo ninu gbigbogun ti toko-taya ohun nitori oun ko setan lati le won jade. Ibinu oro ti baba naa so ni won ni Iyabo ba pada sile yii, bee lo seleri fun toko-tiyawo naa pe oun setan lati fina si gbogbo dukia won, ati pe ihooho ni won yoo ba jade kuro nibe.

Ninu alaye ti Abileko Damilola se f’Iwe Iroyin Yoruba, o ni lale ojo tawon loo sanwo fun baba lanloodu lawon gba ile ijosin awon lo lati loo kopa ninu eto adura kan to n lo lowo nibe. O ni nibi eto naa lawon wa tawon araadugboawon fi pe awon sori foonu ni nnkan bii aago merin aabo idaji pe ina ti jo gbogbo dukia awon patapata. O ni lesekese lawon kuro ni soosi, tawon gba ile lo.

O te siwaju pe nigba tawon pada denu ile nidaaji ojo naa, nise lawon ri awon ero ti won pe jo siwaju ile ohun bamubamu ti won n wo bi eefin ti bo gbogbo ibe kan. Damilola ni nigba naa lawon too sakiyesi pe gbogbo dukia awon titi to fi mo awon nnkan osin awon lo ti jona mole tan. Sugbon iyalenu ibe ni pe ina ohun ko de inu yara keji to je ti Iyabo to wa legbee todo awon. O ni abo aja nla kan toun atoko oun ti n sin bo lati bii odun mejo seyin ni won pa, ti won si gbe oku e senu ona de awon.

Awon isele buruku ohun lo fa a ti iyaale ile yii fi fori le ago olopaa to wa l’Enu-Owa, niluu Ondo, lati loo foro naa to won leti. Idi niyi ti awon agbofinro ohun se pe Baba Iyabo si tesan won lati waa salaye oun to mo nipa oro naa.

Ninu oro baba lanloodu ti won mo si Pasito Kolegbaje lo ti je ko di mimo pe omo oun lo fina si dukia awon ayalegbe oun. Bakan naa lo loun ti figba kan ko jale pe Iyabo ko ni i le gbe ninu ile ohun nitori iwa re, sugbon leyin opolopo ebe latodo awon eeyan lo je koun pada siju aanu wo o.

Leyin ojo keta tisele yii waye lowo awon olopaa te Iyabo, asiko naa lo jewo fun won pe loooto loun fina si dukia awon oko ati iyawo yii. O ni nnkan to fa a ko ju ti eefin ina eja tobinrin yii n yan to n wonu yara oun. Bee lo loun ti so fun baba oun saaju ojo yii pe ko le awon toko-taya naa jade, sugbon ti ko da oun loun.

Ni bayii, Iyabo ti wa lagoo olopaa to wa niluu Akure, iwadii si n te siwaju lori oro naa.


Nigba ti oga olopaa to wa niluu Akure n fidi isele naa mule, o ni Iyabo ti jewo pe loooto loun fina si dukia awon ayalegbe baba oun, bee lo loun setan lati sanwo gbogbo dukia to baje nibe

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Saturday, January 25 @ 03:10:40 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"L’Ondo, Iyabo Dana Sun Yara Awon Ayelegbe Baba Re, O Ni Won N Di Oun Lowo" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: