Gbagede Yoruba
 



Iyen Lawon Yii Naa Se N So Kantan-kantan
 
Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Iyen Lawon Yii Naa Se N So Kantan-kantan

Awon ti won n se oselu PDP nile Yoruba wa naa nibi, awon yii naa ki i ronu, nibi ti aye ba koju si, awon yoo si keyin sibe, ohun tawon eeyan se n foju alainilaari ati ole lasan wo won niyen. Loooto si ni, iwa won jo iwa ole nigba mi-in, o maa n jo iwa ole, alapa-ma-sise, ati eni ti ko moju ti ko mora nitori ohun to fee je. E wo gbogbo bi nnkan se ri yii, e wo gbogbo wahala to ba egbe PDP yii, e wo ariwo tawon araalu paapaa n pa pe Jonathan ko kun oju osunwon, ko mo kinni kan i se, nise lo fi ete sile to n pa lapalapa, ti won si n so pe ijoba re lo fere buru ju nile yii, oto ni ironu to ba awon eeyan tiwa ti won n se PDP nile Yoruba o.

Awon ti won le ba Jonathan soro n loo ba a loru, won ko je ba a losan-an ki aye ma so won lenu, awon ti won ko si le ba a soro jinna si i, onikaluku n fori ara re pamo. Sugbon awon ti won n se PDP nile Yoruba nibi kora won jo, won sepade pajawiri, won waa gbe iwe jade pe inu awon dun, awon si faramo ijoba Jonathan, awon gbe osuba fun un, awon si fowo si i ko maa sejoba naa lo kanrinkese.



Won ko duro nibe, won ni Tukur ti won n wo yen, oun gan-an logaa awon, awon ti feran e ju, awon si fe e nipo alaga egbe naa, ko si wahala fun un, bo ba ti boju weyin bayii, awon ni yoo ri nibi gbogbo. Awon oponu! Egbe n fo mo eeyan lori, okunrin naa yo gbogbo awon omo iya won ti won jo n se egbe nipo, o fi Oyinlola se yeye, o fi abuku kan awon Oni atawon to ku, iyen ko kan awon oniyeye ti won lawon PDP yii o, eyi to kan won ni ki Jonathan ati Tukur maa jo niso, nitori ijekuje ti won fee je.

Kontirakito kuku lo po ninu oloselu tele, ise ijoba ti won yoo gba ni won n le kiri. Bi ko ba se bee, o daju pe bi awon eeyan wonyi ba fi oro naa to awon omo egbe won to ku leti, ti won ba awon ti won dibo fun egbe naa soro, won yoo ri i pe ko senikan ti yoo tele won lati maa ki Jonathan laya, tabi lati maa fowo soya pe ijoba re dara, o te awon lorun.

Bo ba ya, won yoo ni egbe awon ko wole nile Yoruba, oponu ko si nile Yoruba, ologbon lo wa nibe, bi won ba si ti ri awon ole ati onijekuje bayii, won da won mo latookan!
Iro niyen jare Eyi lo fa a ti oro gomina ipinle Niger, Muazu Babangida Aliyu, ko se gbodo jo enikeni loju.

Okunrin naa wa lara awon ti won fo egbe PDP, o wa lara awon gomina meje ti won n kiri tele pe awon ko fe Jonathan, o si wa lara awon gomina to ba Atiku lo. Sugbon gbogbo iyen lo daa, afi nigba to fi oro mi-in ti ko kan araalu bo oselu re, to so pe wahala PDP yii le da gbogbo Naijira ru, o le fo Naijiria si wewe. Nitori kin ni? Se eni ti ko je gbii a maa ku gbii ni.

Sebi ibi ti e ba gbe amala de ni e oo jo de, ki eeyan ma ma jo ijo eleya de ita tiwa o. Afi to ba se pe Babangida Aliyu yii mo ohun tawon araalu ko mo, bo ba se pe awon Hausa elegbe re ti mura lati da Naijiria ru bi Jonathan ko ba gbejoba fun won, iyen nikan lo fi le so ohun to n so jade lenu. Sebi ki i se egbe PDP nikan lo wa niluu, bi oko kan ko si lo Oyingbo loni-in, egbeegberun re yoo lo.

Bi egbe PDP ko ba ni anfaani ti yoo se fun awon eeyan mo, sebi awon araalu yoo ba inu egbe oselu mi-in lo. Bi awon asaaju egbe naa funra won ba si lu u fo, ti won yo ponpo ti won fi n lu egbe won, ko si eyi to kan awon araalu nibe, sebi bi egbe won ba tuka tan, kaluku won yoo ba ibomi-in lo. Ona kan ko wo oja, bee ni iwofun ni itelorun, ohun to ba te ni lorun la a se.

Sugbon lati maa waa so pe Naijiria yoo daru nitori egbe PDP fo, nitori pe tiwon ba won, nitori pe ojooro ati eru pelu etan ti won ti se fun gbogbo omo Naijiria lati ojo yii wa ja jo won loju, isokuso lasan gbaa ni. Egbe PDP yoo fo, iyen ki i se iroyin mo nitori egbe ohun ti fo, Olorun nikan lo le da a pada.

Sugbon ko si ohun ti yoo kan awon omo Naijiria ninu iyen, ko si si ohun ti yoo fo Naijiria, Olorun yoo kan fun won ni egbe mi-in ati awon oloselu mi-in ti won ki i se ole ati wobia, ti won ki i se awon ti won n re mekunnu je. Bi egbe PDP ba fo ti gbogbo awon oloselu inu re si fonka, ohun to dara fun awon omo Naijiria ni, nitoti eleyii yoo maa je kilokilo fun gbogbo awon asebaje ti won ba ko egbe oselu jo lati mo pe ohun ti i tan ni eegun-odun o, omo alagbaa paapaa yoo fowo ra akara jeko. Aliyu, loo jokoo jee, e bara yin sohun-un jare!


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Saturday, January 25 @ 04:11:33 PST Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu:
Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu



"Iyen Lawon Yii Naa Se N So Kantan-kantan" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com