Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
[ Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin ]

·Gbogbo Musulumi Jakejado Orileede Naijiriya Ni Babayemi Gba Niyanju Lati Se Awok
·Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Ikolu Awon South Africa Si Naijiria - Ekunrere
·Xenophobia (Ikorira-Ajeji) Attack: Awon Omo Naijiria Ti Yari Pe Awon Naa Yo Gbes
·Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
·Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
·Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
·Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
·Eru n Bawon Ara Mushin Nitori Oriyomi Ti Won Dajo Iku Fun
·Aafaa Wo Gau N'Ijare, Orebinrin Re Lo Seyun Fun, Niyen Ba Gbabe Ku

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Ija PDP Bureke: Obasanjo, Babangida, Anenih Ati Jonathan Dota Ara Won
 
 
Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
Lati Owo Olawale Adejare

Ija PDP Bureke: Obasanjo, Babangida, Anenih Ati Jonathan Dota Ara Won


O ti pe ti oro naa ti n lo labele tele, ariwo lotun-un, ija losi, e de-aiyede lorisiirisii, nigba naa ni awon ologbon si ti mo pe egbe ti won maa n so pe awon ni won tobi ju ni gbogbo Afrika, iyen PDP ti fo pekepeke bayii o. Oro naa le ju bi awon eeyan ti n ro o si lo, ija agba nikan ko, ija nipa eni ti yoo se olori Naijiria lodun 2015 ni, ohun to je ki kinni naa le koko niyen. Egbe ti fo si meji bayii, Atiku ti ko awon kan jo, o fi Muhammed Kawu Baraje se alaga; awon ti Aare Goodluck Jonathan naa duro, Bamanga, Tukur lolori awon. Sugbon oro ti di tile-ejo, oro si ti dohun tawon asofin atawon agbaagba egbe naa n da si, bi Tukur ti n binu ni Jonathan n binu, sugbon Atiku ati Baraje so pe awon kapa gbogbo won, awon yoo si le won lo. Bee ni ija nla bere laarin egbe PDP atijo ati egbe PDP tuntun, bi nnkan si se wa yii, bi won ko ba tete yanju re, afaimo ko ma je ohun ti yoo so egbe naa di egbe ana niyen, nitori yoo fonka debii pe ko ni i see sa jo mo.

Bee ni won ko ri oro naa yanju loooto. Lojo Eti, Fraide, ose to koja yii, awon Baba isale egbe naa pejo siluu Abuja: Olusegun Obasanjo, Ibrahim Babangida, Tony Anenih, Barnabas Gemade, Ahmadu Ali, gbogbo won ti won ti je olori ati asaaju egbe naa nigba kan, won ni won fee pari ija naa ni kia.Sugbon gbogbo bi won se fa oro ohun mora won lenu to niwaju awon agbaagba yii, ko senikan to gba ninu awon mejeeji to n ja, tara won nikan ni won fe ko se. Tukur ni ki Atiku atawon eeyan re ma pe ara won ni PDP tuntun mo, ki won foribale fawon tawon je alase PDP, ki won si fi awon sile kawon yanju ija egbe awon gomina.
Sugbon awon Atiku ni ohun tawon n fe ni pe Jonathan ko gbodo dupo Aare ni 2015, Tukur ko gbodo se alaga egbe mo, won gbodo yanju ija awon gomina, bee ni Jonathan ko gbodo fi EFCC deruba gomina kankan mo. Nibi yii ni jebete ti gbomo le awon ti won fee pari ija naa lowo, nitori ko seni to gba fenikan.

Bee, amukun-un eru re wo loro naa, o ni oke nikan le n wo e ko wo isale, lati ile ni oro naa ti wo wa. Jonathan atawon ti won n ba oun sise ko fe kawon ti won n da soro yii da si i rara.

Won ti koko pe ipade kan tele ti won ni ki won pari ija yii, bo tile je pe ko si Obasanjo nibe, nise ni okunrin olori Naijiria naa binu jade, o ni wahala to wa nile naa, Obasanjo lo da a sile, gbogbo awon ti won n ba oun ja yii, omo Obasanjo ni gbogbo won, oun lo si wa nisale to n runa si i, oun to si da ija yii sile naa ni ko mo bi yoo ti pari re, ki enikeni ma ko wahala ba oun Jonathan ni toun. Bee ni awon kan n bu Tony Anenih naa, won ni ko feran Bamanga

Tukur tele, oun paapaa si feran bi awon kan se n foju e gbole yii, o si wa ninu awon ti won n fe ki won le Tukur lo, nitori bee, ko le pari ija kankan fawon. Bakan naa lawon kan n so pe oro Babangida funra re gba ifura, nitori ore to n ba awon asaaju APC se lasiko yii, ati pe gomina to buru ju ninu awon ti won n ba Jonathan ja yii, Gomina ipinle re ni.

Sugbon ninu oro to wa nile yii, eni ti aya re n ja ju ni Jonathan funra re, oun ati alaga egbe naa lodo tie, iyen Bamanga. Idi ni pe nigba ti oro naa bere, nise ni won ti ro pe ko ni i feju, ati pe awon gomina meje pelu Atiku ti won n binu yii, nigba ti won ko ba ri ero leyin won, won yoo pada wa sinu egbe, tabi ki won kora won lo sinu egbe mi-in. Oro ko ri bee rara o, nitori bi egbe naa ti bere ni awon asofin bii ogota ti so pe awon n lo sinu egbe naa, ati pe egbe ohun lawon yoo se ni tawon bi ina n jo bi ole n ja, nwon si se, afaimo nile igbimo asofin kekere naa ko ni i ye oro Jonathan funra re wo, bo ba si see se ki won yo o danu nipo to wa.

Bi awon ti n so eyi bee naa ni awon asofin agba, awon seneto kan tun dide, ti won ni awon wa leyin egbe PDP tuntun ni tawon, inu egbe naa lawon n lo, awon ko ba Tukur se. Awon kan ninu won tile leri pe awon yoo yo David Mark ti i se olori awon asofin naa bi awon ba ti wole pada, nitori okan lara awon eeyan Jonathan ni, oun ni ko si je kawon se ise awon bii ise latojo yii wa. Eleyii bi Tukur ninu, o si ba a leru gidi. Oun naa mo pe ewu wa loko Longe, nitori egbe awon alatako ohun ti n fi ese mule si i. N lo ba binu, o si so oko-oro si Atiku atawon ti won n tele kiri. O hale mo awon asofin paapaa, atawon gomina, atawon ti won n tele Atiku, o ni afaimo ki won ma sewon, nitori ohun ti won n se yen, bii eni to fee dite gbajoba ni, won n te ofin loju, eni to ba si te ofin loju, olopaa ni yoo mu un. O ni bi gomina kan tabi asofin kan, tabi oloselu to wa ninu ijoba PDP ba ni oun n segbe PDP tuntun kan, awon yoo yo o nipo re, nitori oruko egbe PDP tawon lo fi wole ibo, ko si le wa nipo naa ko so pe oun n segbe PDP tuntun yeye kan. Nibi toro naa ka a lara de, nise lo pe awon oniroyin jo sinu ile egbe naa, to si so pe ki won ba oun kede e faye pe Atiku, Baraje ati Oyinlola n fewon sere o, bee ni awon gomina gbogbo ti won wa nipo ti won tun n sepade ote pelu Atiku yoo so ipo naa nu laipe rara.

Eleyii bi awon Atiku atawon eeyan re ninu, won si so pe ase lasan ni Tukur n so, won ni oro naa dun un, o fee ke ni. Won ni ko sohun to le se fawon, nitori awon ti gbe odidi PDP lo, korofo re lo gbe dani. Se ni gbara tawon ti da egbe si meji nibi ipade won ti won se l’Abuja ni ojo kefa. osu kesan-an yii, ti won binu jade nibe, ti won si loo kede egbe won tuntun ni won ti gba ile-ejo lo, ti won si so pe ki Adajo da awon lare pe awon lawon ni egbe, ki i se Tukur, ati pe ki Tukur fi egbe naa sile fawon. Oro naa wa nile-ejo, ile-ejo si n seto lati gbo o. Bi ile-ejo ti n gbo oro naa, awon egbe PDP tuntun yii loo gba ile-egbe won tuntun, won ni awon ko le gbe ile egbe atijo mo, ati pe ni Sekiteria tawon gba yii, nibe lawon yoo ti ma pase egbe awon. Eto ti won si n se ni pe won yoo pe awon oniroyin gbogbo jo, atawon agbaagba egbe PDP tuntun yii sibe, won yoo si kede pe won si i, ipade awon Obasanjo lo da kinni naa duro.

Sugbon awon Tukur naa ko duro, nigba toun naa t iri ibi ti ina oro naa n jo lo, kia lo ti pe awon eeyan tire naa jo, tawon naa si gba ile-ejo lo. Won ni ki adajo so pe ko sohun to n je egbe PDP tuntun, egbe PDP kan naa lo wa, ati pe oun Bamanga Tukur ni olori egbe ohun. Ni ojo Eti, iyen ojo Fraide, ose to koja yii, nile-ejo naa jokoo, won mura lati gbo oro naa. Sugbon gbogbo ohun ti Bamanga Tukur atawon looya re so pe kileejo se, iyen ni pe ki awon Atiku ma pe ara won ni egbe PDP, ki won ma se ipade kankan, ki won ma si ni ile-egbe, gbogbo iyen ni Adajo ni oun ko ti i le soro le lori, sugbon o so fun won pe ati otun, ati osi, ki kaluku sinmi na, won ko gbodo se ohunkohun titi toun yoo fi gbo ejo naa, toun yoo si da a. Iyen ni pe ati otun o, ati osi o, ibi ti onikaluku ba oro re de naa ni ko ti sinmi, won ko gbodo dawo le nnkan mi-in lati se mo.

Sugbon bi ile-ejo ti so bayii, Bamanga Tukur ko duro mo, o ni ohun ti ile-ejo so ni pe ki awon Atiku ma ti i loo da egbe kankan sile, kia lo si ti ko awon soja, awon olopaa, atawon agbofinro gbogbo leyin, ni won ba lo sile egbe PDP tuntun naa, won si ti i pa. Ki i se pe won ti i pa nikan ni, won ko awon olopaa yipo gbogbo

ibe, won si so pe enikeni ti won ba ri to ba rin ni gberegbere ibe, won yoo mu un ti mole ni. Nibi toro ti waa fo loju leekan si i niyen. Atiku binu, Oyinlola binu, Kawu Baraje ti i se alaga egbe si so pe iwa eranko ni Tukur hu yii, nitori arufin ni, ohun tile-ejo so ko lo se yii, afaimo ni ko si ni i fewon jura. O ni bi awon ba fa oro naa de ile-ejo, Bamanga yoo ma sewon, nitori ohun tile-ejo so pe ko gbodo se lo ti se.

Nibi toro naa de duro ree, sugbon o tun ku ni ibon n ro, ojoojumo ni idan tuntun n jade lati inu egbe PDP,

eyi ti won yoo tun mu jade bayii lenikan ko ti i le so.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Saturday, January 25 @ 04:17:27 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu:
Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

"Ija PDP Bureke: Obasanjo, Babangida, Anenih Ati Jonathan Dota Ara Won" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: