Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Babalawo Naa Fee Soogun Owo, Lo Ba Loo Ge Eya Ara Oku Ni Ite
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Babalawo Naa Fee Soogun Owo, Lo Ba Loo Ge Eya Ara Oku Ni Ite

Oloun n lo awon onisegun lati fopin si isoro aye awon eeyan, sugbon pupo ninu won ko le wo isoro ara won. Idi ree tawon Yoruba fi maa n powe pe atupa kan ki i riran ri idi ara e, bee ni obe ko le mu ko gbe eeku ara e laelae.

Sugbon ko jo pe okunrin onisegun kan, Abideen Raheem, nigbagbo ninu owe yii pelu bo se pinnu lati soogun owo funra e pelu awon eya ara eeyan atawon ohun eelo mi-in, bee ni oro beyin yo nigba tawon olopaa ka odidi apa oku meji ati ori kan to loo hu ninu saare mo on lowo.

Okunrin eni odun marunlelogbon to n fipa wa owo naa ni ko je ki awon oku olokuu sun-un-re lona orun pelu bo se mu obe loo ge ori ati orun owo mejeeji lojo Aje, Monde, ojo kesan-an, osu yii.




Sugbon Oloun to ti ko o lo ni ki owo awon agbofinro te jagunlabi lojo Isegun, Tusde, ojo ketadinlogun, osu yii, nibi to ti n se aajo bi yoo se fi eya ara oku ohun gun ose nitori owo.

Gege b’Iwe Iroyin Yoruba se gbo, awon ara adugbo Masfala, n’Ibadan, ti Raheem n gbe ni won ri eegun oku eeyan ninu ile kan ti won n ko lowo nitosi ile e to gbe e pamo si. Won ta iko ajo eleto aabo ipinle Oyo, Operation Burst, lolobo, bo tile je pe won ko mo eni to ko o sibe.

Iwadii awon agbofinro yii pelu awon egbe won lati ago olopaa Ogbere, n’Ibadan, ti won lo sibe lo je ki asiri tu pe okunrin onisegun tawon eeyan ti maa n fi oju eni pataki wo laduugbo naa lo wa nidii asemase ohun, bo tile je pe awon eegun orun owo nikan ni won ba ninu ora ti Raheem di won si nibe.

Raheem jewo pe oun loun gbe awon eya ara eeyan ohun pamo loooto, sugbon oun ko paayan kankan. O ni lara oku kan toun ri legbee titi ni Too Geeti ona Eko loun ti ge awon eya ara naa.

Iwadii awon olopaa fidi e mule pe iro funfun balau lokunrin afurasi odaran naa n pa pelu bi won se ye gbogbo agbegbe naa wo finnifinni, sugbon won ko ri nnkan to jo oku eeyan kankan nibe. Leyin naa lokunrin afipa-wowo onisegun naa jewo pe inu saare to wa ni Aba Onde loun ti ge owo ati ori oku ohun.

Nigba to n ba akoroyin wa soro, Raheem to pera e lomo bibi ilu Ibadan jewo pe oogunowo loun fee se, ati pe ojukokoro toun ni lati dolowo lonakona lo sun oun de idi iwa eleya ohun.

Gege bo se so, “Onisegun ni mi. Ki baba to ko mi nise too ku ni won ti ko mi bi won se n se aajo owo. Mo tun maa n sin adie, mo si ni isoro nidii e lo je ki okan mi lo sibi nnkan ti mo se yii. Leyin aawe to koja yii, ogorun-un lo ku ninu awon adie ti mo n sin, iyen ni mo se ni ki n gbiyanju aajo owo ti oga mi ko mi ki won too ku.

“Owo eeyan wa lara eroja oogun yen, mo wa loo hu oku ni ite oku awon Musulumi to wa ni Aba Onde. O pe ti mo ti n wa awon eya ara oku yen, mo si ti maa n gba ibi ite oku ohun koja tipe ki n too mo-on-mo loo hu oku nibe lojo yen.

“Ki i se pe mo mu ada tabi oko; lowo, owo naa ni mo fi wa ile ti mo fi hu oku yen jade ti mo si fi obe ge ibi ti mo fe. Ko soro fun mi lati ge e nitori oku yen wule ti jera.”

Okunrin eni odun marunlelogbon naa fi kun un pe, “Eegun owo eeyan ni won ni ki n jo papo mo igbin pelu ijapa atawon eroja kan, ki n waa po o po mo ose abuwe. Won ni ti mo ba se e, ti mo le maa fi ose yen we ori ti mo si n fon omi re si ileele ibi ti mo ti n sise, owo maa de nitori awon onibaara a maa ya wa ni.

“Lojo Monde ni mo loo sise yen, mo waa toju gbogbo e sinu poli baagi kan, mo gbe e sitosi ite oku ohun.

Monde ose to tele e ni mo loo ko awon owo yen, sugbon ori si wa nibi ti mo gbe e si nibe.” Raheem, baba olomo meta yii to bebe fun oju aanu ijoba so pe, “Mo kabaamo pe mo se e, sugbon ti owo awon olopaa ko ba te mi bayii naa, mi o le mo pe Oloun n be. Mi o tun dan iru e wo mo laye bi mo ba fi le bo ninu eleyii.

Alukoro ileese olopaa nipinle Oyo, DSP Olabisi Okuwobi-Ilobanafor, salaye pe oga agba olopaa ipinle naa, Mohammed Indabawa, ti pase pe ki won tana wadii isele ohun daadaa. O ni leyin ti eka iwadii nileese

olopaa (SCID) ba pari ni won yoo gbe okunrin afurasi odaran naa lo sile-ejo.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Saturday, January 25 @ 04:48:14 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Babalawo Naa Fee Soogun Owo, Lo Ba Loo Ge Eya Ara Oku Ni Ite" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  







:-: Go Home :-: Go Top :-: