Gbagede Yoruba
 



NDLEA Ya Bo Oko Igbo Laginju Aala Oyo Ati Osun, Ni Won Ba Dana Sun Gbogbo E
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

NDLEA Ya Bo Oko Igbo Laginju Aala Oyo Ati Osun, Ni Won Ba Dana Sun Gbogbo E

Leyin nnkan bii ose meji ti won sa awon toogi to n yo araalu lenu kaakiri ilu Ibadan, ajo to n gbogun ti ogbin ati lilo egboogi oloro lorile-ede yii, NDLEA, eka tipinle Oyo, tun kolu awon ti won n se ogbin igbo.

Oko igbo nla nla meta otooto tawon arufin eeyan kan da sinu aginju nitosi abule kan ti won n pe ni Osun Eleja, nipinle Oyo, ni won tu pale. Apapo ile ti won fi gbin ohun ogbin aibofinmu ohun to eeka merindinlogbon, gbogbo e lawon agbofinro yii si dana sun patapata l'Ojoru, Wesde, ose to koja.



Aginju iberu la ba maa pe ibi ti won da awon oko naa si. Bo tile je pe ori ile ipinle Osun ni, ko se e se fawon agbofinro won lati debe nitori ko sona teeyan le ba wobe lati Osun. Opin ilu patapata nibi aala ipinle Oyo ati Osun lo wa, ona abule kan to n je Osun Eleja, nijoba ibile Ona-Ara, nipinle Oyo, nikan leeyan le gba debe, ori omi si ni oluware ni lati gba koja.

Abule Osun Eleja si igboro Ibadan to irin-ajo wakati kan pelu moto. Leyin teeyan ba wo oko-oju-omi koja si odi keji lohun-un ni yoo sese bere irin-ajo naa pelu ese loju ona tooro kan ninu aginju ohun, eyi to kun fun koto gegele, odo keekeekee atawon itakun igi nla nla.

Gege bi akiyesi akoroyin wa to ba won rin irin-ajo naa, enu ise ni okan ninu awon to da oko aibofinmu ohun wa lasiko tawon osise ajo NDLEA fi ka a mobe, igba to gburoo awon agbofinro lo kan lugbo. Idi ni pe won se ahere kan si egbe okan ninu awon oko naa, opolopo ohun eelo inu ile bii ibusun, a¯wo¯n ipefon, ose, epo, ororo atawon nnkan mi-in lo wa nibe.

Eni naa ko duro pa redio to n gbo lowo to fi sa lo. Obe egusi gbigbona ati eja lanase ti won ba ninu ahere ohun pelu aaro idana gbigbona lo fi han pe ko pe rara ti enikan kuro nibe.

Kia ni won da epo bentiroolu si ahere ti won fi igi ati koriko ko naa, won si dana sun un.

Bee ni won fi ada ge gbogbo ewe igbo ti won ba ninu oko naa atawon oko igbo meji mi-in ti won da sitosi e.

Bo tile je pe a ko ri eni daruko awon to ni oko naa, awon to mo asiri ise yii so pe o see se ko je ileefowopamo lawon eeyan naa ti ya owo ti won fi da oko aibofinmu ohun, sugbon oto ni ohun ti won maa n so fawon banki pe awon fee gbin sinu oko ti won ba fee yawo ohun.

Ohun to fidi eyi mule loooto ni awon poporo agbado kookan to wa ninu oko igbo naa, eyi to fi han pe agbado ni won koko gbin sori ile yii ki won too gbin igbo ropo e ni kete ti won kore agbado tan.

Alaga ijoba ibile Ona-Ara, Onarebu Ismaila Babatunde Oyetunde, naa ba awon agbofinro lo sibi akanse ise naa. Saaju ojo yii la gbo pe okunrin alaga kansu ohun ti seto bi irin-ajo naa yoo se kese jari.

Onarebu Oyetunde ni bo tile je pe ki i se inu ijoba ibile oun ni won ti ri ohun to lodi sofin naa, igba akoko ree ti won yoo gburoo iru e ni sakaani ijoba ibile Ona-Ara.

Gege bo se so,"Ki i se ijoba ibile mi ni won da oko igbo yen si, sugbon odo wa ni won n gbe awon kinni yen gba koja. Iyen lawa naa se dide lati ran awon ajo NDLEA atawon agbofinro yooku lowo nitori awon to n gbin igbo atawon to n ta igbo n dunkooko mo igbaye-gbadun awa araalu, awa ko si faaye gba odaran nijoba ibile wa." Nigba to n ba awon oniroyin soro leyin ise ohun, oga agba fun ajo NDLEA nipinle Oyo, Abileko Omolade Faboyede ni, "A gbo finrinfinrin pe awon kan n gbin igbo laduugbo yen la se lo lati ba awon ogbin yen je leyin ta a sewadii. A si n so gbogbo agbegbe yen yika, enikeni ta a ba ri to ba ta felefele nibe, mimu la maa mu un. Erongba wa ni lati ri i pe awon eeyan ko ta tabi gbin igbo, tabi ra egboogi oloro mo nipinle Oyo pelu ifowo sowo po awon agbofinro mi-in." O waa seleri pe ajo NDLEA si maa sabewo ojiji sawon ijoba ibile yooku to wa nipinle Oyo lati ba gbogbo oko ti won fi gbin igbo jakejado je. Bee lo ro awon ara abule ati igberiko gbogbo lati tete ta ajo NDLEA lolobo nigba yoowu ti won ba sakiyesi pe won n gbin iru nnkan bayii nibikibi lagbegbe won.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, March 30 @ 04:21:48 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu



"NDLEA Ya Bo Oko Igbo Laginju Aala Oyo Ati Osun, Ni Won Ba Dana Sun Gbogbo E" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com