Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun
[ Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun ]

·Gbigba Kadara Gbo - Al-Imaan Bi-l-Qadar (Ayanma Tabi Akosile)
·Umaru Gbe Oogun Wo Kootu, Ladajo Ba Da Igbejo Duro Kia
·Fasasi Ko Iyawo e Sile N'Ibadan, O Ni Ko Ro Amala Fun Baba Oun
·Adajo Ni Ki Won Fi Emmanuel, Ayederu Looya, Sogba Ewon Kirikiri
·Alake To Fee Ko Oko Dero Ewon N'Ilorin
·Yekeen Fee Ko Munira n'Ilorin, O Ni Latigba Tawon Ti Fera Loun Ti n Ru, Tou
·Adajo Ni Kawon Ebi Oko Medinat Da Ogun Oko Re Pada Fun un
·Igbeyawo Ogun Odun Daru L'Osogbo
·Lori Oro Ti Ko To Nnkan, Awon Olopaa Fibon Fa Femi Lorun Ya, Ni Won Ba Sa Lo

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Ija PDP: Awon Olori Ile Igbimo Asofin Koyin Si Jonathan
 
 
Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Ija PDP: Awon Olori Ile Igbimo Asofin Koyin Si Jonathan


Awon eeyan ti ro pe ija naa yoo pari ni, sugbon ohun to sele lose to koja yii fi han pe afaimo ni egbe PDP yii ko ni i fo si welewele, nitori oro naa ti di egbinrin ote bayii, bi won ti n pa okan lokan n ruwe. Lojo Isegun, lose to koja ni kinni naa tun bu gbau, afi bii igba ti awon eeyan kan bu epo bentiroolu si i, gbogbo awon ti won si wa nibe ni won gbiyanju ki won ri ina naa pa, sugbon nise lo n ke si hoo hoo hoo. Laarin awon asofin ni o, nibi ti awon gende ti n gbara won lesee, ti won n fi agbada elomi-in yi i loju ki won too ko ifoti bo o, ti awon asofin ti won si ti pe nigboro n nawo gbe sia ti won n ju u firi, oro si di gidigbo gidigbo nile igbimo asofin. Ija awon PDP naa lo bureke debe, awon asaaju egbe naa tuntun atawon Gomina meje ti won lawon ko fe Jonathan ni won lo sile igbimo, won ni awon fee loo ri awon asofin yii ki awon le so ohun to n lo fun won, ohun to si fa idi ariwo naa niyen o.

Kawu Baraje, alaga egbe PDP tuntun yii lo ko awon Gomina meje leyin, won si de ile igbimo asofin kekere nibi ti Aminu Tambuwal atawon asaaju ile igbimo naa ti n duro de won, won ni awon loro lati ba won so. Bi won ti de ile igbimo naa ti won bere oro, nise ni okan ninu awon asofin naa, Henry Ofongo lati Bayelsa fo siwaju, to ni ki Baraje sinmi, won ko fe e nibe, Bamanga Tukur lawon mo, bi Baraje si se n soro lo n fariwo di i lowo.Nigba naa lawon omo ile igbimo kan dide, ni won ba sun mo Ofongo, won fa a seyin, enikan ninu won si la a nigbaaju ako, nibe ni ijangbon ti bere nitori awon mi-in fee gbeja oun naa, nija ba dija igboro, lawon asofin ba n gbara won lesee karakara. Agbada funfun ni Afeez Adelowo lati Oyo wo, sugbon nigba ti obinrin kan ti won pe ni Binta Masi Garba wo o mora, o ya agbada naa kanle ni o, bee lawon kan he sia ninu won, lo si di gbau, gbau! Sugbon pelu e naa o, Baraje soro nile igbimo yii, o ba awon asofin soro, won si fetibale sohun to so. Eleyii gan-an lo bi Jonathan ninu, oun atawon omoose re nileese Aare. Kia ni won bere eto, won si n wa ona ti won yoo fi yo olori ile igbimo asofin kekere yii, iyen Tambuwal danu. Igba ti won tun waa ri i pe olori ile igbimo asofin agba, iyen David Mark, naa ko fi taratara gba ti Jonathan mo, to je eyin PDP tuntun lo wa, won ni ki won yo oun naa danu ni yoo dara. Ni won ba bere ise. Won fee gbe owo fun won nile igbimo, ki awon asofin le koyin si awon oga won. Sugbon nigba toro naa ko tete yanju, ti Aare ranse pe obinrin to je asoju ati oludamoran fun un lori oro awon asofin yii, Joy Emordi, iyen so fun un pe ona ti won fee gba yii ko dara, bi won ba fawon asofin lowo, won fowo won jona lasan ni. Iyen bi Jonathan ninu, o si yo obinrin naa kuro nipo re, o loun ko fe e mo, nitori ko mose.
Oro naa ko tan sibe o. Awon asofin atawon olori PDP tuntun yii ni ko soro kankan ti awon fee ba Jonathan so, afi bo ba koko gba pe oun ko ni i du ipo aare lodun 2015. Baraje tile fibinu soro si i, o lohun ti Obasanjo fee se lodun 2007 ti gbogbo won gbogun ti i pe ko le se olori Naijiria leemeta ni Jonathan fee fogbon alumokoroyi se yii, ohun ti yoo si bu u lowo gidi ni. Sugbon awon ti won wa nileese Aare binu soko oro si oun naa pada, won ni ohun to ye ki Baraje se ni ko ba awon looya re soro, ki won le salaye fun un pe Jonathan ko ti i lo saa meji ka ma ti i so pe yoo lo saa meta, won ni saa keji lo sese fee lo, o si ye ki awon looya ti won ba mose le tumo ofin fun olori PDP tuntun naa. Kia ni Baraje naa ti ta mo Aare atawon omo re, to si so fun won pe asiri won ti tu, gbogbo ona ti won fee gba lati yo David Mark ati Aminu Tambuwal lawon ti ri o, bee nitori pe won fee tumo ofin naa daadaa fun Jonathan lo se fee yo won.


Bo tile je pe nise nileese Aare si n so pe awon ko yo enikan o, ko sohun to kan awon ninu oro ile igbimo, sibe won n gbiyanju gidigidi lati yo awon olori ile igbimo naa nitori won ni ota awon ni won n se. Sugbon nigba ti yoo fi di ojo Eti, o ti han pe oro naa ti di eti mo won lowo, won ko le ri won yo.

Ikanra eleyii nijoba Jonathan fi ja pasipootu akanse ti awon omo ile igbimo naa n lo kuro lowo won. Akanse pasipootu yii maa n faaye gba gbogbo awon asofin naa lati lo sorile-ede yoowu ti won ba fee lo lagbaaye lai ni i si wahala kan fun won. Won ko ni i se wahala lati gba fisa, pasipootu won yii ni yoo maa silekun gbogbo fun won. Sugbon ileese Aare ti gba awon pasipootu naa lowo awon asofin atawon olori won, won si se eleyii ki won le fi hale mo awon asofin naa ni o, ki won le se ohun ti won fe ki won se> ki won yo awon olori won ni. Oro naa ti di ohun ti aya awon araalu paapaa n ja le lori, nitori nise ni Olubunmi Okojie ti i se eni-owo awon ijo Aguda so pato pe ki Jonathan ma du ipo aare ni 2015 o, bo ba se bee yoo lewu gidi fun Naijiria. Ebe ni okunrin naa be Jonathan, o si so fun un pe iran ti oun ri si i ko daa rara ni. Sugbon kaka ki Jonathan atawon eeyan re gbo, oto ni ohun tawon n so. Won ni awon Gomina ti won n ja ija naa yoo kan abuku laipe rara, nitori gbogbo ohun ti won n beere lowo Jonathan yen, ko si eyi ti yoo se nibe. Won ni okunrin naa yoo du ipo aare ni 2015 yoo si wole, bee ni ko ni i gboro si awon Gomina naa lenu lae, ko si le pe ti awon yoo fi fi ofin ijoba apapo mu won. Sugbon awon Gomina naa ni awon ko bikita o, Sule Lamido ti Jigawa tile so pe bi oro naa ba ja siku foun, oun faramo on. Bayii ni ija naa si n fojoojumo le si i, ti awon Gomina naa si ti n palemo lati lo sinu egbe PDM, tabi Accord, won nibe lawon yoo si gba de inu egbe APC.

Ohun ti awon kan tile n ro ni pe awon agbaagba ti won ti da soro naa lati ile, iyen awon ti Olusegun Obasanjo saaju won nijosi yoo le yanju oro naa pata, sugbon o jo pe iyen naa ti tun forisanpon, nitori Obasanjo funra re ti jawo nibe bayii, o ni oun ko se mo. Loooto Baba naa so pe nitori ti awon eka PDP mejeeji - PDP atijo ati tuntun - ko gboro si oun lenu, ti won ko si tele gbogbo ohun ti awon so loun se yowo yo ese ni toun, awon ti won modi oro so pe abuku ti Jonathan atawon omo re fi kan Obasanjo lo je ko koyin si won ni tie. Se igba kan wa ti Jonathan so pe Obasanjo lo da wahala sile foun, nitori gbogbo awon ti won n ba oun ja yii, awon omo Obasanjo ni won, bi Obasanjo ba si fee yanju oro naa to ba ti ba won soro ni won yoo gbo si i lenu. Loro kan, Jonathan ko fokan tan Obasanjo, o ni bo ti n se oun naa lo tun n gba oun, bawo loun yoo waa se dupe lowo eni to n se ni to tun n gba ni.

Nibi toro naa waa wa bayii ni pe o jo pe Jonathan ti pinnu lati fi agidi mu gbogbo awon ti won ko ba gba tie, ileri ti wa lati yo awon minisita to ba n ba awon Baraje ati egbe PDP tuntun se, bee ni opo awon ti won si wa nile igbimo asofin ni yoo so ipo won nu, gbogbo awon to ba feran ara won gbodo ba Jonathan se ni. Sugbon awon omo egbe PDP tuntun yii so pe Jonathan kan n se galala lasan ni, won ni olowo re ki i se Olorun asiri re lo bo, ati pe bi oun ba ka eni tire, Olorun yoo te eni tuntun, ohun ti won yoo mura si lati se fun un naa ni pe ko ni i pada di aare lodun 2015, gbogbo ohun to ba gba lawon yoo fun un. Bee Jonathan funra e ti so pe oun ko nibi kan i lo o, o ni bi awon eeyan naa fe bi won ko, oun naa loun yoo maa se aare lo lodun 2015, ko senikan to lagbara lati yo oun o. Nje wahala nla ko lo n bo ni Naijiria yii, oro naa ti da bii oko Sango, ibi ti yoo wole si ko seni to le so.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, March 30 @ 05:01:53 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu:
Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

"Ija PDP: Awon Olori Ile Igbimo Asofin Koyin Si Jonathan" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: