Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Ikoja Aaye Kan Ree O: Won Ni Abule Asasin Ni Won Fi Nofiu Adeyemi Joba Le Lori
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Johnson Akinpelu, Abeokuta

Ikoja Aaye Kan Ree O: Won Ni Abule Asasin Ni Won Fi Nofiu Adeyemi Joba Le Lori


Awon araalu Kukudi ati Obinrintin n’Ijaye ti kegbajare pe ki gbogbo agbaye gba awon lowo okunrin kan, Oba Nofiu Adeyemi Otunba, ti Alake fi joba ni abule kan ti won n pe ni Asasin, sugbon to n pe ara e ni Onijaye, eyi ti ko si ba ofin mu. Bee ni won lo tun fee maa je gaba lori awon ti won ki i sara ilu e, o fee ko won sabe e ni tipatipa.

Awon oloye ilu mejeeji ni won wa sileese Iwe Iroyin Yoruba to wa l’Abeokuta, nibi ti won ti waa fehonu han. Awon Oloye ti won wa naa ni: Oloye Rasak Adesola Obe to je Balogun Ijaye Kukudi; Oloye Adepoju Rasaki, Seriki Ijaye Kukudi; Oloye Kola Popoola, Lukotun Ijaye Kukudi ati Oloye Rasidi Ajakaye, Apagun-pote Ijaye Kukudi.

Awon oloye Ijaye Obinrintin tawon naa wa si ofiisi wa lojo naa ni: Oloye Asimiyu Ayinde Okeyale, Jagunna Ijaye Obinrintin; Oloye Musiliu Fatunbi Adeniji, Baala Ijaye Obinrintin; Oloye Sikiru Ojekunle, Seriki Ijaye Obinrintin.Gege bi Iwe Iroyin Yoruba se gbo, lojo ketala, osu karun-un, odun 2011, nijoba ipinle Ogun, labe Gomina tele, Otunba Gbenga Daniel, fowo si yiyan Oba Nofiu Adeyemi gege bii Oba Asasin (Ijaye-Tuntun), eyi ti won lo ti bere si i lo ipo e latojo kejila osu karun-un odun 2011.

Sugbon si iyalenu awon, se ni okunrin yii ko pe ara e ni Olu Asasin ti won fi je bi ko se Onijaye.

Bee lawon oloye yii fesun kan Oba naa pe o n koja aaye re nipa bo se n wona lati maa pase ti ko nitumo fawon ti ki i se omo ilu e. Eyi to waa buru ju ninu awon esun Oba ohun ni pe se lo n lo awon olopaa lati fi maa dunkooko mo awon oloye naa, won ni ko sohun to fa eyi ju pe o ti sise olopaa ri lo.

Awon oloye naa te siwaju pe leyin to je Olu Asasin lo pe gbogbo awon omo Ijaye Kukudi ati Obinrintin sipade kan to waye l’Ojobo, Tosde, ojo kewaa, osu kefa, odun 2011, nibi ipade yii gan-an ni wahala ti koko bere, nigba ti won ni Oba beere awon iwe ti Kukudi ati Obinrintin fi n sepade lati le je koun mo nnkan ti won n se lagbegbe won. Sugbon se lawon yen yari pe ko si nnkan to jo o nitori agbegbe awon yato si ibi to joba le lori, ko si lagbara koja ibi tijoba fi si, ati pe Asasin ni won pe e ki i se Onijaye.

Nigba ti Oloye Rasak Adesola Obe to je Balogun Kukudi Ijaye n ba oniroyin wa soro, o ni ni nnkan bii odun 2007 lawon ara Ijaye ko leta si Alake tile Egba, Oba Adedotun Gbadebo pe awon Ijaye naa n fee oba gege bii Onijaye, sugbon Kabiyesi so fun won pe oun ko le fun won ni Onijaye nitori pe ko seni to ti i joye naa latigba ti won ti de Abeokuta, o ni kaka bee, ki a koko loo je Baale, to ba ya oun yoo fun wa nigbeega.

Ko pe si akoko naa lo ni won fi Nofiu Adeyemi je Baale Asasin, ko too di pe ijoba Alake fun un ni igbega si Olu Asasin. Okan lara abule to wa ni Ijaye, afi bo se waa so ara e di Onijaye ni ko ye awon, to waa fee maa fi tipatipa joba le awon lori.

Balogun Kukudi naa so pe oun ranti pe lojo ti Alake fi Nofiu joba, o te e mo on leti pe ibi ti akoso e mo ko koja abule Asasin. Pabambari e ni bo se ni Oba naa fi olopaa mu oun ati Lukotun Kukudi, Oloye Kola Popoola, lori esun pe awon ran apaayan soun lati pa oun.

O ni bi ko ba se opelope Olorun, o ku die ko lo ola pe o ti sise olopaa ri le awon lori, sugbon tawon agbofinro to gbo ejo naa sise takuntakun, ti won si ri okodoro oro. Koda o ni titi di akoko yii, ko ti i deyin leyin awon, o si fee maa lo agbara le awon lori.

Bakan naa ni gbogbo awon oloye lati Obinrintin to ba oniroyin wa soro fi aidunnu won han lori iwa Oba Adeyemi naa, won ni ko yee pe ara e ni Onijaye mo.

Lati le gbo tenu Oba ti won fesun kan naa ni oniroyin wa se pe e sori foonu re, sugbon kaka ki Oba yii fun wa lesi, nise lo n pariwo, to si n hale mo wa pe ti a ba gbe iroyin naa jade, oun yoo gbe wa lo sile-ejo. O tun so pe oun ko ti i setan lati ba wa soro, ati pe ti akoko oro ba to, oun yoo ranse si wa.

Suuru ti akoroyin wa fi ba Oba yii soro lo mu un wale, sugbon Kabiyesi naa ko yee pariwo soro, ohun to so ni pe lara awon oloye ohun n gbero lati pa oun, eyi to ni ejo won si wa ni Eleweran.

Lori bo se n je Onijaye, alaye to se ni pe awon baba nla oun lo n je Ade Onijaye, awon lo gbe ade wolu Ijaye, bee loun si letoo lati je e. Sugbon titi di akoko yii, Oba naa ko pe wa fun oro to seleri pe oun fee so.

Oniroyin wa tun de aafin Alake tile Egba, okan lara awon agbenuso Oba naa so fun wa pe oro naa da bii igba t’Oba Nofiu Adeyemi ba koja aaye re ni. O ni loooto Olu Asasin ni Alake fi je, koda Kabiyesi te e mo on leti pe ipo re ko koja Asasin to wa.

Bee niwadii wa tun gbe wa de ileeese to n ri soro ijoba ibile ati oye jije nipinle Ogun, eyi to wa lofiisi Gomina niluu Abeokuta, ohun ti won so ni pe loooto lawon Ijaye tako bi Oba naa se n pe ara re ni Onijaye, sugbon a gbo pe won ni Komisanna ti pe e, o si kilo fun un pe ko yee pe ara re ni Onijaye nita gbangba mo.

Titi di akoko ti a n ko iroyin yii jo, Onijaye ni Oba Nofiu Adeyemi si ko si ara okan lara awon moto e to n gbe e kiri, eyi.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, March 30 @ 05:30:20 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Ikoja Aaye Kan Ree O: Won Ni Abule Asasin Ni Won Fi Nofiu Adeyemi Joba Le Lori" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: