Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo
[ Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo ]

·E Waa Wo Simia To Pa Oree Re L'Osogbo o
·Nitori Foonu, Baale Ile Meji Jabo Sinu Konga, Loju Ese Ni Won Ku
·Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
·Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
·O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
·Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
·Grace Atale Re Pa Oko e N'Iyana-Ipaja
·Oro o, Iku Gbigbona Leleyi o! Nibi Ti Johnson Ti n Taja Loju Titi L'Akure N
·O Ma Se O! Dauda To n Tun Redio Se Gan Mona L'Osogbo

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Eyi Ni Bi Won Se Sinku Agagu Atawon Ohun To Sele Ki Won Too Sin In
 
 
Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere
Lati Owo Solomon Adewoye, Akure

Eyi Ni Bi Won Se Sinku Agagu Atawon Ohun To Sele Ki Won Too Sin In


Gbogbo eto lo ti to lojo naa, awon ti won fiwe pe ti de, bee ni gbogbo ileese redio mereerin to wa nipinle Ondo ti n pariwo ikede isinku Oloogbe Agagu, eyi tawon oloselu atawon elegbejegbe sanwo fun. Gbogbo awon ore ati ojulumo re si ti pe sibi gbagede ominira to wa niluu Akure.

Gomina ipinle Ondo, Dokita Olusegun Mimiko atiyawo re, Olukemi, ti wa ni papako-ofurufu ilu Akure lati tewo gba oku Agagu. Awon komisanna, awon asofin, to fi mo awon omo egbe oselu PDP ni won ti wa nibe. Koda, iyawo Agagu, Arabinrin Olufunke Agagu atawon omo re obinrin meji, Solape ati Omowumi ti wa nikale ni papako- ofurufu ohun pelu aburo oloogbe toruko re n je Femi Agagu.Awon igbimo eto isinku tijoba sagbekale re ni won kuku seto naa, bee ni gbogbo eto si ti to l’Ojobo, Tosde, ose to koja yii, olorin ti n korin, bee ni won ti pin iwe eto fawon to ti wa nijokoo lojo naa, sugbon sadeede niroyin ibanuje kan wole wa. Ki lo sele? Ko seni to le so.

Lojiji ni Gomina Olusegun Mimiko gba ipe kan lori aago re, oju-ese loun atiyawo re wonu moto lo, ti won si pada sile ijoba. Ka too wi ka too fo, lokookan ejeeji lawon eeyan bere si i fi papako-ofurufu naa sile, titi to fi mo iyawo atawon omo olokuu.

Ki lo waa sele gan-an nibeere topolopo awon to wa nibe ti ko ti i mo ohun to n lo nigboro Eko n bi ara won, idi si ree ti onikaluku won se n pe ilu Eko lati mo ohun to n sele ni pato.

Bee lopo n sare wo ero ayelujara to wa lori foonu re lati mo idi tawon eeyan se n fi papako- ofurufu ohun sile lai dagbere fenikan. “Haa! Ijamba nla ti sele, ko gbodo je bee, iroyin buruku leyi o. Haa, haa, haa! Awon meloo lo wa nibe, se gbogbo won ti ku ni. Bawo lo se sele gan-an”, nigbe to n tenu awon eeyan to ri ohun ti won ko sori ero ayelujara n pa kiri pe oko-ofurufu Associated to n gbe oku Gomina ana yii bo ti ja lule, bee lo je pe awon eeyan ogun lo wa ninu re.

Ka too seju peu, ko seeyan kankan ni papako-ofurufu naa mo. Gbagede ominira ti won ti fee seye ikeyin fun Agagu ti sofo, awon olorin ko le korin mo, awon oniroyin to fee gbeto naa safefe ko si le sise mo, nise ni gbogbo eeyan bere si i pe lotun-un, ti won n pe losi, awon kan jokoo ti ero ibanisoro won lati fi wo ohun to n sele. Afi bi iroyin ti gba ilu kan pe oko baalu to n gbe oku bo ti ja lule l’Ekoo, lesekese niroyin yii kan ka gbogbo ilu Akure, bee lariwo ekun n so ni gbogbo ona; ati eni to feran Agagu, ati eni ti ko feran e lo n pariwo iru ki leleyii! Nise ni Mimiko bu sekun gbaragada nile ijoba, iru iroyin ibanuje wo leyi. Awon eeyan ogun lo wa ninu oko baalu naa, sugbon ko seni to mo oruko gbogbo won, nise lawon eeyan bere si i so orisiirisii oro, bee lawon kan n daruko awon to see se ki won wa ninu e.

Ki lo de ti won ko fi moto gbe oku re? Bawo lo se je pe laarin iseju kan ti baalu naa gbera lo ja lule? Eyi lawon ibeere topo eeyan n beere, sugbon ti won ko ri enikeni dahun si. Ati paapaa, Gomina ana nipinle Ondo ni Agagu, bee lo ti se Minisita foro ohun amusagbara ati oko-ofurufu ri, fun idi eyi, won gbodo pon oku e le daadaa lo se je ki won fi baalu gbe e lawon mi-in woye.

Gbogbo ilu dake roro, nise lawon eeyan pe si ofiisi PDP to wa lopopona Oyemekun, niluu Akure. Wahala ti de, isele ajalu nla ti sele, opo n so pe Gbenga Obasanjo wa ninu isele naa, won ni akobi Agagu, iyen Feyi, to tun je okunrin kan soso ti oloogbe naa bi wa ninu isele ohun, eyi lo tun da awuyewuye miiran sile. Bawo wa la se fee mo awon to wa ninu isele yii gan-an? Gomina Mimiko to wole lo pelu ipe orisiirisii to n gba ni oogun buruku bo, toju e si ti pon pelu ibeere lenu e pe, ‘Iru ki leleyii Olodumare.’ Leyin wakati kan niroyin gba igboro kan pe Feyi Agagu ati Deji Falae to je omo Oloye Olu Falae wa ninu oko baalu naa, pelu awon molebi atawon agbokuu jo.

Leyin naa niroyin tun de setiigbo awon eeyan pe gbogbo awon eeyan merin tijoba ipinle Ondo ran lo s’Ekoo lati tele oku pada wa siluu Akure lo ti dagbere faye. Awon merin naa ni: Deji Falae, Komisanna feto asa ati igbafe< Daji Olayiwola Bernard, lara awon to n ri si wole wode Gomina Mimiko; Deji Afolabi ati Arabinrin Alabi, awon mejeeji yii ni asoju ijoba ipinle Ondo lori eto ilu niluu Eko (Liaison Officer).

Nise ni Gomina Olusegun Mimiko tun bu sekun gbaragada nile ijoba. “Elo, Bawo ni, se won si wa laye?

Deji ti ku, Daji nko@ Haa, aye o, aye o.” Eyi loro to jade lenu Gomina nile ijoba. Gbogbo awon osise re naa bu sekun, ko si seni to wa nile ijoba lowuuro ojo naa ti omije ko bo loju re, nise loju gbogbo won kore lowo, ko si serin-in lenu eni kankan won, paro nile ijoba da.

Nigba to maa se die, iroyin ajalu buruku ohun fi han pe Feyi to je akobi Agagu ati ana re ti won jo wa ninu oko baalu ohun ko ku, sugbon won farapa. Nise lariwo ta nibi ti gbogbo awon omo egbe oselu PDP wa lati ilu oludije sipo gomina lodun to koja, iyen Oloye Olusola Oke, bi won se gbo pe awon mejeeji wa laaye bayii ni gbogbo won fo soke fun ayo, ti won si n dupe. Asiko naa loju iyawo Agagu, Arabinrin Olufunke too wa sile die nitori iya naa ko mo bo se n se e mo ni gbogbo asiko yii. Bakan naa lawon omo e obinrin ko roju ara won lakooko ohun. Sugbon ni kete ti won gbo pe Feyi si wa laye ni won bere si i turaka die die.

Lowo irole, ni deede agogo marun-un ni Mimiko too loo tufo isele naa fawon obi Deji Falae, iyen Oloye Olu Falae. Dajudaju adanu nla lo je fun baba arugbo naa pelu boun atiyawo re ko se le soro senikeni rara titi ti akoroyin wa fi kuro nile re lowo aago meje ale.

Bo tile je pe Deji Falae ki i se akobi re, sugbon omo naa je okan pataki lara ogo idile ohun. Bee ni won tun kede iku Daji Bernard naa fun iyawo re atawon omo meta to fi sile saye lo. Kayeefi kan to waa sele ni pe posi ti won gbe oku Agagu si, ko si nnkan kan to se e nibi ti won gbe e si.

Nigba to si di owo aago mefa irole ni alaga egbe oselu PDP nipinle Ondo, Ogbeni Ebenezer Alabi, kede pe awon yoo te siwaju ninu eto isinku naa niwon igba tomo oloogbe si wa laye. Bee lo fi aidunnu re han sawon to ba isele ohun lo. O waa so pe nigba ti posi ati oku ko ti jona sinu isele ohun, awon yoo maa ba eto isinku naa lo.

Ohunto je ki eronpileeni naa jabo Ohunto je ki eronpileeni naa jabo Ko si eni to le so pato ohun to je ki eronpileeni naa jabo bee yen. Bo tile je pe awon araalu Iju-Odo, l’Ondo, niluu Olusegun Agagu so pe adura repete lawon gba ki aburu kan ma le sele lojo naa, ati pe bo ba se pe awon ko gbadura ni, ohun ti yoo sele iba ju bee lo, nise ni awon kan n so pe lara eronpileeni yii gan-an ni nnkan to fa wahala ohun wa. Won ni eru po ju lara re ni, eru to si po lo je ki ijamba naa tete sele si i nigba ti okan ninu awon injinni re baje.

Awon kan so pe ero ogbon lo ye ki baalu kekere naa ko, bo tile je pe ogun pere lo ko, sugbon epo to n lo to wa ninu e ti po ju eyi to ye ko ro sinu lo, eleyii je ki eronpileeni ohun ti fi segbee kan, nigba ti injinni kan si baje ninu injinni meji to ni, eyo kan to ku ko le gbe eru to wa ninu re, ohun to je ko fi segbee kan, to si ja lule niyen. Ati pelu, ero ti ko po yii naa lo je ko tete gbina, ti ina naa ko si se e wonu re laarin iseju kan bayii to bere. Ohun to si je ki opolopo awon ti won wa nibe jona ku niyen. Oku leleyii a bi ALAAYE?

?? Ohun ti awon eeyan ti won koko ri ana Agagu, iyen Femi Akinsanya n bi ara won leere niyen. Nigba ti eronpileeni naa n fi dugbedugbe to si jabo, ko tete gbina lesekese, o fere to iseju kan leyin to ti jabo ki ina too se lojiji, to si gba gbogbo inu baalu ati ayika kan, ti ko si senikan to riran tabi to le jade mo. Sugbon ni gbara ti eronpileeni naa gbera ni kinni kan sele to ya awon ti won wa nibe lenu.

Nise ni okunrin kan yo latinu eronpileeni naa, o si n rin lo taara sibi tawon eeyan wa, bo tile je pe ko mo ibi to n lo, o saa n rin lo ni. Loooto o ti farapa, eje si ti wa lara re, sugbon oju re ko jo teni to riran tabi to mo ibi to n lo, iyen lawon ti won duro se n wo o pe se eeyan ni abi oku to ku to si ji jade kuro nibe.

Ko pe rara ti okunrin naa jade ti ina nla se lara baalu naa, ti ko si tun seni to le jade mo. Igba ti won sunmo on ni won mo pe ki i se oku, won si sare gbe e digbadigba lo sibi ti won ti le toju e, nigba naa ni won si sese mo pe oko omo Agagu ni, Femi Akinsanya loruko re. Olorun funra re lo ko o yo.

Eyi ni oruko awonto wa ninu oko baalu naa: to wa ninu oko baalu naa: Feyi Agagu Femi Akinsanya Akintunde Joseph

Akeem Akintunde Tunji Okusanya Chijioke Duru Kingsley Amaechi Deji Afolabi Mrs. E.O. Alabi Daji Bernard Deji Falae Samson Hassan Olatunji Okusanya Awon osise oko baalu ohun osise oko baalu ohun osise oko baalu ohun Awako baalu, Kaputeni Yakubu atawon alabasise re bii> Saroh Elaiye (Amoju-ero) Oyinlola Ibrahim Felix Tatoye Owolabi Samson Bi a ti se n wi yii, oku to ku ninu baalu naa ti di meeedogun o, nitori enikan ti tun ku nijeta ode yii, ninu awon ti won n gba itoju, bee ni awon miin paapaa ko ti i laju latojo ti oro naa ti sele, won ko ti i mo ibi ti won wa rara. Sugbon nigba ti awon molebi ro oro naa paapaapa, won ni ohun to dara ni kawon ma da eto isinku Agagu duro, ki awon kuku sin oku re gege bii awon ti dajo tele, bo tile je pe awon ko ni i se e lalariwo mo. Bee

naa ni won si se.


Lojo ti won Lojo ti won sinku Agagu sinku Agagu sinku Agagu Lowuuro kutu ojo Jimoh, Fraide, ose to koja yii, ni won ti n kede re lori redio pe eto isinku oloogbe naa yoo pada waye gege bi won se pinnu, ti won si ro gbogbo eeyan, paapaa julo awon omo egbe oselu PDP nipinle naa lati peju-pese sibi ayeye ohun. Aago mokanla ni won fi eto isin si niluu oloogbe, sugbon aago meji ku iseju mewaa ni won too gbe oku Agagu de ileejosin St Paul Anglican Church to wa ni Iju-Odo, niluu re.

Iwadii fi han pe awon omo olokuu sese loo gba oku pada niluu Eko lowuuro ojo naa ni, bee ni won sese loo ra posi tuntun miiran lati fi gbe oku Gomina ana naa si. Ileese Bells to wa niluu Eko ati Akure lo pese posi alawo buluu ohun.

Lati nnkan bii aago mesan-an owuro lawon eeyan ti n tu jade lati lo s’Iju-Odo, lati loo bu ola ikeyin fun oloogbe. Awon omo e obinrin meji, Solape ati Omowumi ti wa nikale pelu iya won. Bee ni Femi Agagu to je aburo re naa ti wa nibe pelu awon molebi, ara ati ojulumo. Awon oloselu naa ko si gbeyin.

Inu ile Agagu kun fofo, ati ita e pelu. Se ile naa ko kuku tobi pupo, koda eeyan ko le mo pe ile Gomina nibe.

Ile ohun si fi iru igbe aye ti baba naa gbe nigba to wa laye han, nitori awon oloselu egbe e to wa ninu ile naa lojo yii so pe eyi tawon ko siluu awon ju mewaa eyi ti Agagu ko lo, nitori naa eeyan ti ki i se owo ilu basubasu ni.

Saaju ki won too gbe oku de ni awon molebi Agagu ti fi atejade kan ti aburo Agagu, iyen Femi Agagu, fowo si sita pe awon ba awon idile to padanu emi won ninu ijamba oko-ofurufu naa kedun lopolopo, ti won si so pe eto isinku Agagu yoo waye lai lariwo lo. Ati pe gbogbo eto tijoba ipinle Ondo ti se lori eto isinku naa lawon ti da duro lati le bu ola fawon to padanu emi won. Won ro awon eeyan lati se pele, ki won ma si yo ayo ayoju rara nitori awon fee se oku naa ni bonkele ti ko ni i la ariwo kankan lo rara ni. Sugbon dipo bee, ese ko gbero ni Iju-Odo rara. Ti ki i baa si se ijamba to sele ni, ko seni to le so bi ero yoo se po to lojo naa.


Awon Gomina ana nipinle Osun, Ekiti ati Ogun ti wa nikale nile Agagu pelu awon oloselu miiran ti gbogbo won si n takuroso lori isele ijamba to sele naa ati oro egbe won.

Nigba ti yoo fi di aago mokanla ti won fi eto si, inu ileejosin naa ko gba eeyan mo, koda nise lawon eeyan duro si gbogbo oju ferese ijo naa lati le foju won gan-an-ni ohun to n lo nibe. Niwaju soosi naa ni won gbe iboji ti won yoo sin Agagu si. Nigba to di aago meji ku iseju mewaa ni won gbe oku re de, ti isin si bere ni pereu lai fi akoko sofo rara.

Eni-Owo Joshua Ebunoluwa Ogunele lo waasu lojo naa. Okunrin naa so pe o ye kawon molebi Agagu maa dupe pe Olorun ko won yo ninu ijamba oko baalu naa, ati pe to ba je pe oku yii ti jona ni, ko ni i seni ti yoo wa sibi isinku ohun rara. O juwe igbe aye Agagu gege bii eni ti ko wa ile aye moya rara nitori pe ko jo awon oloselu kan to je pe owo ilu ni won n ko pamo. O ni ti Oloogbe ba wa lara awon eeyan bee, gbogbo owo ati ile to ni ni yoo di ti elomiran nitori won ko ni i ko won lo sorun. O waa ro gbogbo eeyan to wa nibe lati maa lepa ijoba orun ju awon ohun aye lo, nitori ohun aye yoo ba aye lo, bee ni pe ko sohun ti a o mu lo sorun ninu gbogbo ohun ti a ba ko jo laye.

Ni deede aago meta aabo ni isin pari, ti won si gbe oku Agagu si koto. Nise ni omije gba oju gbogbo eeyan kan leyin ti won gbe e sinu ile lojo yii.

Opo awon oloselu lo peju sibe lojo yii. Ninu oro Aare Goodluck Jonathan, eni ti Minisita foro awon olopaa, Navy Captain Caleb Olubolade, soju fun, o juwe Agagu gege bii oloselu tooto to ti la ipa rere sinu oselu. Bee ni ise rere to ti gbe ile aye se ni ko seni to le gbagbe laelae. O waa ba awon idile ati ipinle Ondo kedun isele ijamba ohun.

Die lara awon to wa nibi eto isinku naa ni: Olagunsoye Oyinlola, Segun Oni, Alao Akala ati Gbenga Daniel, ti gbogbo won je Gomina ana nipinle Osun, Ekiti, Oyo ati Ogun. Minisita fun eto imo nipa awon ohun eelo iroyin, Arabinrin Mobolaji Johnson, awon asofin, atawon oloselu miiran ni won wa nibe.

Mimiko kede ojo meta fun aawe ati adura Mimiko kede ojo meta fun aawe ati adura Gomina ipinle Ondo, Dokita Olusegun Mimiko kede aawe ati adura fun odidi ojo meta nitori isele ijamba oko baalu naa to pa awon osise ijoba ipinle Ondo merin. Mimiko so eyi di mimo lakooko to n ba awon olugbe ipinle Ondo soro lori redio ati telifisan lori isele buruku ohun. Gomina naa so pe asiko ati sunmo Olorun niyi, ki awon si gbadura gidi ki iru isele bayii ma se waye mo.

Bee lo dupe lowo gbogbo awon omo orile-ede Naijiria fun biba ipinle naa daro awon eni rere to lo.

Se saaju nijoba apapo ti ran Minisita fun oro awon olopaa, Navy Captain Caleb Olubolade, lati waa sabewo si Gomina loruko Aare Goodluck Jonathan, bee ni abenugan awon omo ile igbimo asoju-sofin l’Abuja, Ogbeni Tambuwal naa wa lati ba ipinle Ondo kedun, to si jejee ipinnu ijoba lati wadii isele naa.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, June 08 @ 20:02:40 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· EsinIslam Media Yoruba
· Ekunrere Nipa Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere:
Oye Okere Tilu Saki, Ile-ejo Ni Mogaji Ko Gbodo Gbe Igbese Kankan Bayii


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

"Eyi Ni Bi Won Se Sinku Agagu Atawon Ohun To Sele Ki Won Too Sin In" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: