Gbagede Yoruba
 



Owo Olopaa Te Dimeji To N Ji Okada
 
Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Owo Olopaa Te Dimeji To N Ji Okada

Nnkan ko senuure fun omokunrin eni odun mokandinlogbon kan, Oladimeji, towo awon olopaa te lori esun idigunjale, oro to si n ti enu e jade n se awon eeyan ni kayeefi.

Dimeji ni nitori enikan ti ja oun lole ri loun naa se gbodo di adigunjale ki oun le gbesan oro ti won da oun, sugbon o gbagbe asayan oro awon agba pe oro to o da mi ni mo da o ni ki i je ki oro tan nile. O ni iru iwaasu bee ko si ninu iwe owe toun, owe kan soso toun mo ni pe bi adie da oun loogun nu, oun yoo fo o leyin, bi adie ohun ko ba ye eyin, oun yoo fo ti adie mi-in di i lai mo pe atimole olopaa ni ero buruku bee yoo gbe e de.Ise okada ni Oladimeji n se nigba kan ri, sugbon lojo kan lole da a lona to si ji okada naa gbe mo on lowo.

Lati ojo naa ni jagunlabi ti pinnu pe oun ko ni i sise mi-in mo laye oun, afi ise ole, ko si si nnkan mi-in ti oun yoo maa fipa gba lowo awon eeyan ju okada.Yoruba bo, won ni eni ti yoo ba sowo ale, dandan ni ko ra eni atin-in. Ko pe ti okunrin to pera e lomo bibi ilu Ogbomoso yii bere ole jija lo wa ibon ilewo kan, n lo ba kuku sora e di adigunjale loju paali nitori bi ibon se te e lowo lo tun mu awon ole peepeepe mi-in mo on, bii ko deede ja wo ibi ti awon omo ileewe LAUTECH l'Ogbomoso ba po si, ko si fibon gba ero ibanisoro won pata.



Bi Dimeji se n fibon gba okada, to n gba owo ati ero ibanisoro ree ti owo palaba e fi segi laipe yii nigba ti oga awon olopaa to n gbogun ti idigunjale (SARS) ni ekun Oyo si Ogbomoso, DSP Olusola Aremu atawon omo e deede loo ka a mo ibi to ti n jaye ori e l'Ogbomoso leyin ti won ti ri eni ta won lolobo.

Nigba to n dahun ibeere awon oniroyin ni olu-ileese olopaa ipinle Oyo to wa ni Eleyele, n'Ibadan, okunrin olokada to sora e di adigunjale osan gangan ohun salaye idi to fi so ole jija dise.

O so o di mimo pe, "Mo gba masinni ti mo fee fi maa sise okada pelu adehun lati maa sanwo diedie, nise ni won si gba a lowo mi. Enikan to dibon bii ero to ni ki n gbe oun lo sibi kan lo gba a lowo mi; mo kan waa ro owo san lori nnkan ti ko wulo fun mi ni. Ati san owo okada yen nira fun mi gan-an, iyen lemi naa se pinnu lati maa da awon eeyan loro ti won da mi."Gege bo se salaye ona to n gba sise to lodi sofin naa, o ni, "

Mo maa n da awon olokada duro, ma a ni ki won gbe mi lo sibi kan. Ta a ba ti de adugbo to ba da, to je pe ko si eeyan nibe, ma a yo ibon si olokada yen, ma a si ni ko mu kokoro okada re wa."Ni ibamu pelu ibeere akoroyin wa, paapaa nipa ibi to ti ri ibon, okunrin eni odun mokandinlogbon naa dahun, "Okada merin ni mo ti gba, ore mi kan ti a n pe ni Jesu lo fun mi nibon yen. Ibon yen naa ni mo fi n jale l'Ogbomoso, ohun ni mo fi n gba foonu lowo awon omo ileewe LAUTECH. Inu kilaasi ni mo ti maa n loo ba won ti mo si maa gba foonu won."Nje ki lo n fi awon okada to ba ji gbe se, Oladimeji ni oun ta meji, bee loun n lo meji yooku.

O ni awon toun ta yen, oun tu won pale ni, oun waa ta awon eya ara won.Lojo Isegun, Tusde, to koja ni DSP Olabisi Okuwobi-Ilobanafor ti i se Alukoro ileese olopaa ipinle Oyo fi oju afurasi-adigunjale naa han gbogbo aye nipase awon oniroyin l'Eleyele, Ibadan, ti i se olu-ileese won.

O fi da awon to wa nibe loju pe laipe ni Oladimeji yoo foju bale-ejo. O ni oga agba awon olopaa nipinle Oyo, Mohammed Indabawa ti bere eto lati pe okunrin naa lejo

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, June 08 @ 21:02:40 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue:
O Ga O! Awon Olopaa Ati Adigunjale Fibon Para Won Loju Ija Niluu Ibadan: Awon Ol


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue



"Owo Olopaa Te Dimeji To N Ji Okada" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com