Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose
[ Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose ]

·Won Ni Akeem Pa Sajenti Opeyemi Iyawo Re, O Ti N Se Faaji Lewon Bayi
·Eyi Ni Bi Pasito Se Gbe Majele Je Ni Ipinle-Ogun
·Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
·Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
·Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
·Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
·Orekunrin Bukola Fee Fi i Soogun Owo N'Ibadan
·Nitori Wahala Ojoojumo, Igbeyawo Odun Mefa Tuka L'Osogbo
·Won Ti Ran Oga Ileewe To Fipa Ba Akekoo Re Lo Po Lewon Odun Mewaa L'Ekiti

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Nje Ija Ooni Ati Alaafin Le Pari Laye Yii Bi? (Apa Keji)
 
 
Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere
Lati Owo Adewale Adejare

Nje Ija Ooni Ati Alaafin Le Pari Laye Yii Bi? (Apa Keji)


Lori oro ti mo bere lose to koja yii orisiirisii idasi ni mo gba, ona ti kaluku kan fi da soro naa lo yato ni. Inu mi dun fun kinni kan, iyen naa ni pe opolopo awon ti won da soro yii ni won gba pe ni tododo, awon Oba meji ti oro won se pataki ju naa ni Ooni ati Alaafin, ti won si gba pelu mi pe iti ogede lasan ni oro Awujale ati Oba Eko, ko to ohun teeyan yoo maa lo ada si rara. Bi aarin Ooni ati Alaafin ba ti gun rege, ohun to ku yoo see se, nitori awon oba to ku yoo maa tele won.

Sugbon oro naa ko ye awon mi-in, ohun ti won n so ni pe ki lawon oba wonyi le se, awon oba wonyi gan-an ni isoro wa, ki a pa won ti ki a yan asaaju, bi a ba ti yan asaaju fun Yoruba, o pari niyen. Oro ti awon wonyi naa so ye mi, nitori mo mo pe ibi ti oro ye awon paapaa de, ati bi oro naa ti ka won lara to ni won fi n soro ti won n so. Sugbon awon kinni kan wa ti a gbodo mo.

Akoko ni pe awon oba ti a ri yii ni ami-idanimo akoko fun Yoruba, bi a ba ti yowo ede ti a n so lenu. Nibi ti nnkan ba ti dara, oba to ba je lo ye ko ko asa ati imo awon eeyan re dani, oba ti ko ba ti le se eleyii ko ye ni oba rara ni. Ni ile Yoruba yii si niyi, boya a fe, boya a ko, Ooni ati Alaafin ni asaaju awon oba wa. Awon wonyi lo ye ki agbara ile Yoruba wa lowo won, nitori lati igba iwase, agbara Yoruba ti wa lowo won ri.Oduduwa ni ipile isokan Yoruba, ipo Oduduwa si ni Ooni wa yii, bee ni fun opolopo odun, Alaafin ni opomulero to di isokan yii mu laarin Yoruba gbogbo. Bi ko ba si ipile (Oduduwa), ko ni i si opomulero (Alaafin), bee ni bi ko ba si opomulero yii, o see se ka ti gbagbe Oduduwa paapaa. Ohun ti ipo Ooni ati ti Alaafin se se pataki ju ti gbogbo oba to ku lo nile Yoruba niyen.
Awon ti won n daruko awon oloselu ko ro arojinle nipa ola. Awon ti mo n wi ni awon ti won n te atejise ranse si mi pe oloselu lo le se asaaju Yoruba, oun lo le to wa sona, ti awon kan ninu won si fee ma ba mi ja nitori oro Bola pe ona ti won n gba loni-in yii lo ti dara ju, ninu awon ti won jo wa nibe yii lo ye ka gbe asaaju fun, ki emi ma fi ote ba ohun to n dara je, eni ti Olorun fe ni Olorun yan, Bola ti di asaaju Yoruba boya emi fe boya emi ko.

Gbogbo enu ni mo fi so o pe awon wonyi ko mo kinni kan rara. Omo kekere ri owo odun kan, o ni oun yoo bere si i pa eran ileya, se o mo bi odun to n bo yoo se ri ni. Bi awon Bola atawon ti won n tele won ba ni oni, ta lo mo awon ti won yoo ni ola. Nile Yoruba nibi, sebi loju wa ni agbara se wa lowo Obafemi Awolowo, sebi agbara naa bo sowo Akintola fungba die, se awon eeyan ko ranti mo ni.

Tabi awon eeyan ti gbagbe pe agbara Western Region ti won n pe ni South West bayii ti wa lowo Adeyinka Adebayo ri, to se pe ko si enikan ti i da oka re ko bi gbogbo ile Yoruba yii ti to. Boya ni eni kankan tile ranti mo pe ko sibi kankan ti won ti jokoo ti won ti yan Obafemi Awolowo ni asaaju Yoruba, Asaaju ti won n pe Awolowo, nipase Adeyinka Adebayo ni. Lasiko ti ogun abele fee bere, gbogbo awon eeyan to wa ni Naijiria ni won sepade, ki kaluku le mo iha ti yoo ko soro ogun naa, bee ni won si n yan awon asoju ti yoo maa lo sipade gbogbo ti Naijiria ba fee se. Ipade igbimo yii ti ile Yoruba ni Adeyinka Adebayo pe s’Ibadan lojo kejila, osu kejo, odun 1966, bo si ti soro to fi si ipade naa tan lo dide to ni ki awon omo igbimo naa yan alaga won ti yoo maa saaju won lo sipade gbogbo, awon ti won wa nibe si yan Obafemi Awolowo.

Mo fe ki e wo kinni kan ninu oro yii o, ki i se igba ti Awolowo n se olori ijoba ni won yan an bii asaaju yii, rara, o ti kuro nibe, bee ni ko ti i di minisita ninu ijoba Gowon paapaa nigba ti won fi mu un. Ohun ti won so ni pe ki i se igba ti agbara oselu ba wa lowo enikan ni won n yan iru eni bee sipo tabi ti won n fi eni bee joye, awon to ba se bee, alatenuje lasan ni won. Idi ni pe igba kan n lo igba kan n bo ni oro ile aye yii, eni to ni oni ko ni yoo ni ola, iwa ti opo eeyan si n hu nigba ti won ba n wa nnkan yato si eyi ti won yoo hu bi kinni naa ba te won lowo tan.

Sugbon kinni kan ni ko le pare titi ti aye yoo fi pare, iyen naa ni iwa. Bi eniyan ba je ologbon, onimo, to waa fi iwa omoluabi kun un, ko siru ipo ti tohun wa, tabi igba yoowu to wa nipo naa ti ko ni i se e daadaa. Iru eni ti mo n wi niyen.

Bi a ba n soro pe agbara oselu wa lowo Bola, nitori e la se gbodo mu un tabi ka mu ninu awon omoleyin re, awon omo Yoruba nla nla ti won ko soselu nko: Bode Akindele, Baba Gbonigi, Bisoobu Ladigbolu, Benjamin Adekunle, Alani Akinrinade, Wole Soyinka, Bolanle Awe, Adeyinka Adebayo ati awon omo Yoruba pataki bee. Bakan naa ni awon onisowo omo Yoruba kan wa ti a ko le ro seyin bi a ba fee soro eni ti yoo je asaaju ati bi Yoruba yoo se goke: Michael Adenuga, Oba Otudeko, atawon oworomasasa ati bee bee lo. Ki i se gbogbo awon eleyii lo feran oselu, bee gbogbo won ko ni won n wa leyin Bola, awon mi-in ko tile feran re rara. Eyi lo se je pe bi awon kan ba dide, ti won fi tipatipa so pe oun ni asaaju, awon kan ko ni i gba, won ko si ni i foribale fun un. Bakan naa ni bi eeyan ba mu Obasanjo to fi i se asaaju Yoruba loni-in, awon ota ati alatako ti yoo dide si i yoo le ni egbaagbeje.

Iyen lo se je pe awon ti won n kanju pe ka tete yan asaaju Yoruba, ka daruko enikan, oro naa ko ye won to ni. Bi a ba daruko enikan, ti awon eka to ku nile Yoruba, boya awon oloselu tabi awon onisowo tabi awon omowe onimo-ijinle ko ba fowo si i, eni naa ko ni i le pase fenikan, asaaju inu yara re lasan ni yoo si je, asaaju ti ko lase lenu. Koda, yeye lawon eeyan yoo maa fi i se, won yoo ni asaaju yin lo n lo yen! Nibi ti awon oba wa ti se pataki niyen, Alaafin ati Ooni. Bo ba je enikan la fee mu, koda ko je oloselu naa la fee mu, ti gbogbo Yoruba ba ni awon fowo si i, ti Ooni ati Alaafin si jokoo sibi kan ti won fa owo okunrin naa soke, tabi obinrin naa, ti won so pe asaaju Yoruba ree, ti won jawe le e lori tabi sebura fun un niwaju awon gomina gbogbo, ti gbogbo won si gba lati teriba fun un, iru asaaju bee ni mo n wi. Asaaju Yoruba gan-an niyen.

Ohun to se se pataki ki aarin Ooni ati Alaafin gun niyen. Se e ri i lasiko ti a wa yii, afi ka jokoo ka ba ara wa sooto oro lori oro ija Ooni ati Alaafin. Iwe kan wa to n da ile Yoruba ru, iwe ti Johnson ko to pe ni History of Yoruba ni. Iwe yii ni awon oloselu maa n lo julo nigba ti won ba fee da nnkan ru, iwe yii ni awon MKOAbiola hu jade lodun 1980, lasiko ija UPN ati NPN nile Yoruba, ati nitori pe won fee fi abuku kan Awolowo, won fee fi idi re remi. Gbogbo ija buruku te e ri laarin awon oba wa loni-in yii, asiko ti ija naa bere niyen. Kin ni Johnson so? Kin ni itan Yoruba so? Kin ni laakaye so? Awon ohun ti a oo yewo niyi, ka le tu idi ija Ooni ati Alaafin wo, boya iyen yoo seranlowo lati pari ija naa, ti ile Yoruba yoo si fi de ibi ti a fe ko de. Ki lo fa ija Ooni ati Alaafin? Ose to n ba la o bere si i salaye e funra wa.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, June 08 @ 21:24:42 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· EsinIslam Media Yoruba
· Ekunrere Nipa Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere:
Oye Okere Tilu Saki, Ile-ejo Ni Mogaji Ko Gbodo Gbe Igbese Kankan Bayii


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

"Nje Ija Ooni Ati Alaafin Le Pari Laye Yii Bi? (Apa Keji)" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: