Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Bunmi Ni Aje Lomo Lun, Lo Ba Le E Jade Nile L'Akure
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Iyiade Oluseye, Akure

Bunmi Ni Aje Lomo Lun, Lo Ba Le E Jade Nile L'Akure


Iyalenu nla loro ohun je lojo Isegun, Tusde, ose to koja, nigba ti Iwe Iroyin Yoruba ri omobinrin kan ti ko ti i ju omo odun meeedogun lo ninu ile akoku kan laduugbo Alakara, lojuna to lo s’Idanre, lagbegbe Oke-Aro, niluu Akure. Omobinrin yii pelu awon eru re bii aso atawon ohun eelo idana mi-in to n lo lo wa lodo re ninu ile ohun, bee la si ri pako gbooro kan to teso le lori to fi n sun nibe.

Leyin pe won fi paanu bo ile akoku naa lori, ko tun si aabo kankan to tun wa nibe, nitori pe ko nilekun, debii pe yoo ni ferese, gbayawu ni gbogbo re wa, eyi lo mu wa wonu ile naa lo lati foro wa omobinrin ohun lenu wo nipa boro se je gan-an.Ninu iforowero Iwe Iroyin Yoruba pelu Folorunso Oluwafunke, o ni oruko iya oun ni Orimoloye Bunmi, ti baba re si n je Folorunso Oluwafemi, eni to filu Eko sebugbe. Omobinrin ohun tesiwaju pe omo bibi ilu Owo, nijoba ibile Owo lawon obi oun. O ni odo iya oun loun n gbe ko too di pe o loo sewadii lodo awon wolii, aafaa ati babalawo, to si je pe oro kan naa ti won so fun un nibi meteeta ni pe bi ko ba le oun jade kuro ni sakaani re, oro ile aye e ko le nitumo, o leyii lo je ko le oun jade, ti ko si ro tojo ikunle mo oun lara. Funke to so pe oun je omoleewe Commercial Grammar School to wa l’Oke-Aro, l’Akure, bee lo ni oun pelu awon to n sedanwo oniwee mewaa (NECO) to n lo lowo, ati pe lati bii ose merin loun ti n gbe ninu ile akoku ohun, latibe naa lo si ti n loo sedanwo re.

Araadugbo kan lo ti koko loo foro naa to ileese olopaa B Division to wa niluu Akure leti, leyii to mu ki won ranse pe iya omo yii pelu omo re sagoo won boya won a le ri oro ohun yanju.

Gege bomo ohun se so, o lawon agbofinro naa be iya oun pe ko mu oun sodo, ko ma si se gbiyanju ati da oun pada sodo iya baba oun to n gbe niluu Owo, leyii to ni obinrin naa gba, to si seleri ati se bee, sugbon bi won ti pada dele lo ti so fomo re pe kaka ko duro sodo oun, majele loun a fi pa a, oro yii lo ba omode naa leru to tun fi sa jade, to si pada sile akoku naa.

Nigba t’Iwe Iroyin Yoruba koko debi isele ohun, aafaa kan toruko re n je Adeola la ba nibe to n gbiyanju lati fi okada gbe omo yii lo, nigba ti akoroyin wa si beere ibi to n gbe e lo, ohun to so ni pe awon olopaa lo so pe koun gbe e, nibe la ti beere eri ti yoo fihan pe loooto lolopaa ran an nise naa, bee la ni awon agbofinro naa ati iya e nikan lo letoo lati waa mu un kuro nibe.

Okunrin aafaa naa so pe iya re o le waa mu un niwon bo se wa latimole awon olopaa, sugbon nigba toro ohun dariwo ti gbogbo eeyan si ti pejo sibe lo mu ki aafaa sare pe eni to je iya omode naa, si iyalenu wa, kia lobinrin ohun ti okunrin yii lo wa latimole olopaa sare de, to si taku pe ko seni ti won bi daa to le so pe koun ma mu omo oun kuro nibe pelu epe randu randu to n fi bale. Bee lo woya ija pelu awon eeyan to wa nibe.

Ajo to n ri soro awon obinrin nipinle Ondo ti da soro naa bayii, won si ti tewo gba itoju omodebinrin ohun, eni ti won ti taari sile awon omo ti ko lobii to wa niluu Akure. Ajo ohun so pe afaimo keni to je iya omo naa ma foju bale-ejo lori esun lilo omo nilokulo leyin ti won ba pari iwadii won lori oro naa.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, June 26 @ 00:12:13 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Bunmi Ni Aje Lomo Lun, Lo Ba Le E Jade Nile L'Akure" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: