Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
[ Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu ]

·Iwosi Yii Si Ti N Po Ju Fun Yoruba, Ibi Ti Won Ba Wa De Ree O
·Bo Se Daa Niyen... Sugbon Kan Naa Lo Wa Nibe
·Bi Iro Ba Lo Logun Odun...
·Sebi Eyin Naa Gbo Ti Dino Melaye Ni Kogi
·Won Ni Alaga PDP Ku Sori Asewo N'Ipokia
·Awon Asofin Ni Kijoba Apapo Se Afara Elese Si Osodi-Apapa
·E Gbo! Kin Ni Fayose Wa Lo Si China?
·E Ko Sekeseke Si Won Lowo Jare
·Bee Ni Buhari Ko Wi Nnkan Kan

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Jinnijinni mu Aguiyi Ironsi atawon ti won jo n sejoba re, nigba tawon oba ile Ha
 
 
Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise
Lati Owo Akoroyin Olootu

Jinnijinni mu Aguiyi Ironsi atawon ti won jo n sejoba re, nigba tawon oba ile Hausa ko hilahilo ba a

Gege bi a ti n ba kinni ohun bo, awon kinni kan ti wa nile to n bi awon Hausa gbogbo ninu, atawon soja, atawon oloselu, atawon araalu paapaa, iyen ko too di ojo kerindinlogbon, osu karun-un, odun 1966, ti wahala bere fun ijoba soja Ogagun Agba Aguiyi Ironsi. Awon kinni kan wa to n bi awon Hausa yii ninu, nitori awon naa ti ri i, tabi won ro o lokan, won si gbagbo pe awon Ibo ko wa lati tun aye awon tawon je Hausa se, won fee ba a je pata ni. Eni to ba fee pa ni, a ki i sun asunpara ninu ile e, iyen lawon Hausa yii ti se n se awon eto gbogbo labele, ti won si ti n ba ara won soro ko too di ojo ti won bere ija yii. Ki i se ojo ti kinni yii bu gbamu lo bere, awon kinni kan ti wa nile tele, igba ti Ironsi ko si ri ona yanju awon nnkan wonyi, toun naa ko si huwa bii eni pe ki i se awon Ibo lo n ti i lo je kawon Hausa binu.

Ninu ijoba Ironsi, afi bii eni pe awon Ibo lo n se e ni, nitori awon Ibo lo fi yi ara re ka.Awon kinni kan wa to se pataki ninu ijoba ologun, iyen naa lawon eeyan ti won ba yi olori ijoba ka, atawon ti won ba fi se oga nidii ise ologun gbogbo. Awon ti won ba je oga ileese ologun gbogbo yii se pataki pupo nitori bi ko ba si tiwon, ko senikan to le gba ijoba tabi doju ijoba bee bole. Nitori pe awon wonyi ni olori-ologun gbogbo, awon ti won ba wa nibe gan-an lawon soja gba pe won ni ijoba. Ati nitori ti Ironsi gbe awon ipo yii fawon omo Ibo, won mo pe ko le soro fun un lati pa gbogbo Hausa run to ba fee pa won run, bee ni ko le soro fun un lati yo awon Hausa kuro ninu ise soja ti yoo si fi awon Ibo gbogbo se oga won.

Eleyii ko fi okan awon Hausa yii bale, nitori ohun ti Ironsi fee se gan-an ko ye won.

Ninu ijoba yii, iyen ninu ijoba Ironsi, eni to je bii igbakeji re, iyen olori olu ileese ijoba ologun ni Babafemi Ogundipe, leyin naa lo si kan Yakubu Gowon gege bii olori awon ologun ile, iyen soja. Leyin naa, awon omo Ibo lo ku to n je olori ileese ologun gbogbo.

George Kurubo ni olori awon omo-ogun ofurufu, Hilary Njoku ni olori awon omo-ogun ni Second Brigade, H. Igboba ni olori awon omo-ogun ni Second Battalion, G. Okon Weze ni olori awon omo-ogun Abeokuta Garrison, Major Nzefili ni olori awon omo-ogun Fourth Battalion, Major Ochei ni olori awon omo-ogun Eso Ijoba Apapo, Ogagun Bassey ni olori awon omo-ogun First Brigade, Major Okoro ni olori awon omo-ogun Third Battalion, Major F. Akagha ni olori omo-ogun Depot, nigba ti Muhammed Shuwa si je olori omo-ogun Fifth Battalion.

Bayii lo je ninu awon oga ologun metala ti won n sejoba, Yoruba kan soso lo wa ninu won, Hausa meji, ati Ibo mewaa. Bi won ti n se iyen lowo ni Ironsi se agbega fawon oga soja meeedogbon, won gbe won lati ipo Mejo (Major) lo si ipo Leftenanti Konel (Lt. Colonel).

Awon eeyan ro pe kinni naa ko dara to niru asiko bee, nigba ti ilu n sofo lowo, ti won ko ti i kede boya Balewa ti ku tabi ko ti i ku, ti won ko si ti i sejo awon ti won ni won fi ibon pa won. Sugbon iyen gan-an ko lo fa ibinu awon eeyan. Ohun to fa ibinu to po julo ni pe ninu awon meeedogbon yii, iyen awon meeedogbon ti won so di Leftenanti konel yii, mokandinlogun ni omo Ibo to wa ninu won. Iyen ni pe ninu awon meeedogbon, Ibo lo ko mokandinlogun, won fun Hausa ni marun-un pere, won si gbe omo Yoruba eyo kan soso ga.

Awon soja Hausa ti won gbe ga nigba naa ni: Hassan Usman Katsina, Joe Akahan, Muhammadu Shuwa, Muritala Muhammed ati Haruna Ibrahim. Yoruba kan naa lo wa ninu won o, Femi Olutoye loun. Bii igba ti Ironsi atawon ti won n ba a damoran ko mo ohun ti won n se ni. Abi nigba tijoba re se igbega fun soja meeedogbon, to je eyo Yoruba kan lo wa ninu won, ti Hausa je marun-un pere, tawon omo Ibo si je mokandinlogun. Ko tile waa je pe bi nnkan se ri ree, ko se pe awon soja Ibo yii lo kuku po to bee ti won si ni anfaani nla bayii, ko ye ko je iru asiko ti nnkan n gbona lorisiirisii ona bayii ni Ironsi yoo fowo si i ki won gbe Ibo mokandinlogun ga ninu awon oga soja meeedogbon. Bo ba sun kinni naa siwaju, ko se nnkan kan. Lara ohun to fa ibinu nile Hausa ree, nitori gbogbo ohun to n sele ni won n gbo.

Bee bi gbogbo eleyii ti n lo ni awon Ibo n fi awon Hausa gbogbo se yeye, bo je ninu ologun, bo si je laarin ilu, won n fi won se yeye pe Olorun ti mu won. Olorun lo mo awon ti won ya aworan kan ti won si n ha aworan naa kiri aarin oja ati ibi tawon Hausa yii ba ti po si julo. Aworan naa fi Sardauna Sokoto, Alaaji Ahmadu Bello han, o kunle, o n be Ogagun Nzeogwu to yinbon pa a, bee ni omi si n jabo loju Sardauna yii pelu lawani to gbe sori re. Aworan yii ni awon Ibo naa n gbe kaakiri, won yoo si maa le e mo ara moto ati niwaju ile won. Bee ile Hausa ni won n gbe o, bi omo Hausa kan ba si fee soro to n se bii alagbara, foto naa ni won yoo fi han an, ti won yoo waa fi ede Hausa so bayii pe “Shi ne maganin ku”, “Oko iya yin niyen,≈ tabi “Oun lo kapa yin!” Kinni kan tun waa wa tijoba Ironsi se fun won nile Hausa to ka won lara. Teletele, bi enikeni ba fee wo ise ijoba nile Hausa, won ko ni i je ko wo o bi ki i baa se pe tohun sedanwo ede Hausa, o si yege daadaa. Iyen ni pe ki won too gba enikeni si ise lodo won lohun-un, bo ba ti je ise ijoba, won yoo ri aridaju pe eni to gbo ede Hausa, to le ko o sile, to si le ka a ni, nitori opolopo ohun ti won n se lodo won, ede Hausa lawon fi n se e, ati pe won ko fe keni ti ki i baa se ara awon di oga le awon lori nibi ise ijoba awon. Ki awon oyinbo too lo ni won ti n seto naa, nigba tawon oyinbo yii si lo, won kuku tubo mura si i. Sugbon nitori pe eto naa di awon Ibo lowo gan-an lati le di olori ise ijoba lodo won leyin tawon oyinbo ti lo, won ko fe e rara, opolopo awon Ibo ni won si ti pada siluu won nitori e.

Bi nnkan won ti wa ree to si n lo deede ki Ironsi too de rara ni. Afi bi Ironsi si ti de to pase pe osise ijoba kan, tabi eni to ba fee wose naa ko gbodo sedanwo lede Hausa mo, beeyan ba ti gbo ede oyinbo, o ti pari, oyinbo ni kaluku yoo maa fi wose ijoba. Awon Hausa ko gboyinbo to bee, opolopo awon osise won ko si gboyinbo rara ni. Ohun ti eyi tumo si ni pe awon alejo, paapaa awon Ibo ni won yoo tun di oga ni ileese won niyi, awon ni yoo tun maa pase, ti awon ti won je omo oniluu ko si ni i rise se, tabi ti won yoo maa se omo- odo fun won. Ohun to kan Ironsi ninu pe ki awon Hausa ma fi ede won gba osise sise niluu won ko ye enikan, sugbon nigba to je awon omo Ibo ni oga nibe ki won too le won, ohun ti gbogbo awon Hausa ro ni pe Ironsi tun n ko awon Ibo to ti lo tele bo ki won waa maa se oga awon.

Awon ibinu orisiirisii to ti wa nile tele niyi ko too waa di igba ti Ironsi kede pe awon yoo tun pa gbogbo ipinle run, ko ni i si ipinle Hausa ati Yoruba tabi ti Ibo mo, awon yoo kan pin Naijiria sona marundinlogoji lapapo ni. Nigba naa ni awon Hausa yii ro pe Ironsi kuku fee pari eto gbogbo lati je awon niya, o fee fi iya je awon loooto ni. Eyi lo fa a to se pe bi won ti se kirun Asubaa won tan laaaro ojo kerindinlogbon, osu karunun, odun 1966 yii, ariwo lailaa lo gba gbogbo ilu nla nla nile Hausa kan, ko si senikan to le duro wo kinni ohun, nitori ero to ro jade po ju awon ti enikeni le da duro lo. Bi won ti n foju kan ile awon Ibo ni won n dana sun won, omo Ibo yoowu ti won ba si ri lona, pipa ni, ko soju aanu fun won. Bi won se n kolu won ninu soobu won ti won n pa won, bee ni won yoo tun keru won lo ni repete, ti won n dana sun won. Oja Kano to je nibe ni awon Ibo po ju si, nise lawon onija naa ya wo ibe, won si da soobu awon eeyan naa ya soto, won sun gbogbo e kanle bamu, won si keru towo won te lo.

Ona ti kinni naa gba wa fi han pe ki i se awon Hausa nikan ni won pete kinni ohun paapaa. Ki ijaagboro naa too bere, asoju ijoba ibile geesi ni Naijiria nigba naa, Ogbeni Francis Cummings-Bruce, ti lo sile Hausa lohun-un, bee lo se orisiirisii ipade pelu awon eeyan nibe, idi ipade re ko si ye enikan, paapaa nigba to je pe Ironsi sese sofin pe ki won pa gbogbo ipinle re ni. Awon eeyan ti won mo idi oro so pe ori irin-ajo tokunrin oyinbo yii lo pelu ohun to je ki ijaagboro naa bere, ko si le to bo se le to yii, won loun lo so fawon asaaju Hausa pe bi won ko ba ja lasiko naa, a je pe Ibo yoo so won deru ni Naijiria ni. Oun nikan si ko o, awon oluko kan wa ni Yunifasiti Ahmadu Bello ti won sese da sile nigba naa to je oyinbo ni won, awon naa ni won n ko awon Hausa yii ni ona ti won yoo gba, ti won si te iwe jade lede Hausa lati so pe ki awon eeyan naa dide ki won gbeja ara won.

Gbogbo eleyii lo je ki kinni naa sise bee, nitori bi won ti bere ni Kano, ko pe to fi wo Kaduna, bee lo de Zaria, gbogbo ile Hausa si gbina. Ohun to ya awon oga ologun ti won je Ibo lenu ni pe Hassan Katsina ti i se gomina nibe ko se ohun to ye ko se. Won ni nigba tija naa koko bere, to ti han pe apa awon olopaa ko ka a, awon ologun to wa nibe ni ki Katsina ko soja jade, nitori ko sohun ti Hausa tun beru bii soja laye yii, won beru ibon won, bi won ba ti ri ibon naa ni won yoo sa lo pata. Sugbon Katsina loun ko le pase ki soja jade, oun si n seto kan, oun fe kawon olopaa tubo sise owo won. Bee awon olopaa ko doju ija ko awon ti won n jijaagboro naa, koda awon naa tun n ba won lowo si i, won jo n lu awon Ibo ni, won si jo n ba dukia won je ni, nitori pupo ninu awon olopaa naa, olopaa ibile ni won, Hausa ni gbogbo won.

Bee lo se pe lati aaro ojo kerindinlogbon tija naa ti bere, to si feju repete lojo kokandinlogbon, gomina ile Hausa ko ko awon soja jade, afi nigba toro naa bo sori pata, ti awon ti won fee paayan ti paayan, ti won si ti ba awon ohun ti won fee baje pata je tan, igba naa lo pase pe ki soja jade, awon soja si jade, won le awon onija to ku lo. Sugbon nnkan ti baje koja aala, o ti baje koja atunse. Opolopo awon omo Ibo atawon Yoruba mi-in ni won ti sa kuro nile Hausa, won sa pada lo siluu won, won ni o daa ju ki emi awon o ba kinni naa lo.

Loooto si ni Gomina Katsina sofin ki onile-gbele, tofin koofiu de gbogbo eeyan mole, sugbon bija naa ti koja bee, o ti je ki nnkan baje ko too se e, ko si sohun meji to fa eleyii ju pe oun naa mo nipa e, gege bi awon kan ti wi, won ni won so fun un daadaa.

Nigba toro ri bayii, idarudapo sele l'Ekoo naa, okan Ironsi ko si bale rara. Ki la o ti se eleyii si, ijoba ma fee fo mo oun lori ree, won ni bo ti n ronu niyen o. Se Katsina lo si pase fun un pe ki iyen pe gbogbo awon oba ile Hausa jo, ki won sepade, ki won si mo bi won yoo ti se wa opin si kinni naa ti iru ija bee ko fi ni i sele mo rara. N lawon oba ile Hausa ba pade o, ni won ba sepade laarin ara won. Oba Sokoto wa nibe, oba Kano wa nibe, atawon oba to lenu nile Hausa gbogbo. Sugbon ohun ti Ironsi ro ko lo sele nibi ipade won yii, ki i se ohun toun fokan si ni awon oba wonyi se. Kaka ki awon oba Hausa sepade lori oro to wa nile ati bi alaafia yoo se pada wa saduugbo won, nise ni won fun Ironsi ni gbedeke, won ni ti ko ba pa ofin to sese se yii re, iyen ofin to fi pa awon ipinle run yii, ti ko ba pa ofin naa re kia, kekere ni wahala to sele yii o, ohun ti yoo sele yoo ju bee lo fun un.

Awon oba Hausa wonyi ni ohun tawon ko ni i gba, awon ko ni i gba a ni, awon Hausa ko fe ofin naa, afi ki Ironsi yi i pada kia, bi bee ko, nnkan mi-in yoo sele o. Dajudaju, ki i se awon oba yii lo n soro, awon ti won wa nidii oro naa ju awon ti Ironsi n ri nita gbangba. Isoro wa fun ijoba Ironsi, bo ba gba ohun tawon oba yii wi, a je pe ijoba re ti subu niyen, enu ki awon Hausa wonyi maa da wahala sile bi ofin kan ba jade ti ko te won lorun ni, bi ko ba si gba ase tawon oba yii pa wole, o daju pe won yoo tun da wahala mi-in sile fun un, o si see se ki ijoba re ma le bo ninu wahala tuntun naa. Bayii ni Ironsi ko si idaamu, ko si tete mo ohun ti yoo se. N lo ba sare pe awon ojogbon jo lorisiirisii, awon naa si jokoo, won n ronu ohun ti Ironsi yoo se. Ki logaa ologun naa waa se o? O dose to n bo!

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Tuesday, April 28 @ 00:29:35 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise:
Orin Ewi ni Yoruba - Yoruba Poems: Awon Owe Yoruba Proverbs Alo Oro


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

"Jinnijinni mu Aguiyi Ironsi atawon ti won jo n sejoba re, nigba tawon oba ile Ha" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: