Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Ofo-emi kan re o! Won yinbon pa Jeje n'Ijoko Ota
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Akoroyin Olootu

Ofo-emi kan re o! Won yinbon pa Jeje n'Ijoko Ota

Ariwo ikunle abiyamo o lawon eeyan to n gbe laduugbo Sawmill, n'Ijoko, niluu Ota, n pa nigba ti won ri i bi awon kan se yinbon pa okunrin eni odun mejidinlogoji kan toruko e n je Jeje Oni, ti omokunrin naa si wa ninu agbara eje titi to fi dagbere faye.

Gege bi iwadii Iwe Iroyin Yoruba, ise telo ni Jeje n se ni Ijoko, ibi ti soobu e wa ko jinna si aafin Oba Ogunseye tawon kan dana sun ni nnkan bii ose merin seyin.

Won ni o je enikan ti ko feran lati maa ra ounje je nita, eyi lo fa a to fi gbona ile lo l'Ojobo, Tosde, ti i se ojo kejo, osu yii, ni nnkan bii aago meta osan pelu awon ore e leyin tiyawo e pe e pe ounje osan ojo naa ti dele. Bi won se gbera ti won n lo sile ti Jeje n gbe ni Agoro ni won sakiyesi pe awon kan n tele awon.Bi ara se fu won ni won lo mu ki Jeje naa maa sare lori okada e to n wa, sugbon lojiji lawon eeyan naa bere si i rojo ibon si okada naa. Ese ni won ni ibon naa ti koko ba a to si subu, nibe ni awon ika naa ti rojo ibon si i ti won si gba emi e.

Loju-ese ti won ri i pe Jeje ti ku lawon eeyan naa sa lo ti won ko si ti i ri won titi di akoko yii. Sugbon ohun ta a tun gbo ni pe o pe tawon kan ti foju si omokunrin omo bibi ilu Ekiti naa lara, won ni o wa lara awon alatileyin Oba Ogunseye.

Okan lara awon tisele naa soju e to ba Iwe Iroyin Yoruba soro so pe okan lara awon onise owo ti soobu e ko jinna si ti Jeje loun, ore si lawon. Okunrin naa so pe Jeje pe oun pe kawon jo loo jeun osan nile lojo naa ni.

"Jeje lo wa okada lojo naa ti mo si wa leyin e. Ko pe ta a de Sawmill ti ko fi bee jinna sile e ni Agoro la sakiyesi pe awon kan n tele wa. Ohun kan ti mo gbo ni pe, 'Ara won ni, ara won ni', ti won si bere si i yinbon. Ibon ti won fee yin mo mi ti ko ba mi lo ba ore mi lese, to si subu, nibe ni won ti raaye dana ibon si i lara.

''Se ni mo loo sapamo sibi kan ti mo sa asala femi-in mi, nigba ti mo fi maa jade, awon ero ti pe le ore mi lori, bee lo wa ninu agbara eje. O ti ku patapata. Loju-ese ni mo ti lo si tesan awon olopaa ni Sango ti mo loo fi to won leti." A gbo pe Jeje lo kole to n gbe naa ni Agoro, gbogbo awon to mo on mo ise telo ni won sapejuwe e gege bii oniwa tutu, ohun ti won si n beere lowo ara won ni pe kin ni omokunrin naa se fawon to gbemi e lojiji yii.

Sugbon titi di akoko ti a n ko iroyin yii, okan awon olugbe Ijoko ko ti i bale nitori ko ti i pe ose merin tawon kan ti won pe ni omoleyin Oba Matanmi lo si aafin ti won si dana sun un, bee ni won ba opo nnkan je.

Alagba kan to n je Amos Jimoh to ba Iwe Iroyin Yoruba soro so pe ero okan awon ni pe latigba ti won ti dana sun aafin Ogunseye ni gbogbo e ti lo sile, laimo pe ko ti i tan ninu won. O ni ti Jeje ti won gba emi e lojiji yii je nnkan aburu nla.

Nigba ti akoroyin wa pe Muyiwa Adejobi to je agbenuso awon olopaa nipa isele naa, o ni owo awon ti ba enikan to n je Hakeem Oluomo, bo tile je pe awon ko ti i ka esun eni ti won pa si i lorun, sugbon owo te e lori pe won ba awon nnkan ija oloro lowo e.

Adejobi fi kun un pe awon ti bere iwadii lori eni ti won pa naa, bee lawon tun ti ko awon olopaa lo si agbegbe ohun ni Ijokoo. O waa seleri pe gbogbo awon to sise ibi naa lowo yoo te laipe.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Tuesday, April 28 @ 00:37:10 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Ofo-emi kan re o! Won yinbon pa Jeje n'Ijoko Ota" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: