Abala Yi Wa Lati EsinIslam Media :: http://esinislam.com/MediaYoruba URL Fun Itan Yi Ni: http://esinislam.com/MediaYoruba/modules.php?name=News&file=article&sid=1031 Lati Owo Akoroyin OlootuE ma ro iku ro Buhari oNibayi ti Buhari ti di aare, ayipada kankan ko jo wipe o le ba ile Yoruba nitori iwa aburu awon omo oduduwa si ara won. Se oro oselu, paapaa nile Yoruba, bii ogun ni. Nile yii lawon oloselu ti maa n ro iku ro ara won, won a si maa ro pe bi ota tabi alatako awon ba ku lawon yoo too le wole ibo, tabi tawon yoo too le wa ni ipo awon. Idi tawon oloselu kan ninu PDP se n ro iku ro Buhari ko yeeyan, ti won n ro pe ko ku nikan lo daa, ko ku lo le mu won wole. Ayo Fayose ni gomina ipinle Ekiti, sugbon bii igba toun gan-an lo n saaju awon ti won n ro pe ki Muhammadu Buhari yii ku laipe ojo ni. Won lo ti dagba, won ni ojo-ori re ti po ju, won ni ko si bo se le sejoba pelu ojo-ori bee, won ni ara re ko tun ya. Bee, gbogbo awon eeyan yii lo mo o, won mo pe oro Olorun ko ri bee. Nigba mi-in, bi a ba gbojule e pe igi gbigbe ni yoo wo;, o le je igi tutu ni yoo wo;, Olorun nikan lo mo ojo tiku yoo pa awon eda aye. Lona keji, igba akoko ko niyi ti eni to ti le lomo aadorin odun yoo dupo aare, ni Naijiria wa yii naa si ni. Lodun 1983 ti won n seto idibo lati yan aare, omo odun merinlelaaadorin (74) ni Obafemi Awolowo i se, oun lo si saaju egbe UPN, to n so pe ki gbogbo ilu dibo foun. Bee nigba ti Awolowo wa lomo aadota odun ni 1959, o ti gbe apoti bakan naa. Ni 1983 yii, omo odun mejidinlogorin (78) ni Nnamdi Azikwe i se lasiko ti won n se kampeeni ibo yii, oun lo dupo aare loruko egbe won, egbe NPP, bakan naa lo si ti dupo yii lodun 1959. Ogbon ori ati iriri pelu laakaye to jinle ni won fi n sejoba, bi eeyan ba si ti dagba to ni yoo ni awon nnkan wonyi si. Nidii eyi, ko si ohun to buru rara nibe bi Buhari ba fee sejoba, o ti ni iriri, o si ti logbon lori daadaa. Bee ni oro oselu ko gbodo la ki enikan maa ro iku si eni keji re lo, ki lo wa nibe, kin ni a fee gba nibe, e¯re¯ wo ni yoo je fun PDP bi Buhari ba ku, tabi Naijiria je ogun ile baba enikan ni, sebi gbogbo wa naa la ni in. Ati pe ohun ti ko ye awon oloselu ni pe bi enikan ba sejoba, o niye odun ti yoo lo ti elomiran yoo fi bo si i, bee ni Naijiria ko ni i tori e pare, eni to ba sejoba ni yoo kuro nibe, boya iku pa a ni o, tabi o lo saa tire tan, tabi won yo o kuro nile ijoba. Titi aye ni Naijiria yoo wa bi a ko ba fi owo ara wa ba a je, sugbon afi kawon oloselu yii mo pe gbogbo ipo ko ni yoo bo si won lowo, ki i se gbogbo igba ni awon yoo wa nibi kan, iran kan yoo maa lo, iran mi-in yoo maa bo ni, oselu ti a ba si n se ti a n ro iku ro ara wa, oselu ole ni, oselu ijekuje, ki i se ife araalu rara, ohun ti kaluku won yoo je ni won n wa. E ma foselu ba ilu yii je, e ma tori oselu ro iku ro enikeni, ko daa o, Olorun ko fe bee Koko: Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin Comments 💬 التعليقات
|