Ale Lo Maa N Fi Moto Gbe Iyawo Mi Wale Lati Ibi Ise Lalaale — Jimoh
 
Abala Yi Wa Lati
EsinIslam Media :: http://esinislam.com/MediaYoruba
 
URL Fun Itan Yi Ni:
http://esinislam.com/MediaYoruba/modules.php?name=News&file=article&sid=1194

 
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Ale Lo Maa N Fi Moto Gbe Iyawo Mi Wale Lati Ibi Ise Lalaale — Jimoh

Bi ejo ti okunrin birikila kan, Jimoh Alli, ro ni kootu ba se e tele pelu bo se so pe ale lo maa n gbe iyawo oun wale lati ibi ise lalaale, afaimo ni ko ni i je pe ale ohun lobinrin naa yoo ba lo gbeyin, iyen bi ile-ejo ba tu igbeyawo won ka.

Iyawo birikila yii, Titilayo Alli, lo ro kootu ibile Ojaba to wa ni Mapo, n'Ibadan, lati tu igbeyawo olodun mewaa to wa laarin oun ati oko re ka lojo Eti, (Fraide), to koja. O ni okunrin naa ki i se ojuse oko le oun atawon omo re lori, eyi to mu koun ko jade nile e ninu osu kejila, odun to koja. Sugbon oun ti waa ri i bayii pe igbese naa ko fi bee lagbara to, afi ki ile-ejo kuku tu igbeyawo awon ka patapata.

Ninu awijare re, oko iyawo so pe awawi lasan ni iyawo oun n se nitori gbogbo ojuse oko loun n se lori iyawo atawon omo oun ninu ile, ati pe nitori o n yan ale, ti ife okunrin naa si ti ko si i lori lo se pe ejo naa.
Gege bo se so, ''Lati odun to koja lo ti yowo-kowo. Won n pe bobo kan ni AY, oun lo maa n tele kiri. Leyin ti won ba jo se ohun to wu won tan, bobo AY yen lo maa n gbe e wale lale.

Mo maa n jeun nita kiri ni nitori iyawo mi ki i tete wole boro. Nigba ti mo ba dele ti mi o ba a nile, ti mo ti reti reti e ni okunrin yen yoo sese fi moto gbe e wale.

''Ti mo ba bi i leere pe ki lo wa laarin oun ati AY, aa ni ko si nnkan kan laarin awon. Oju mi bayii ni bobo yen yoo se pe e lori foonu nigba mi-in, pe nibo lo wa, iyawo mi a ni oun wa nile, bobo yen a waa ni ibi bayii bayii lawon wa tawon ti n se faaji, ko waa ba awon.'' Jimoh to n gbe opopona Liberty, lagbegbe Oke-Ado, n'Ibadan, fidi e mule pe lati nnkan bii osu mewaa seyin ni Titilayo ti ko jade nile oun pelu awon omo mejeeji tawon bi, ati pe obinrin naa lo n da bukaata won gbo latigba naa.

Bo tile je pe Titilayo ko soro nipa esun ale yiyan ti oko e fi kan an, obinrin onisowo yii so pe loooto lo ti fere to odun kan bayii toun ti jade nile oko oun, toun si da renti ile, sibe, oun ko ti i ni oko mi-in, o kan je pe ife okunrin toun bimo meji fun yii ti yo lokan oun patapata ni.

Bee lo fi Bibeli bura pe nnkan kan ko tun ni i da oun pelu Jimoh po mo lae.

Nigba to n sapejuwe iyawo e gege bii eni ti ko se e saaanu, okunrin mekaniiki yii so pe nigba ti foonu koko jade loun ko egberun lona aadota naira (N50,000) fun Titilayo pe ko fi ra kaadi ipe ori ero ibanisoro lati maa ta a, sugbon obinrin naa se owo ohun mokumoku pelu bo se so pe egbon oun kan loun ko o fun.

Sa, adajo kootu naa, Oloye Odunade Ademola, ti sun idajo sojo kesan-an, osu yii, iyen ojo Aje, (Monde), to n bo.


 

Koko: Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga


Comments 💬 التعليقات