Grace Atale Re Pa Oko e N'Iyana-Ipaja
 
Abala Yi Wa Lati
EsinIslam Media :: http://esinislam.com/MediaYoruba
 
URL Fun Itan Yi Ni:
http://esinislam.com/MediaYoruba/modules.php?name=News&file=article&sid=1271

 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Grace Atale Re Pa Oko e N'Iyana-Ipaja

Ko seni to le so pato ohun ti Lucky Bassey, eni odun mokandinlaaadota se fun iyawo re Grace, eni odun mokanlelogbon, ti ko se ro nnkan kan mi-in ro o ju pe ko da emi re legbodo lo pelu bo se fi obe idana dunbu re. Eyi lo mu kadajo ile-ejo majisireeti kan to wa l'EbuteMeta pase pe koun ati orekunrin re ti won jo gbimo-po seku pa oko re ohun si wa latimole ogba ewon to wa ni Ikoyi.

Gege bi Iwe Iroyin Yoruba se gbo, ni nnkan bii aago merin oru ojo keeedogbon, osu kin-in-ni, odun yii, nisele naa waye ni ojule ketalelogun, laduugbo Abari, n'Iyana-Ipaja, niluu Eko, iyen nigba ti Grace gbimo-po pelu orekunrin re to n je Benjamin Otu lati pa oko re ti won jo wa lati Akwa Ibom pelu obe idana. Ohun to si buru ju ninu oro naa ni pe oju oorun ni oko omobinrin yii wa tawon mejeeji fi pitu owo won.
Nise ni Benjamin di ese okunrin naa mu nigba ti Grace to fe nisu loka mu obe, to si fi re e lorun, koda omobinrin yii duro daadaa lati ri i pe elemii gba a ko too ke sawon araale.

Sugbon Olorun ti ko si leyin asebi lo je kawon olopaa ro o daadaa pe oro naa ki i soju lasan.

Nigba ti won si fi ma-mu-gari gbe Grace de Panti ni Yaba, o ni ki won se oun jeeje o. O ni ki i se oun nikan loun da ise ohun se, oun ati Benjamin lawon jo sise naa. Nigba tawon yen naa si gbe ore re de, iyen naa jewo pe loooto loro ri bee, sugbon ise esu ni.

Nigba ti agbenuso ijoba, Inspekito Godwin Agoi, n ka esun sawon afurasi odaran naa leti, esun igbimo-po lati sise ibi ati ipaniyan lo fi kan won. Iru iwa bayii ni Agoi so pe o lodi sofin ipinle Eko ti won sagbekale re lodun 2011, to si tun nijiya nla ninu pelu. O so siwaju pe oun maa fi eda iwe esun naa sowo si eka to n ri soro idajo nipinle Eko fun imoran to peye.

Nigba ti Adajo (Iyaafin) M.O. Olajuwon n gba si agbenuso ijoba naa lenu, o pase pe ki won loo fi awon afurasi odaran ohun satimole ogba ewon to wa ni Ikoyi titi ti won yoo fi gbo amoran latodo oludari to n ri soro igbejo nipinle Eko.

O waa sun igbejo lori esun naa sojo kokandinlogbon, osu kerin, odun yii.



 

Koko: Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo


Comments 💬 التعليقات