Bo Se Daa Niyen... Sugbon Kan Naa Lo Wa Nibe
 
Abala Yi Wa Lati
EsinIslam Media :: http://esinislam.com/MediaYoruba
 
URL Fun Itan Yi Ni:
http://esinislam.com/MediaYoruba/modules.php?name=News&file=article&sid=1326

 
Bo Se Daa Niyen... Sugbon Kan Naa Lo Wa Nibe

Bi eeyan ba ri ohun to n sele ni awon ile ijoba wa lasiko yii, okan onitohun yoo maa bale pe o da bii pe awon ijoba yii fee to ona to dara, awon oloselu kookan ti won ko moyato laarin oselu ati ijoba sise yoo yose to ba ya.

Sugbon awon ohun to n sele, ati bi awon eeyan naa se n seto ijoba won fihan pe nnkan yoo dara fun wa bo ba n ba bayii lo. Sanwo-Olu, gomina ipinle Eko, ra moto marundinlaaadoje (125), o fi okada marundinlogoji (35) ti i nidii, o ko o fawon olopaa ati awon agbofinro to ku, o ni ki won pin kinni naa laarin ara won, fun eto aabo to peye ni gbogbo ipinle re.

Bi oun ti n ko tire fun won, bee naa ni Dapo Abiodun ti ipinle Ogun naa ko ogorun-un moto, ati ogorun-un meji okada nla fawon olopaa odo tire naa, o ni ki awon naa fi maa seto aabo to peye. Ko si ohun ti eeyan le se ju ka ki awon gomina wonyi lo, paapaa lasiko ti ko sowo lowo ijoba pupo, to si je won sese tun de ile ijoba ni.
Sugbon won mo inira awon eeyan, won si ri iberu ati ifoya won pe nnkan ko dara. Bi awon olopaa ba fee ja, ti won ko ba ni irin ise nko, sebi awon odaran ati awon ajinigbe to wa niluu yii yoo kan maa tobi si i ni, ti won yoo si maa ba ise aburu won lo. Sugbon bi irinse gidi ba wa, ti moto to le sare daadaa wa, ko si ohun to yara ran awon olopaa wa lowo ju bee lo.

Sugbon kan to wa nibe ni pe se awon olopaa so pe awon kinni yii lo n je awon niya, se won so fun won pe nitori ti ko si moto lawon ko se sise awon. Bi won ba so bee, oro naa yoo dara bi awon gomina yii se se yii.

Sugbon ti won ko ba so bee fun won, to je awon idi mi-in lo n di won lowo, to je boya ariwo ti awon eeyan n pa pe awon ara Abuja lo n pase pe ki won ma mu Fulani, ki won ma fiya je Hausa fun won, koda nigba ti won ba ba won nidii iwa odaran, aa je pe ki i se iya moto lo n je won niyen, bi eeyan ba si fi gbogbo aye yii ra moto fun won, awon araalu ti won n rin jeeje won laago meje aabo si mejo ale lawon olopaa yoo maa sa kiri lati gba owo lowo won, ti won yoo ni awon mu won nibi ti won ti n rin irin-oru.

Nitori e lo se je ki i se moto nikan lawon gomina yii yoo ra, tabi iru awon inawo yii nikan ni won yoo maa se, won gbodo maa pe awon olori olopaa adugbo wonyi si koro, ki won jo soro, ki won si mo ohun to n sele loooto, iyen ni won yoo fi le mo ona ti won yoo gba lati koju isoro to ba wa.

Eyi ti won se yii daa o, ki i se pe ko dara, o tile daa gan-an ni. Bo ba je awon olopaa naa lo n gbabode, gbogbo aye yoo ri won bayii, won yoo mo pe ki i se awon gomina ni ko da si isoro won. Olorun yoo kuku mu alaafia ba wa nile Yoruba, ogun ajinigbe ko ni i ko wa lo.


 

Koko: Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu


Comments 💬 التعليقات