Oye Baba Adinni Fee Da Wahala Sile Laarin Awon Musulumi L’Osogbo
 
Abala Yi Wa Lati
EsinIslam Media :: http://esinislam.com/MediaYoruba
 
URL Fun Itan Yi Ni:
http://esinislam.com/MediaYoruba/modules.php?name=News&file=article&sid=646

 
Lati Owo Florence Babasola, Osogbo

Oye Baba Adinni Fee Da Wahala Sile Laarin Awon Musulumi L’Osogbo

Ti a ba n soro nipa awon ilu ti asa ati isembaye ti fun ni okiki, okan pataki ni ilu Osogbo ti i se olu-ilu ipinle Osun je. Yato si eyi, ni ti oro esin naa, o kere tan, iwadii fi han pe idameta ninu idamerin awon omo bibi ilu Osogbo ni won je elesin musulumi. Ko si ya eeyan lenu pelu bo se je pe Imaamu Agba patapata fun gbogbo ile Yoruba to fi mo Edo atipinle Delta, Sheikh Mustapha O. Ajisafe, wa lati ilu Osogbo.

Sugbon sa, o se ni laaanu pe mosalasi gbogbogbo ilu Osogbo to wa lorita Oja-Oba, niluu naa ko bojumu, se ni mosalasi naa to ti wa fun aimoye odun kan wa nibe lasan, ko si nnkan to ba igba mu ninu re.


Idi niyi ti igbimo Imaamu atawon musulumi niluu Osogbo se sepade, lojo kokandinlogun, osu keji odun to koja, ti won si gbe igbimo kan kale labe alaga, Alaaji Ajadi Adekilekun Badmus, ti won si fun won ni ise pataki lati se. Awon ise ohun ni lati ko mosalasi nla naa pelu atunse ibi to ye lona ti yoo ba ode oni mu; lati mojuto Yidi gbogbogbo ilu Osogbo; pipa owo wole fun mosalasi gbogbogbo ti ilu Osogbo; ati fifi awon eniyan to ba ye je oye esin musulumi.

Ni kete ti won se ifilole awon igbimo yii nile Alaaji Omidiran ni won bere ise. Gege bi a se gbo, pelu iranlowo owo ti igbimo yii n ri latodo Baba Omidiran, won bere kiko abala kan lara mosalasi naa, won se fensi yi i ka, bee ni won tun se awon ise pepeepe mi-in.

Ninu odun to koja, gege bi ise ti won gbe le igbimo naa lowo, won pinnu leyin ifikunlukun ati ase latodo Sheikh Mustapha Ajisafe lati fi okan pataki lara awon musulumi ilu Osogbo, Omooba Adeleke Oduola je oye Baba Adinni.

Eto ifinijoye yii ni won n se lowo to fi da bii eni pe nnkan fee daru, die lo si ku ki isele naa pin ilu Osogbo si meji, nitori nise lawon igbimo naa rora da ise duro lori atunko mosalasi naa, ti won so pe niwon igba ti won ti fi eeku ida le awon lowo, o ye ki awon le beere iku to pa baba awon.

Ori eleyii ni won wa tawon kan ti won pe ara won ni Igbimo Musulumi fi fon iwe laarin ilu Osogbo pe eekan omo bibi ilu Osogbo kan lo fee fa owo aago ise awon igbimo mosalasi naa seyin pelu bo se so pe oun ko faramo eni ti won fee fi joye ati pe oun ni elomi-in toun fe ko joye naa.

Lati tanmole soro yii, Iwe Iroyin Yoruba lo sodo Alaaji Adekilekun Badmus to je alaga igbimo ohun, Baba yii salaye pe leyin ti Baba Ajisafe sefilole igbimo awon, tawon si ti bere ise oniruuru ni eekan kan to tun je oloye esin fun ile Yoruba, Alaaji Olatunde Badmus ti gbogbo awon eeyan mo si Tuns deede so pe oko (farm) oun ni mosalasi gbogbogbo ilu Osogbo, ati pe oun ti ni igbimo toun yan ti yoo maa se awon ise mereerin ti Baba Ajisafe gbe fun awon.

Alaaji Bayo Salami lo si pinnu lati fun ni oye Baba Adinni ti ilu Osogbo tigbimo ti fun Omooba Oduola.

Leyin eyi lo tun waa so pe oun fee fi awon merin kan joye esin. Okan ninu awon oye yii ni oye Baba Adinni Osogbo, oye ti won ti fun omo ilu Osogbo kan tele ti oluware si ye ko wuye ninu osu to koja, sugbon ti won ni lati fagi le e nitori atako tawon kan se lai si idi pataki kan.

Igbese dida oye ti won fee je yii duro lo waa fa a ti ilu fi pin si meji. Eleyii ni yoo je eleekeji, bee ni won se nigba ti won fee fi Oloogbe Rasheed Igbalaye je oye esin, sugbon ti won fun elomi-in nigba yen. Se o waa to ki enikan deede so ara re di apase waa. Yato si eekan kan niluu Osogbo to kole si Powerline ti won lo ti nawo to le ni aadojo milionu naira (#150m) lori kiko abala kan ninu mosalasi yii, a o ti i ri olowo miiran to na kobo tabi da kobo si ise to n lo lowo yii.

Okan lara awon omo igbimo naa so pe yato si oye Baba Adinni yii, won ni Alaaji Tunde Badmus ti pinnu lati tun fun awon eeyan kan ni oye Aare Musulumi ilu Osogbo, Otun Baba Adinni ilu Osogbo atawon mi-in.

Baba Adekilekun fi kun oro tie pe gbogbo nnkan to n sele yii lo fa ifaseyin si ise to n lo lowo ni mosalasi gbogbogbo naa ni nnkan bii ose meloo seyin, eyi lo si fa ipade igbimo gbogbogbo musulumi ilu Osogbo nile Asiwaju ilu naa, iyen Alaaji Hamed Omidiran lojo kerindinlogun, osu kin-in ni, odun yii.

Nibi ipade naa la gbo pe won ti fi emi imoore ati igbekele kikun ninu igbimo Baba Adekilekun Badmus han, won si tun ro igbimo naa lati maa te siwaju ninu ise ti won gbe le won lowo.

Lara awon ti won wa nibi ipade ohun ni Ataoja tilu Osogbo, Oba Jimoh Olanipekun, Sheikh Ajisafe, Baba Omidiran, Alhaji Musa Animasahun, to je igbakeji Imaamu Agba, Alaaji Haron Adediran (Igbaketa Imaamu), Alaaji Ajadi Badmus, Alaaji Moniade (Olori Ratibi), Alaaji Sule Olawale (Olori Alasaru), Alaaji G.O. Salawu to je akowe igbimo mosalasi ati Alaaji Oreofero ati bee bee lo.

Iwe Iroyin Yoruba ko atejise ranse sori foonu Alaaji Olatunde Badmus lati gbo awijare tiwon lori esun ti won fi kan won ohun. Sugbon leyin wakati kan, iyen aago meji ku ogun iseju ni akoroyin ede oyinbo kan gbe foonu re fun akoroyin wa pe Komreedi Amitolu Shittu to je amugbalegbe fun Tuns fee ba a soro. Amitolu so pe ki Iwe Iroyin Yoruba mo iru iroyin ti yoo gbe jade, ati pe ki a ma se ba awon ti won ko ni i le soro toro ba di tile-ejo ni nnkan kan papo.

Lori oye Baba Adinni ti won fee fun Omooba Oduola, Amitolu so pe, Ko si omo ilu Osogbo kankan to le faramo on pe ki won fun Baba Oduola ni oye Baba Adinni, idi ni pe gbogbo awon omo re ni won ti di Kristeni, baba gan-an funra won ko je Musulumi, bee ni ko je Kristeni.

Eyi ti won ba fee se gan-an ni ki won so, oye Baba Adinni ki i se oye ti won kan le deede fun eeyan kan saa, e beere idi ti Baba Oduola fi fee joye naa ni tipatipa. Lojo ayeye ojoobi ti won se koja, se ni Pasito soosi kan n gbadura kikankikan nibe, so ye ko ri bee nile Musulumi.

Iwe Iroyin Yoruba koja si ile Omooba Oduola, Baba naa salaye pe, Musulumi ododo ni mi, mo si ti kopa ribiribi lori oro esin Musulumi niluu Osogbo, eleyii lo fa a ti Imaamu Agba Onilewura fi fun mi loye Babalaje Adinni nigba aye won, sugbon n ko je oye yii ti won fi ku. Nigba ti Baba Atanda di Imaamu Agba ti won si tu iwe kan an, won ko leta si mi pe se n ko ni i waa je oye ti Baba Onilewura fun mi ni, n ko je oye yen titi ti Baba Atanda fi ku. Nigba ti Baba Ajisafe debe, awon naa tun ko leta pe ki n waa je oye yii, idi ti n ko fi je e tele ni pe won ti fun mi ni Aare apapo ti Mubarakat Society of Nigeria, idi niyi ti mo fi n lora lati je oye nibomi-in. Sugbon nigba to ya, mo pinnu pe o ye ki n je oye ti won fun mi, emi ni mo waa pe Baba Ajisafe funra mi pe mo fee je oye ti won ni ki n je, sugbon to ba je pe ko ti i fun enikeni ni oye Baba Adinni ti ilu Osogbo ti Baba S. Kolapo je, mo ni o wu mi ju Babalaje lo.

Baba Ajisafe ni awon a loo pe awon igbimo awon jo lati wo o boya awon ko ti i fun elomi-in loye yen, Leyin eyi ni won fun mi ni leta gege bii Baba Adinni ti ilu Osogbo. Won ni ki n kowe pada ti mo ba faramo on, mo si ko leta pada si won pe mo faramo on, won waa so pe igba wo ni mo fee je e, mo ni lagbara Olorun, mo fee je e po mo ayeye ojoobi ti mo fee se lojo kejilelogun, osu kejila, odun to koja ni. Bayii la bere oniruuru igbese, awon asaaju esin wa sibi, a jo n soro.

Ohun ti mo koko ri ni pe lojo ti won pari adura laafin, Tunde Badmus wa nibe, o waa so nibe lojo yen pe ko le se e se fawon kan ti won fee joye. Oro yen bi mi ninu, mo waa so pe n ko je e mo.

Gbogbo awon Aafaa to wa l«Osogbo pata to je oloye esin lo wa sibi, to fi dori asoju Baba Imaamu. Won so fun mi pe ki n ma je ki ohunkohun da mi lokan ru, won ni Baba Imaamu agba atawon igbimo re lo ni ase ati agbara lati fun enikeni loye Adinni, niwon igba ti Ataoja ba ti fowo si i, to si ti je oba Musulumi. Emi naa gba leyin igba naa.

Won waa so nnkan kan lojo naa pe ti oye yen ko ba se e je pelu ayeye ojoobi mi, ki n maa se ojoobi lo, igba tawon ba pari aawo to wa laarin Tunde Badmus ati Baba Ajisafe, iyen Imaamu Agba(ati pe awon mo pe aawo wa laarin emi pelu re naa), nigba tawon ba pari gbogbo re, a a maa je oye Baba Adinni.

Ooto la ri ninu awon omo mi to je Kristeni, o si po ninu awon idile niluu Osogbo ti a ni Musulumi ati Kristieni. Iyawo mi merin ni won ti lo si Mecca, emi naa si ti lo leemeta ko too di pe agba de. L«Osogbo loni-in, ko sile eni ti e le de, atawon ti won n gbogun yii, ti e ko ni i ba Kristeni ninu awon omo won. Awon ti won gbogun yii naa le omo won nile nitori pe won se Kristeni.

Ile Baba Oduola ni Iwe Iroyin Yoruba wa ti ipe Alaaji Bayo Salami fi wole, ohun tawon naa so ni pe ki Iwe Iroyin Yoruba mo iru awon ti yoo gba iroyin lenu won, ki won ma je awon ti won ko ni i le yoju nigba toro ba beyin yo.

Laaaro ojo Fraide, ojo keeedogbon, osu to koja, akoroyin wa lo sodo Sheikh Ajisafe ni Ile Arikalamu. Baba naa salaye pe, Awa ti a je alakooso mosalasi ko mo nnkan kan nipa iwe ti won n fon kiri, onikaluku saa n se nnkan to wu u ni, won o si ko oro wa siwaju wa, oro ti ko ba si kan ni, eeyan ki i so o. Awa n ba ise tiwa lo, o digba ta a ba fee se nnkan ti won ba waa ni ka ma se e. Ko seni to di wa lowo, enikan o kowe si wa, won o si doju ko wa, ki la fe waa maa so.

Igba to ba ya, awon ti won n se gbun-gbun-gbun laarin ara won a ko oro wa siwaju wa, a ko le so pe bee ni tabi bee ko.«« Ni ti oye Baba Adinni to ye ko ti waye nipari odun to koja, Sheikh Ajisafe ni, E ma ba oro lo sibe yen, ohun gbogbo ti yanju nipa re. Ko si wahala kankan rara.




 

Koko: Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin


Comments 💬 التعليقات