Ija Iyawo Jonathan Ati Turai: Nibi Ti Nnkan Baje Fun Wa De Niyen O
 
Abala Yi Wa Lati
EsinIslam Media :: http://esinislam.com/MediaYoruba
 
URL Fun Itan Yi Ni:
http://esinislam.com/MediaYoruba/modules.php?name=News&file=article&sid=720

 
Lati Owo Ademola Adejare

Ija Iyawo Jonathan Ati Turai: Nibi Ti Nnkan Baje Fun Wa De Niyen O

Orisiirisii ni ohun ti a o maa ri nile yii, Olorun nikan lo si le ko wa yo. Awon eeyan ti won n so pe boya ni ijoba kan wa ti iwa ibaje re gbile to ti awon Jonathan yii ko puro, loooto ijoba jegudujera nijoba PDP lataaro ojo wa, sugbon ti aye Jonathan yii waa le igba kan si i.

Ko si si ohun to je ki iwa ibaje naa maa gbile ju pe awon ti won je olori ilu funra won ganan, iyen Jonathan ati iyawo re, iwa ibaje ko jinna si eyinkule won rara ni. won yoo si maa se awon kinni naa bii ti eni ti ko ni ojuti, tabi bii ti eni ti oro awon araalu ko ja mo nnkan kan leti won.


Nigba ti ijoba Jonathan so pe won gba ile kan bayii lowo Turai, iyawo Yar’adua ni 2011, gbogbo eeyan ni won so pe ko si ohun to dara to o, won ni to ba ti je Turai fi ona ti ko to gba ile naa ni, ki ijoba gba a lowo re, ko se nnkan kan.

Ohun ti gbogbo awon ti won so bee ro ni pe Jonathan ati ijoba re fee maa gbogun ti iwa ibaje ni. Sugbon nigba ti iroyin jade leyin naa pe oro ko ma ri bee, ile ti won gba lowo Turai, iyawo Jonathan funra e lo gba a o, enu ya gbogbo eni to gbo o ni, won si n so pe iru ki lawon omo Naijiria tun ha si yii.

Bo ba je elomi-in ni, bo ba je eni to beru oro awon araalu, nigba ti oro si waa di ariwo bee, sebi o ye ki won jawo ninu e ni, ki won si so pe awon ko se mo, tabi ki won wa iro kan pa pe Patience ko lo gba ile naa.

Sugbon won ko se kinni kan, kaka bee, nise niyawo Jonathan bere si i ran eegun apa, to si n so pe ko si eni to le ba oun so o ki ile naa ma je toun, o ni egbe oun lo ni ile, ko si si bi oun ko se ni i lo ile naa fun egbe.

Titi ti oro naa fi de ile-ejo, ti oro naa di wahala, awon eeyan yii ko jawo, bee ni won ko si sinmi leyin Turai.

Ose to koja yii nile-ejo waa da ejo naa, ti won ni Patience ko lo nile, Turai ni.

Adajo tie fi ogbon soro buruku ranse si iyawo Jonathan, bee eni to ba n soro buruku funyawo eni, oluwa re lo n ba wi.

O ni ki i se pe iyawo Jonathan fee lo ile naa fun idagbasoke ilu kankan ni ija to wa laarin oun ati Turai, o kan fee gba ile naa lowo e ko si lo o fun anfaani ara tire ni.

Eyi to waa buru ni pe nigba toro ba da bayii, awon eni ibi ti awon eeyan yii gba sise won yoo si maa gbe leyin won, won yoo ni ijoba lawon n sise fun, won yoo maa ba ole puro, won yoo maa puro pelu odale, won yoo maa ba ilu je won a ni awon n tun ilu se.

Ohun ti ko je ki orile-ede wa lo sibi kankan niyen, iwa ibaje lotun-un losi, todo awon olori wa gan-an lo si buru julo. Ki Naijiria too le bo ninu isoro to wa niwaju wa gbogbo yii, afi ki gbogbo awon olori ta a ni lasiko yii wabi gba lo. Onibaje ni gbogbo won!

Nibi Ti Nnkan Baje Fun Wa De Niyen O

Se eyin naa ti gbo ti Oyinbo, Oyinbo olomi-iye. Ki i kuku se oyinbo alawo-funfun o, awon eeyan lo fun un loruko yii, eeyan dudu ni, omo Ibo to n gbe nipinle Imo. Omode ni o, ko ti i ju omo ogun odun le die lo, sugbon nitori pe eeyan pupa ni ni won se n pe e ni Oyinbo, bo tile je pe ise buruku lawon ti won n pe e bee gbe fun un.

Obinrin kan ti won n pe ni Madam One thousand lo gba a sile, ise to si gba a si naa ni ise ko maa ba awon omobinrin keekeekee sun, awon omo ti won ti too loyun, ti won ko ju bii odun meeedogun si odun meeedogbon lo. Bi won ba ti ri omobinrin kan ti won tan an pe awon yoo fun un lowo, oun naa yoo gba lati loyun, Oyinbo yoo si ba a sun ti yoo fi loyun, won yoo si toju omo naa ti yoo fi bimo, bo ba ti bimo ni won yoo gba omo naa lowo re.

Ko sohun meji ti won n fi omo naa se ju pe won n ta won lo, awon ti won n ra omo ti mo ibe, won kan n lo sibe lati ra awon omo naa ni. Beeyan fe okunrin, yoo ri ra, beeyan fe obinrin, yoo ri ra. Ohun ti a n so ni pe awon eeyan yii ko nise meji ti won n se ju ki won sowo omo lo, won n wa awon ti won n bimo fun won, won si n ta awon omo naa.

Won ko bimo nitori pe ki won le to o tabi ki won le wo won dagba, won n bi won nitori ki won le ta won ni. Ati eni to n fun won loyun ati awon ti won n fun loyun, ati eni to ko gbogbo won jo, ko sohun meji ti won n se ju ise omo lo. Bi nnkan se ri ni Naijiria niyi o, bi emi ko se jo wa loju si omo ree, bi ise Olorun ko se je nnkan kan loju wa to niyen. Keeyan kan jokoo sibi kan ko si ni oun ko nise meji ju koun wa awon ti won yoo maa bimo lo, won yoo maa bimo, oun yoo si maa ta omo ti won ba bi. Awon eleyii ko niberu ijoba, won ko niberu eeyan, won ko niberu Oloun! Howu, nnkan buruku n sele si wa nile yii o.




 

Koko: Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin


Comments 💬 التعليقات